Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Máàkù 11:1-33

11  Wàyí o, nígbà tí wọ́n ń sún mọ́ tòsí Jerúsálẹ́mù, Bẹtifágè àti Bẹ́tánì+ ní Òkè Ńlá Ólífì, ó rán méjì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ,+  ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ sínú abúlé tí ẹ ń wò yìí, gbàrà tí ẹ bá sì ti kọjá sínú rẹ̀, ẹ óò rí agódóńgbó kan tí a so, lórí èyí tí ìkankan nínú aráyé kò tíì jókòó rí; ẹ tú u, kí ẹ sì mú un wá.+  Bí ẹnikẹ́ni bá sì sọ fún yín pé, ‘Èé ṣe tí ẹ fi ń ṣe èyí?’ ẹ sọ pé, ‘Olúwa nílò rẹ̀, yóò sì fi í ránṣẹ́ padà síhìn-ín ní kíá.’”+  Nítorí náà, wọ́n lọ, wọ́n sì rí agódóńgbó náà tí a so sí ẹnu ilẹ̀kùn, lóde ní ojú pópó tí ó yà sẹ́gbẹ̀ẹ́, wọ́n sì tú u.+  Ṣùgbọ́n àwọn kan lára àwọn tí wọ́n dúró síbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn pé: “Kí ni ẹ ń ṣe tí ẹ ń tu agódóńgbó náà?”+  Wọ́n sọ fún àwọn wọ̀nyí gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ; wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lọ.+  Wọ́n sì mú agódóńgbó+ náà wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n sì tẹ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn sórí rẹ̀, ó sì jókòó sórí rẹ̀.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ọ̀pọ̀ ènìyàn tẹ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè+ wọn sí ojú ọ̀nà, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn gé àwọn ẹ̀ka eléwé+ láti inú àwọn pápá.+  Àwọn tí wọ́n sì ń lọ níwájú àti àwọn tí wọ́n ń bọ̀ lẹ́yìn sì ń ké jáde ṣáá pé: “Gbà là, ni àwa bẹ̀bẹ̀!+ Alábùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà!+ 10  Alábùkún ni ìjọba Dáfídì baba wa tí ń bọ̀!+ Gbà là, ni àwa bẹ̀bẹ̀, ní àwọn ibi gíga lókè!” 11  Ó sì wọ Jerúsálẹ́mù, sínú tẹ́ńpìlì; ó sì wo ohun gbogbo yí ká, àti pé, gẹ́gẹ́ bí wákàtí ọjọ́ ti lọ jìnnà nísinsìnyí, ó jáde lọ sí Bẹ́tánì pẹ̀lú àwọn méjìlá náà.+ 12  Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Bẹ́tánì, ebi ń pa á.+ 13  Láti òkèèrè, ó tajú kán rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí ó ní ewé, ó sì lọ wò ó bóyá òun lè rí ohun kan lórí rẹ̀. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ó dé ìdí rẹ̀, kò rí nǹkan kan bí kò ṣe àwọn ewé, nítorí kì í ṣe àsìkò ọ̀pọ̀tọ́.+ 14  Nítorí náà, ní ìdáhùnpadà, ó wí fún un pé: “Kí ẹnì kankan má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.”+ Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì fetí sílẹ̀. 15  Wàyí o, wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù. Níbẹ̀, ó wọ inú tẹ́ńpìlì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà, tí wọ́n sì ń rà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì sojú tábìlì àwọn olùpààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tí ń ta àdàbà;+ 16  kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbé nǹkan èlò la tẹ́ńpìlì kọjá, 17  ṣùgbọ́n ó tẹra mọ́ kíkọ́ni àti sísọ pé: “A kò ha kọ ọ́ pé, ‘Ilé mi ni a óò máa pè ní ilé àdúrà+ fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè’?+ Ṣùgbọ́n ẹ ti sọ ọ́ di hòrò àwọn ọlọ́ṣà.”+ 18  Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin sì gbọ́ èyí, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti pa á run;+ nítorí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, nítorí gbogbo ogunlọ́gọ̀ náà ń ṣe háà sí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nígbà gbogbo.+ 19  Nígbà tí alẹ́ bá sì ti lẹ́, wọn a jáde kúrò nínú ìlú ńlá náà. 20  Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n ń kọjá lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà tí ó ti rọ pátápátá láti gbòǹgbò.+ 21  Nítorí náà, ní rírántí rẹ̀, Pétérù wí fún un pé: “Rábì, wò ó! igi ọ̀pọ̀tọ́ tí o gégùn-ún fún ti rọ pátápátá.”+ 22  Ní ìfèsìpadà, Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. 23  Lóòótọ́ ní mo wí fún yín pé ẹnì yòówù tí ó bá sọ fún òkè ńlá yìí pé, ‘Gbéra sọ sínú òkun,’ tí kò sì ṣiyèméjì nínú ọkàn-àyà rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó ní ìgbàgbọ́ pé ohun tí òun sọ yóò ṣẹlẹ̀, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un.+ 24  Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún yín pé, Gbogbo ohun tí ẹ bá gbàdúrà fún, tí ẹ sì béèrè, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé ẹ kúkú ti rí wọn gbà, ẹ ó sì ní wọn.+ 25  Nígbà tí ẹ bá sì dúró tí ẹ ń gbàdúrà, ẹ dárí ohun yòówù tí ẹ ní lòdì sí ẹnikẹ́ni jì í;+ kí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lè dárí àwọn àṣemáṣe yín jì yín pẹ̀lú.”+ 26  —— 27  Wọ́n sì tún wá sí Jerúsálẹ́mù. Bí ó sì ti ń rìn nínú tẹ́ńpìlì, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbà ọkùnrin wá sọ́dọ̀ rẹ̀,+ 28  wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: “Ọlá àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? tàbí ta ní fún ọ ní ọlá àṣẹ yìí láti máa ṣe nǹkan wọ̀nyí?”+ 29  Jésù wí fún wọn pé: “Dájúdájú, èmi yóò béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ yín. Kí ẹ dá mi lóhùn, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò sì sọ ọlá àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín.+ 30  Ìbatisí+ láti ọwọ́ Jòhánù, ṣé láti ọ̀run ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn? Ẹ dá mi lóhùn.”+ 31  Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fèrò wérò láàárín ara wọn, pé: “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ yóò sọ pé, ‘Nítorí náà, èéṣe tí ẹ kò gbà á gbọ́?’+ 32  Ṣùgbọ́n àwa ha gbójúgbóyà láti sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn’?”—Wọ́n bẹ̀rù ogunlọ́gọ̀, nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí gbà pé Jòhánù jẹ́ wòlíì ní ti tòótọ́.+ 33  Tóò, ní ìfèsìpadà fún Jésù, wọ́n sọ pé: “Àwa kò mọ̀.” Jésù sì sọ fún wọn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò sọ ọlá àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé