Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Máàkù 6:1-56

6  Ó sì lọ kúrò níbẹ̀, ó sì wá sí ìpínlẹ̀ ìbí rẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀ lé e.+  Nígbà tí ó di sábáàtì, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni nínú sínágọ́gù; háà sì ṣe iye tí ó pọ̀ jù lára àwọn tí ń fetí sílẹ̀, wọ́n sì wí pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí ti rí nǹkan wọ̀nyí?+ Èé sì ti ṣe tí a fi ní láti fún ọkùnrin yìí ní ọgbọ́n yìí, tí irúfẹ́ àwọn iṣẹ́ agbára bẹ́ẹ̀ sì fi di ṣíṣe láti ọwọ́ rẹ̀?  Èyí ni káfíńtà náà+ ọmọkùnrin Màríà+ àti arákùnrin Jákọ́bù+ àti Jósẹ́fù àti Júdásì àti Símónì,+ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àwọn arábìnrin rẹ̀ sì wà pẹ̀lú wa níhìn-ín, àbí wọn kò sí?” Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọsẹ̀ lára rẹ̀.+  Ṣùgbọ́n Jésù ń bá a lọ ní sísọ fún wọn pé: “A kì í ṣàìbọlá fún wòlíì kan àyàfi ní ìpínlẹ̀ ìbí rẹ̀+ àti láàárín àwọn ìbátan rẹ̀ àti ní ilé òun fúnra rẹ̀.”+  Nítorí náà, kò lè ṣe iṣẹ́ agbára kankan níbẹ̀ àyàfi kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé díẹ̀ lára àwọn aláìsàn, ó sì wò wọ́n sàn.  Ní tòótọ́, ó ṣe kàyéfì nípa àìnígbàgbọ́ wọn. Ó sì lọ káàkiri sí àwọn abúlé náà ní àlọyíká, ó ń kọ́ni.+  Wàyí o, ó fi ọlá àṣẹ pe àwọn méjìlá náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ rírán wọn jáde ní méjì méjì,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fún wọn ní ọlá àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí àìmọ́.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó pa àṣẹ ìtọ́ni fún wọn láti má ṣe gbé nǹkan kan dání fún ìrìnnà àjò náà àyàfi ọ̀pá nìkan, kí ó má ṣe sí búrẹ́dì, kí ó má ṣe sí àsùnwọ̀n oúnjẹ,+ kí ó má ṣe sí owó bàbà nínú àpò ara àmùrè wọn,+  ṣùgbọ́n kí wọ́n de sálúbàtà mọ́ ẹsẹ̀, kí wọ́n má sì wọ ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ méjì.+ 10  Síwájú sí i, ó wí fún wọn pé: “Ibì yòówù tí ẹ bá ti wọ ilé kan,+ ẹ dúró síbẹ̀ títí ẹ ó fi jáde kúrò ní ibẹ̀.+ 11  Níbikíbi tí ibì kan kò bá sì ti gbà yín tàbí gbọ́ ọ̀rọ̀ yín, nígbà tí ẹ bá ń jáde kúrò níbẹ̀, ẹ gbọn ìdọ̀tí tí ó wà lábẹ́ ẹsẹ̀ yín dànù, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn.”+ 12  Nítorí náà, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì wàásù kí àwọn ènìyàn bàa lè ronú pìwà dà;+ 13  wọn a sì máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù púpọ̀ jáde,+ wọn a sì fi òróró+ pa àwọn aláìsàn, wọn a sì wò wọ́n sàn.+ 14  Wàyí o, ó dé etí-ìgbọ́ Ọba Hẹ́rọ́dù, nítorí orúkọ Jésù di mímọ̀ fún gbogbo gbòò, àwọn ènìyàn sì ń wí pé: “Jòhánù olùbatisí ni a ti gbé dìde kúrò nínú òkú, ní tìtorí ìyẹn sì ni àwọn iṣẹ́ agbára fi ń ṣe nínú rẹ̀.”+ 15  Ṣùgbọ́n àwọn mìíràn ń wí pé: “Èlíjà ni.”+ Síbẹ̀, àwọn mìíràn ń wí pé: “Wòlíì kan tí ó dà bí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì ni.”+ 16  Ṣùgbọ́n nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́ èyí, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Jòhánù tí mo bẹ́ lórí, ẹni yìí ni a ti gbé dìde.”+ 17  Nítorí Hẹ́rọ́dù fúnra rẹ̀ ránṣẹ́ jáde, ó sì fi àṣẹ ọba mú Jòhánù, ó sì dè é nínú ẹ̀wọ̀n ní tìtorí Hẹrodíà aya Fílípì arákùnrin rẹ̀, nítorí ó ti gbé e níyàwó.+ 18  Nítorí Jòhánù ti sọ léraléra fún Hẹ́rọ́dù pé: “Kò bófin mu fún ọ láti ní aya arákùnrin rẹ.”+ 19  Ṣùgbọ́n Hẹrodíà di kùnrùngbùn+ sí i, ó sì ń fẹ́ pa á, ṣùgbọ́n kò lè ṣe bẹ́ẹ̀.+ 20  Nítorí Hẹ́rọ́dù bẹ̀rù+ Jòhánù, ó mọ̀ pé ó jẹ́ olódodo àti ènìyàn mímọ́;+ ó sì pa á mọ́ láìséwu. Lẹ́yìn gbígbọ́+ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ohun tí yóò ṣe sì rú u lójú púpọ̀, síbẹ̀ ó ń bá a lọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀. 21  Ṣùgbọ́n ọjọ́ tí ó wọ̀+ dé, nígbà tí Hẹ́rọ́dù se àsè oúnjẹ alẹ́ ní ọjọ́ ìbí+ rẹ̀ fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ onípò gíga jù lọ àti àwọn ọ̀gágun àti àwọn ẹni iwájú pátápátá ní Gálílì. 22  Ọmọbìnrin Hẹrodíà yìí gan-an sì wọlé wá, ó sì jó, ó sì mú inú Hẹ́rọ́dù àti àwọn tí wọ́n rọ̀gbọ̀kú+ pẹ̀lú rẹ̀ dùn. Ọba wí fún omidan náà pé: “Béèrè fún ohun yòówù tí o bá fẹ́ lọ́wọ́ mi, èmi yóò sì fi í fún ọ.” 23  Bẹ́ẹ̀ ni, ó búra fún un pé: “Ohun yòówù tí o bá béèrè lọ́wọ́ mi, èmi yóò fi í fún ọ,+ títí kan ìdajì ìjọba mi.”+ 24  Ó sì jáde lọ, ó sì wí fún ìyá rẹ̀ pé: “Kí ni kí èmi béèrè fún?” Ó wí pé: “Orí Jòhánù olùbatisí.”+ 25  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó wọlé pẹ̀lú ìṣekánkán lọ sọ́dọ̀ ọba, ó sì ṣe ìbéèrè rẹ̀, pé: “Mo fẹ́ kí o fún mi ní orí Jòhánù Oníbatisí nínú àwo pẹrẹsẹ ní báyìí-báyìí.” 26  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi, síbẹ̀ ọba kò fẹ́ ṣàìkà á sí, nítorí àwọn ìbúra àti àwọn tí wọ́n rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì náà.+ 27  Nítorí náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ọba rán ẹ̀ṣọ́kùnrin kan lọ, ó sì pàṣẹ fún un láti gbé orí rẹ̀ wá. Ó sì lọ, ó sì bẹ́ ẹ lórí nínú ẹ̀wọ̀n,+ 28  ó sì gbé orí rẹ̀ wá nínú àwo pẹrẹsẹ, ó sì gbé e fún omidan náà, omidan náà sì gbé e fún ìyá rẹ̀.+ 29  Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n wá, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀, wọ́n sì tẹ́ ẹ sínú ibojì ìrántí kan.+ 30  Àwọn àpọ́sítélì sì kóra jọpọ̀ síwájú Jésù, wọ́n sì ròyìn fún un, gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n sì ti fi kọ́ni.+ 31  Ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, ẹ̀yin fúnra yín, ní ẹ̀yin nìkan sí ibi tí ó dá,+ kí ẹ sì sinmi díẹ̀.”+ Nítorí ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ń wá tí wọ́n sì ń lọ, wọn kò sì ní àkókò kankan tí ọwọ́ dilẹ̀, àní láti jẹ oúnjẹ.+ 32  Nítorí náà, wọ́n gbéra lọ nínú ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi tí ó dá ní àwọn nìkan.+ 33  Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn rí wọn tí wọ́n ń lọ, ọ̀pọ̀ sì mọ̀ nípa rẹ̀, àti láti gbogbo àwọn ìlú ńlá náà, wọ́n jùmọ̀ fi ẹsẹ̀ sáré lọ sí ibẹ̀, wọ́n sì ṣáájú wọn.+ 34  Tóò, ní jíjáde, ó rí ogunlọ́gọ̀ ńlá, ṣùgbọ́n àánú+ wọ́n ṣe é, nítorí wọ́n dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.+ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.+ 35  Ní báyìí o, wákàtí ọjọ́ ti lọ, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Àdádó ni ibí, wákàtí ọjọ́ sì ti lọ nísinsìnyí.+ 36  Rán wọn lọ, kí wọ́n lè lọ sí eréko àti àwọn abúlé tí ń bẹ ní àyíká, kí wọ́n sì ra nǹkan fún ara wọn láti jẹ.”+ 37  Ní ìfèsìpadà, ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ẹ fún wọn ní nǹkan láti jẹ.” Látàrí èyí, wọ́n wí fún un pé: “Ṣé kí a lọ ra àwọn ìṣù búrẹ́dì tí iye owó rẹ̀ tó igba owó dínárì, kí a sì fi wọ́n fún àwọn ènìyàn náà láti jẹ?”+ 38  Ó wí fún wọn pé: “Ìṣù búrẹ́dì mélòó ni ẹ ní? Ẹ lọ wò ó!” Lẹ́yìn rírí i dájú, wọ́n wí pé: “Márùn-ún, yàtọ̀ sí ẹja méjì.”+ 39  Ó sì fún gbogbo ènìyàn náà ní ìtọ́ni láti rọ̀gbọ̀kú ní ẹgbẹẹgbẹ́+ sórí koríko tútù.+ 40  Wọ́n sì fi ara lélẹ̀ ní àwùjọ-àwùjọ ọlọ́gọ́rùn-ún àti aláàádọ́ta.+ 41  Wàyí o, ní mímú ìṣù búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo òkè ọ̀run, ó sì súre,+ ó sì bu+ àwọn ìṣù búrẹ́dì náà sí wẹ́wẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, kí àwọn wọ̀nyí bàa lè gbé wọn síwájú àwọn ènìyàn náà; ó sì pín ẹja méjì náà fún gbogbo wọn. 42  Nítorí náà, gbogbo wọ́n jẹ, wọ́n sì yó;+ 43  wọ́n sì kó èébù jọ, ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá, yàtọ̀ sí àwọn ẹja náà. 44  Síwájú sí i, àwọn tí wọ́n jẹ nínú àwọn ìṣù búrẹ́dì náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin.+ 45  Láìjáfara, ó sì ṣe é ní ọ̀ranyàn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọ́n sì lọ ṣáájú sí èbúté òdì-kejì síhà Bẹtisáídà, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ rán ogunlọ́gọ̀ náà lọ.+ 46  Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí ó ti sọ fún wọn pé ó dìgbòóṣe, ó lọ sí òkè ńlá kan láti gbàdúrà.+ 47  Alẹ́ ti lẹ́ wàyí, ọkọ̀ ojú omi náà sì wà ní àárín òkun, ṣùgbọ́n ó wà ní òun nìkan lórí ilẹ̀.+ 48  Nígbà tí ó sì rí i pé wọ́n dojú kọ ìṣòro+ nínú títukọ̀ wọn, nítorí ẹ̀fúùfù ṣọwọ́ òdì sí wọn, ní nǹkan bí ìṣọ́ kẹrin òru, ó wá síhà ọ̀dọ̀ wọn, ó ń rìn lórí òkun; ṣùgbọ́n ó ní ìtẹ̀sí láti ré wọn kọjá. 49  Nígbà tí wọ́n tajú kán rí i tí ó ń rìn lórí òkun, wọ́n ronú pé: “Ìran abàmì kan ni!” wọ́n sì ké sókè.+ 50  Nítorí gbogbo wọ́n rí i, wọ́n sì dààmú. Ṣùgbọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ mọ́kànle, èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.”+ 51  Ó sì gòkè sínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú wọn, ẹ̀fúùfù náà sì rọlẹ̀. Látàrí èyí, wọ́n ṣe kàyéfì gidigidi nínú ara wọn,+ 52  nítorí wọn kò tíì mòye ìtúmọ̀ àwọn ìṣù búrẹ́dì náà, ṣùgbọ́n ọkàn-àyà wọn ń bá a lọ nínú ìpòkúdu ní lílóye.+ 53  Nígbà tí wọ́n sì sọdá sórí ilẹ̀, wọ́n wọ Jẹ́nẹ́sárẹ́tì, wọ́n sì dá ọkọ̀ òkun ró sí itòsí.+ 54  Ṣùgbọ́n gbàrà tí wọ́n jáde kúrò nínú ọkọ̀ ojú omi náà, àwọn ènìyàn dá a mọ̀, 55  wọ́n sì sáré yí ká gbogbo ẹkùn ilẹ̀ yẹn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àkéte gbé àwọn tí ń ṣòjòjò káàkiri lọ sí ibi tí wọ́n gbọ́ pé ó wà. 56  Níbikíbi tí ó bá sì ti wọ àwọn abúlé tàbí àwọn ìlú ńlá tàbí eréko,+ wọn a gbé àwọn aláìsàn sí àwọn ibi ọjà, wọ́n a sì rọ̀ ọ́ kí wọ́n lè fọwọ́ kan+ ìṣẹ́tí+ ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ lásán. Gbogbo àwọn tí wọ́n sì fọwọ́ kàn án ni a mú lára dá.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé