Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Mátíù 1:1-25

1  Ìwé ọ̀rọ̀-ìtàn+ nípa Jésù Kristi, ọmọkùnrin Dáfídì,+ ọmọkùnrin Ábúráhámù:+   Ábúráhámù bí Ísákì;+ Ísákì bí Jékọ́bù;+ Jékọ́bù bí Júdà+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀;   Júdà bí Pérésì+ àti Síírà nípasẹ̀ Támárì; Pérésì bí Hésírónì;+ Hésírónì bí Rámù;+   Rámù bí Ámínádábù; Ámínádábù bí Náṣónì;+ Náṣónì bí Sálímọ́nì;+   Sálímọ́nì bí Bóásì nípasẹ̀ Ráhábù;+ Bóásì bí Óbédì nípasẹ̀ Rúùtù;+ Óbédì bí Jésè;+   Jésè bí Dáfídì+ ọba.+  Dáfídì bí Sólómọ́nì+ nípasẹ̀ aya Ùráyà;   Sólómọ́nì bí Rèhóbóámù;+ Rèhóbóámù bí Ábíjà; Ábíjà+ bí Ásà;+   Ásà bí Jèhóṣáfátì;+ Jèhóṣáfátì bí Jèhórámù;+ Jèhórámù bí Ùsáyà;   Ùsáyà bí Jótámù; Jótámù+ bí Áhásì;+ Áhásì bí Hesekáyà;+ 10  Hesekáyà bí Mánásè;+ Mánásè+ bí Ámọ́nì;+ Ámọ́nì+ bí Jòsáyà; 11  Jòsáyà+ bí Jekonáyà+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkónilọ sí Bábílónì.+ 12  Lẹ́yìn ìkónilọ sí Bábílónì Jekonáyà bí Ṣéálítíẹ́lì;+ Ṣéálítíẹ́lì bí Serubábélì;+ 13  Serubábélì bí Ábíúdù; Ábíúdù bí Élíákímù; Élíákímù bí Ásórì; 14  Ásórì bí Sádókù; Sádókù bí Ákímù; Ákímù bí Élíúdù; 15  Élíúdù bí Élíásárì; Élíásárì bí Mátáánì; Mátáánì bí Jékọ́bù; 16  Jékọ́bù bí Jósẹ́fù ọkọ Màríà, nípasẹ̀ ẹni tí a bí Jésù,+ ẹni tí a ń pè ní Kristi.+ 17  Nípa báyìí, gbogbo ìran náà, láti ọ̀dọ̀ Ábúráhámù títí di ìgbà Dáfídì, jẹ́ ìran mẹ́rìnlá, àti láti ọ̀dọ̀ Dáfídì títí di ìgbà ìkónilọ sí Bábílónì, jẹ́ ìran mẹ́rìnlá, àti láti ìgbà ìkónilọ sí Bábílónì títí di ìgbà Kristi, jẹ́ ìran mẹ́rìnlá. 18  Ṣùgbọ́n ìbí Jésù Kristi jẹ́ ní ọ̀nà yìí. Ní àkókò tí ìyá rẹ̀ Màríà jẹ́ àfẹ́sọ́nà+ Jósẹ́fù, a rí i pé ó lóyún láti ọwọ́ ẹ̀mí mímọ́+ ṣáájú kí a tó so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan. 19  Bí ó ti wù kí ó rí, Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ olódodo, tí kò sì fẹ́ sọ ọ́ di ìran àpéwò fún gbogbo ènìyàn,+ pète-pèrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀+ ní bòókẹ́lẹ́. 20  Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí ó ti fara balẹ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí, wò ó! áńgẹ́lì Jèhófà fara hàn án nínú àlá, ó wí pé: “Jósẹ́fù, ọmọkùnrin Dáfídì, má fòyà láti mú Màríà aya rẹ sí ilé, nítorí èyíinì tí ó lóyún rẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.+ 21  Yóò bí ọmọkùnrin kan, kí ìwọ sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù,+ nítorí òun yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀++ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”+ 22  Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ ní ti gidi, kí a lè mú èyíinì tí Jèhófà sọ+ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ ṣẹ,+ pé: 23  “Wò ó! Wúńdíá+ náà yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, wọn yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì,”+ èyí tí, nígbà tí a bá túmọ̀ rẹ̀, ó túmọ̀ sí, “Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú Wa.”+ 24  Nígbà náà ni Jósẹ́fù jí lójú oorun rẹ̀, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì Jèhófà ti darí rẹ̀, ó sì mú aya rẹ̀ sí ilé. 25  Ṣùgbọ́n kò bá a dàpọ̀+ títí ó fi bí ọmọkùnrin kan;+ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé