Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Málákì 4:1-6

4  “Nítorí, wò ó! ọjọ́ náà ń bọ̀ tí ń jó bí ìléru,+ gbogbo àwọn oníkùgbù àti gbogbo àwọn tí ń hùwà burúkú yóò sì dà bí àgékù pòròpórò.+ Ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò sì jẹ wọ́n run dájúdájú,” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, “tó bẹ́ẹ̀ tí kì yóò fi fi yálà gbòǹgbò tàbí ẹ̀tun+ sílẹ̀ fún wọn.  Oòrùn òdodo yóò sì ràn+ dájúdájú fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, pẹ̀lú ìmúniláradá ní ìyẹ́ apá+ rẹ̀; ẹ ó sì jáde lọ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì fi àtẹ́sẹ̀ talẹ̀ bí àwọn ọmọ màlúù àbọ́sanra.”+  “Ẹ ó sì tẹ àwọn ẹni burúkú mọ́lẹ̀ dájúdáju, nítorí wọn yóò dà bí erukutu lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní ọjọ́ náà tí èmi yóò gbé ìgbésẹ̀,”+ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.  “Ẹ rántí òfin Mósè ìránṣẹ́ mi, èyí tí mo fi pàṣẹ fún un ní Hórébù nípa gbogbo Ísírẹ́lì, àní àwọn ìlànà àti àwọn ìpinnu ìdájọ́.+  “Wò ó! Èmi yóò rán Èlíjà wòlíì+ sí yín ṣáájú dídé ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà.+  Òun yóò sì yí ọkàn-àyà àwọn baba padà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ, àti ọkàn-àyà àwọn ọmọ padà sọ́dọ̀ àwọn baba; kí n má bàa wá, kí n sì kọlu ilẹ̀ ayé ní ti tòótọ́ ní fífi í fún ìparun.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé