Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Máàkù 2:1-28

2  Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn àwọn ọjọ́ díẹ̀, ó tún wọ Kápánáúmù, wọ́n sì ròyìn pé ó wà ní ilé.+  Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn kóra jọ, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò fi sí àyè kankan mọ́, àní kì í ṣe ní àyíká ẹnu ilẹ̀kùn pàápàá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀+ náà fún wọn.  Àwọn ènìyàn sì gbé alárùn ẹ̀gbà kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí àwọn mẹ́rin gbé.+  Ṣùgbọ́n bí wọn kò ti lè gbé e tààràtà wá bá Jésù ní tìtorí ogunlọ́gọ̀ náà, wọ́n ṣí òrùlé ibi tí ó wà, nígbà tí wọ́n sì ti dá ihò lu, wọ́n sọ àkéte tí alárùn ẹ̀gbà náà dùbúlẹ̀ sí kalẹ̀.+  Nígbà tí Jésù sì rí ìgbàgbọ́ wọn,+ ó wí fún alárùn ẹ̀gbà náà pé: “Ọmọ, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì.”+  Wàyí o, àwọn kan lára àwọn akọ̀wé òfin wà níbẹ̀, wọ́n jókòó, wọ́n sì ń gbèrò nínú ọkàn-àyà wọn+ pé:  “Èé ṣe tí [ọkùnrin] yìí fi ń sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí? Ó ń sọ̀rọ̀ òdì. Ta ni ó lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini bí kò ṣe ẹnì kan, Ọlọ́run?”+  Ṣùgbọ́n Jésù, ní fífi òye mọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ pé wọ́n ń gbèrò ní ọ̀nà yẹn nínú ara wọn, ó wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń gbèrò nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn-àyà yín?+  Èwo ni ó rọrùn jù, láti sọ fún alárùn ẹ̀gbà náà pé, ‘A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì,’ tàbí láti sọ pé, ‘Dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn’?+ 10  Ṣùgbọ́n kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ ènìyàn+ ní ọlá àṣẹ láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini ní ilẹ̀ ayé,”+—ó sọ fún alárùn ẹ̀gbà náà pé: 11  “Mo wí fún ọ, Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé rẹ.”+ 12  Látàrí ìyẹn, ó dìde, ó sì gbé àkéte rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì rìn jáde níwájú gbogbo wọn,+ tí ó fi jẹ́ pé ẹnu ya gbogbo wọn gan-an, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, pé: “Àwa kò tíì rí ohun tí ó dà bí rẹ̀ rí.”+ 13  Ó tún jáde lọ sẹ́bàá òkun; gbogbo ogunlọ́gọ̀ náà sì ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣáá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn. 14  Ṣùgbọ́n bí ó ti ń kọjá lọ, ó tajú kán rí Léfì+ ọmọkùnrin Áfíọ́sì tí ó jókòó ní ọ́fíìsì owó orí, ó sì wí fún un pé: “Di ọmọlẹ́yìn mi.” Bí ó sì ti dìde, ó tẹ̀ lé e.+ 15  Lẹ́yìn náà, ó ṣẹlẹ̀ pé ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì nínú ilé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó orí+ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì rọ̀gbọ̀kú pẹ̀lú Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, nítorí pé wọ́n pọ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.+ 16  Ṣùgbọ́n àwọn akọ̀wé òfin ti àwọn Farisí, nígbà tí wọ́n rí i pé ó ń bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àti àwọn agbowó orí jẹun, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ṣé ó ń bá àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun ni?”+ 17  Nígbà tí ó gbọ́ èyí, Jésù wí fún wọn pé: “Àwọn tí wọ́n lókun kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣàmódi nílò rẹ̀. Èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”+ 18  Wàyí o, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn Farisí sọ ààwẹ̀ gbígbà dàṣà. Nítorí náà, wọ́n wá, wọ́n sì wí fún un pé: “Èé ṣe tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí fi sọ ààwẹ̀ gbígbà dàṣà, ṣùgbọ́n tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kò sọ ààwẹ̀ gbígbà dàṣà?”+ 19  Jésù sì wí fún wọn pé: “Nígbà tí ọkọ ìyàwó bá wà pẹ̀lú wọn àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó kò lè gbààwẹ̀,+ àbí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀? Níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ní ọkọ ìyàwó pẹ̀lú wọn, wọn kò lè gbààwẹ̀.+ 20  Ṣùgbọ́n àwọn ọjọ́ yóò dé nígbà tí a óò mú ọkọ ìyàwó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, nígbà náà wọn yóò sì gbààwẹ̀ ní ọjọ́ yẹn.+ 21  Kò sí ẹnì kankan tí í rán ìrépé aṣọ tí kò tíì súnkì sórí ògbólógbòó ẹ̀wù àwọ̀lékè; bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ okun rẹ̀ a tú kúrò lára rẹ̀, tuntun kúrò lára ògbólógbòó, yíya náà yóò sì burú jù.+ 22  Pẹ̀lúpẹ̀lù, kò sí ẹnì kan tí í fi wáìnì tuntun sínú àwọn ògbólógbòó àpò awọ; bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, wáìnì náà a bẹ́ àwọn awọ náà, a sì pàdánù wáìnì náà àti àwọn awọ náà pẹ̀lú.+ Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn a máa fi wáìnì tuntun sínú àwọn àpò awọ tuntun.”+ 23  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé ó ń rìn la àwọn pápá ọkà kọjá ní sábáàtì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ ya+ àwọn erín ọkà.+ 24  Nítorí náà, àwọn Farisí ń wí fún un pé: “Wò ó! Èé ṣe tí wọ́n fi ń ṣe ohun tí kò bófin mu ní sábáàtì?”+ 25  Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò tíì fìgbà kan rí ka ohun tí Dáfídì+ ṣe nígbà tí ó ṣaláìní, tí ebi sì ń pa á, òun àti àwọn ọkùnrin tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀?+ 26  Bí ó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, nínú ìròyìn nípa Ábíátárì+ olórí àlùfáà, tí ó sì jẹ àwọn ìṣù búrẹ́dì àgbékawájú,+ èyí tí kò bófin mu+ fún ẹnikẹ́ni láti jẹ àyàfi àwọn àlùfáà, tí ó sì mú lára rẹ̀ pẹ̀lú fún àwọn ọkùnrin tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀?”+ 27  Nítorí náà, ó ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Sábáàtì wáyé nítorí ènìyàn,+ kì í sì í ṣe pé ènìyàn wáyé nítorí sábáàtì;+ 28  nítorí bẹ́ẹ̀ Ọmọ ènìyàn jẹ́ Olúwa, àní ti sábáàtì pàápàá.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé