Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Máàkù 13:1-37

13  Bí ó ti ń jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé: “Olùkọ́, wò ó! àwọn òkúta àti ilé wọ̀nyí mà kàmàmà o!”+  Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù wí fún un pé: “Ṣé ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí?+ Lọ́nàkọnà, a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta+ kan níhìn-ín tí a kì yóò wó palẹ̀.”+  Bí ó sì ti jókòó lórí Òkè Ńlá Ólífì ní ìdojúkọ tẹ́ńpìlì náà, Pétérù+ àti Jákọ́bù àti Jòhánù àti Áńdérù bẹ̀rẹ̀ sí béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ níkọ̀kọ̀+ pé:  “Sọ fún wa, Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì ìgbà tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ pé kí gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá sí ìparí?”+  Nítorí náà, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí wí fún wọn pé: “Ẹ ṣọ́ra kí ẹnì kankan má ṣì yín lọ́nà.+  Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá ní orúkọ mi, wí pé, ‘Èmi ni ẹni náà,’ wọn yóò sì ṣi ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́nà.+  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun, ẹ má ṣe jáyà; nǹkan wọ̀nyí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe ìsinsìnyí.+  “Nítorí orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba,+ ìsẹ̀lẹ̀+ yóò wà láti ibi kan dé ibòmíràn, àìtó oúnjẹ+ yóò wà. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà.+  “Ní tiyín, ẹ máa ṣọ́ra yín; àwọn ènìyàn yóò fà yín lé àwọn kóòtù àdúgbò lọ́wọ́,+ wọn yóò sì lù yín nínú àwọn sínágọ́gù,+ a ó sì fi yín sórí àpótí ìdúrórojọ́ níwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn.+ 10  Pẹ̀lúpẹ̀lù, a ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere+ náà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.+ 11  Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń mú yín lọ láti fà yín léni lọ́wọ́, ẹ má ṣàníyàn ṣáájú nípa ohun tí ẹ ó sọ;+ ṣùgbọ́n ohun yòówù tí a bá fi fún yín ní wákàtí yẹn, ẹ sọ èyí, nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí mímọ́ ni.+ 12  Síwájú sí i, arákùnrin yóò fa arákùnrin lé ikú lọ́wọ́, baba yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọmọ,+ àwọn ọmọ yóò sì dìde sí àwọn òbí, wọn yóò sì ṣe ikú pa wọ́n;+ 13  ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn ní tìtorí orúkọ mi.+ Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin+ ni ẹni tí a ó gbà là.+ 14  “Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra+ tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro+ tí ó dúró níbi tí kò yẹ (kí òǹkàwé lo ìfòyemọ̀),+ nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.+ 15  Kí ẹni tí ó wà ní orí ilé má ṣe sọ̀ kalẹ̀, tàbí kí ó wọlé lọ mú ohunkóhun jáde kúrò nínú ilé rẹ̀;+ 16  kí ẹni tí ó wà ní pápá má sì padà sí àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn láti mú ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀.+ 17  Ègbé ni fún àwọn obìnrin tí ó lóyún àti àwọn tí ń fi ọmú fún ọmọ ọwọ́ ni ọjọ́ wọnnì!+ 18  Ẹ máa gbàdúrà kí ó má ṣẹlẹ̀ ní ìgbà òtútù;+ 19  nítorí ọjọ́ wọnnì yóò jẹ́ àwọn ọjọ́ ìpọ́njú+ irúfẹ́ èyí ti kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá tí Ọlọ́run dá títí di àkókò yẹn, kì yóò sì tún ṣẹlẹ̀ mọ́.+ 20  Ní ti tòótọ́, láìjẹ́ pé Jèhófà+ ké àwọn ọjọ́ náà kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là. Ṣùgbọ́n ní tìtorí àwọn àyànfẹ́+ tí ó ti yàn,+ ó ti ké àwọn ọjọ́ náà kúrú.+ 21  “Nígbà náà, pẹ̀lú, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Ẹ wò ó! Kristi nìyí níhìn-ín,’ ‘Ẹ wò ó! Òun nìyẹn lọ́hùn-ún,’+ ẹ má ṣe gba èyí gbọ́.+ 22  Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde,+ wọn yóò sì fúnni ní àwọn àmì àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu+ láti mú àwọn àyànfẹ́ ṣáko lọ, bí ó bá ṣeé ṣe.+ 23  Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra;+ mo ti sọ ohun gbogbo fún yín tẹ́lẹ̀.+ 24  “Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ wọnnì, lẹ́yìn ìpọ́njú yẹn, oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, 25  àwọn ìràwọ̀ yóò sì máa jábọ́ láti ọ̀run, àwọn agbára tí ń bẹ ní ọ̀run ni a ó sì mì.+ 26  Nígbà náà ni wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn+ tí ń bọ̀ nínú àwọsánmà pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.+ 27  Nígbà náà ni òun yóò sì rán àwọn áńgẹ́lì jáde, yóò sì kó àwọn àyànfẹ́+ rẹ̀ jọpọ̀ láti inú ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun ilẹ̀ ayé títí dé ìkángun ọ̀run.+ 28  “Wàyí o, ẹ kọ́ àpèjúwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́: Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ tuntun bá yọ ọ̀jẹ̀lẹ́, tí ó sì mú ewé rẹ̀ jáde, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́lé.+ 29  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá rí nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé òun ti sún mọ́ tòsí, lẹ́nu ilẹ̀kùn.+ 30  Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé ìran yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀.+ 31  Ọ̀run+ àti ilẹ̀ ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀+ mi kì yóò kọjá lọ.+ 32  “Ní ti ọjọ́ yẹn tàbí wákàtí náà, kò sí ẹni tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba.+ 33  Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò,+ nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́.+ 34  Ó dà bí ọkùnrin kan tí ó ń rin ìrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀,+ tí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì fi ọlá àṣẹ fún àwọn ẹrú rẹ̀, tí ó fún olúkúlùkù ní iṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì pàṣẹ fún olùṣọ́nà láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà. 35  Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà,+ nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí ọ̀gá ilé náà ń bọ̀, yálà nígbà tí alẹ́ ti lẹ́ tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru tàbí ìgbà kíkọ àkùkọ tàbí ní kùtùkùtù òwúrọ̀;+ 36  kí ó bàa lè jẹ́ pé, nígbà tí ó bá dé lójijì, òun kò ní bá yín lójú oorun.+ 37  Ṣùgbọ́n ohun tí mo sọ fún yín ni mo sọ fún gbogbo ènìyàn, Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé