Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Máàkù 15:1-47

15  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bí ojúmọ́ ti mọ́, àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn akọ̀wé òfin, àní gbogbo Sànhẹ́dírìn, ṣe ìfikùnlukùn,+ wọ́n sì de Jésù, wọ́n sì mú un lọ, wọ́n sì fi í lé Pílátù lọ́wọ́.+  Nítorí náà, Pílátù bi í léèrè pé: “Ìwọ ha ni ọba+ àwọn Júù bí?” Ní dídá a lóhùn, ó wí pé: “Ìwọ fúnra rẹ wí i.”+  Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn ohun púpọ̀ kàn án.+  Wàyí o, Pílátù tún bẹ̀rẹ̀ sí bi í léèrè, pé: “Ṣé o kò ní èsì kankan láti fọ̀ ni?+ Wo bí ẹ̀sùn tí wọ́n fi ń kàn ọ́ ti pọ̀ tó.”+  Ṣùgbọ́n Jésù kò dáhùn mọ́, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnu bẹ̀rẹ̀ sí ya Pílátù.+  Tóò, láti àjọyọ̀ dé àjọyọ̀, ó máa ń tú ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún wọn, ẹni tí wọ́n bá tọrọ.+  Ní àkókò náà, ẹni tí wọ́n ń pè ní Bárábà wà nínú àwọn ìdè pẹ̀lú àwọn adìtẹ̀ sí ìjọba, àwọn tí wọ́n ṣìkà pànìyàn nínú ìdìtẹ̀ wọn sí ìjọba.+  Nítorí náà, ogunlọ́gọ̀ dìde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìtọrọ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó máa ń ṣe fún wọn.  Pílátù dá wọn lóhùn, pé: “Ẹ ha fẹ́ kí n tú ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yín bí?”+ 10  Nítorí ó mọ̀ pé nítorí ìlara+ ni àwọn olórí àlùfáà ṣe fi í lé òun lọ́wọ́.+ 11  Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà ru ogunlọ́gọ̀ náà sókè pé kàkà bẹ́ẹ̀ kí ó tú Bárábà sílẹ̀ fún wọn.+ 12  Ní ìfèsìpadà, Pílátù tún ń sọ fún wọn pé: “Kí wá ni kí n ṣe sí ẹni tí ẹ ń pè ní ọba+ àwọn Júù?”+ 13  Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n ké jáde pé: “Kàn án mọ́gi!”+ 14  Ṣùgbọ́n Pílátù ń bá a lọ ní sísọ fún wọn pé: “Họ́wù, ohun búburú wo ni ó ṣe?” Síbẹ̀, wọ́n túbọ̀ ké jáde pé: “Kàn án mọ́gi!”+ 15  Látàrí èyí, bí Pílátù ti fẹ́ láti tẹ́ ogunlọ́gọ̀ náà lọ́rùn,+ ó tú Bárábà sílẹ̀ fún wọn, àti pé, lẹ́yìn nína Jésù ní pàṣán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti kàn án mọ́gi.+ 16  Wàyí o, àwọn ọmọ ogun mú un wọnú àgbàlá, èyíinì ni, wọnú ààfin gómìnà; wọ́n sì pe gbogbo ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun jọ,+ 17  wọ́n sì fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò múra fún un, wọ́n sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí.+ 18  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kí i pé: “Kú déédéé ìwòyí o,+ ìwọ Ọba àwọn Júù!” 19  Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n a fi ọ̀pá esùsú gbá a ní orí, wọ́n a sì tutọ́ sí i lára àti pé, ní títẹ eékún wọn ba, wọn a wárí fún un.+ 20  Níkẹyìn, nígbà tí wọ́n ti fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n bọ́ aṣọ aláwọ̀ àlùkò náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n sì fi ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n sì mú un jáde láti kàn án mọ́gi.+ 21  Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ẹnì kan tí ń kọjá lọ, Símónì kan tí ó jẹ́ ará Kírénè, tí ó ń bọ̀ láti ìgbèríko, baba Alẹkisáńdà àti Rúfọ́ọ̀sì, pé kí ó gbé òpó igi oró rẹ̀ nílẹ̀.+ 22  Nítorí náà, wọ́n mú un wá sí ibi Gọ́gọ́tà, èyí tí, nígbà tí a bá túmọ̀ rẹ̀, ó túmọ̀ sí Ibi Agbárí.+ 23  Níhìn-ín, wọ́n gbìyànjú láti fún un ní wáìnì tí a fi òjíá sọ di líle,+ ṣùgbọ́n kò mu ún.+ 24  Wọ́n sì kàn án mọ́gi, wọ́n sì pín ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀+ nípa ṣíṣẹ́ kèké lé wọn lórí ní ti èwo ni ẹnì kan yóò mú.+ 25  Ó ti di wákàtí kẹta+ nísinsìnyí, wọ́n sì kàn án mọ́gi. 26  Àkọlé ẹ̀sùn+ lòdì sí i ni a sì kọ sókè pé, “Ọba Àwọn Júù.”+ 27  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n kan àwọn ọlọ́ṣà méjì mọ́gi pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan ní ọ̀tún rẹ̀ àti ọ̀kan ní òsì rẹ̀.+ 28  —— 29  Àwọn tí ń kọjá lọ a sì sọ̀rọ̀ sí i tèébú-tèébú,+ wọ́n a mi orí wọn síwá sẹ́yìn, wọ́n a sì wí pé: “Ṣíọ̀! Ìwọ tí o máa wó tẹ́ńpìlì palẹ̀, tí o sì máa fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ,+ 30  gba ara rẹ là nípa sísọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí òpó igi oró.”+ 31  Lọ́nà kan náà pẹ̀lú ni àwọn olórí àlùfáà ń ṣe yẹ̀yẹ́ láàárín ara wọn pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin, wọ́n sì ń sọ pé: “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kò lè gba ara rẹ̀ là!+ 32  Kí Kristi Ọba Ísírẹ́lì sọ̀ kalẹ̀ nísinsìnyí kúrò lórí òpó igi oró, kí a lè rí, kí a sì gbà gbọ́.”+ Àní àwọn tí a kàn mọ́gi pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ń gàn án.+ 33  Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn kan ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà títí di wákàtí kẹsàn-án.+ 34  Ní wákàtí kẹsàn-án, Jésù ké ní ohùn rara pé: “Élì, Élì, làmá sàbakitanì?” èyí tí, nígbà tí a bá túmọ̀ rẹ̀, ó túmọ̀ sí: “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi ṣá mi tì?”+ 35  Àwọn kan lára àwọn tí wọ́n dúró nítòsí, nígbà tí wọ́n gbọ́, bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Ẹ wò ó! Ó ń pe Èlíjà.”+ 36  Ṣùgbọ́n ẹnì kan sáré, ó rẹ kànrìnkàn sínú wáìnì kíkan, ó fi í sórí ọ̀pá esùsú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fún un mu,+ ó wí pé: “Ẹ jọ̀wọ́ rẹ̀! Ẹ jẹ́ kí a wò ó bóyá Èlíjà yóò wá gbé e sọ̀ kalẹ̀.”+ 37  Ṣùgbọ́n Jésù ké igbe rara, ó sì gbẹ́mìí mì.+ 38  Aṣọ ìkélé+ ibùjọsìn sì ya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀.+ 39  Wàyí o, nígbà tí ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó dúró sí tòsí níwájú rẹ̀ rí pé ó ti gbẹ́mìí mì lábẹ́ ipò wọ̀nyí, ó wí pé: “Dájúdájú, Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí.”+ 40  Àwọn obìnrin sì ń bẹ tí ń wòran láti òkèèrè,+ lára wọn ni Màríà Magidalénì àti Màríà ìyá Jákọ́bù Kékeré àti ti Jósè, àti Sàlómẹ̀,+ 41  àwọn tí wọ́n máa ń bá a rìn,+ tí wọ́n sì máa ń ṣe ìránṣẹ́ fún un nígbà tí ó wà ní Gálílì, àti ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin mìíràn tí wọ́n jọ gòkè wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 42  Wàyí o, bí ó ti di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ nísinsìnyí, níwọ̀n bí ó sì ti jẹ́ Ìpalẹ̀mọ́, èyíinì ni, ọjọ́ tí ó ṣáájú sábáàtì, 43  Jósẹ́fù ará Arimatíà wá, mẹ́ńbà kan tí ó ní ìsì rere nínú Àjọ Ìgbìmọ̀, ẹni tí òun fúnra rẹ̀ pẹ̀lú ń dúró de ìjọba Ọlọ́run.+ Ó lo ìgboyà láti wọlé síwájú Pílátù, ó sì béèrè fún òkú+ Jésù. 44  Ṣùgbọ́n Pílátù ṣe kàyéfì bóyá ó ti kú nísinsìnyí, àti pé, ní fífi ọlá àṣẹ pe ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà, ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó ti kú nísinsìnyí. 45  Nítorí náà, lẹ́yìn mímọ̀ dájú láti ọ̀dọ̀ ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà, ó yọ̀ǹda òkú náà fún Jósẹ́fù.+ 46  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ó ra aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, ó sì gbé e sọ̀ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà náà dì í, ó sì tẹ́ ẹ+ sínú ibojì+ kan tí a gbẹ́ sínú àpáta ràbàtà kan; ó sì yí òkúta sí ẹnu ọ̀nà ibojì ìrántí náà.+ 47  Ṣùgbọ́n Màríà Magidalénì àti Màríà ìyá Jósè ń bá a lọ ní wíwo ibi tí a tẹ́ ẹ sí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé