Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Máàkù 7:1-37

7  Wàyí o, àwọn Farisí àti àwọn kan lára àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n ti wá láti Jerúsálẹ́mù kóra jọ yí i ká.+  Nígbà tí wọ́n sì rí i pé àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń fi ọwọ́ ẹlẹ́gbin jẹ oúnjẹ wọn, èyíinì ni, àwọn tí a kò fọ̀+  nítorí àwọn Farisí àti gbogbo àwọn Júù kì í jẹun láìjẹ́ pé wọ́n fọ ọwọ́ wọn títí dé ìgúnpá, wọ́n ń di òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn ènìyàn ìgbà àtijọ́ mú ṣinṣin,  àti pé, nígbà tí wọ́n bá ti ọjà dé, wọn kì í jẹun láìjẹ́ pé wọ́n wẹ ara wọn mọ́ nípasẹ̀ ìbùwọ́n; ọ̀pọ̀ òfin àtọwọ́dọ́wọ́+ mìíràn sì wà tí wọ́n ti gbà láti dì mú ṣinṣin, àwọn ìbatisí àwọn ife àti àwọn orù àti àwọn ohun èlò bàbà;+  nítorí náà, àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin wọ̀nyí béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Èé ṣe tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kì í hùwà ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti àwọn ènìyàn ìgbà àtijọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń fi ọwọ́ ẹlẹ́gbin jẹ oúnjẹ wọn?”+  Ó wí fún wọn pé: “Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú nípa ẹ̀yin alágàbàgebè, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé,+ ‘Àwọn ènìyàn yìí ń fi ètè wọn bọlá fún mi, ṣùgbọ́n ọkàn-àyà wọn jìnnà réré sí mi.+  Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́.’+  Ní pípa àṣẹ Ọlọ́run tì, ẹ̀yin di òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti ènìyàn mú ṣinṣin.”+  Síwájú sí i, ó ń bá a lọ ní sísọ fún wọn pé: “Ẹ fi ọgbọ́n féfé pa àṣẹ+ Ọlọ́run tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan láti di òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín mú ṣinṣin. 10  Fún àpẹẹrẹ, Mósè wí pé, ‘Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ,’+ àti pé, ‘Ẹni tí ó bá kẹ́gàn baba tàbí ìyá, kíkú ni kí ó kú.’+ 11  Ṣùgbọ́n ẹ wí pé, ‘Bí ènìyàn kan bá sọ fún baba rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ pé: “Ohun yòówù tí mo ní nípa èyí tí o fi lè jẹ àǹfààní lára mi jẹ́ kọ́bánì,+ (èyíinì ni, ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́+ fún Ọlọ́run,)”’— 12  ẹ kò jẹ́ kí ó ṣe ẹyọ ohun kan mọ́ fún baba rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀,+ 13  ẹ sì tipa báyìí sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run+ di aláìlẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nípasẹ̀ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín tí ẹ fi léni lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ nǹkan+ tí ó fara jọ èyí ni ẹ sì ń ṣe.” 14  Nítorí náà, ní pípe ogunlọ́gọ̀ náà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún wọn pé: “Ẹ fetí sí mi, gbogbo yín, kí ẹ sì lóye ìtúmọ̀ rẹ̀.+ 15  Kò sí ohun kan láti òde ara ènìyàn tí ó kọjá sínú rẹ̀ tí ó lè sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin; ṣùgbọ́n ohun tí ń jáde wá láti inú ènìyàn ni àwọn ohun tí ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin.”+ 16  —— 17  Wàyí o, nígbà tí ó ti kúrò lọ́dọ̀ ogunlọ́gọ̀ náà wọ inú ilé kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bi í léèrè nípa àpèjúwe náà.+ 18  Nítorí náà, ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin pẹ̀lú ha jẹ́ aláìmòye bí ti wọn?+ Ṣé ẹ kò mọ̀ pé kò sí ohun kan láti òde tí ń kọjá sínú ènìyàn tí ó lè sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin, 19  níwọ̀n bí kò ti kọjá sínú ọkàn-àyà rẹ̀, bí kò ṣe sínú ìfun rẹ̀, a sì kọjá síta sínú ihò ẹ̀gbin?”+ Nípa báyìí, ó polongo pé gbogbo oúnjẹ mọ́.+ 20  Síwájú sí i, ó wí pé: “Èyíinì tí ń jáde wá láti inú ènìyàn ni ohun tí ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin;+ 21  nítorí láti inú, láti inú ọkàn-àyà àwọn ènìyàn,+ ni àwọn èrò tí ń ṣeni léṣe ti ń jáde wá: àgbèrè,+ olè jíjà, ìṣìkàpànìyàn,+ 22  panṣágà, ojúkòkòrò,+ àwọn iṣẹ́ ìwà burúkú, ẹ̀tàn, ìwà àìníjàánu,+ ojú tí ń ṣe ìlara, ọ̀rọ̀ òdì, ìrera, àìlọ́gbọ́n-nínú. 23  Gbogbo ohun burúkú wọ̀nyí ń jáde wá láti inú, wọ́n sì ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin.”+ 24  Ó dìde láti ibẹ̀, ó sì lọ sínú ẹkùn ilẹ̀ Tírè àti Sídónì.+ Ó sì wọ ilé kan, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa rẹ̀. Síbẹ̀, kò lè bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí;+ 25  ṣùgbọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ní ẹ̀mí àìmọ́ gbọ́ nípa rẹ̀, ó sì wá, ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 26  Obìnrin náà jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì, ará Foníṣíà ti Síríà; ó sì ń rọ̀ ọ́ ṣáá pé kí ó lé ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò lára ọmọbìnrin òun.+ 27  Ṣùgbọ́n ó bẹ̀rẹ̀ nípa sísọ fún un pé: “Kọ́kọ́ jẹ́ kí àwọn ọmọ yó ná, nítorí kò tọ́ kí a mú búrẹ́dì àwọn ọmọ,+ kí a sì sọ ọ́ sí àwọn ajá kéékèèké.”+ 28  Bí ó ti wù kí ó rí, ní ìfèsìpadà, ó wí fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, sà, síbẹ̀ àwọn ajá kéékèèké lábẹ́ tábìlì a sì máa jẹ́ nínú èérún+ ti àwọn ọmọ kéékèèké.”+ 29  Látàrí ìyẹn, ó sọ fún un pé: “Nítorí sísọ èyí, máa lọ; ẹ̀mí èṣù náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.”+ 30  Nítorí náà, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó sì bá+ ọmọ kékeré náà tí ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn, ẹ̀mí èṣù náà sì ti jáde lọ. 31  Wàyí o, bí ó ti ń padà bọ̀ láti inú ẹ̀kun ilẹ̀ Tírè, ó la Sídónì kọjá lọ sí òkun Gálílì gòkè la àárín àwọn ẹ̀kun ilẹ̀ Dekapólì+ kọjá. 32  Níhìn-ín ni wọ́n ti mú ọkùnrin adití kan tí ó sì ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ wá bá a, wọ́n sì pàrọwà fún un pé kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e.+ 33  Ó sì mú un lọ kúrò lọ́dọ̀ ogunlọ́gọ̀ náà ní òun nìkan, ó sì ki àwọn ìka rẹ̀ bọ àwọn etí ọkùnrin náà àti pé, lẹ́yìn tí ó tutọ́, ó fọwọ́ kan ahọ́n rẹ̀.+ 34  Ní gbígbé ojú rẹ̀ sókè sí ọ̀run,+ ó mí kanlẹ̀,+ ó sì wí fún un pé: “Éfátà,” èyíinì ni, “Là.” 35  Tóò, agbára ìgbọràn rẹ̀ ṣí,+ ìṣòro ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ bí ó ti yẹ. 36  Pẹ̀lú èyíinì, ó pàṣẹ fún wọn láti má sọ fún ẹnikẹ́ni;+ ṣùgbọ́n bí ó ṣe túbọ̀ ń pàṣẹ fún wọn tó, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe túbọ̀ ń pòkìkí rẹ̀ tó.+ 37  Ní tòótọ́, háà+ ṣe wọ́n lọ́nà tí ó ṣe àrà ọ̀tọ̀ jù lọ, wọ́n sì wí pé: “Ó ti ṣe ohun gbogbo dáadáa. Ó tilẹ̀ ń mú kí àwọn adití gbọ́ràn, kí àwọn aláìlèsọ̀rọ̀ sì sọ̀rọ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé