Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Máàkù 9:1-50

9  Síwájú sí i, ó ń bá a lọ ní wíwí fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Àwọn kan wà lára àwọn tí wọ́n dúró níhìn-ín tí kì yóò tọ́ ikú wò rárá títí wọn yóò fi kọ́kọ́ rí i kí ìjọba Ọlọ́run dé ná nínú agbára.”+  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà, Jésù mú Pétérù àti Jákọ́bù àti Jòhánù lọ́wọ́, ó sì mú wọn wá sí orí òkè ńlá kan tí ó ga fíofío kan ní àwọn nìkan. A sì yí i padà di ológo níwájú wọn,+  ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ sì wá mọ́ yòò, ó funfun gbòò ju bí afọṣọ èyíkéyìí lórí ilẹ̀ ayé ti lè sọ wọ́n di funfun.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, Èlíjà pẹ̀lú Mósè fara hàn wọ́n, wọ́n sì ń bá Jésù sọ̀rọ̀.+  Ní ìdáhùnpadà, Pétérù sì wí fún Jésù pé: “Rábì, ó dára púpọ̀ fún wa láti wà níhìn-ín, nítorí náà, jẹ́ kí a gbé àgọ́ mẹ́ta nà ró, ọ̀kan fún ọ àti ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà.”+  Ní ti tòótọ́, kò mọ bí òun ì bá ṣe dáhùn padà, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gan-an.  Àwọsánmà sì gbára jọ, ó ṣíji bò wọ́n, ohùn+ kan sì wá láti inú àwọsánmà náà pé: “Èyí ni Ọmọ mi,+ olùfẹ́ ọ̀wọ́n; ẹ fetí sí i.”+  Lójijì, bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n wò yí ká, wọn kò sì rí ẹnì kankan pẹ̀lú wọn mọ́, àyàfi Jésù nìkan.+  Bí wọ́n ti ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti orí òkè ńlá náà, ó pa àṣẹ ìtọ́ni fún wọn lọ́nà tí ó ṣe kedere láti má ṣèròyìn+ ohun tí wọ́n rí fún ẹnikẹ́ni, títí di ẹ̀yìn ìgbà tí Ọmọ ènìyàn bá ti dìde kúrò nínú òkú.+ 10  Wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ náà sínú ọkàn-àyà, ṣùgbọ́n wọ́n jíròrò láàárín ara wọn ohun tí dídìde yìí kúrò nínú òkú túmọ̀ sí. 11  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bi í léèrè, pé: “Èé ṣe tí àwọn akọ̀wé òfin fi ń sọ pé Èlíjà+ gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá?”+ 12  Ó wí fún wọn pé: “Lóòótọ́, Èlíjà kọ́kọ́ wá, ó sì mú ohun gbogbo padà bọ̀ sípò;+ ṣùgbọ́n báwo ni ó ṣe jẹ́ pé a kọ̀wé rẹ̀ nípa Ọmọ ènìyàn pé ó gbọ́dọ̀ fara gba ìjìyà púpọ̀,+ kí a sì hùwà sí i bí aláìjámọ́ nǹkan kan?+ 13  Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, ní ti tòótọ́, Èlíjà+ ti wá, wọ́n sì ṣe gbogbo nǹkan tí wọ́n fẹ́ sí i, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nípa rẹ̀.”+ 14  Wàyí o, nígbà tí wọ́n wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù, wọ́n kíyè sí ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ó yí wọn ká àti àwọn akọ̀wé òfin tí ń bá wọn ṣe awuyewuye.+ 15  Ṣùgbọ́n gbàrà tí gbogbo ogunlọ́gọ̀ náà tajú kán rí i, wọ́n ta kìjí, àti pé, ní sísáré tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kí i. 16  Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Awuyewuye kí ni ẹ ń bá wọn ṣe?” 17  Ẹnì kan nínú ogunlọ́gọ̀ náà sì dá a lóhùn pé: “Olùkọ́, mo mú ọmọkùnrin mi wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ó ní ẹ̀mí tí kò lè sọ̀rọ̀;+ 18  ibikíbi tí ó bá sì ti gbá a mú, ó máa ń gbé e ṣánlẹ̀, a sì máa yọ ìfófòó lẹ́nu, a sì máa wa eyín pọ̀, a sì máa pàdánù okun rẹ̀. Mo sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ láti lé e jáde, ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é.”+ 19  Ní ìdáhùnpadà, ó wí fún wọn pé: “Ìran aláìnígbàgbọ́,+ báwo ni èmi yóò ti máa bá a lọ pẹ̀lú yín pẹ́ tó? Báwo ni èmi yóò ti máa fara dà fún yín pẹ́ tó? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi.”+ 20  Nítorí náà, wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní rírí i, kíákíá ni ẹ̀mí náà fi gìrì mú ọmọ náà, lẹ́yìn tí ó sì ti ṣubú lulẹ̀, ó ń yí gbiri káàkiri, ó ń yọ ìfófòó lẹ́nu.+ 21  Ó sì béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé: “Báwo ni ó ti pẹ́ tó tí èyí ti ń ṣẹlẹ̀ sí i?” Ó wí pé: “Láti ìgbà ọmọdé wá; 22  léraléra ni ó sì máa ń sọ ọ́ sínú iná àti sínú omi láti pa á run.+ Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun, ṣe ojú àánú sí wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.” 23  Jésù wí fún un pé: “Gbólóhùn ọ̀rọ̀ yẹn, ‘Bí ìwọ bá lè’! Họ́wù, ohun gbogbo lè rí bẹ́ẹ̀ fún ẹnì kan bí ẹni náà bá ní ìgbàgbọ́.”+ 24  Ní kíké jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, baba ọmọ kékeré náà sọ pé: “Mo ní ìgbàgbọ́! Ràn mí lọ́wọ́ níbi tí mo ti nílò ìgbàgbọ́!”+ 25  Wàyí o, ní kíkíyèsí pé ogunlọ́gọ̀ ń sáré bọ̀ wá pé lé wọn lórí, Jésù bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí lọ́nà mímúná,+ ó wí fún un pé: “Ìwọ ẹ̀mí tí kò lè sọ̀rọ̀, tí ó sì dití, mo pàṣẹ fún ọ, jáde kúrò lára rẹ̀, kí o má sì wọ inú rẹ̀ mọ́.” 26  Lẹ́yìn tí ó sì ti ké jáde tí ọ̀pọ̀ gìrì sì mú un léraléra, ó jáde;+ ó sì dà bí òkú, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn tí ó pọ̀ jù nínú wọ́n fi ń wí pé: “Ó ti kú!” 27  Ṣùgbọ́n Jésù di ọwọ́ rẹ̀ mú, ó sì gbé e dìde, ó sì dìde.+ 28  Nítorí náà, lẹ́yìn tí ó wọ ilé kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ níkọ̀kọ̀ pé: “Èé ṣe tí àwa kò lè lé e jáde?”+ 29  Ó sì wí fún wọn pé: “Irú èyí kò lè jáde nípasẹ̀ ohunkóhun àyàfi nípasẹ̀ àdúrà.”+ 30  Láti ibẹ̀, wọ́n kúrò, wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ la Gálílì kọjá, ṣùgbọ́n kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀. 31  Nítorí ó ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ń sọ fún wọn pé: “Ọmọ ènìyàn ni a ó fi lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́, wọn yóò sì pa á,+ ṣùgbọ́n, láìka pípa á sí, yóò dìde ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà.”+ 32  Bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò lóye àsọjáde náà, wọ́n sì ń fòyà láti bi í léèrè.+ 33  Wọ́n sì wá sí Kápánáúmù. Wàyí o, nígbà tí ó wà nínú ilé, ó bi wọ́n léèrè pé: “Kí ni ẹ ń jiyàn lé lórí lójú ọ̀nà?”+ 34  Wọ́n dákẹ́, nítorí lójú ọ̀nà, wọ́n ti jiyàn láàárín ara wọn lórí ẹni tí ó tóbi jù.+ 35  Nítorí náà, ó jókòó, ó sì pe àwọn méjìlá náà, ó sì wí fún wọn pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́, kí ó jẹ́ ẹni ìkẹyìn nínú gbogbo yín àti òjíṣẹ́ gbogbo yín.”+ 36  Ó sì mú ọmọ kékeré kan, ó mú un dúró ní àárín wọn, ó sì fi àwọn apá rẹ̀ yí i ká, ó sì wí fún wọn pé:+ 37  “Ẹnì yòówù tí ó bá gba ọ̀kan nínú irúfẹ́ àwọn ọmọ kéékèèké bẹ́ẹ̀ nítorí orúkọ mi, gbà mí; ẹnì yòówù tí ó bá sì gbà mí, kò gba èmi nìkan, ṣùgbọ́n àti ẹni tí ó rán mi jáde pẹ̀lú.”+ 38  Jòhánù wí fún un pé: “Olùkọ́, a rí ọkùnrin kan tí ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípa lílo orúkọ rẹ, a sì gbìyànjú láti dí i lọ́wọ́,+ nítorí pé kò bá wa rìn.”+ 39  Ṣùgbọ́n Jésù wí pé: “Ẹ má ṣe gbìyànjú láti dí i lọ́wọ́, nítorí kò sí ẹni tí yóò ṣe àwọn iṣẹ́ agbára ní orúkọ mi tí yóò lè tètè kẹ́gàn mi;+ 40  nítorí ẹni tí kò bá lòdì sí wa, wà fún wa.+ 41  Nítorí ẹnì yòówù tí ó bá fún yín ní ife+ omi mu nítorí ìdí náà pé ẹ jẹ́ ti Kristi,+ lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, kì yóò pàdánù èrè rẹ̀ lọ́nàkọnà. 42  Ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí tí wọ́n gbà gbọ́ kọsẹ̀, yóò sàn fún un bí a bá gbé ọlọ irúfẹ́ èyí tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ máa ń yí kọ́ ọrùn rẹ̀, kí a sì gbé e sọ sínú òkun ní ti gidi.+ 43  “Bí ọwọ́ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀ pẹ́nrẹ́n, gé e kúrò; ó sàn fún ọ láti wọ inú ìyè ní aláàbọ̀ ara ju kí o lọ pẹ̀lú ọwọ́ méjì sínú Gẹ̀hẹ́nà, sínú iná tí kò ṣeé pa.+ 44  —— 45  Bí ẹsẹ̀ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò; ó sàn fún ọ láti wọ inú ìyè ní arọ+ ju kí a gbé ọ pẹ̀lú ẹsẹ̀ méjì sọ sínú Gẹ̀hẹ́nà.+ 46  —— 47  Bí ojú rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, sọ ọ́ nù;+ ó sàn fún ọ láti wọ ìjọba Ọlọ́run ní olójú kan ju kí a gbé ọ pẹ̀lú ojú méjì sọ sínú Gẹ̀hẹ́nà,+ 48  níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí a kì í sì í pa iná náà.+ 49  “Nítorí a gbọ́dọ̀ fi iná dun olúkúlùkù bí iyọ̀.+ 50  Iyọ̀ dára púpọ̀; ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá sọ okun rẹ̀ nù pẹ́nrẹ́n, kí ni ẹ ó fi mú òun fúnra rẹ̀ dùn?+ Ẹ ní iyọ̀+ nínú ara yín, kí ẹ sì pa àlàáfíà+ mọ́ láàárín ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé