Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Málákì 1:1-14

1  Ọ̀rọ̀ ìkéde: Ọ̀rọ̀ Jèhófà+ nípa Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Málákì:  “Mo nífẹ̀ẹ́ yín,”+ ni Jèhófà wí. Ẹ sì ti sọ pé: “Ọ̀nà wo ni o gbà nífẹ̀ẹ́ wa?”+ “Arákùnrin Jékọ́bù+ kọ́ ni Ísọ̀ í ṣe?” ni àsọjáde Jèhófà. “Ṣùgbọ́n mo nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù,+  Ísọ̀+ ni mo sì kórìíra; níkẹyìn, mo sì sọ àwọn òkè ńlá rẹ̀ di ahoro,+ ogún rẹ̀ ni mo sì sọ di ti àwọn akátá aginjù.”+  “Nítorí tí Édómù ń sọ pé, ‘A ti fọ́ wa túútúú, ṣùgbọ́n a ó padà, a ó sì kọ́ àwọn ibi tí a pa run dahoro,’ èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Àwọn, ní tiwọn, yóò kọ́ ọ; ṣùgbọ́n èmi, ní tèmi, yóò ya á lulẹ̀.+ Dájúdájú, àwọn ènìyàn yóò pè wọ́n ní “ìpínlẹ̀ ìwà burúkú” àti “àwọn ènìyàn tí Jèhófà ti dá lẹ́bi+ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”  Ojú yín yóò sì rí i, ẹ̀yin fúnra yín yóò sì sọ pé: “Kí Jèhófà di àgbégalọ́lá lórí ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì.”’”+  “‘Ọmọ, ní tirẹ̀, ń bọlá fún baba;+ ìránṣẹ́, sì ń bọlá fún ọ̀gá+ rẹ̀ atóbilọ́lá. Nítorí náà bí mo bá jẹ́ baba,+ ọlá mi dà?+ Bí mo bá sì jẹ́ Atóbilọ́lá Ọ̀gá, ẹ̀rù+ mi dà?’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí fún yín, ẹ̀yin àlùfáà tí ń tẹ́ńbẹ́lú orúkọ mi.+ “‘Ẹ sì ti wí pé: “Ọ̀nà wo ni a gbà tẹ́ńbẹ́lú orúkọ rẹ?”’  “‘Nípa mímú oúnjẹ+ eléèérí wá sórí pẹpẹ mi ni.’ “‘Ẹ sì ti wí pé: “Ọ̀nà wo ni a gbà sọ ìwọ di eléèérí?”’ “‘Nípa sísọ tí ẹ ń sọ pé: “Tábìlì+ Jèhófà jẹ́ ohun ìtẹ́ńbẹ́lú.”+  Nígbà tí ẹ bá sì mú ẹran tí ó fọ́jú wá fún fífi rúbọ: “Kì í ṣe ohun tí ó burú.” Nígbà tí ẹ bá sì mú ẹran tí ó yarọ tàbí aláìsàn wá: “Kì í ṣe ohun tí ó burú.”’”+ “Jọ̀wọ́, mú un wá sọ́dọ̀ gómìnà rẹ. Yóò ha ní inú dídùn sí ọ, tàbí yóò ha fi inú rere gbà ọ́?” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.  “Wàyí o, ẹ jọ̀wọ́, ẹ tu Ọlọ́run lójú,+ kí ó lè fi ojú rere+ hàn sí wa. Ọwọ́ yín ni èyí ti ṣẹlẹ̀. Yóò ha fi inú rere gba ẹnikẹ́ni nínú yín?” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí. 10  “Ta sì ni nínú yín tí yóò ti àwọn ilẹ̀kùn?+ Ẹ kò sì dá iná pẹpẹ mi—lásán.+ Èmi kò ní inú dídùn sí yín,” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, “èmi kò sì ní ìdùnnú+ nínú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn láti ọwọ́ yín.” 11  “Nítorí láti yíyọ oòrùn àní dé wíwọ̀ rẹ̀, orúkọ mi yóò tóbi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ ibi gbogbo ni a ó sì ti rú èéfín+ ẹbọ, a óò mú ọrẹ wá fún orúkọ mi, àní ẹ̀bùn+ tí ó mọ́; nítorí pé orúkọ mi yóò tóbi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,”+ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí. 12  “Ṣùgbọ́n ẹ ń sọ mi di aláìmọ́+ nípa sísọ tí ẹ ń sọ pé, ‘Tábìlì Jèhófà jẹ́ eléèérí, èso rẹ̀ sì jẹ́ ohun ìtẹ́ńbẹ́lú, oúnjẹ+ rẹ̀.’ 13  Ẹ sì ti wí pé, ‘Wò ó! Ẹ wo bí ìdánilágara+ rẹ̀ ti pọ̀ tó!’ ẹ sì ti mú kí a ṣítìmú sí i,” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí. “Ẹ sì ti mú ohun tí a fà ya wá, àti èyí tí ó yarọ, àti aláìsàn;+ bẹ́ẹ̀ ni, ẹ ti mú un wá bí ẹ̀bùn. Èmi ha lè ní ìdùnnú nínú rẹ̀ ní ọwọ́ yín bí?”+ ni Jèhófà wí. 14  “Ègún sì ni fún ẹni tí ń hùwà àlùmọ̀kọ́rọ́yí nígbà tí akọ ẹran wà nínú agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀, tí ó sì ń jẹ́ ẹ̀jẹ́, tí ó sì ń fi èyí tí ó ti di alábùkù rúbọ sí Jèhófà.+ Nítorí Ọba+ ńlá ni mí,” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, “orúkọ mi yóò sì jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé