Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Lúùkù 6:1-49

6  Wàyí o, ní sábáàtì kan, ó ṣẹlẹ̀ pé ó ń la àwọn pápá ọkà kọjá, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń ya,+ wọ́n sì ń jẹ àwọn erín ọkà, wọ́n ń fi ọwọ́ wọn ra wọ́n.+  Látàrí èyí, àwọn kan nínú àwọn Farisí wí pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń ṣe ohun tí kò bófin mu+ ní sábáàtì?”+  Ṣùgbọ́n Jésù wí ní ìfèsìpadà fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò tíì ka ohun náà tí Dáfídì+ ṣe, nígbà tí ebi ń pa òun àti àwọn ọkùnrin tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀?+  Bí ó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, tí ó sì gba àwọn ìṣù búrẹ́dì àgbékawájú,+ tí ó sì jẹ, tí ó sì fi díẹ̀ fún àwọn ọkùnrin tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, èyí tí kò bófin mu fún ẹnì kankan láti jẹ bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan?”+  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Olúwa sábáàtì ni Ọmọ ènìyàn jẹ́.”+  Ó sì ṣe ní sábáàtì+ mìíràn, ó wọ inú sínágọ́gù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni. Ọkùnrin kan sì wà níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ.+  Àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí ń ṣọ́+ ọ lójú méjèèjì nísinsìnyí láti rí i bóyá yóò ṣe ìwòsàn ní sábáàtì, kí wọ́n lè rí ọ̀nà kan láti fẹ̀sùn kàn án.+  Bí ó ti wù kí ó rí, ó mọ èrò wọn,+ síbẹ̀síbẹ̀ ó wí fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé: “Dìde, kí o sì dúró ní àárín.” Ó sì dìde, ó sì mú ìdúró rẹ̀.+  Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé: “Èmi béèrè lọ́wọ́ yín, Ó ha bófin mu ní sábáàtì láti ṣe rere+ tàbí láti ṣeni léṣe, láti gba ọkàn là tàbí láti pa á run?”+ 10  Lẹ́yìn tí ó sì ti wo gbogbo wọn yí ká, ó wí fún ọkùnrin náà pé: “Na ọwọ́ rẹ.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀, a sì mú ọwọ́ rẹ̀ padà bọ̀ sípò.+ 11  Ṣùgbọ́n orí wọn wá gbóná, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jíròrò ohun tí wọ́n lè ṣe sí Jésù.+ 12  Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ó jáde lọ sórí òkè ńlá láti gbàdúrà,+ ó sì ń bá a lọ nínú àdúrà gbígbà sí Ọlọ́run+ ní gbogbo òru náà. 13  Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ojúmọ́, ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì yan méjìlá lára wọn, àwọn tí ó pè ní “àpọ́sítélì” pẹ̀lú:+ 14  Símónì, ẹni tí ó tún pè ní Pétérù,+ àti Áńdérù arákùnrin rẹ̀, àti Jákọ́bù àti Jòhánù,+ àti Fílípì+ àti Batolómíù, 15  àti Mátíù àti Tọ́másì,+ àti Jákọ́bù ọmọkùnrin Áfíọ́sì, àti Símónì tí a ń pè ní “onítara,”+ 16  àti Júdásì ọmọkùnrin Jákọ́bù, àti Júdásì Ísíkáríótù, ẹni tí ó di ọ̀dàlẹ̀.+ 17  Ó sì sọ̀ kalẹ̀ pẹ̀lú wọn, ó sì mú ìdúró rẹ̀ ní ibi títẹ́jú pẹrẹsẹ kan, ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà níbẹ̀, àti ògìdìgbó ńlá àwọn ènìyàn+ láti gbogbo Jùdíà àti Jerúsálẹ́mù àti ìgbèríko ẹ̀bá òkun Tírè àti Sídónì, àwọn tí wọ́n wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí a sì mú wọn lára dá kúrò nínú àwọn àìsàn wọn.+ 18  Kódà, àwọn tí ẹ̀mí àìmọ́ ń dà láàmú ni a wòsàn. 19  Gbogbo ogunlọ́gọ̀ náà sì ń wá ọ̀nà láti fọwọ́ kàn án,+ nítorí pé agbára+ ń jáde lọ láti ara rẹ̀, ó sì ń mú gbogbo wọn lára dá. 20  Ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé:+ “Aláyọ̀ ni ẹ̀yin òtòṣì,+ nítorí pé tiyín ni ìjọba Ọlọ́run. 21  “Aláyọ̀ ni ẹ̀yin tí ebi ń pa+ nísinsìnyí, nítorí pé a óò bọ́ yín yó.+ “Aláyọ̀ ni ẹ̀yin tí ń sunkún nísinsìnyí, nítorí pé ẹ óò rẹ́rìn-ín.+ 22  “Aláyọ̀ ni yín nígbàkigbà tí àwọn ènìyàn bá kórìíra+ yín, àti nígbàkigbà tí wọ́n bá ta yín nù láwùjọ, tí wọ́n sì gàn yín, tí wọ́n sì ta orúkọ yín nù+ gẹ́gẹ́ bí ẹni burúkú nítorí Ọmọ ènìyàn. 23  Ẹ yọ̀ ní ọjọ́ yẹn, kí ẹ sì fò sókè, nítorí, wò ó! èrè yín pọ̀ ní ọ̀run, nítorí ìwọ̀nyẹn ni ohun kan náà tí àwọn baba ńlá wọn ti máa ń ṣe sí àwọn wòlíì.+ 24  “Ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹ̀yin ọlọ́rọ̀,+ nítorí tí ẹ ń ní ìtúnú yín ní kíkún.+ 25  “Ègbé ni fún ẹ̀yin tí a bọ́ yó bámúbámú nísinsìnyí, nítorí pé ebi yóò pa yín.+ “Ègbé, ẹ̀yin tí ẹ ń rẹ́rìn-ín nísinsìnyí, nítorí pé ẹ ó ṣọ̀fọ̀, ẹ ó sì sunkún.+ 26  “Ègbé, nígbàkígbà tí gbogbo ènìyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín ní dáadáa, nítorí nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn baba ńlá wọn ṣe sí àwọn wòlíì èké.+ 27  “Ṣùgbọ́n mo wí fún ẹ̀yin tí ń fetí sílẹ̀ pé, Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín,+ láti máa ṣe rere+ sí àwọn tí ó kórìíra yín, 28  láti máa súre fún àwọn tí ń gégùn-ún fún yín, láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń fi ìwọ̀sí lọ̀ yín.+ 29  Ẹni tí ó bá gbá ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ kan,+ gbé èkejì fún un pẹ̀lú; àti pé, ẹni tí ó bá gba+ ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ lọ, má ṣe dù ú ní ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ pàápàá. 30  Fi fún olúkúlùkù ẹni tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ,+ àti lọ́wọ́ ẹni tí ń kó àwọn nǹkan rẹ lọ ni kí ìwọ má ṣe béèrè wọn padà. 31  “Pẹ̀lúpẹ̀lù, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.+ 32  “Àti pé bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tí wọ́n ń nífẹ̀ẹ́ yín, ìyìn wo ni ó jẹ́ fún yín? Nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá a máa nífẹ̀ẹ́ àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ wọn.+ 33  Bí ẹ bá sì ń ṣe rere sí àwọn tí ń ṣe rere sí yín, ìyìn wo ni ó jẹ́ fún yín ní ti gidi? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá a máa ṣe bákan náà.+ 34  Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ẹ bá ń wín àwọn tí ẹ retí láti rí gbà láti ọ̀dọ̀ wọn láìsí èlé,+ ìyìn ọlá wo ni ó jẹ́ fún yín? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá a máa wín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láìsí èlé kí wọ́n bàa lè gba ohun kan náà padà.+ 35  Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa ṣe rere àti láti máa wínni láìsí èlé,+ láìretí ohunkóhun padà; èrè yín yóò sì pọ̀, ẹ ó sì jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ,+ nítorí pé ó jẹ́ onínúrere+ sí àwọn aláìlọ́pẹ́ àti àwọn ẹni burúkú. 36  Ẹ máa bá a lọ ní dídi aláàánú, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú.+ 37  “Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́ lọ́nàkọnà;+ ẹ sì dẹ́kun dídánilẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi lọ́nàkọnà. Ẹ máa bá a nìṣó ní títúnisílẹ̀, a ó sì tú yín sílẹ̀.+ 38  Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín.+ Wọn yóò da òṣùwọ̀n àtàtà, tí a kì mọ́lẹ̀, tí a mì pọ̀, tí ó sì kún àkúnwọ́sílẹ̀ sórí itan yín. Nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n padà fún yín.”+ 39  Lẹ́yìn náà, ó tún sọ àpèjúwe kan fún wọn pé: “Afọ́jú kò lè fi afọ́jú mọ̀nà, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn méjèèjì yóò tàkìtì sínú kòtò, àbí wọn kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀?+ 40  Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kan kò ga ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí a fún ní ìtọ́ni lọ́nà pípé yóò dà bí olùkọ́ rẹ̀.+ 41  Èé ṣe tí ìwọ fi wá ń wo èérún pòròpórò tí ó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n tí o kò kíyè sí igi ìrólé tí ó wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ?+ 42  Báwo ni ìwọ ṣe lè wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Arákùnrin, yọ̀ǹda fún mi láti yọ èérún pòròpórò tí ó wà nínú ojú rẹ kúrò,’ nígbà tí ó jẹ́ pé ìwọ fúnra rẹ kò wo igi ìrólé tí ó wà nínú ojú tìrẹ yẹn?+ Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ+ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì ríran kedere bí o ṣe lè yọ èérún pòròpórò tí ó wà nínú ojú arákùnrin rẹ+ kúrò. 43  “Nítorí kò sí igi àtàtà kan tí ń mú èso jíjẹrà jáde; ẹ̀wẹ̀ kò sí igi jíjẹrà kan tí ń mú èso àtàtà jáde.+ 44  Nítorí igi kọ̀ọ̀kan ni a ń mọ̀ nípasẹ̀ èso tirẹ̀.+ Fún àpẹẹrẹ, àwọn ènìyàn kì í kó ọ̀pọ̀tọ́ jọ láti orí igi ẹ̀gún, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gé èso àjàrà lára igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún.+ 45  Ẹni rere a máa mú ohun rere jáde wá láti inú ìṣúra rere+ ọkàn-àyà rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni burúkú a máa mú ohun tí í ṣe burúkú jáde wá láti inú ìṣúra burúkú rẹ̀; nítorí lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu rẹ̀ ń sọ.+ 46  “Èé ṣe tí ẹ fi wá ń pè mí ní ‘Olúwa! Olúwa!’ ṣùgbọ́n tí ẹ kò ṣe àwọn ohun tí mo wí?+ 47  Olúkúlùkù ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, tí ó sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì ṣe wọ́n, èmi yóò fi ẹni tí ó jọ hàn yín:+ 48  Ó dà bí ọkùnrin kan tí ń kọ́ ilé kan, ẹni tí ó walẹ̀ jìn, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ sórí àpáta ràbàtà. Nítorí náà, nígbà tí ìkún omi+ dé, odò ya lu ilé yẹn, ṣùgbọ́n kò lágbára tó láti mì í, nítorí kíkọ́ tí a kọ́ ọ dáadáa.+ 49  Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹni tí ó bá gbọ́, tí kò sì ṣe,+ ó dà bí ọkùnrin kan tí ó kọ́ ilé kan sórí ilẹ̀ láìsí ìpìlẹ̀. Odò ya lù ú, ó sì wólulẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìwópalẹ̀+ ilé náà sì wá pọ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé