Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Máàkù 12:1-44

12  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé: “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan,+ ó sì ṣe ọgbà yí i ká, ó sì gbẹ́ ẹkù ìfúntí wáìnì, ó sì gbé ilé gogoro kan nà ró,+ ó sì gbé e fún àwọn aroko,+ ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀.+  Wàyí o, ní àsìkò yíyẹ, ó rán ẹrú kan jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn aroko náà, kí ó lè gbà lára àwọn èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ àwọn aroko náà.+  Ṣùgbọ́n wọ́n mú un, wọ́n lù ú ní ìlùkulù, wọ́n sì rán an lọ lọ́wọ́ òfo.+  Ó sì tún rán ẹrú mìíràn jáde lọ sọ́dọ̀ wọn; ẹni yẹn ni wọ́n sì lù ní orí tí wọ́n sì tàbùkù sí.+  Ó sì rán òmíràn jáde, wọ́n sì pa ẹni yẹn; àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn, wọ́n lu àwọn kan nínú wọn ní ìlùkulù, wọ́n sì pa àwọn kan nínú wọn.  Ó ní ẹnì kan sí i, ọmọ tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọ̀wọ́n.+ Ó rán an jáde lọ sọ́dọ̀ wọn níkẹyìn, ó wí pé, ‘Wọ́n yóò bọ̀wọ̀ fún ọmọ mi.’+  Ṣùgbọ́n àwọn aroko wọnnì sọ láàárín ara wọn pé, ‘Ajogún nìyí.+ Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, ogún náà yóò sì jẹ́ tiwa.’+  Nítorí náà, wọ́n mú un, wọ́n sì pa á,+ wọ́n sì sọ ọ́ sóde ọgbà àjàrà náà.+  Kí ni ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà yóò ṣe? Yóò wá, yóò sì pa àwọn aroko náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà+ náà fún àwọn ẹlòmíràn.+ 10  Ṣé ẹ kò tíì ka ìwé mímọ́ yìí rí pé, ‘Òkúta+ tí àwọn akọ́lé kọ̀ tì, èyí ti di olórí òkúta igun ilé.+ 11  Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èyí ti wá, ó sì jẹ́ ohun ìyanu ní ojú wa’?”+ 12  Látàrí èyíinì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti gbá a mú, ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù ogunlọ́gọ̀, nítorí wọ́n ṣàkíyèsí pé àwọn ni ó ní lọ́kàn tí ó fi sọ àpèjúwe náà. Nítorí náà, wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì lọ.+ 13  Lẹ́yìn náà, wọ́n rán àwọn kan lára àwọn Farisí àti lára àjọ ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Hẹ́rọ́dù+ jáde lọ bá a, láti mú un nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ 14  Nígbà tí wọ́n dé, àwọn wọ̀nyí sọ fún un pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ jẹ́ olùsọ òtítọ́, ìwọ kò sì bìkítà fún ẹnikẹ́ni, nítorí ìwọ kì í wo ìrísí òde àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́:+ Ó ha bófin mu láti san owó orí fún Késárì tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́? 15  Ṣé kí a san án, tàbí kí a má san án?”+ Bí ó ti jádìí àgàbàgebè wọn, ó wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń dán mi wò? Ẹ mú owó dínárì kan wá fún mi kí n wò ó.”+ 16  Wọ́n mú ọ̀kan wá. Ó sì wí fún wọn pé: “Àwòrán àti àkọlé ta ni èyí?” Wọ́n wí fún un pé: “Ti Késárì ni.”+ 17  Nígbà náà, Jésù wí pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì,+ ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”+ Ẹnu sì bẹ̀rẹ̀ sí yà wọ́n sí i.+ 18  Wàyí o, àwọn Sadusí wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn tí wọ́n sọ pé kò sí àjíǹde, wọ́n sì bi í léèrè pé:+ 19  “Olùkọ́, Mósè kọ̀wé fún wa pé bí arákùnrin ẹnì kan bá kú, tí ó sì fi aya sílẹ̀ sẹ́yìn ṣùgbọ́n tí kò fi ọmọ sílẹ̀, arákùnrin rẹ̀+ ní láti fẹ́ aya náà, kí ó sì gbé ọmọ dìde láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ fún arákùnrin rẹ̀.+ 20  Àwọn arákùnrin méje wà; èkíní sì fẹ́ aya kan, ṣùgbọ́n nígbà tí ó kú, kò fi ọmọ kankan sílẹ̀.+ 21  Èkejì sì fẹ́ ẹ, ṣùgbọ́n ó kú láìfi ọmọ sílẹ̀; ẹ̀kẹta sì jẹ́ ní ọ̀nà kan náà. 22  Àwọn méjèèje kò sì fi ọmọ kankan sílẹ̀. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obìnrin náà pẹ̀lú kú.+ 23  Ní àjíǹde, èwo nínú wọn ni yóò jẹ́ aya fún? Nítorí àwọn méjèèje ni wọ́n fẹ́ ẹ ṣe aya.”+ 24  Jésù wí fún wọn pé: “Èyí ha kọ́ ni ìdí tí ẹ fi ṣàṣìṣe, mímọ̀ tí ẹ kò mọ yálà Ìwé Mímọ́ tàbí agbára Ọlọ́run?+ 25  Nítorí nígbà tí wọ́n bá dìde kúrò nínú òkú, àwọn ọkùnrin kì í gbéyàwó bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n wọ́n yóò wà gẹ́gẹ́ bí àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run.+ 26  Ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, pé a gbé wọn dìde, ṣé ẹ kò kà á nínú ìwé Mósè, nínú ìròyìn nípa igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún, bí Ọlọ́run ṣe sọ fún un pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù’?+ 27  Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè. Ẹ mà kúkú ṣàṣìṣe o.”+ 28  Wàyí o, ọ̀kan lára àwọn akọ̀wé òfin tí ó ti gòkè wá, tí ó sì gbọ́ tí wọ́n ń ṣe awuyewuye, ní mímọ̀ pé ó ti dá wọn lóhùn lọ́nà tí ó dára púpọ̀, béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Àṣẹ wo ni èkíní nínú gbogbo wọn?”+ 29  Jésù dáhùn pé: “Èkíní ni, ‘Gbọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì, Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ Jèhófà kan ṣoṣo,+ 30  kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.’+ 31  Èkejì nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’+ Kò sí àṣẹ mìíràn tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ.” 32  Akọ̀wé òfin náà wí fún un pé: “Olùkọ́, ìwọ wí dáadáa ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́, ‘Ọ̀kan ṣoṣo ni Òun, kò sì sí òmíràn yàtọ̀ sí Òun’;+ 33  àti pé nínífẹ̀ẹ́ rẹ̀ yìí pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà ẹni àti pẹ̀lú gbogbo òye ẹni àti pẹ̀lú gbogbo okun ẹni àti nínífẹ̀ẹ́ aládùúgbò ẹni gẹ́gẹ́ bí ara ẹni yìí níye lórí lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ.”+ 34  Látàrí èyí, ní fífi òye mọ̀ pé ó ti dáhùn pẹ̀lú làákàyè, Jésù wí fún un pé: “Ìwọ kò jìnnà sí ìjọba Ọlọ́run.” Ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kan tí ó ní ìgboyà mọ́ láti bi í ní ìbéèrè.+ 35  Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó ń fèsì, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí sọ gẹ́gẹ́ bí ó ti ń kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì pé: “Báwo ni ó ṣe jẹ́ tí àwọn akọ̀wé òfin fi sọ pé Kristi jẹ́ ọmọkùnrin Dáfídì?+ 36  Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́,+ Dáfídì fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Jèhófà wí fún Olúwa mi pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.”’+ 37  Dáfídì fúnra rẹ̀ pè é ní ‘Olúwa,’ ṣùgbọ́n báwo ni ó ṣe wá jẹ́ pé ó jẹ́ ọmọkùnrin rẹ̀?”+ Ogunlọ́gọ̀ ńlá náà sì ń fetí sí i pẹ̀lú ìdùnnú.+ 38  Ó sì ń bá a lọ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ láti sọ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn akọ̀wé òfin+ tí wọ́n ń fẹ́ láti máa rìn káàkiri nínú aṣọ ńlá, tí wọ́n sì ń fẹ́ ìkíni ní àwọn ibi ọjà 39  àti àwọn ìjókòó iwájú nínú àwọn sínágọ́gù àti àwọn ibi yíyọrí ọlá jù lọ níbi oúnjẹ alẹ́.+ 40  Àwọn ni wọ́n ń jẹ ilé+ àwọn opó run, wọ́n sì ń gba àdúrà gígùn fún bojúbojú; àwọn wọ̀nyí yóò gba ìdájọ́ tí ó wúwo jù.”+ 41  Ó sì jókòó ní ìdojúkọ àwọn àpótí ìṣúra,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkíyèsí bí ogunlọ́gọ̀ náà ṣe ń sọ owó sínú àwọn àpótí ìṣúra; ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì ń sọ ẹyọ owó púpọ̀ sínú wọn.+ 42  Wàyí o, òtòṣì opó kan wá, ó sì sọ ẹyọ owó kéékèèké méjì sínú rẹ̀, tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an.+ 43  Nítorí náà, ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé òtòṣì opó yìí sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ owó sínú àwọn àpótí ìṣúra náà;+ 44  nítorí gbogbo wọ́n sọ sínú rẹ̀ láti inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n, láti inú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní sínú rẹ̀, gbogbo ohun ìní ìgbésí ayé rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé