Málákì 3:1-18
3 “Wò ó! Èmi yóò rán ońṣẹ́+ mi, òun yóò sì tún ọ̀nà ṣe níwájú mi.+ Olúwa tòótọ́+ yóò sì wá sí tẹ́ńpìlì+ Rẹ̀ lójijì, ẹni tí ẹ ń wá, àti ońṣẹ́+ májẹ̀mú+ náà, ẹni tí ẹ ní inú dídùn sí.+ Wò ó! Dájúdájú, òun yóò wá,” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.+
2 “Ṣùgbọ́n ta ni ó lè fara da ọjọ́ dídé+ rẹ̀, ta sì ni ẹni tí yóò dúró nígbà tí ó bá fara hàn?+ Nítorí òun yóò dà bí iná ẹni tí ń yọ́ nǹkan mọ́+ àti gẹ́gẹ́ bí ọṣẹ ìfọṣọ+ alágbàfọ̀.+
3 Òun yóò sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń yọ́ fàdákà,+ tí ó sì ń fọ̀ ọ́ mọ́, yóò sì fọ àwọn ọmọ Léfì+ mọ́; yóò sì mú wọn mọ́ kedere bí wúrà+ àti bí fàdákà, dájúdájú, wọn yóò di àwọn ènìyàn tí ń mú ọrẹ ẹbọ+ ẹ̀bùn wá fún Jèhófà nínú òdodo.
4 Ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn Júdà àti ti Jerúsálẹ́mù yóò sì mú inú Jèhófà dùn ní ti tòótọ́,+ bí ti àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn àti bí ti àwọn ọdún ìgbàanì.+
5 “Dájúdájú, èmi yóò sì sún mọ́ yín fún ìdájọ́,+ èmi yóò sì di ẹlẹ́rìí+ yíyára kánkán lòdì sí àwọn oníṣẹ́ oṣó,+ àti lòdì sí àwọn panṣágà,+ àti lòdì sí àwọn tí ń ṣe ìbúra èké,+ àti lòdì sí àwọn tí ń lu jìbìtì sí owó ọ̀yà òṣìṣẹ́+ tí ń gbowó ọ̀yà, sí opó+ àti sí ọmọdékùnrin aláìníbaba,+ àti àwọn tí ń lé àtìpó+ dànù, nígbà tí wọn kò bẹ̀rù mi,”+ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.
6 “Nítorí èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.+ Ẹ̀yin sì jẹ́ ọmọ Jékọ́bù; ẹ kò wá sí òpin+ yín.
7 Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá yín ni ẹ ti yapa kúrò nínú àwọn ìlànà mi, ẹ kò sì pa wọ́n mọ́.+ Ẹ padà sọ́dọ̀ mi, dájúdájú, èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ yín,”+ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.
Ẹ sì ti wí pé: “Ọ̀nà wo ni àwa yóò gbà padà?”
8 “Ará ayé yóò ha ja Ọlọ́run lólè bí? Ṣùgbọ́n ẹ ń jà mí lólè.”
Ẹ sì ti wí pé: “Ọ̀nà wo ni a gbà jà ọ́ lólè?”
“Nínú ìdá mẹ́wàá àti nínú àwọn ọrẹ ni.
9 Ègún ni ẹ ń fi mí gún,+ èmi ni ẹ sì ń jà lólè—orílẹ̀-èdè yìí látòkè délẹ̀.
10 Ẹ mú gbogbo ìdá mẹ́wàá+ wá sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́, kí oúnjẹ bàa lè wà nínú ilé+ mi; kí ẹ sì jọ̀wọ́, dán mi wò nínú ọ̀ràn+ yìí,” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, “bóyá èmi kì yóò ṣí ibodè ibú omi ọ̀run+ fún yín, kí èmi sì tú ìbùkún dà sórí yín ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.”+
11 “Dájúdájú, èmi yóò sì bá ẹni tí ń jẹni run+ wí lọ́nà mímúná nítorí yín, òun kì yóò sì run èso ilẹ̀ fún yín,+ bẹ́ẹ̀ ni àjàrà inú pápá kì yóò já sí aláìléso fún yín,” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.
12 “Gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì pè yín ní aláyọ̀+ dájúdájú, nítorí ẹ̀yin fúnra yín yóò di ilẹ̀ inú dídùn,”+ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.
13 “Líle ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹ sọ sí mi,”+ ni Jèhófà wí.
Ẹ sì ti wí pé: “Kí ni a bá ara wa sọ lẹ́nì kìíní-kejì lòdì sí ọ?”+
14 “Ẹ ti wí pé, ‘Kò wúlò rárá láti sin Ọlọ́run.+ Èrè wo sì ni ó wà níbẹ̀ pé a pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe mọ́ sí i, àti pé a ti rìn ní ìdoríkodò ní tìtorí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun?+
15 Àti nísinsìnyí, a ń pe àwọn oníkùgbù ní aláyọ̀.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn olùhu ìwà burúkú ni a gbé ró.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n ti dán Ọlọ́run wò, wọ́n sì ń mú un jẹ.’”+
16 Ní àkókò yẹn, àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà+ bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì, olúkúlùkù pẹ̀lú alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, Jèhófà sì ń fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀.+ Ìwé ìrántí kan ni a sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ sílẹ̀ níwájú rẹ̀+ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà àti fún àwọn tí ń ronú lórí orúkọ+ rẹ̀.
17 “Dájúdájú, wọn yóò sì di tèmi,”+ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, “ní ọjọ́ náà nígbà tí èmi yóò mú àkànṣe dúkìá+ wá. Èmi yóò sì fi ìyọ́nú hàn sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń fi ìyọ́nú hàn sí ọmọ rẹ̀ tí ń sìn ín.+
18 Dájúdájú, ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú,+ láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.”+