Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Lúùkù 8:1-56

8  Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó ń rin ìrìn àjò lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.+ Àwọn méjìlá náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀, 2  àti àwọn obìnrin kan+ tí a ti wòsàn kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí burúkú àti àìsàn, Màríà tí àwọn ènìyàn ń pè ní Magidalénì, lára ẹni tí ẹ̀mí èṣù méje ti jáde,+ 3  àti Jòánà+ aya Kúsà, ọkùnrin tí Hẹ́rọ́dù fi ṣe alámòójútó, àti Sùsánà àti ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin mìíràn, àwọn ẹni tí ń ṣèránṣẹ́ fún wọn láti inú àwọn nǹkan ìní wọn.  Wàyí o, nígbà tí ogunlọ́gọ̀ ńlá ti kóra jọpọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n lọ bá a láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá, ó sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àpèjúwe+ kan pé:  “Afúnrúgbìn kan jáde lọ láti fún irúgbìn rẹ̀. Tóò, bí ó tí ń fúnrúgbìn, díẹ̀ lára rẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ojú ọ̀nà, a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ṣà á jẹ.+  Òmíràn balẹ̀ sórí àpáta ràbàtà, àti pé, lẹ́yìn rírújáde, ó gbẹ dànù nítorí ṣíṣàìní ọ̀rinrin.+  Òmíràn bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún tí wọ́n sì bá a dàgbà sókè fún un pa.+  Òmíràn bọ́ sórí erùpẹ̀ rere, àti pé, lẹ́yìn rírújáde, ó mú èso jáde ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún.”+ Bí ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí, ó tẹ̀ síwájú láti ké jáde pé: “Kí ẹni tí ó ní etí láti fetí sílẹ̀, fetí sílẹ̀.”+  Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ohun tí àpèjúwe yìí lè túmọ̀ sí.+ 10  Ó wí pé: “Ẹ̀yin ni a yọ̀ǹda fún láti lóye àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìjọba Ọlọ́run, ṣùgbọ́n fún àwọn ìyókù, ó jẹ́ ní àwọn àpèjúwe,+ kí ó bàa lè jẹ́ pé, bí wọ́n tilẹ̀ ń wò, kí wọ́n lè máa wò lásán àti pé, bí wọ́n tilẹ̀ ń gbọ́, kí wọ́n má lè lóye ìtúmọ̀ rẹ̀.+ 11  Wàyí o, èyí ni ìtúmọ̀ àpèjúwe+ náà: Irúgbìn náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.+ 12  Àwọn ti ẹ̀bá ojú ọ̀nà ni àwọn ẹni tí ó ti gbọ́,+ lẹ́yìn náà Èṣù+ wá, ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò nínú ọkàn-àyà wọn, kí wọ́n má bàa gbà gbọ́, kí a sì gbà wọ́n là.+ 13  Àwọn ti orí àpáta ràbàtà ni àwọn ẹni tí ó jẹ́ pé, nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ, wọ́n fi ìdùnnú gba ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí kò ní gbòǹgbò; wọ́n gbà gbọ́ fún àsìkò kan, ṣùgbọ́n ní àsìkò ìdánwò, wọ́n yẹsẹ̀.+ 14  Ní ti èyíinì tí ó bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún, ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó ti gbọ́, ṣùgbọ́n, nípa dídi ẹni tí àwọn àníyàn àti ọrọ̀ àti adùn+ ìgbésí ayé yìí gbé lọ, a fún wọn pa pátápátá, wọn kò sì mú nǹkan kan wá sí ìjẹ́pípé.+ 15  Ní ti èyíinì tí ó wà lórí erùpẹ̀ àtàtà, ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó jẹ́ pé, lẹ́yìn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ọkàn-àyà àtàtà àti rere,+ wọ́n dì í mú ṣinṣin, wọ́n sì so èso pẹ̀lú ìfaradà.+ 16  “Kò sí ẹnì kan, lẹ́yìn títan fìtílà, tí í fi ohun èlò bò ó tàbí tí í gbé e sábẹ́ ibùsùn, bí kò ṣe kí ó gbé e sórí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọlé wá lè rí ìmọ́lẹ̀.+ 17  Nítorí kò sí ohun tí a fi pa mọ́,+ tí kì yóò fara hàn kedere, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohunkóhun tí a rọra tọ́jú pa mọ́, tí kì yóò di mímọ̀, tí kì yóò sì wá sí ojútáyé.+ 18  Nítorí náà, ẹ máa fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀; nítorí ẹnì yòówù tí ó bá ní, a óò fún un ní púpọ̀ sí i,+ ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí kò bá ní, àní ohun tí ó lérò pé òun ní, ni a ó gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”+ 19  Wàyí o, ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ̀+ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ogunlọ́gọ̀ náà.+ 20  Bí ó ti wù kí ó rí, a ròyìn rẹ̀ fún un pé: “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ dúró lóde, wọn ń fẹ́ láti rí ọ.”+ 21  Ní ìfèsìpadà, ó wí fún wọn pé: “Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni àwọn wọ̀nyí tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣe é.”+ 22  Ó sì ṣe ní ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ náà, òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi kan, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí a sọdá sí ìhà kejì adágún.” Nítorí náà, wọ́n ṣíkọ̀.+ 23  Ṣùgbọ́n bí wọ́n ti ń lọ lójú omi, ó sùn lọ. Wàyí o, ìjì ẹlẹ́fùúùfù lílenípá kan sọ̀ kalẹ̀ sórí adágún náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kún fún omi, wọ́n sì wà nínú ewu.+ 24  Níkẹyìn, wọ́n lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì jí i, ní sísọ pé: “Olùkọ́ni, Olùkọ́ni, a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣègbé!”+ Ní gbígbéra nílẹ̀, ó bá ẹ̀fúùfù àti ìrugùdù omi náà wí lọ́nà mímúná,+ wọ́n sì rọlẹ̀, ìparọ́rọ́ sì dé. 25  Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé: “Ìgbàgbọ́ yín dà?” Ṣùgbọ́n bí ẹ̀rù ti bà wọ́n, ẹnu yà wọ́n, wọ́n ń sọ fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Ta nìyí ní ti gidi, nítorí ó ń pa àṣẹ ìtọ́ni fún ẹ̀fúùfù àti omi pàápàá, wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i?”+ 26  Wọ́n sì gúnlẹ̀ sí èbúté ní ilẹ̀ àwọn ará Gérásà, èyí tí ó wà ní ìhà òdì-kejì Gálílì.+ 27  Ṣùgbọ́n bí ó ti jáde sórí ilẹ̀, ọkùnrin kan láti ìlú ńlá náà, ẹni tí ó ní àwọn ẹ̀mí èṣù, pàdé rẹ̀. Fún àkókò ìgbà pípẹ́ ni kò sì ti wọ aṣọ, kì í sì í gbé ní ilé, bí kò ṣe láàárín àwọn ibojì.+ 28  Ní rírí Jésù, ó ké sókè, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, àti pẹ̀lú ohùn rara ó wí pé: “Kí ní pa tèmi tìrẹ pọ̀,+ Jésù Ọmọ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ? Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe mú mi joró.”+ 29  (Nítorí tí ó ti ń pàṣẹ fún ẹ̀mí àìmọ́ náà láti jáde kúrò lára ọkùnrin náà. Fún ìgbà tí ó ti pẹ́ ni ó ti dì í mú pinpin,+ a sì ti fi ẹ̀wọ̀n àti ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè é léraléra lábẹ́ ìṣọ́, ṣùgbọ́n ó máa ń já àwọn ìdè náà, tí ẹ̀mí èṣù náà a sì tì í lọ sí àwọn ibi tí ó dá.) 30  Jésù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó wí pé: “Líjíónì,” nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí èṣù ti wọ inú rẹ̀.+ 31  Wọ́n sì ń pàrọwà+ fún un láti má ṣe pàṣẹ fún wọn láti lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.+ 32  Wàyí o, ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀+ tí ó pọ̀ ní iye ń jẹun níbẹ̀ lórí òkè ńlá náà; nítorí náà, wọ́n pàrọwà fún un láti gbà wọ́n láyè láti wọ inú àwọn wọnnì.+ Ó sì gbà wọ́n láyè. 33  Nígbà náà ni àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò lára ọkùnrin náà, tí wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ọ̀wọ́ ẹran náà sì tú pùú sáré ré bèbè ọ̀gbun náà kọjá sínú adágún, wọ́n sì kú sómi.+ 34  Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn darandaran rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sá lọ, wọ́n sì ròyìn fún ìlú ńlá àti fún eréko náà.+ 35  Nígbà náà ni àwọn ènìyàn jáde wá láti rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sì wá bá Jésù, wọ́n sì rí ọkùnrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde kúrò lára rẹ̀, tí ó wọṣọ, ó sì wà nínú èrò inú rẹ̀ yíyèkooro, ó jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jésù; ẹ̀rù sì bà wọ́n.+ 36  Àwọn tí wọ́n ti rí i ròyìn fún wọn bí a ṣe mú ọkùnrin náà tí ó jẹ́ òǹdè ẹ̀mí èṣù lára dá.+ 37  Nítorí náà, gbogbo ògìdìgbó láti ìgbèríko tí ó wà ní àyíká àwọn ará Gérásà rọ̀ ọ́ pé kí ó kúrò lọ́dọ̀ wọn, nítorí tí ìbẹ̀rù ńláǹlà+ mú wọn. Nígbà náà ni ó wọ ọkọ̀ ojú omi, ó sì yí padà lọ. 38  Bí ó ti wù kí ó rí, ọkùnrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde lára rẹ̀ ń bẹ̀bẹ̀ ṣáá pé kí òun máa bá a lọ; ṣùgbọ́n ó rán ọkùnrin náà lọ, ní sísọ pé:+ 39  “Mú ọ̀nà rẹ pọ̀n padà sí ilé, sì máa bá a nìṣó ní ṣíṣèròyìn àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe fún ọ.”+ Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ó lọ, ó ń pòkìkí àwọn ohun tí Jésù ṣe fún un+ jákèjádò ìlú ńlá náà. 40  Nígbà tí Jésù padà dé, ogunlọ́gọ̀ náà fi inú rere gbà á, nítorí pé gbogbo wọ́n ti ń fojú sọ́nà fún un.+ 41  Ṣùgbọ́n, wò ó! ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jáírù wá, [ọkùnrin] yìí sì jẹ́ alága sínágọ́gù. Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jésù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pàrọwà fún un pé kí ó wọ ilé òun,+ 42  nítorí ó ní ọmọbìnrin bíbí kan ṣoṣo tí ó jẹ nǹkan bí ọmọ ọdún méjìlá, tí ó sì ń kú lọ.+ Bí ó ti ń lọ, àwọn ogunlọ́gọ̀ ṣùrù bò ó.+ 43  Obìnrin kan, tí ó ti ń jìyà lọ́wọ́ ìṣàn ẹ̀jẹ̀+ fún ọdún méjìlá, ẹni tí kò ṣeé ṣe fún láti rí ìwòsàn gbà lọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni,+   44  sún mọ́ ọn láti ẹ̀yìn, ó sì fọwọ́ kan ìṣẹ́tí+ ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀,+ ní ìṣẹ́jú akàn, ìṣàn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dúró.+ 45  Nítorí náà, Jésù wí pé: “Ta ni ẹni tí ó fọwọ́ kàn mí?”+ Nígbà tí gbogbo wọ́n ń sẹ́, Pétérù wí pé: “Olùkọ́ni, àwọn ogunlọ́gọ̀ bò ọ́ yí ká, wọ́n sì há ọ mọ́ gádígádí.”+ 46  Síbẹ̀síbẹ̀, Jésù wí pé: “Ẹnì kan fọwọ́ kàn mí, nítorí mo róye pé agbára+ jáde lọ lára mi.”+ 47  Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé kò bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí, obìnrin náà wá, ó ń wárìrì, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ ọ́ di mímọ̀ níwájú gbogbo ènìyàn ìdí tí òun fi fọwọ́ kàn án àti bí a ṣe mú òun lára dá ní ìṣẹ́jú akàn.+ 48  Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá;+ máa bá ọ̀nà rẹ lọ ní àlàáfíà.”+ 49  Nígbà tí ó ṣì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, aṣojú kan fún alága sínágọ́gù wá, ó wí pé: “Ọmọbìnrin rẹ ti kú; má ṣe tún kó ìyọnu bá olùkọ́ mọ́.”+ 50  Ní gbígbọ́ èyí, Jésù dá a lóhùn pé: “Má bẹ̀rù, sáà ti fi ìgbàgbọ́ hàn,+ a ó sì gbà á là.” 51  Nígbà tí ó dé ilé náà, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé pẹ̀lú òun àyàfi Pétérù àti Jòhánù àti Jákọ́bù àti baba àti ìyá ọmọdébìnrin náà.+ 52  Ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ń sunkún, wọ́n sì ń lu ara wọn nínú ẹ̀dùn-ọkàn nítorí rẹ̀. Nítorí náà, ó wí pé: “Ẹ dẹ́kun sísunkún,+ nítorí kò kú, ṣùgbọ́n ó ń sùn ni.”+ 53  Látàrí èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi í rẹ́rìn-ín tẹ̀gàn-tẹ̀gàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé ó ti kú.+ 54  Ṣùgbọ́n ó dì í ní ọwọ́ mú, ó sì pè é, ó wí pé: “Ọmọdébìnrin, dìde!”+ 55  Ẹ̀mí rẹ̀+ sì padà, ó sì dìde+ ní ìṣẹ́jú akàn, ó sì pa àṣẹ ìtọ́ni pé kí a fún un ní nǹkan láti jẹ.+ 56  Tóò, àwọn òbí rẹ̀ kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe; ṣùgbọ́n ó fún wọn ní ìtọ́ni láti má ṣe sọ nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ náà fún+ ẹnì kankan.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé