Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Lúùkù 5:1-39

5  Ní àkókò kan nígbà tí ogunlọ́gọ̀ ń ṣù mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, tí wọ́n sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ adágún Jẹ́nẹ́sárẹ́tì.+  Ó sì rí ọkọ̀ ojú omi méjì tí wọ́n gúnlẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ adágún náà, ṣùgbọ́n àwọn apẹja ti jáde kúrò nínú wọn, wọ́n sì ń fọ àwọ̀n wọn.+  Ní wíwọ ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ ojú omi náà, èyí tí ó jẹ́ ti Símónì, ó sọ fún un pé kí ó wa ọkọ̀ ojú omi náà lọ síwájú díẹ̀ kúrò ní ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ogunlọ́gọ̀ láti inú ọkọ̀ ojú omi+ náà.  Nígbà tí ó ṣíwọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ó sọ fún Símónì pé: “Wa ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi tí ó jindò, kí ẹ sì rọ àwọn àwọ̀n yín sísàlẹ̀+ fún àkópọ̀ ẹja.”  Ṣùgbọ́n ní ìfèsìpadà, Símónì wí pé: “Olùkọ́ni, ní gbogbo òru ni àwa ṣe làálàá, a kò sì mú nǹkan kan,+ ṣùgbọ́n nítorí àṣẹ àsọjáde rẹ, ṣe ni èmi yóò rọ àwọn àwọ̀n náà sísàlẹ̀.”  Tóò, nígbà tí wọ́n ṣe èyí, wọ́n kó ògìdìgbó ńlá ẹja. Ní ti tòótọ́, àwọn àwọ̀n wọn bẹ̀rẹ̀ sí fà ya sọ́tọ̀ọ̀tọ̀.  Nítorí náà, wọ́n ṣẹ́wọ́ sí àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn nínú ọkọ̀ ojú omi kejì láti wá ṣèrànwọ́ fún wọn;+ wọ́n sì wá lóòótọ́, wọ́n sì kún ọkọ̀ ojú omi méjèèjì, tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ̀nyí fi bẹ̀rẹ̀ sí rì.  Ní rírí èyí, Símónì Pétérù+ wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jésù, ó wí pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Olúwa.”+  Nítorí pé ìyàlẹ́nu bo òun àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní tìtorí àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó, 10  bákan náà sì ni Jákọ́bù àti Jòhánù, àwọn ọmọkùnrin Sébédè,+ tí wọ́n jẹ́ alájọpín pẹ̀lú Símónì. Ṣùgbọ́n Jésù wí fún Símónì pé: “Dẹ́kun fífòyà. Láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò máa mú àwọn ènìyàn láàyè.”+ 11  Nítorí náà, wọ́n dá àwọn ọkọ̀ náà padà wá sí ilẹ̀, wọ́n sì pa ohun gbogbo tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.+ 12  Ní àkókò kan lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó wà ní ọ̀kan nínú àwọn ìlú ńlá náà, wò ó! ọkùnrin kan tí ó kún fún ẹ̀tẹ̀! Nígbà tí ó tajú kán rí Jésù, ó dojú bolẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́, ó wí pé: “Olúwa, bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.”+ 13  Àti nítorí náà, ní nína ọwọ́ rẹ̀, ó fọwọ́ kàn án, ó wí pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà sì pòórá kúrò lára rẹ̀.+ 14  Ó sì pa àṣẹ ìtọ́ni fún ọkùnrin náà láti má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni:+ “Ṣùgbọ́n lọ, kí o sì fi ara rẹ han àlùfáà,+ kí o sì rú ẹbọ+ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìwẹ̀nùmọ́ rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ṣe lànà sílẹ̀, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn.”+ 15  Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ túbọ̀ ń tàn kálẹ̀ sí i, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá a sì máa kóra jọpọ̀ láti fetí sílẹ̀ àti kí a lè wo àìsàn wọn sàn.+ 16  Bí ó ti wù kí ó rí, ó ń bá a lọ ní wíwà ní ipò àdádó ní àwọn aṣálẹ̀, ó sì ń gbàdúrà.+ 17  Ó sì ṣe ní ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ náà, ó ń kọ́ni, àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ òfin tí wọ́n jáde wá láti gbogbo àwọn abúlé Gálílì àti Jùdíà àti Jerúsálẹ́mù sì jókòó níbẹ̀; agbára Jèhófà sì wà níbẹ̀ fún un láti ṣe ìmúláradá.+ 18  Sì wò ó! àwọn ọkùnrin tí ń gbé ọkùnrin kan tí ó jẹ́ alárùn ẹ̀gbà lórí ibùsùn, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti gbé e wọlé, kí wọ́n sì gbé e sí iwájú rẹ̀.+ 19  Nítorí náà, nígbà tí wọn kò rí ọ̀nà gbé e wọlé ní tìtorí ogunlọ́gọ̀ náà, wọ́n gun òkè lọ sí òrùlé, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ pẹ̀lú ibùsùn kékeré náà gba àárín àwo ìbolé sí àárín àwọn tí ń bẹ níwájú Jésù.+ 20  Nígbà tí ó sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí pé: “Ọkùnrin yìí, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”+ 21  Nítorí èyí, àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí gbèrò, ní sísọ pé: “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀ òdì?+ Ta ní lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo?”+ 22  Ṣùgbọ́n Jésù, ní fífi òye mọ èrò wọn, sọ ní dídá wọn lóhùn pé: “Kí ni ẹ ń gbèrò nínú ọkàn-àyà yín?+ 23  Èwo ni ó rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tàbí láti sọ pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn’?+ 24  Ṣùgbọ́n kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ ènìyàn ní ọlá àṣẹ ní ilẹ̀ ayé láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini—” ó sọ fún ọkùnrin alárùn ẹ̀gbà náà pé: “Mo wí fún ọ, Dìde, sì gbé ibùsùn kékeré rẹ, kí o sì mú ọ̀nà ilé rẹ pọ̀n.”+ 25  Ní ìṣẹ́jú akàn, ó dìde níwájú wọn, ó gbé ohun tí ó ti máa ń dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó ń yin Ọlọ́run lógo.+ 26  Nígbà náà ni ayọ̀ púpọ̀ jọjọ+ kún inú gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì kún fún ìbẹ̀rù, wọ́n wí pé: “Àwa ti rí ohun àjèjì lónìí!”+ 27  Wàyí o, lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ó jáde lọ, ó sì rí agbowó orí kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Léfì tí ó jókòó ní ọ́fíìsì owó orí, ó sì wí fún un pé: “Di ọmọlẹ́yìn mi.”+ 28  Ó fi ohun gbogbo+ sílẹ̀ sẹ́yìn, ó dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé e. 29  Pẹ̀lúpẹ̀lù, Léfì se àsè ìṣenilálejò rẹpẹtẹ fún un ní ilé rẹ̀; ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn agbowó orí sì wà níbẹ̀ àti àwọn mìíràn tí wọ́n wà pẹ̀lú wọn ní rírọ̀gbọ̀kú nídìí oúnjẹ.+ 30  Látàrí èyí, àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin wọn bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, pé: “Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé ẹ ń jẹ, ẹ sì ń mu pẹ̀lú àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀?”+ 31  Ní ìfèsìpadà, Jésù wí fún wọn pé: “Àwọn tí ó lera kò nílò oníṣègùn,+ ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀.+ 32  Èmi kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.”+ 33  Wọ́n wí fún un pé: “Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù a máa gbààwẹ̀ lemọ́lemọ́, wọn a sì máa ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ti àwọn Farisí máa ń ṣe, ṣùgbọ́n àwọn tìrẹ ń jẹ, wọ́n sì ń mu.”+ 34  Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ kò lè mú kí àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó wà pẹ̀lú wọn, ẹ lè ṣe bẹ́ẹ̀ bí?+ 35  Síbẹ̀, àwọn ọjọ́ yóò dé nígbà tí a óò mú ọkọ ìyàwó+ lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn+ ní tòótọ́; nígbà náà, wọn yóò gbààwẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì.”+ 36  Síwájú sí i, ó ń bá a lọ láti fún wọn ní àpèjúwe kan pé: “Kò sí ẹni tí í gé ìrépé lára ẹ̀wù àwọ̀lékè tuntun tí í sì í rán an sórí ògbólógbòó ẹ̀wù àwọ̀lékè; ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà náà ìrépé tuntun yóò ya kúrò àti pé ìrépé náà láti ara ẹ̀wù àwọ̀lékè tuntun kò ní bá ògbólógbòó mu.+ 37  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, kò sí ẹni tí í fi wáìnì tuntun sínú àwọn ògbólógbòó àpò awọ; ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà náà wáìnì tuntun yóò bẹ́ àwọn àpò awọ+ náà, yóò sì dà sílẹ̀, àwọn àpò awọ náà yóò sì bàjẹ́.+ 38  Ṣùgbọ́n wáìnì tuntun ni a gbọ́dọ̀ fi sínú àwọn àpò awọ tuntun. 39  Kò sí ẹni tí ó ti mu ògbólógbòó wáìnì tí í fẹ́ tuntun; nítorí òun a sọ pé, ‘Ògbólógbòó+ gbámúṣé.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé