Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Máàkù 10:1-52

10  Láti ibẹ̀, ó dìde, ó sì wá sí ààlà ilẹ̀ Jùdíà àti sí òdì-kejì Jọ́dánì, àwọn ogunlọ́gọ̀ sì tún kóra jọpọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó sì ti jẹ́ àṣà rẹ̀ láti máa ṣe, ó tún ń bá a lọ ní kíkọ́ wọn.+  Wàyí o, àwọn Farisí tọ̀ ọ́ wá, láti dán an wò, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bi í léèrè yálà ó bófin mu fún ọkùnrin láti kọ aya sílẹ̀.+  Ní ìdáhùn, ó wí fún wọn pé: “Kí ni Mósè pa láṣẹ fún yín?”  Wọ́n wí pé: “Mósè yọ̀ǹda kíkọ ìwé ẹ̀rí ìlélọ, kí a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”+  Ṣùgbọ́n Jésù wí fún wọn pé: “Ní tìtorí líle-ọkàn+ yín ni ó ṣe kọ̀wé àṣẹ yìí fún yín.  Bí ó ti wù kí ó rí, láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá ‘Ó dá wọn ní akọ àti abo.+  Ní tìtorí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀,  àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’;+ tí ó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan.  Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”+ 10  Nígbà tí ó tún wà nínú ilé,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí bi í léèrè nípa èyí. 11  Ó sì wí fún wọn pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó ṣe panṣágà+ lòdì sí i, 12  bí obìnrin kan, lẹ́yìn kíkọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, bá sì ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú òmíràn pẹ́nrẹ́n, ó ṣe panṣágà.”+ 13  Wàyí o, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè fọwọ́ kàn wọ́n; ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn bá wọn wí kíkankíkan.+ 14  Ní rírí èyí, ìkannú Jésù ru, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun, nítorí ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.+ 15  Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnì yòówù tí kò bá gba ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré kì yóò wọ inú rẹ̀ lọ́nàkọnà.”+ 16  Ó sì gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn.+ 17  Bí ó sì ti ń jáde lọ ní ọ̀nà rẹ̀, ọkùnrin kan sáré wá, ó sì wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bi í léèrè pé: “Olùkọ́ Rere, kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 18  Jésù wí fún un pé: “Èé ṣe tí o fi pè mí ní ẹni rere?+ Kò sí ẹni rere, àyàfi ẹnì kan, Ọlọ́run.+ 19  Ìwọ mọ àwọn àṣẹ náà, ‘Má ṣìkà pànìyàn,+ Má ṣe panṣágà,+ Má jalè,+ Má ṣe jẹ́rìí èké,+ Má lu jìbìtì,+ Bọlá fún baba àti ìyá rẹ.’”+ 20  Ọkùnrin náà wí fún un pé: “Olùkọ́, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo ti pa mọ́ láti ìgbà èwe mi wá.” 21  Jésù wò ó, ó sì ní ìfẹ́ fún un, ó sì wí fún un pé: “Ohun kan ni ó kù nípa rẹ: Lọ, ta àwọn ohun tí o ní, kí o sì fi fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.”+ 22  Ṣùgbọ́n ó banú jẹ́ nítorí àsọjáde náà, ó sì lọ pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn, nítorí ó ní ohun ìní púpọ̀.+ 23  Lẹ́yìn wíwò yí ká, Jésù wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun tí ó ṣòro fún àwọn tí wọ́n ní owó+ láti wọ ìjọba Ọlọ́run!”+ 24  Ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu bá+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn nítorí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ní ìdáhùnpadà, Jésù tún wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun tí ó ṣòro láti wọ ìjọba Ọlọ́run! 25  Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.”+ 26  Háà túbọ̀ ṣe wọ́n sí i, wọ́n sì wí fún un pé: “Ní ti tòótọ́, ta ni a lè gbà là?”+ 27  Ní wíwò wọ́n tààràtà, Jésù wí pé: “Fún ènìyàn kò ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún Ọlọ́run, nítorí ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”+ 28  Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí wí fún un pé: “Wò ó! Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì ti ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”+ 29  Jésù wí pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Kò sí ẹnì kan tí ó fi ilé sílẹ̀ tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí ìyá tàbí baba tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá nítorí mi àti nítorí ìhìn rere+ 30  tí kì yóò gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún+ nísinsìnyí ní sáà àkókò yìí, àwọn ilé àti àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn ìyá àti àwọn ọmọ àti àwọn pápá, pẹ̀lú àwọn inúnibíni,+ àti nínú ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀, ìyè àìnípẹ̀kun. 31  Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ yóò jẹ́ ẹni ìkẹyìn, àti ẹni ìkẹyìn yóò jẹ́ ẹni àkọ́kọ́.”+ 32  Wàyí o, wọ́n ń tẹ̀ síwájú ní ojú ọ̀nà gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, Jésù sì ń lọ níwájú wọn, kàyéfì sì ṣe wọ́n; ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n tẹ̀ lé e bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó mú àwọn méjìlá náà wá sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn nípa nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ pé yóò ṣẹlẹ̀ sí i:+ 33  “Àwa nìyí, tí a ń tẹ̀ síwájú gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, a ó sì fa Ọmọ ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá a lẹ́bi ikú, wọn yóò sì fà á lé àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,+ 34  wọn yóò sì fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọn yóò sì tutọ́ sí i lára, wọn yóò sì nà án lọ́rẹ́, wọn yóò sì pa á, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, yóò dìde.”+ 35  Jákọ́bù àti Jòhánù, àwọn ọmọkùnrin Sébédè+ méjèèjì, sì wá síwájú rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé: “Olùkọ́, àwa fẹ́ kí o ṣe ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè lọ́wọ́ rẹ fún wa.”+ 36  Ó wí fún wọn pé: “Kí ni ẹ ń fẹ́ kí n ṣe fún yín?” 37  Wọ́n wí fún un pé: “Yọ̀ǹda fún wa láti jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ọ̀kan ní òsì rẹ, nínú ògo rẹ.”+ 38  Ṣùgbọ́n Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ kò mọ ohun tí ẹ ń béèrè fún. Ṣé ẹ lè mu ife tí èmi ń mu, tàbí kí a batisí yín pẹ̀lú ìbatisí tí a fi ń batisí mi?”+ 39  Wọ́n wí fún un pé: “Àwa lè ṣe bẹ́ẹ̀.” Látàrí ìyẹn, Jésù wí fún wọn pé: “Ife tí mo ń mu ni ẹ óò mu, àti ìbatisí tí a fi ń batisí mi ni a ó fi batisí yín.+ 40  Bí ó ti wù kí ó rí, jíjókòó yìí ní ọ̀tún mi tàbí ní òsì mi kì í ṣe tèmi láti fi fúnni,+ ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti àwọn tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún.” 41  Tóò, nígbà tí àwọn mẹ́wàá yòókù gbọ́ nípa rẹ̀, ìkannú wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ru sí Jákọ́bù àti Jòhánù.+ 42  Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn pípè wọ́n wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ mọ̀ pé àwọn tí wọ́n fara hàn pé wọ́n ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn ẹni ńlá wọn a sì máa lo ọlá àṣẹ lórí wọn.+ 43  Báyìí kọ́ ni láàárín yín; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín,+ 44  ẹnì yòówù tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú gbogbo yín.+ 45  Nítorí Ọmọ ènìyàn pàápàá wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un,+ bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́ kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà+ ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.”+ 46  Wọ́n sì wá sí Jẹ́ríkò. Ṣùgbọ́n bí òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti ogunlọ́gọ̀ títóbi ṣe ń jáde kúrò ní Jẹ́ríkò, Báátíméù (ọmọkùnrin Tíméù), afọ́jú tí ó jẹ́ alágbe, jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú ọ̀nà.+ 47  Nígbà tí ó gbọ́ pé Jésù ará Násárétì ni, ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, ó sì ń sọ pé: “Ọmọkùnrin Dáfídì,+ Jésù, ṣàánú fún mi!”+ 48  Látàrí èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un kíkankíkn pé kí ó dákẹ́; ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ ni ó túbọ̀ ń kígbe sí i pé: “Ọmọkùnrin Dáfídì, ṣàánú fún mi!”+ 49  Nítorí náà, Jésù dúró, ó sì wí pé: “Ẹ pè é.” Wọ́n sì pe ọkùnrin afọ́jú náà, wọ́n wí fún un pé: “Mọ́kànle, dìde, ó ń pè ọ́.”+ 50  Ní bíbọ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ jùnù, ó fò sókè lórí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì lọ sọ́dọ̀ Jésù. 51  Ní dídá a lóhùn, Jésù wí pé: “Kí ni ìwọ fẹ́ kí n ṣe fún ọ?”+ Ọkùnrin afọ́jú náà wí fún un pé: “Rábónì, jẹ́ kí n tún ríran.”+ 52  Jésù sì wí fún un pé: “Máa lọ, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó tún ríran,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé e ní ojú ọ̀nà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé