Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Máàkù 8:1-38

8  Ní ọjọ́ wọnnì, nígbà tí ogunlọ́gọ̀ ńlá kan tún ń bẹ, tí wọn kò sì ní nǹkan kan láti jẹ, ó fi ọlá àṣẹ pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì wí fún wọn pé:+  “Àánú+ ogunlọ́gọ̀ náà ń ṣe mí, nítorí pé ó ti di ọjọ́ mẹ́ta báyìí tí wọ́n ti wà pẹ̀lú mi, tí wọn kò sì ní nǹkan kan láti jẹ;  bí mo bá sì ní láti rán wọn lọ sí ilé wọn ní gbígbààwẹ̀, okun wọn yóò tán ní ojú ọ̀nà. Ní tòótọ́, àwọn kan lára wọn wá láti ibi jíjìnnàréré.”  Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dá a lóhùn pé: “Láti ibo ni ẹnikẹ́ni níhìn-ín ní ibi àdádó yìí ti lè fi ìṣù búrẹ́dì bọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí yó?”+  Síbẹ̀, ó ń bá a lọ láti béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ìṣù búrẹ́dì mélòó ni ẹ ní?” Wọ́n wí pé: “Méje.”+  Ó sì fún ogunlọ́gọ̀ náà ní ìtọ́ni láti rọ̀gbọ̀kú sórí ilẹ̀, ó sì mú ìṣù búrẹ́dì méje náà, ó dúpẹ́,+ ó bù wọ́n, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti fi fúnni, wọ́n sì fi wọ́n fún ogunlọ́gọ̀ náà.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n ní ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀; àti pé, lẹ́yìn sísúre sí ìwọ̀nyí, ó sọ fún wọn pẹ̀lú láti fi ìwọ̀nyí fúnni.+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n jẹ, wọ́n sì yó, wọ́n sì kó àṣẹ́kùsílẹ̀ èébù jọ, ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ ìpèsè méje.+  Síbẹ̀, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọkùnrin wà níbẹ̀. Níkẹyìn, ó rán wọn lọ.+ 10  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó wọ ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wá sí àwọn apá Dámánútà.+ 11  Níhìn-ín, àwọn Farisí jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣe awuyewuye, wọ́n ń wá àmì kan láti ọ̀run wá lọ́wọ́ rẹ̀, láti dán an wò.+ 12  Nítorí náà, ó kérora gidigidi+ nínú ẹ̀mí rẹ̀, ó sì wí pé: “Èé ṣe tí ìran yìí fi ń wá àmì kan? Lóòótọ́ ni mo wí, A kì yóò fi àmì kankan fún ìran yìí.”+ 13  Pẹ̀lú èyíinì, ó fi wọ́n sílẹ̀, ó tún wọkọ̀, ó sì lọ sí èbúté òdì-kejì. 14  Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́, wọ́n gbàgbé láti kó ìṣù búrẹ́dì dání, wọn kò sì ní nǹkan kan pẹ̀lú wọn nínú ọkọ̀ ojú omi àyàfi ìṣù búrẹ́dì kan ṣoṣo.+ 15  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pa àṣẹ ìtọ́ni fún wọn lọ́nà tí ó ṣe kedere, ó sì wí pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti ìwúkàrà Hẹ́rọ́dù.”+ 16  Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ba ara wọn jiyàn lẹ́nì kìíní-kejì lórí òtítọ́ náà pé wọn kò ní ìṣù búrẹ́dì kankan.+ 17  Ní kíkíyèsí èyí, ó wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń jiyàn lórí níní tí ẹ kò ní ìṣù búrẹ́dì kankan?+ Ṣé ẹ kò tíì róye síbẹ̀, kí ẹ sì lóye ìtúmọ̀ rẹ̀ ni? Ṣé ọkàn-àyà yín pòkúdu nínú lílóye ni?+ 18  ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ní ojú, ṣé ẹ kò ríran ni; àti pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ní etí, ṣé ẹ kò gbọ́ran ni?’+ Ẹ kò ha sì rántí, 19  nígbà tí mo bu ìṣù búrẹ́dì márùn-ún+ fún ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin, mélòó ni ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ èébù tí ẹ kó jọ?” Wọ́n wí fún un pé: “Méjìlá.”+ 20  “Nígbà tí mo bu méje fún ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọkùnrin, mélòó ni iye ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ ìpèsè àwọn èébù tí ẹ kó jọ?” Wọ́n sì wí fún un pé: “Méje.”+ 21  Pẹ̀lú èyíinì, ó wí fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò tíì lóye ìtúmọ̀ rẹ̀ síbẹ̀?”+ 22  Wàyí o, wọ́n gúnlẹ̀ ní Bẹtisáídà. Níhìn-ín ni àwọn ènìyàn ti mú ọkùnrin afọ́jú kan wá bá a, wọ́n sì pàrọwà fún un pé kí ó fọwọ́ kàn+ án. 23  Ó sì di ọwọ́ ọkùnrin afọ́jú náà mú, ó mú un jáde sẹ́yìn òde abúlé náà, àti pé, lẹ́yìn tí ó tutọ́+ sí ojú rẹ̀, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ìwọ ha rí ohunkóhun bí?” 24  Ọkùnrin náà sì gbé ojú sókè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Mo rí àwọn ènìyàn, nítorí mo ṣàkíyèsí àwọn ohun tí ó jọ igi, ṣùgbọ́n wọ́n ń rìn káàkiri.” 25  Lẹ́yìn náà, ó tún gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú ọkùnrin náà, ọkùnrin náà sì ríran kedere, a sì mú un padà bọ̀ sípò, ó sì ń rí ohun gbogbo ní ketekete. 26  Nítorí náà, ó rán an lọ sí ilé, wí pé: “Ṣùgbọ́n má ṣe wọ abúlé.”+ 27  Wàyí o, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí àwọn abúlé Kesaréà Fílípì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ léèrè ní ọ̀nà, ní sísọ fún wọn pé: “Ta ni àwọn ènìyàn ń sọ pé mo jẹ́?”+ 28  Wọ́n sọ fún un pé: “Jòhánù Oníbatisí,+ àti àwọn mìíràn, Èlíjà,+ síbẹ̀ àwọn mìíràn, Ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.”+ 29  Ó sì bi wọ́n léèrè pé: “Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin, ta ni ẹ sọ pé mo jẹ́?” Ní ìdáhùn, Pétérù sọ fún un pé: “Ìwọ ni Kristi náà.”+ 30  Látàrí ìyẹn, ó fi àìyẹhùn pàṣẹ fún wọn láti má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni nípa òun.+ 31  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn pé Ọmọ ènìyàn gbọ́dọ̀ fara gba ọ̀pọ̀ ìjìyà, kí àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin sì kọ̀ ọ́ tì, kí a sì pa á,+ kí ó sì dìde ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà.+ 32  Ní tòótọ́, àìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀ ni ó fi ń sọ gbólóhùn yẹn. Ṣùgbọ́n Pétérù mú un lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí lọ́nà mímúná.+ 33  Ó yí padà, ó bojú wo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì bá Pétérù wí lọ́nà mímúná, ó sì wí pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì, nítorí kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.”+ 34  Wàyí o, ó pe ogunlọ́gọ̀ náà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.+ 35  Nítorí ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là yóò pàdánù rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá pàdánù ọkàn rẹ̀ nítorí èmi àti ìhìn rere yóò gbà á là.+ 36  Ní ti gidi, àǹfààní wo ni ó jẹ́ fún ènìyàn kan láti jèrè gbogbo ayé, kí ó sì pàdánù ọkàn rẹ̀?+ 37  Ní ti gidi, kí ni ènìyàn kan yóò fi fúnni ní pàṣípààrọ̀ fún ọkàn rẹ̀?+ 38  Nítorí ẹnì yòówù tí ó bá tijú èmi àti àwọn ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panṣágà àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, Ọmọ ènìyàn pẹ̀lú yóò tijú+ rẹ̀ nígbà tí ó bá dé nínú ògo Baba rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì mímọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé