Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Mátíù 10:1-42

10  Nítorí náà, ó fi ọlá àṣẹ pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá, ó sì fún wọn ní ọlá àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí àìmọ́,+ láti lé àwọn wọ̀nyí jáde àti láti ṣe ìwòsàn gbogbo onírúurú òkùnrùn àti gbogbo onírúurú àìlera ara.  Orúkọ àwọn àpọ́sítélì méjìlá+ náà ni ìwọ̀nyí:+ Èkínní, Símónì, ẹni tí a ń pè ní Pétérù,+ àti Áńdérù+ arákùnrin rẹ̀; àti Jákọ́bù ọmọkùnrin Sébédè+ àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀;  Fílípì àti Bátólómíù;+ Tọ́másì+ àti Mátíù+ agbowó orí; Jákọ́bù ọmọkùnrin Áfíọ́sì,+ àti Tádéọ́sì;  Símónì tí í ṣe Kánánéánì,+ àti Júdásì Ísíkáríótù, ẹni tí ó dà á+ níkẹyìn.  Àwọn méjìlá wọ̀nyí ni Jésù rán jáde, ní fífún wọn ní àṣẹ ìtọ́ni wọ̀nyí pé:+ “Ẹ má ṣe lọ sí ojú ọ̀nà àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ má sì wọ ìlú ńlá Samaria kan;+  ṣùgbọ́n, dípò bẹ́ẹ̀, ẹ lọ léraléra sọ́dọ̀ àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n sọnù.+  Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa wàásù, pé, ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’+  Ẹ wo àwọn aláìsàn sàn,+ ẹ gbé àwọn ẹni tí ó ti kú dìde, ẹ mú kí àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, ẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.+  Ẹ má ṣe wá wúrà tàbí fàdákà tàbí bàbà sínú àpò ara àmùrè yín,+ 10  tàbí àsùnwọ̀n oúnjẹ fún ìrìnnà àjò náà, tàbí ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ méjì, tàbí sálúbàtà tàbí ọ̀pá; nítorí òṣìṣẹ́ yẹ fún oúnjẹ rẹ̀.+ 11  “Ìlú ńlá tàbí abúlé èyíkéyìí tí ẹ bá wọ̀, ẹ wá ẹni yíyẹ inú rẹ̀ kàn, kí ẹ sì dúró níbẹ̀ títí ẹ ó fi kúrò.+ 12  Nígbà tí ẹ bá ń wọ ilé, ẹ kí agbo ilé náà; 13  bí ilé náà bá sì yẹ, kí àlàáfíà tí ẹ fẹ́ fún un wá sórí rẹ̀;+ ṣùgbọ́n bí kò bá yẹ, kí àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ yín padà sọ́dọ̀ yín. 14  Ibì yòówù tí ẹnikẹ́ni kò bá ti gbà yín wọlé tàbí fetí sí ọ̀rọ̀ yín, nígbà tí ẹ bá ń jáde kúrò ní ilé yẹn tàbí ìlú ńlá yẹn, ẹ gbọn ekuru ẹsẹ̀ yín dànù.+ 15  Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Yóò ṣeé fara dà fún ilẹ̀ Sódómù+ àti Gòmórà ní Ọjọ́ Ìdájọ́ jù fún ìlú ńlá yẹn lọ.+ 16  “Wò ó! Mo ń rán yín jáde gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàárín àwọn ìkookò;+ nítorí náà, ẹ jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò,+ síbẹ̀ kí ẹ jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.+ 17  Ẹ máa ṣọ́ra yín lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn;+ nítorí wọn yóò fà yín lé àwọn kóòtù àdúgbò lọ́wọ́,+ wọn yóò sì nà yín lọ́rẹ́+ nínú àwọn sínágọ́gù wọn.+ 18  Họ́wù, wọn yóò fà yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba+ nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí+ fún wọn àti fún àwọn orílẹ̀-èdè. 19  Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí wọ́n bá fà yín léni lọ́wọ́, ẹ má ṣàníyàn nípa báwo tàbí kí ni ẹ ó sọ; nítorí a ó fi ohun tí ẹ ó sọ fún yín ní wákàtí yẹn;+ 20  nítorí kì í wulẹ̀ ṣe ẹ̀yin ni ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí Baba yín ni ó ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín.+ 21  Síwájú sí i, arákùnrin+ yóò fa arákùnrin lé ikú lọ́wọ́, àti baba ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ yóò sì dìde sí àwọn òbí, wọn yóò sì ṣe ikú pa wọ́n.+ 22  Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn ní tìtorí orúkọ mi;+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.+ 23  Nígbà tí wọ́n bá ṣe inúnibíni sí yín ní ìlú ńlá kan, ẹ sá lọ sí òmíràn;+ nítorí lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹ kì yóò parí àlọyíká+ àwọn ìlú ńlá Ísírẹ́lì lọ́nàkọnà títí Ọmọ ènìyàn yóò fi dé.+ 24  “Ọmọ ẹ̀yìn kò ju olùkọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹrú kò ju olúwa rẹ̀.+ 25  Ó tó fún ọmọ ẹ̀yìn láti dà bí olùkọ́ rẹ̀, àti ẹrú bí olúwa rẹ̀.+ Bí àwọn ènìyàn bá ti pe baálé ilé ní Béélísébúbù,+ mélòómélòó ni wọn yóò pe àwọn ti agbo ilé rẹ̀ bẹ́ẹ̀? 26  Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù wọn; nítorí kò sí nǹkan kan tí a bò mọ́lẹ̀ tí kì yóò di títú síta, kò sì sí àṣírí tí kì yóò di mímọ̀.+ 27  Ohun tí mo sọ fún yín nínú òkùnkùn, ẹ sọ ọ́ nínú ìmọ́lẹ̀; ohun tí ẹ sì gbọ́ tí a sọ wúyẹ́wúyẹ́, ẹ wàásù rẹ̀ láti orí ilé.+ 28  Ẹ má sì bẹ̀rù+ àwọn tí ń pa ara ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ọkàn; ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ bẹ̀rù ẹni+ tí ó lè pa àti ọkàn àti ara run nínú Gẹ̀hẹ́nà.+ 29  Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré?+ Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀.+ 30  Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà.+ 31  Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.+ 32  “Nígbà náà, olúkúlùkù ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ níní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi níwájú àwọn ènìyàn, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò jẹ́wọ́ níní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run; 33  ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi níwájú àwọn ènìyàn, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò sẹ́ níní ìsopọ̀+ pẹ̀lú rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run. 34  Ẹ má rò pé mo wá láti fi àlàáfíà lélẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé; èmi kò wá láti fi àlàáfíà+ lélẹ̀, bí kò ṣe idà. 35  Nítorí mo wá láti fa ìpínyà, láti pín ọkùnrin níyà sí baba rẹ̀, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, àti ọ̀dọ́ aya sí ìyá ọkọ+ rẹ̀. 36  Ní tòótọ́, àwọn ọ̀tá ènìyàn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn agbo ilé òun fúnra rẹ̀. 37  Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ni tí ó pọ̀ fún baba tàbí ìyá ju èyí tí ó ní fún mi, kò yẹ fún mi; ẹni tí ó bá sì ní ìfẹ́ni tí ó pọ̀ fún ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ju èyí tí ó ní fún mi, kò yẹ fún mi.+ 38  Ẹnì yòówù tí kò bá sì tẹ́wọ́ gba òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò yẹ fún mi.+ 39  Ẹni tí ó bá rí ọkàn rẹ̀, yóò pàdánù rẹ̀, ẹni tí ó bá sì pàdánù ọkàn rẹ̀ nítorí mi, yóò rí i.+ 40  “Ẹni tí ó bá gbà yín, gbà mí pẹ̀lú, ẹni tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni náà pẹ̀lú tí ó rán mi jáde.+ 41  Ẹni tí ó bá gba wòlíì kan nítorí pé ó jẹ́ wòlíì, yóò gba èrè wòlíì,+ ẹni tí ó bá sì gba olódodo nítorí pé ó jẹ́ olódodo, yóò gba èrè olódodo.+ 42  Àti pé ẹnì yòówù tí ó bá fún ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí ní kìkì ife omi tútù mu nítorí pé ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn, mo sọ fún yín ní tòótọ́, òun kì yóò pàdánù èrè rẹ̀ lọ́nàkọnà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé