Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Lúùkù 9:1-62

9  Lẹ́yìn náà, ó pe àwọn méjìlá náà jọ, ó sì fún wọn ní agbára àti ọlá àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀mí èṣù àti láti ṣe ìwòsàn àwọn àìsàn.+  Nítorí náà, ó rán wọn jáde láti wàásù ìjọba Ọlọ́run àti láti ṣe ìmúláradá,  ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ má ṣe gbé nǹkan kan dání fún ìrìnnà àjò náà, yálà ọ̀pá tàbí àsùnwọ̀n oúnjẹ, tàbí búrẹ́dì tàbí owó fàdákà; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ní ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ méjì.+  Ṣùgbọ́n ibì yòówù tí ẹ bá ti wọ ilé kan, ẹ dúró síbẹ̀, kí ẹ sì lọ láti ibẹ̀.+  Ibì yòówù tí àwọn ènìyàn kò bá sì ti gbà yín, nígbà tí ẹ bá ń jáde kúrò ní ìlú ńlá yẹn,+ ẹ gbọn ekuru ẹsẹ̀ yín dànù fún ẹ̀rí lòdì sí wọn.”+  Lẹ́yìn náà, ní bíbẹ̀rẹ̀, wọ́n la ìpínlẹ̀ náà já láti abúlé dé abúlé, ní pípolongo ìhìn rere àti ṣíṣe ìwòsàn níbi gbogbo.+  Wàyí o, Hẹ́rọ́dù olùṣàkóso àgbègbè náà gbọ́ nípa gbogbo ohun tí ń ṣẹlẹ̀, ọkàn rẹ̀ sì dàrú gidigidi nítorí àwọn kan ń sọ pé a ti gbé Jòhánù dìde kúrò nínú òkú,+  ṣùgbọ́n àwọn mìíràn pé Èlíjà ti fara hàn, ṣùgbọ́n síbẹ̀ àwọn mìíràn pé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì ìgbàanì ti dìde.  Hẹ́rọ́dù wí pé: “Jòhánù ni mo ti bẹ́ lórí.+ Ta wá ni ẹni yìí, tí mo ń gbọ́ irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí nípa rẹ̀?” Nítorí náà, ó ń wá ọ̀nà+ láti rí i. 10  Nígbà tí àwọn àpọ́sítélì sì padà, wọ́n ròyìn àwọn ohun tí wọ́n ti ṣe fún un.+ Pẹ̀lú èyíinì, ó mú wọn lọ́wọ́, ó sì fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ibi ìdákọ́ńkọ́+ nínú ìlú ńlá tí a ń pè ní Bẹtisáídà. 11  Ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n mọ̀, àwọn ogunlọ́gọ̀ tẹ̀ lé e. Ó sì fi inú rere gbà wọ́n, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ fún wọn nípa ìjọba Ọlọ́run,+ ó sì mú àwọn tí wọ́n nílò ìwòsàn lára dá.+ 12  Nígbà náà ni ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Àwọn méjìlá náà wá nísinsìnyí, wọ́n sì wí fún un pé: “Rán ogunlọ́gọ̀ náà lọ, kí wọ́n lè lọ sínú àwọn abúlé àti eréko tí ń bẹ ní àyíká, kí wọ́n sì lè wá ibùwọ̀, kí wọ́n sì wá àwọn ìpèsè oúnjẹ, nítorí pé lóde níhìn-ín ibi tí ó dá ni a wà.”+ 13  Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ẹ fún wọn ní nǹkan láti jẹ.”+ Wọ́n wí pé: “Àwa kò ní nǹkan kan ju ìṣù búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì,+ àyàfi bóyá bí àwa fúnra wa bá lọ ra àwọn èlò oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn wọ̀nyí.”+ 14  Ní ti tòótọ́, wọ́n jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin.+ Ṣùgbọ́n ó wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ mú kí wọ́n rọ̀gbọ̀kú gẹ́gẹ́ bí nídìí oúnjẹ, ní àwùjọ-àwùjọ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ nǹkan bí àádọ́ta.”+ 15  Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì mú kí gbogbo wọ́n rọ̀gbọ̀kú. 16  Lẹ́yìn náà, ní mímú ìṣù búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo òkè ọ̀run, ó súre sórí wọn, ó sì bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn láti gbé kalẹ̀ níwájú ogunlọ́gọ̀ náà.+ 17  Nítorí náà, gbogbo wọ́n jẹ, wọ́n sì yó, a sì kó àṣẹ́kùsílẹ̀ tí wọ́n ní jọ, èébù apẹ̀rẹ̀ méjìlá.+ 18  Lẹ́yìn náà, bí ó ti ń gbàdúrà ní òun nìkan ṣoṣo, àwọn ọmọ ẹ̀yìn kóra jọpọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì bi wọ́n léèrè, pé: “Ta ni àwọn ogunlọ́gọ̀ ń sọ pé mo jẹ́?”+ 19  Ní ìfèsìpadà, wọ́n sọ pé: “Jòhánù Oníbatisí; ṣùgbọ́n àwọn mìíràn, Èlíjà, àti síbẹ̀ àwọn mìíràn, pé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì ìgbàanì ti dìde.”+ 20  Nígbà náà ni ó sọ fún wọn pé: “Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin, ta ni ẹ sọ pé mo jẹ́?” Pétérù sọ ní ìfèsìpadà pé:+ “Kristi+ ti Ọlọ́run.” 21  Nígbà náà, nínú ọ̀rọ̀ tí ó bá wọn sọ kíkankíkan, ó fún wọn ní ìtọ́ni láti má ṣe máa sọ èyí fún ẹnikẹ́ni,+ 22  ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Ọmọ ènìyàn gbọ́dọ̀ fara gba ọ̀pọ̀ ìjìyà, kí àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin sì kọ̀ ọ́ tì, kí a sì pa á,+ kí a sì gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta.”+ 23  Nígbà náà ni ó ń bá a lọ láti sọ fún gbogbo ènìyàn pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀,+ kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.+ 24  Nítorí ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là yóò pàdánù rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá pàdánù ọkàn rẹ̀ nítorí mi ni ẹni tí yóò gbà á là.+ 25  Ní ti gidi, àǹfààní wo ni ẹnì kan ṣe ara rẹ̀ bí ó bá jèrè gbogbo ayé, ṣùgbọ́n tí ó pàdánù ara rẹ̀ tàbí tí ó ṣòfò?+ 26  Nítorí ẹnì yòówù tí ó bá tijú èmi àti àwọn ọ̀rọ̀ mi, Ọmọ ènìyàn yóò tijú ẹni yìí nígbà tí ó bá dé nínú ògo rẹ̀ àti ti Baba àti ti àwọn áńgẹ́lì mímọ́.+ 27  Ṣùgbọ́n mo sọ fún yín lótìítọ́, Àwọn kan wà lára àwọn tí wọ́n dúró níhìn-ín tí kì yóò tọ́ ikú wò rárá títí wọn yóò fi kọ́kọ́ rí ìjọba Ọlọ́run.”+ 28  Ní ti tòótọ́ gan-an, ní nǹkan bí ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Pétérù àti Jòhánù àti Jákọ́bù lọ́wọ́, ó sì gun orí òkè ńlá lọ láti gbàdúrà.+ 29  Bí ó sì ti ń gbàdúrà, ìrísí+ ojú rẹ̀ di èyí tí ó yàtọ̀, aṣọ-ọ̀ṣọ́ rẹ̀ sì di funfun tí ń dán yinrin.+ 30  Pẹ̀lúpẹ̀lù, wò ó! àwọn ọkùnrin méjì ń bá a sọ̀rọ̀, àwọn ẹni tí í ṣe Mósè àti Èlíjà.+ 31  Àwọn wọ̀nyí fara hàn pẹ̀lú ògo, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa lílọ rẹ̀ tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ fún un láti mú ṣẹ ní Jerúsálẹ́mù.+ 32  Wàyí o, Pétérù àti àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ ni oorun ń kùn gidigidi; ṣùgbọ́n nígbà tí ojú wọ́n dá, wọ́n rí ògo+ rẹ̀ àti àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n dúró pẹ̀lú rẹ̀. 33  Bí a sì ti ń ya àwọn wọ̀nyí kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Pétérù wí fún Jésù pé: “Olùkọ́ni, ó dára púpọ̀ fún wa láti wà níhìn-ín, nítorí náà, jẹ́ kí a gbé àgọ́ mẹ́ta nà ró, ọ̀kan fún ọ àti ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà,” bí kò ti mọ ohun tí ó ń sọ.+ 34  Ṣùgbọ́n bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, àwọsánmà kan gbára jọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣíji bò wọ́n. Bí wọ́n ti wọ inú àwọsánmà náà, ẹ̀rù bà wọ́n.+ 35  Ohùn+ kan sì wá láti inú àwọsánmà náà, wí pé: “Èyí ni Ọmọ mi, ẹni tí a ti yàn.+ Ẹ fetí sí i.”+ 36  Bí ohùn náà sì ti dún, Jésù nìkan ṣoṣo ni a rí.+ Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́, wọn kò sì ròyìn fún ẹnikẹ́ni ní ọjọ́ wọnnì èyíkéyìí nínú àwọn ohun tí wọ́n rí.+ 37  Ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, nígbà tí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ láti òkè ńlá náà, ogunlọ́gọ̀ ńlá pàdé rẹ̀.+ 38  Sì wò ó! ọkùnrin kan ké jáde láti inú ogunlọ́gọ̀ náà, pé: “Olùkọ́, mo bẹ̀ ọ́ kí o bojú wo ọmọkùnrin mi, nítorí pé òun nìkan ṣoṣo+ ni mo bí,+ 39  sì wò ó! ẹ̀mí kan+ máa ń gbé e, a sì ké jáde lójijì, a sì fi gìrì mú un pẹ̀lú ìfófòó, agbára káká ni ó sì fi máa ń fi í sílẹ̀ lẹ́yìn tí ó bá ti pa á lára. 40  Mo sì bẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ láti lé e jáde, ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é.”+ 41  Ní ìdáhùnpadà, Jésù wí pé: “Ìran aláìnígbàgbọ́ àti onímàgòmágó,+ báwo ni èmi yóò ti máa bá a lọ pẹ̀lú yín pẹ́ tó tí èmi yóò sì máa fara dà fún yín? Mú ọmọkùnrin rẹ wá síhìn-ín.”+ 42  Ṣùgbọ́n bí ó ti ń sún mọ́ tòsí pàápàá, ẹ̀mí èṣù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì fi gìrì mú un lọ́nà lílenípá. Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí lọ́nà mímúná, ó sì mú ọmọdékùnrin náà lára dá, ó sì fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́.+ 43  Tóò, háà bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gbogbo wọn sí agbára gíga lọ́lá+ ti Ọlọ́run. Wàyí o, bí ẹnu ti ń ya gbogbo wọn sí gbogbo ohun tí ó ń ṣe, ó wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: 44  “Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ríbi gbé ní etí yín, nítorí Ọmọ ènìyàn ni a ti yàn tẹ́lẹ̀ pé a ó fi lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́.”+ 45  Ṣùgbọ́n wọ́n ń bá a lọ láìní òye àsọjáde yìí. Ní ti tòótọ́, a fi í pa mọ́ fún wọn kí wọ́n má bàa lóye ìtúmọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń fòyà láti bi í léèrè nípa àsọjáde yìí.+ 46  Nígbà náà ni èrò kan wọ àárín wọn ní ti ẹni tí yóò jẹ́ ẹni ńlá jù lọ nínú wọn.+ 47  Jésù, ní mímọ èrò ọkàn-àyà wọn, mú ọmọ kékeré kan, ó gbé e dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀+ 48  ó sì wí fún wọn pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá gba ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi gbà mí pẹ̀lú, ẹnì yòówù tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni tí ó rán mi jáde pẹ̀lú.+ Nítorí ẹni tí ó bá hùwà bí ẹni tí ó kéré jù+ láàárín gbogbo yín ni ẹni ńlá.”+ 49  Ní ìdáhùnpadà, Jòhánù wí pé: “Olùkọ́ni, a rí ọkùnrin kan tí ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde+ nípa lílo orúkọ rẹ, a sì gbìyànjú láti dí i lọ́wọ́,+ nítorí òun kì í bá wa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”+ 50  Ṣùgbọ́n Jésù wí fún un pé: “Ẹ má ṣe gbìyànjú láti dí i lọ́wọ́, nítorí ẹni tí kò bá lòdì sí yín wà fún yín.”+ 51  Bí àwọn ọjọ́ tí a ó gbà á sókè+ ti ń pé bọ̀, ó gbé ojú rẹ̀ sọ́nà gangan láti lọ sí Jerúsálẹ́mù. 52  Nítorí náà, ó rán àwọn ońṣẹ́ jáde ṣáájú rẹ̀. Wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ, wọ́n sì wọ abúlé kan tí í ṣe ti àwọn ará Samáríà,+ láti ṣe ìmúrasílẹ̀ dè é; 53  ṣùgbọ́n wọn kò gbà á, nítorí pé ó ti gbé ojú sọ́nà láti lọ sí Jerúsálẹ́mù.+ 54  Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù àti Jòhánù+ rí èyí, wọ́n wí pé: “Olúwa, ṣé ìwọ fẹ́ kí a sọ fún iná+ kí ó sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, kí ó sì pa wọ́n rẹ́ ráúráú?” 55  Ṣùgbọ́n ó yí padà, ó sì bá wọn wí lọ́nà mímúná. 56  Nítorí náà, wọ́n lọ sí abúlé mìíràn. 57  Wàyí o, bí wọ́n ti ń lọ ní ojú ọ̀nà, ẹnì kan wí fún un pé: “Dájúdájú, èmi yóò tẹ̀ lé ọ lọ sí ibikíbi tí ìwọ bá lọ.”+ 58  Jésù sì wí fún un pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ibi wíwọ̀sí, ṣùgbọ́n Ọmọ ènìyàn kò ní ibì kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.”+ 59  Lẹ́yìn náà, ó wí fún òmíràn pé: “Di ọmọlẹ́yìn mi.” Ọkùnrin náà wí pé: “Gbà mí láyè láti kọ́kọ́ lọ sìnkú baba mi.”+ 60  Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé: “Jẹ́ kí àwọn òkú+ máa sin òkú wọn, ṣùgbọ́n ìwọ lọ, kí o sì máa polongo ìjọba Ọlọ́run káàkiri.”+ 61  Síbẹ̀, òmíràn wí pé: “Dájúdájú, èmi yóò tẹ̀ lé ọ, Olúwa; ṣùgbọ́n kọ́kọ́ gbà mí láyè láti sọ pé ó dìgbòóṣe+ fún àwọn tí ń bẹ ní agbo ilé mi.” 62  Jésù wí fún un pé: “Kò sí ènìyàn tí ó ti fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun ìtúlẹ̀,+ tí ó sì ń wo àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn+ tí ó yẹ dáadáa fún ìjọba Ọlọ́run.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé