Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Máàkù 16:1-20

16  Nítorí náà, nígbà tí sábáàtì+ ti kọjá, Màríà Magidalénì,+ àti Màríà ìyá Jákọ́bù, àti Sàlómẹ̀ ra àwọn èròjà atasánsán kí wọ́n lè wá fi pa á lára.+  Ní kùtù hàì ọjọ́ kìíní+ ọ̀sẹ̀, wọ́n wá síbi ibojì ìrántí náà, nígbà tí oòrùn ti là.+  Wọ́n sì ń sọ, ọ̀kan fún èkejì pé: “Ta ni yóò bá wa yí òkúta kúrò ní ẹnu ọ̀nà ibojì ìrántí náà?”  Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbé ojú sókè, wọ́n rí i pé a ti yí òkúta náà kúrò, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tóbi gan-an.+  Nígbà tí wọ́n wọ inú ibojì ìrántí náà, wọ́n rí ọ̀dọ́kùnrin kan tí ó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún, ó wọ aṣọ funfun, wọ́n sì ta kìjí.+  Ó wí fún wọn pé: “Ẹ dẹ́kun títakìjí. Jésù ará Násárétì ni ẹ ń wá, ẹni tí a kàn mọ́gi.+ A ti gbé e+ dìde, kò sí níhìn-ín. Ẹ wò ó! Ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.+  Ṣùgbọ́n ẹ lọ, ẹ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti Pétérù pé, ‘Ó ń lọ ṣáájú yín sí Gálílì;+ ẹ óò rí i níbẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún yín.’”+  Nítorí náà, nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n sá kúrò ní ibojì ìrántí náà, nítorí ìwárìrì àti èrò ìmọ̀lára tí ó lágbára gbá wọn mú. Wọn kò sì sọ ohunkóhun fún ẹnì kankan, nítorí wọ́n ń bẹ̀rù.+ ÌPARÍ KÚKÚRÚ Àwọn ìwé àfọwọ́kọ àti àwọn ẹ̀dà ìtúmọ̀ kan tí wọ́n dé kẹ́yìn ní ìparí kúkúrú kan nínú, tí ó wà lẹ́yìn Máàkù 16:8, tí ó lọ báyìí pé: Ṣùgbọ́n gbogbo ohun tí a ti pa láṣẹ ni wọ́n ṣèròyìn ní ṣókí fún àwọn tí wọ́n yí Pétérù ká. Síwájú sí i, lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù fúnra rẹ̀ rán ìpòkìkí mímọ́ àti aláìlè-díbàjẹ́ ti ìgbàlà àìnípẹ̀kun jáde nípasẹ̀ wọn láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn. ÌPARÍ GÍGÙN Àwọn ìwé àfọwọ́kọ (ACD) àti àwọn ẹ̀dà ìtúmọ̀ (VgSyc,p) kan tí wọ́n jẹ́ ti ìgbàanì fi ìparí gígùn tí ó tẹ̀ lé e yìí kún un, ṣùgbọ́n èyí tí אBSysArm fò dá:  Lẹ́yìn ó dìde kùtùkùtù ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, ó kọ́kọ́ fara han Màríà Magidalénì, lára ẹni ó ti ẹ̀mí èṣù méje jáde. 10  Ó lọ, ó ròyìn fún àwọn wọ́n ti pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀, wọ́n ń sunkún. 11  Ṣùgbọ́n, nígbà wọ́n gbọ́ ó ti àti ó ti  i, wọn gbà gbọ́. 12   bẹ́ẹ̀ lọ, lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ó fara hàn ìrísí mìíràn fún méjì lára wọn wọ́n jọ ń rìn lọ, wọ́n ti ń lọ ìgbèríko; 13  wọ́n padà wá, wọ́n ròyìn fún àwọn yòókù. Bẹ́ẹ̀ ni wọn gba àwọn wọ̀nyí gbọ́. 14  Ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà, ó fara han àwọn mọ́kànlá náà fúnra wọn wọ́n ti rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì, ó gan àìnígbàgbọ́ àti líle-ọkàn wọn, nítorí wọn gba àwọn wọnnì gbọ́, wọ́n  i nísinsìnyí a ti gbé e dìde kúrò nínú òkú. 15  Ó fún wọn pé: “Ẹ lọ sínú gbogbo ayé, wàásù ìhìn rere fún gbogbo ìṣẹ̀dá. 16  Ẹni ó gbà gbọ́, a batisí ni a ó gbà là, ṣùgbọ́n ẹni gbà gbọ́ ni a óò lẹ́bi. 17  Síwájú  i, àmì wọ̀nyí yóò máa àwọn wọ́n gbà gbọ́ rìn: Nípa lílo orúkọ mi, wọn yóò àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, wọn yóò máa fi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, 18  wọn yóò fi ọwọ́ wọn gbé ejò, wọ́n mu ohunkóhun ń ṣekú pani, yóò ṣe wọ́n lọ́ṣẹ́ rárá. Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn àwọn aláìsàn, àwọn wọ̀nyí yóò sàn.” 19  Nítorí bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn Jésù Olúwa ti wọn sọ̀rọ̀, a gbé e lọ sókè ọ̀run, ó jókòó ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 20   ìbámu pẹ̀lú èyí, wọ́n jáde lọ, wọ́n wàásù níbi gbogbo, nígbà Olúwa ń  wọn ṣiṣẹ́, ó kín ìhìn-iṣẹ́ náà lẹ́yìn nípasẹ̀ àwọn àmì ń  wọn rìn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé