Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Málákì 2:1-17

2  “Wàyí o, àṣẹ yìí wà fún yín, ẹ̀yin àlùfáà.+  Bí ẹ kò bá ní fetí sílẹ̀,+ bí ẹ kò bá sì ní fi ọkàn-àyà+ yín sí i láti fi ògo fún orúkọ mi,”+ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, “Dájúdájú, èmi yóò rán ègún+ sórí yín, èmi yóò sì gégùn-ún fún ìbùkún+ yín. Bẹ́ẹ̀ ni, mo tilẹ̀ ti gégùn-ún fún ìbùkún náà, nítorí pé ẹ kò fi í sí ọkàn-àyà yín.”  “Wò ó! Èmi yóò bá irúgbìn+ tí a fún wí lọ́nà mímúná ní tìtorí yín, èmi yóò sì fọ́n imí sójú yín, imí àwọn àjọyọ̀ yín; ní ti tòótọ́, ẹnì kan yóò sì kó yín lọ sídìí rẹ̀.  Ẹ̀yin yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni mo rán àṣẹ+ yìí sí yín, kí májẹ̀mú+ mi pẹ̀lú Léfì lè máa bá a lọ,”+ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.  “Ní ti májẹ̀mú mi, ó wà pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan tí ó jẹ́ ti ìyè àti ti àlàáfíà,+ mo sì ń fi wọ́n fún un, pẹ̀lú ìbẹ̀rù. Ó sì ń bá a lọ ní bíbẹ̀rù mi;+ bẹ́ẹ̀ ni, nítorí orúkọ mi, òun alára ni a kó ìpayà+ bá.  Àní òfin òtítọ́ sì wà ní ẹnu+ rẹ̀, a kò sì rí àìṣòdodo kankan ní ètè rẹ̀. Ó bá mi rìn ní àlàáfíà àti ní ìdúróṣánṣán,+ ó sì yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ padà kúrò nínú ìṣìnà.+  Nítorí ètè àlùfáà ni èyí tí ó yẹ kí ó pa ìmọ̀ mọ́, òfin sì ni ohun tí ó yẹ́ kí àwọn ènìyàn máa wá ní ẹnu+ rẹ̀; nítorí pé òun ni ońṣẹ́ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.+  “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin—ẹ ti yà kúrò ní ọ̀nà.+ Ẹ ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀ nínú òfin.+ Ẹ ti ba májẹ̀mú Léfì+ jẹ́,” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.  “Èmi pẹ̀lú, ní tèmi, dájúdájú, yóò sì sọ yín di ẹni tí a tẹ́ńbẹ́lú àti ẹni rírẹlẹ̀ sí gbogbo ènìyàn,+ bí ẹ kò ti pa àwọn ọ̀nà mi mọ́, ṣùgbọ́n tí ẹ ń fi ojúsàájú hàn nínú òfin.”+ 10  “Baba kan ha kọ́ ni gbogbo wa ní?+ Ọlọ́run kan ha kọ́ ni ó dá wa?+ Èé ṣe tí a fi ń ṣe àdàkàdekè sí ara wa lẹ́nì kìíní-kejì,+ ní sísọ májẹ̀mú àwọn baba ńlá wa di aláìmọ́?+ 11  Júdà ti ṣe àdàkàdekè, a sì ti ṣe ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ní Ísírẹ́lì àti ní Jerúsálẹ́mù;+ nítorí Júdà ti sọ ìjẹ́mímọ́ Jèhófà+ di aláìmọ́, èyí tí Òun nífẹ̀ẹ́, ó sì ti fi ọmọbìnrin ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè ṣe ìyàwó.+ 12  Jèhófà yóò ké olúkúlùkù ẹni tí ó ṣe é kúrò,+ ẹni tí ó jí kalẹ̀ àti ẹni tí ń dáhùn, kúrò nínú àwọn àgọ́ Jékọ́bù, àti ẹni tí ń mú ọrẹ ẹbọ+ ẹ̀bùn wá fún Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” 13  “Èyí sì ni ohun kejì ti ẹ ṣe, èyí tí ó yọrí sí fífi omijé bo pẹpẹ Jèhófà, pẹ̀lú ẹkún sísun àti ìmí ẹ̀dùn, tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi sí yíyíjú sí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn mọ́ tàbí níní ìdùnnú sí ohunkóhun láti ọwọ́ yín.+ 14  Ẹ sì ti wí pé, ‘Ní tìtorí kí ni?’+ Ní tìtorí èyí, pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ti jẹ́rìí láàárín ìwọ àti aya ìgbà èwe+ rẹ, ẹni tí ìwọ alára ti ṣe àdàkàdekè sí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ẹnì kejì rẹ àti aya májẹ̀mú+ rẹ. 15  Ẹnì kan sì wà tí kò ṣe é, níwọ̀n bí ó ti ní èyí tí ó ṣẹ́ kù lára ẹ̀mí náà. Kí sì ni ohun tí ẹni yẹn ń wá? Irú-ọmọ Ọlọ́run.+ Kí ẹ sì ṣọ́ ara yín ní ti ẹ̀mí+ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì ṣe àdàkàdekè+ sí aya ìgbà èwe rẹ̀. 16  Nítorí òun kórìíra ìkọ̀sílẹ̀,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí; “àti ẹni tí ó ti fi ìwà ipá bo ẹ̀wù+ rẹ̀ mọ́lẹ̀,” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí. “Kí ẹ sì ṣọ́ ara yín ní ti ẹ̀mí yín, kí ẹ má sì ṣe àdàkàdekè.+ 17  “Ẹ ti fi àwọn ọ̀rọ̀ yín dá Jèhófà lágara,+ ẹ sì ti wí pé, ‘Ọ̀nà wo ni a gbà dá a lágara?’ Nípa sísọ tí ẹ ń sọ pé, ‘Olúkúlùkù ẹni tí ó ń ṣe ohun búburú jẹ́ ẹni rere ní ojú Jèhófà, òun alára sì ní inú dídùn sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀’;+ tàbí, ‘Ibo ni Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo+ wà?’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé