Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Lúùkù 4:1-44

4  Wàyí o, Jésù, bí ó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó kúrò ní Jọ́dánì, ẹ̀mí sì ṣamọ̀nà rẹ̀ káàkiri nínú aginjù+  fún ogójì ọjọ́,+ bí Èṣù ti ń dẹ ẹ́ wò.+ Síwájú sí i, kò jẹ nǹkan kan ní ọjọ́ wọnnì, nítorí náà, nígbà tí wọ́n wá sí ìparí, ebi wá ń pa á.  Látàrí èyí, Èṣù wí fún un pé: “Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ fún òkúta yìí kí ó di ìṣù búrẹ́dì.”  Ṣùgbọ́n Jésù fèsì fún un pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kò gbọ́dọ̀ tipa oúnjẹ nìkan ṣoṣo wà láàyè.’”+  Nítorí náà ó mú un gòkè wá, ó sì fi gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé tí a ń gbé hàn án ní ìṣẹ́jú akàn;  Èṣù sì wí fún un pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ+ yìí àti ògo wọn ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú, nítorí pé a ti fi í lé mi lọ́wọ́, ẹnì yòówù tí mo bá sì fẹ́ ni èmi yóò fi í fún.+  Nítorí náà, ìwọ, bí o bá jọ́sìn+ níwájú mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, gbogbo rẹ̀ ni yóò jẹ́ tìrẹ.”  Ní ìfèsìpadà, Jésù wí fún un pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ+ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’”+  Wàyí o, ó mú un lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó sì mú un dúró lórí odi orí òrùlé+ tẹ́ńpìlì, ó sì wí fún un pé: “Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, fi ara rẹ sọ̀kò sílẹ̀ láti ìhín;+ 10  nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Òun yóò pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ, láti pa ọ́ mọ́,’+ 11  àti pé, ‘Wọn yóò gbé ọ ní ọwọ́ wọn, kí ìwọ má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta nígbà kankan.’”+ 12  Ní ìdáhùn, Jésù wí fún un pé: “A sọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run rẹ wò.’”+ 13  Nítorí náà, lẹ́yìn tí ó ti mú gbogbo ìdẹwò náà wá sí ìparí, Èṣù fàsẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ títí di àkókò mìíràn tí ó wọ̀.+ 14  Wàyí o, Jésù padà sí Gálílì+ nínú agbára ẹ̀mí. Ọ̀rọ̀ rere nípa rẹ̀ sì tàn ká gbogbo ìgbèríko tí ó wà ní àyíká.+ 15  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn, gbogbo ènìyàn ń bu ọlá fún un.+ 16  Ó sì wá sí Násárétì,+ níbi tí a ti tọ́ ọ dàgbà; àti pé, gẹ́gẹ́ bí àṣà rẹ̀ ní ọjọ́ sábáàtì, ó wọ inú sínágọ́gù,+ ó sì dìde dúró láti kàwé. 17  Nítorí náà, a fi àkájọ ìwé wòlíì Aísáyà lé e lọ́wọ́, ó sì ṣí àkájọ ìwé náà, ó sì rí ibi tí a ti kọ ọ́ pé: 18  “Ẹ̀mí Jèhófà+ ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì, ó rán mi jáde láti wàásù ìtúsílẹ̀ fún àwọn òǹdè àti ìtúnríran fún àwọn afọ́jú, láti rán àwọn tí a ni lára lọ pẹ̀lú ìtúsílẹ̀,+ 19  láti wàásù ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.”+ 20  Pẹ̀lú èyíinì, ó ká àkájọ ìwé náà, ó dá a padà fún ẹmẹ̀wà náà, ó sì jókòó; gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú sínágọ́gù sì tẹjú mọ́ ọn. 21  Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn pé: “Lónìí, ìwé mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ tán yìí ní ìmúṣẹ.”+ 22  Gbogbo wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́rìí rẹ̀ ní rere, ẹnu sì ń yà wọ́n nítorí àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin+ tí ń jáde láti ẹnu rẹ̀, wọ́n sì ń sọ pé: “Ọmọkùnrin Jósẹ́fù ni èyí, àbí òun kọ́?”+ 23  Látàrí èyí, ó wí fún wọn pé: “Láìsí iyèméjì, ẹ ó lo àpèjúwe yìí fún mi, ‘Oníṣègùn,+ wo ara rẹ sàn; àwọn ohun+ tí a gbọ́ pé ó ti ṣẹlẹ̀ ní Kápánáúmù+ ṣe wọ́n pẹ̀lú níhìn-ín ní ìpínlẹ̀ ìbí rẹ.’”+ 24  Ṣùgbọ́n ó wí pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́ gbà ní ìpínlẹ̀ ìbí rẹ̀. 25  Fún àpẹẹrẹ, mo sọ fún yín ní tòótọ́, Ọ̀pọ̀ opó ní ń bẹ ní Ísírẹ́lì ní àwọn ọjọ́ Èlíjà, nígbà tí a sé ọ̀run pa fún ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà, tí ó fi jẹ́ pé ìyàn ńlá kan mú gbogbo ilẹ̀ náà,+ 26  síbẹ̀síbẹ̀ a kò rán Èlíjà sí ìkankan nínú obìnrin wọnnì, bí kò ṣe sí Sáréfátì+ nìkan ní ilẹ̀ Sídónì sí opó kan. 27  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ọ̀pọ̀ adẹ́tẹ̀ ní ń bẹ ní Ísírẹ́lì ní àkókò Èlíṣà wòlíì, síbẹ̀síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí a wẹ̀ mọ́, bí kò ṣe Náámánì ará Síríà.”+ 28  Wàyí o, gbogbo àwọn tí ń gbọ́ ohun wọ̀nyí nínú sínágọ́gù kún fún ìbínú;+ 29  wọ́n sì dìde, wọ́n sì mú un lọ sí ẹ̀yìn ìlú ńlá náà ní kóyákóyá, wọ́n sì mú un lọ sí téńté gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ńlá lórí èyí tí a tẹ ìlú ńlá wọn dó sí, láti sọ ọ́ sísàlẹ̀ lógèdèǹgbé.+ 30  Ṣùgbọ́n ó kọjá láàárín wọn, ó sì ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.+ 31  Ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Kápánáúmù,+ ìlú ńlá kan ní Gálílì. Ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ sábáàtì; 32  háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀,+ nítorí pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ pẹ̀lú ọlá àṣẹ.+ 33  Wàyí o, ọkùnrin kan wà nínú sínágọ́gù tí ó ní ẹ̀mí kan,+ ẹ̀mí èṣù àìmọ́, ó sì kígbe pẹ̀lú ohùn rara pé: 34  “Háà! Kí ní pa tàwa tìrẹ pọ̀,+ Jésù, ìwọ ará Násárétì?+ Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Mo mọ+ ẹni tí ìwọ jẹ́ gan-an, Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”+ 35  Ṣùgbọ́n Jésù bá a wí lọ́nà mímúná, pé: “Dákẹ́, kí o sì jáde kúrò lára rẹ̀.” Nítorí náà, lẹ́yìn gbígbé ọkùnrin náà ṣánlẹ̀ ní àárín wọn, ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò lára rẹ̀ láìṣe é lọ́ṣẹ́.+ 36  Látàrí èyí, ìyàlẹ́nu bá gbogbo ènìyàn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì, pé: “Irú ọ̀rọ̀ wo nìyí, nítorí pé ó ń fi ọlá àṣẹ àti agbára pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́, wọ́n sì ń jáde?”+ 37  Nítorí náà, ìhìn nípa rẹ̀ ń jáde lọ ṣáá sí ibi gbogbo ní ìgbèríko tí ó wà ní àyíká.+ 38  Lẹ́yìn dídìde kúrò nínú sínágọ́gù, ó wọ ilé Símónì. Wàyí o, akọ ibà ń ṣe ìyá ìyàwó Símónì, wọ́n sì ṣe ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí rẹ̀.+ 39  Nítorí náà, ó dúró lẹ́bàá rẹ̀, ó sì bá ibà+ náà wí lọ́nà mímúná, ibà náà sì fi í sílẹ̀. Ní ìṣẹ́jú akàn, ó dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.+ 40  Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn ń wọ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n ní àwọn ènìyàn tí onírúurú òkùnrùn ń ṣe mú wọn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Nípa gbígbé ọwọ́ rẹ̀ lé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, ó ń wò wọ́n sàn.+ 41  Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú a jáde kúrò lára ọ̀pọ̀lọpọ̀,+ ní kíké jáde àti sísọ pé: “Ìwọ ni Ọmọ+ Ọlọ́run.” Ṣùgbọ́n, ní bíbá wọn wí lọ́nà mímúná, kì í gbà wọ́n láyè láti sọ̀rọ̀,+ nítorí wọ́n mọ̀ pé òun+ ni Kristi+ náà. 42  Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó di ojúmọ́, ó jáde lọ, ó sì rìn síwájú sí ibì kan tí ó dá.+ Ṣùgbọ́n àwọn ogunlọ́gọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wá a kiri, wọ́n sì dé ibi tí ó wà, wọ́n sì gbìyànjú láti dá a dúró kí ó má ṣe lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn. 43  Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.”+ 44  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ó ń bá a lọ ní wíwàásù nínú àwọn sínágọ́gù Jùdíà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé