Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Máàkù 5:1-43

5  Tóò, wọ́n dé ìhà kejì òkun, sí ilẹ̀ àwọn ará Gérásà.+  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn tí ó jáde kúrò nínú ọkọ̀ ojú omi ni ọkùnrin kan tí ó wà lábẹ́ agbára ẹ̀mí àìmọ́ wá pàdé rẹ̀ láti àárín àwọn ibojì ìrántí.+  Ibùgbé rẹ̀ wà láàárín àwọn ibojì náà; àti pé títí di àkókò yẹn, kò sí ẹnì kan rárá tí ó lè dè é pinpin, àní pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n pàápàá,  nítorí ọ̀pọ̀ ìgbà ni a ti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n dè é, ṣùgbọ́n òun a já ẹ̀wọ̀n náà pàrà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ náà a sì já sí wẹ́wẹ́ ní ti gidi; kò sì sí ẹnì kan tí ó ní okun láti ṣèkáwọ́ rẹ̀.  Nígbà gbogbo ṣáá, ní òru àti ní ọ̀sán, ni ó máa ń ké jáde ní àwọn ibojì àti àwọn òkè ńlá, ó sì máa ń fi àwọn òkúta ya ara rẹ̀ yánnayànna.  Ṣùgbọ́n nígbà tí ó tajú kán rí Jésù ní òkèèrè, ó sáré, ó sì wárí fún un,  àti pé, nígbà tí ó ti ké jáde pẹ̀lú ohùn rara,+ ó wí pé: “Kí ní pa tèmi tìrẹ pọ̀, Jésù, Ọmọ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ?+ Mo fi Ọlọ́run mú kí o wá sábẹ́ ìbúra+ pé kí o má ṣe mú mi joró.”+  Nítorí tí ó ti ń sọ fún un pé: “Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́.”+  Ṣùgbọ́n ó bẹ̀rẹ̀ sí béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó sì wí fún un pé: “Orúkọ mi ni Líjíónì,+ nítorí a pọ̀.”+ 10  Ó sì pàrọwà fún un ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti má ṣe rán àwọn ẹ̀mí náà jáde kúrò ní ilẹ̀ náà.+ 11  Wàyí o, ọ̀wọ́ ńlá àwọn ẹlẹ́dẹ̀+ ń jẹun níbẹ̀ ní òkè ńlá náà.+ 12  Nítorí náà, wọ́n pàrọwà fún un, pé: “Rán wa lọ sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, kí a lè wọ inú wọn.” 13  Ó sì gbà wọ́n láyè. Pẹ̀lú èyíinì, àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà jáde, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà; ọ̀wọ́ ẹran náà sì tú pùú sáré ré bèbè ọ̀gbun náà kọjá sínú òkun, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì wọn, wọ́n sì kú sómi nínú òkun náà ní ọ̀kan tẹ̀ lé èkejì.+ 14  Ṣùgbọ́n àwọn darandaran tí ń dà wọ́n sá lọ, wọ́n sì ròyìn rẹ̀ nínú ìlú ńlá àti ní eréko náà; àwọn ènìyàn sì wá láti wo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀.+ 15  Nítorí náà, wọ́n wá bá Jésù, wọ́n sì rí i tí ọkùnrin tí ó jẹ́ òǹdè ẹ̀mí èṣù jókòó, ó wọṣọ, ó sì wà nínú èrò inú rẹ̀ yíyèkooro, ọkùnrin yìí tí ó ti ní líjíónì; ẹ̀rù sì bà wọ́n. 16  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn tí wọ́n ti rí i ṣèròyìn fún wọn bí èyí ṣe ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin náà tí ó jẹ́ òǹdè ẹ̀mí èṣù àti nípa àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà. 17  Nítorí náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pàrọwà fún un láti lọ kúrò ní àwọn àgbègbè wọn.+ 18  Wàyí o, bí ó ti ń wọ ọkọ̀ ojú omi, ọkùnrin tí ó jẹ́ òǹdè ẹ̀mí èṣù tẹ́lẹ̀ rí bẹ̀rẹ̀ sí pàrọwà fún un kí ó lè máa bá a lọ ní wíwà pẹ̀lú rẹ̀.+ 19  Bí ó ti wù kí ó rí, kò gbà fún un, ṣùgbọ́n ó wí fún un pé: “Lọ sí ilé lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ,+ kí o sì ròyìn fún wọn gbogbo ohun tí Jèhófà+ ti ṣe fún ọ àti àánú+ tí ó ní fún ọ.” 20  Ó sì lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pòkìkí ní Dekapólì+ gbogbo ohun tí Jésù ṣe fún un, gbogbo ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì.+ 21  Lẹ́yìn tí Jésù tún ti sọdá padà nínú ọkọ̀ ojú omi sí èbúté òdì-kejì, ogunlọ́gọ̀ ńlá kóra jọpọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì wà lẹ́bàá òkun.+ 22  Wàyí o, ọ̀kan lára àwọn alága sínágọ́gù, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jáírù, wá, nígbà tí ó sì tajú kán rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀,+ 23  ó sì pàrọwà fún un ní ọ̀pọ̀ ìgbà, pé: “Ọmọbìnrin mi kékeré wà ní ipò tí ó légbá kan. Ìwọ yóò ha jọ̀wọ́ wá, kí o sì gbé ọwọ́+ lé e kí ara rẹ̀ lè dá, kí ó sì yè.”+ 24  Látàrí ìyẹn, ó bá a lọ. Ogunlọ́gọ̀ ńlá sì ń tẹ̀ lé e, wọ́n sì há a gádígádí.+ 25  Wàyí o, obìnrin kan wà tí ó ń jìyà lọ́wọ́ ìṣàn ẹ̀jẹ̀+ fún ọdún méjìlá,+ 26  ọ̀pọ̀ oníṣègùn+ sì ti mú ọ̀pọ̀ ìrora bá a, ó sì ti ná gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀, kò sì ṣe é láǹfààní ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, ó burú sí i. 27  Nígbà tí ó gbọ́ àwọn nǹkan nípa Jésù, ó wá láti ẹ̀yìn nínú ogunlọ́gọ̀ náà, ó sì fọwọ́ kan+ ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀; 28  nítorí ó ń sọ ṣáá pé: “Bí mo bá fọwọ́ kan ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ lásán, ara mi yóò dá.”+ 29  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ gbẹ fáú, ó sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé a ti mú òun lára dá nínú àìsàn burúkú náà.+ 30  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pẹ̀lú, Jésù mọ̀ dájú nínú ara rẹ̀ pé agbára+ ti jáde láti ara òun, ó sì yíjú padà láàárín ogunlọ́gọ̀ náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Ta ní fọwọ́ kan ẹ̀wù àwọ̀lékè mi?”+ 31  Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: “Ìwọ rí ogunlọ́gọ̀ tí ń há ọ gádígádí,+ ìwọ ha sì sọ pé, ‘Ta ní fọwọ́ kàn mí?’” 32  Bí ó ti wù kí ó rí, ó ń wò yí ká láti rí obìnrin tí ó ti ṣe èyí. 33  Ṣùgbọ́n obìnrin náà, tí jìnnìjìnnì ti bá, tí ó sì ń wárìrì, bí ó ti mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí òun, ó wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo òtítọ́ náà fún un.+ 34  Ó wí fún un pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà,+ kí o sì ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn burúkú tí ń ṣe ọ́.”+ 35  Nígbà tí ó ṣì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn ọkùnrin kan láti ilé alága sínágọ́gù wá, wọ́n sì wí pé: “Ọmọbìnrin rẹ kú! Èé ṣe tí o tún fi ń kó ìyọnu bá olùkọ́?”+ 36  Ṣùgbọ́n Jésù, bí ó ti fetí kọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ, ó wí fún alága sínágọ́gù náà pé: “Má bẹ̀rù, sáà ti lo ìgbàgbọ́.”+ 37  Wàyí o, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀ lé òun lọ àyàfi Pétérù àti Jákọ́bù àti Jòhánù arákùnrin Jákọ́bù.+ 38  Nítorí náà, wọ́n wá sí ilé alága sínágọ́gù náà, ó sì rí ìdàrúdàpọ̀ aláriwo àti àwọn tí ń sunkún, tí wọ́n sì ń pohùn réré ẹkún, 39  àti pé, lẹ́yìn wíwọlé, ó wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń fa ìdàrúdàpọ̀ aláriwo, tí ẹ sì ń sunkún? Ọmọ kékeré náà kò tíì kú, ṣùgbọ́n ó ń sùn ni.”+ 40  Látàrí èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi í rẹ́rìn-ín tẹ̀gàn-tẹ̀gàn. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ó ti lé gbogbo wọn síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ kékeré náà àti àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì wọlé sí ibi tí ọmọ kékeré náà wà.+ 41  Àti pé, bí ó ti di ọwọ́ ọmọ kékeré náà mú, ó wí fún un pé: “Tàlítà kumì,” èyí tí, nígbà tí a bá túmọ̀ rẹ̀, ó túmọ̀ sí: “Omidan, mo wí fún ọ, Dìde!”+ 42  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, omidan náà sì dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, nítorí ó jẹ́ ẹni ọdún méjìlá. Ní kíá, wọn kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí tí ayọ̀ náà pọ̀ jọjọ.+ 43  Ṣùgbọ́n ó pa àṣẹ ìtọ́ni fún wọn léraléra láti má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mọ̀+ nípa èyí, ó sì sọ pé kí a fún un ní nǹkan láti jẹ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé