Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Lúùkù 7:1-50

7  Nígbà tí ó parí gbogbo àsọjáde rẹ̀ ní etí-ìgbọ́ àwọn ènìyàn, ó wọ Kápánáúmù.+  Wàyí o, ẹrú ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan, ẹni tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ń ṣòjòjò, ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.+  Nígbà tí ó gbọ́ nípa Jésù, ó rán àwọn àgbà ọkùnrin àwọn Júù lọ bá a láti rọ̀ ọ́ láti wá, kí ó sì gba ẹrú òun là láìséwu.  Nígbà náà ni àwọn tí wọ́n wá sọ́dọ̀ Jésù bẹ̀rẹ̀ sí fi taratara pàrọwà fún un, pé: “Ó yẹ ní ẹni tí ìwọ yóò fi èyí dá lọ́lá,  nítorí ó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wa+ àti pé òun alára ni ó kọ́ sínágọ́gù fún wa.”  Nítorí náà, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí kò jìnnà sí ilé náà, ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà ti rán àwọn ọ̀rẹ́ tẹ́lẹ̀ láti sọ fún un pé: “Ọ̀gá, má ṣèyọnu, nítorí èmi kò yẹ ní ẹni tí í gbà ọ́ wọlé sábẹ́ òrùlé mi.+  Fún ìdí yẹn, èmi kò ka ara mi yẹ láti wá sọ́dọ̀ rẹ. Ṣùgbọ́n sọ ọ̀rọ̀ náà, kí o sì jẹ́ kí ara ìránṣẹ́ mi dá.  Nítorí èmi pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí a fi sí ipò ọlá àṣẹ, tí mo ní àwọn ọmọ ogun lábẹ́ mi, èmi a sì wí fún ẹni yìí pé, ‘Mú ọ̀nà rẹ pọ̀n!’ òun a sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, àti fún òmíràn pé, ‘Wá!’ òun a sì wá, àti fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe èyí!’ òun a sì ṣe é.”+  Tóò, nígbà tí Jésù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu yà á sí i, ó sì yíjú sí ogunlọ́gọ̀ tí ń tẹ̀ lé e, ó sì wí pé: “Mo sọ fún yín pé, Èmi kò tíì rí ìgbàgbọ́ tí ó tóbi tó bẹ́ẹ̀+ ní Ísírẹ́lì pàápàá.” 10  Àwọn tí a sì rán, ní pípadà dé ilé, bá ẹrú náà nínú ìlera.+ 11  Kété lẹ́yìn èyí, ó rin ìrìn àjò lọ sí ìlú ńlá tí a ń pè ní Náínì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti ogunlọ́gọ̀ ńlá sì ń bá a rin ìrìn àjò. 12  Bí ó ti sún mọ́ ibodè ìlú ńlá náà, họ́wù, wò ó! wọ́n ń gbé ọkùnrin kan tí ó ti kú+ jáde, ọmọkùnrin bíbí kan ṣoṣo+ ìyá rẹ̀. Yàtọ̀ sí èyí, opó ni. Ogunlọ́gọ̀ tí ó tóbi púpọ̀ láti ìlú ńlá náà tún wà pẹ̀lú rẹ̀. 13  Nígbà tí Olúwa sì tajú kán rí i, àánú+ rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé: “Dẹ́kun sísunkún.”+ 14  Pẹ̀lú èyíinì, ó sún mọ́ ọn, ó sì fọwọ́ kan agà ìgbókùú náà, àwọn tí wọ́n gbé e sì dúró jẹ́ẹ́, ó sì wí pé: “Ọ̀dọ́kùnrin, mo wí fún ọ, Dìde!”+ 15  Ọkùnrin tí ó ti kú náà sì dìde jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó sì fi í fún ìyá rẹ̀.+ 16  Wàyí o, ìbẹ̀rù+ mú gbogbo wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yin Ọlọ́run lógo, pé: “A ti gbé wòlíì ńlá+ kan dìde láàárín wa,” àti pé, “Ọlọ́run ti yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ̀.”+ 17  Ìhìn yìí nípa rẹ̀ sì tàn ká gbogbo Jùdíà àti gbogbo ìgbèríko tí ó wà ní àyíká. 18  Wàyí o, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù ròyìn fún un nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí.+ 19  Nítorí náà, Jòhánù fi ọlá àṣẹ pe àwọn méjì kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì rán wọn sí Olúwa láti sọ pé: “Ṣé ìwọ ni Ẹni Tí Ń Bọ̀ náà tàbí kí a máa fojú sọ́nà fún ẹnì kan tí ó yàtọ̀?”+ 20  Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, àwọn ọkùnrin náà sọ pé: “Jòhánù Oníbatisí rán wa wá sọ́dọ̀ rẹ láti sọ pé, ‘Ṣé ìwọ ni Ẹni Tí Ń Bọ̀ náà tàbí kí a máa fojú sọ́nà fún ẹlòmíràn?’” 21  Ní wákàtí yẹn, ó wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ sàn kúrò nínú àwọn àìsàn+ àti àwọn òkùnrùn burúkú àti àwọn ẹ̀mí burúkú, ó sì ṣe ojú rere sí ọ̀pọ̀ afọ́jú láti ríran. 22  Nítorí bẹ́ẹ̀, ní ìdáhùn, ó sọ fún àwọn méjì náà pé: “Ẹ máa bá ọ̀nà yín lọ,+ ẹ ròyìn ohun tí ẹ rí, tí ẹ sì gbọ́ fún Jòhánù: àwọn afọ́jú+ ń ríran, àwọn arọ ń rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití sì ń gbọ́ràn, a ń gbé àwọn òkú dìde, a ń sọ ìhìn rere+ fún àwọn òtòṣì.+ 23  Aláyọ̀ sì ni ẹni tí kò kọsẹ̀ lára mi.”+ 24  Nígbà tí àwọn ońṣẹ́ Jòhánù lọ tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà nípa Jòhánù pé: “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aginjù? Ṣé esùsú tí ẹ̀fúùfù ń bì síwá sẹ́yìn ni?+ 25  Kí wá ni ẹ jáde lọ wò? Ṣé ọkùnrin tí ó wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè múlọ́múlọ́+ ni? Họ́wù, àwọn tí wọ́n wọ aṣọ ìmúra dídángbinrin, tí wọ́n sì wà nínú fàájì wà ní àwọn ilé ọba.+ 26  Ní ti gidi, kí wá ni ẹ jáde lọ wò? Ṣé wòlíì kan ni?+ Bẹ́ẹ̀ ni, mo sọ fún yín, àti èyí tí ó ju wòlíì kan lọ́pọ̀lọpọ̀.+ 27  Èyí ni ẹni tí a kọ̀wé nípa rẹ̀ pé, ‘Wò ó! Èmi yóò rán ońṣẹ́ mi jáde níwájú rẹ,+ ẹni tí yóò palẹ̀ ọ̀nà rẹ mọ́ ṣáájú rẹ.’+ 28  Mo sọ fún yín, Láàárín àwọn tí obìnrin bí, kò sí ọ̀kan tí ó tóbi ju+ Jòhánù; ṣùgbọ́n ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹni tí ó kéré jù nínú ìjọba Ọlọ́run tóbi jù ú.”+ 29  (Gbogbo ènìyàn àti àwọn agbowó orí, nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, polongo Ọlọ́run ní olódodo,+ níwọ̀n bí a ti fi ìbatisí Jòhánù+ batisí wọn. 30  Ṣùgbọ́n àwọn Farisí àti àwọn ògbóǹkangí nínú Òfin ṣàìka ète+ Ọlọ́run fún wọn sí, níwọ̀n bí a kò ti batisí wọn láti ọwọ́ rẹ̀.) 31  “Ta wá ni èmi yóò fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé, wọ́n sì dà bí ta ni?+ 32  Wọ́n dà bí àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń ké jáde sí ara wọn, tí wọ́n sì wí pé, ‘Àwa fọn fèrè fún yín, ṣùgbọ́n ẹ kò jó; àwa pohùnréré ẹkún, ṣùgbọ́n ẹ kò sunkún.’+ 33  Lọ́nà tí ó bá a mu rẹ́gí, Jòhánù Oníbatisí wá, kì í jẹ búrẹ́dì bẹ́ẹ̀ ni kì í mu wáìnì, ṣùgbọ́n ẹ sọ pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù.’+ 34  Ọmọ ènìyàn wá, ó ń jẹ, ó sì ń mu, ṣùgbọ́n ẹ sọ pé, ‘Wò ó! Ọkùnrin kan tí ó jẹ́ alájẹkì, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún mímu wáìnì, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀!’+ 35  Síbẹ̀ náà, a fi ọgbọ́n+ hàn ní olódodo nípasẹ̀ gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀.”+ 36  Wàyí o, ẹnì kan nínú àwọn Farisí ń rọ̀ ọ́ ṣáá láti bá òun jẹun. Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ó wọ ilé+ Farisí náà, ó sì rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì. 37  Sì wò ó! obìnrin kan tí a mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ìlú ńlá náà gbọ́ pé ó ń rọ̀gbọ̀kú nídìí oúnjẹ nínú ilé Farisí náà, ó sì mú orùba alabásítà+ òróró onílọ́fínńdà wá, 38  àti, ní bíbọ́ sí ipò kan lẹ́yìn lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sunkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi omijé rẹ̀ rin ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nù ún kúrò. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó fi ẹnu ko ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó sì fi òróró onílọ́fínńdà náà pa á. 39  Ní rírí èyí, Farisí tí ó ké sí i sọ nínú ara rẹ̀ pé: “[Ọkùnrin] yìí, bí ó bá jẹ́ wòlíì ni,+ ì bá mọ ẹni àti irú obìnrin tí ẹni tí ń fọwọ́ kan òun jẹ́, pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”+ 40  Ṣùgbọ́n ní ìfèsìpadà, Jésù wí fún un pé: “Símónì, mo ní ohun kan láti sọ fún ọ.” Ó sọ pé: “Olùkọ́, sọ ọ!” 41  “Àwọn ọkùnrin méjì jẹ́ ajigbèsè sí awínni kan; ọ̀kan jẹ gbèsè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó dínárì,+ ṣùgbọ́n èkejì jẹ àádọ́ta. 42  Nígbà tí wọn kò ní ohunkóhun tí wọn yóò fi san án padà, ó dárí ji+ àwọn méjèèjì ní fàlàlà. Nítorí náà, èwo nínú wọn ni yóò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ jù?” 43  Ní ìdáhùn, Símónì wí pé: “Mo rò pé ẹni tí ó dárí púpọ̀ jì ní fàlàlà ni.” Ó wí fún un pé: “Ìwọ ṣèdájọ́ lọ́nà tí ó tọ́.” 44  Pẹ̀lú èyíinì, ó yíjú sí obìnrin náà, ó sì wí fún Símónì pé: “Ṣé o rí obìnrin yìí? Èmi wọ ilé rẹ; ìwọ kò fún mi ní omi+ fún ẹsẹ̀ mi. Ṣùgbọ́n obìnrin yìí fi omijé rẹ̀ rin ẹsẹ̀ mi, ó sì fi irun rẹ̀ nù ún kúrò. 45  Ìwọ kò fẹnu kò mí lẹ́nu rárá;+ ṣùgbọ́n obìnrin yìí, láti wákàtí tí mo ti wọlé, kò dẹ́kun fífi ẹnu ko ẹsẹ̀ mi lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. 46  Ìwọ kò fi òróró pa orí mi;+ ṣùgbọ́n obìnrin yìí fi òróró onílọ́fínńdà pa ẹsẹ̀ mi. 47  Fún ìdí yìí, mo sọ fún ọ, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀, a dárí wọn jì,+ nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ púpọ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí a dárí díẹ̀ jì, nífẹ̀ẹ́ díẹ̀.” 48  Nígbà náà ni ó wí fún un pé: “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì.”+ 49  Látàrí èyí, àwọn tí wọ́n rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì pẹ̀lú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ nínú ara wọn pé: “Ta ni [ọkùnrin] yìí tí ó tilẹ̀ ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini?”+ 50  Ṣùgbọ́n ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ìgbàgbọ́ rẹ ti gbà ọ́ là;+ máa bá ọ̀nà rẹ lọ ní àlàáfíà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé