Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Lúùkù 3:1-38

3  Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìgbà ìjọba Tìbéríù Késárì, nígbà tí Pọ́ńtíù Pílátù jẹ́ gómìnà Jùdíà, tí Hẹ́rọ́dù+ sì jẹ́ olùṣàkóso àgbègbè Gálílì, ṣùgbọ́n tí Fílípì arákùnrin rẹ̀ jẹ́ olùṣàkóso àgbègbè ilẹ̀ Ítúréà àti Tírákónítì, tí Lísáníà sì jẹ́ olùṣàkóso àgbègbè Ábílénè,  ní àwọn ọjọ́ olórí àlùfáà Ánásì àti ti Káyáfà,+ ìpolongo Ọlọ́run tọ Jòhánù+ ọmọkùnrin Sekaráyà wá nínú aginjù.+  Nítorí náà, ó wá sí gbogbo ìgbèríko tí ó wà ní àyíká Jọ́dánì, ó ń wàásù ìbatisí gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀,+  gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn ọ̀rọ̀ Aísáyà wòlíì pé: “Fetí sílẹ̀! Ẹnì kan ń ké jáde ní aginjù pé, ‘Ẹ palẹ̀ ọ̀nà Jèhófà mọ́, ẹ mú àwọn ojú ọ̀nà rẹ̀ tọ́.+  Gbogbo kòtò ọ̀gbàrá ni a gbọ́dọ̀ kún, àti gbogbo òkè ńlá àti òkè kéékèèké ni a óò tẹ́ bẹẹrẹ, àwọn ibi kọ́rọkọ̀rọ gbọ́dọ̀ di ọ̀nà títọ́, àwọn ibi págunpàgun sì gbọ́dọ̀ di ọ̀nà jíjọ̀lọ̀;+  gbogbo ẹran ara yóò sì rí ohun àmúlò Ọlọ́run fún gbígbanilà.’”+  Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ogunlọ́gọ̀ tí ń jáde wá kí ó lè batisí wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀,+ ta ní fi tó yín létí láti sá kúrò nínú ìrunú tí ń bọ̀?+  Nítorí náà, ẹ mú àwọn èso tí ó yẹ ìrònúpìwàdà+ jáde. Kí ẹ má sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Ábúráhámù gẹ́gẹ́ bí baba.’ Nítorí mo wí fún yín pé Ọlọ́run ní agbára láti gbé àwọn ọmọ dìde fún Ábúráhámù láti inú òkúta wọ̀nyí.  Ní tòótọ́, àáké ti wà níbi gbòǹgbò àwọn igi nísinsìnyí; nítorí náà, gbogbo igi tí kò bá ń mú èso àtàtà jáde ni a óò ké lulẹ̀, tí a ó sì sọ sínú iná.”+ 10  Àwọn ogunlọ́gọ̀ náà a sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí wá ni àwa yóò ṣe?”+ 11  Ní ìfèsìpadà, òun a sì sọ fún wọn pé: “Kí ẹni tí ó ní ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ méjì ṣe àjọpín pẹ̀lú ẹni tí kò ní, kí ẹni tí ó ní àwọn ohun jíjẹ sì ṣe bákan náà.”+ 12  Ṣùgbọ́n àwọn agbowó orí pàápàá wá kí a lè batisí wọn, wọ́n sì wí fún un pé: “Olùkọ́, kí ni àwa yóò ṣe?”+ 13  Ó wí fún wọn pé: “Ẹ má ṣe fi dandan béèrè fún ohunkóhun ju ìwọ̀n iye owó orí.”+ 14  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn tí ń bẹ nínú iṣẹ́ ìsìn ológun a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni àwa pẹ̀lú yóò ṣe?” Òun sì wí fún wọn pé: “Ẹ má ṣe fòòró ẹnikẹ́ni tàbí fi ẹ̀sùn kan+ ẹnikẹ́ni lọ́nà èké, ṣùgbọ́n ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ìpèsè yín.”+ 15  Wàyí o, bí àwọn ènìyàn náà ti ń fojú sọ́nà, tí gbogbo wọ́n sì ń rò nínú ọkàn-àyà wọn nípa Jòhánù pé: “Àbí òun ni Kristi náà ni?”+ 16  Jòhánù dáhùn, ní sísọ fún gbogbo wọn pé: “Èmi, ní tèmi, ń fi omi batisí yín; ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, okùn sálúbàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú.+ Yóò fi ẹ̀mí mímọ́ àti iná batisí yín.+ 17  Ṣọ́bìrì ìfẹ́kà rẹ̀ wà ní ọwọ́ rẹ̀ láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tónítóní àti láti kó àlìkámà jọ+ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìyàngbò+ ni yóò fi iná tí kò ṣeé pa sun.”+ 18  Nítorí náà, ó tún fúnni ní ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìyànjú mìíràn, ó sì ń bá a lọ ní pípolongo ìhìn rere fún àwọn ènìyàn. 19  Ṣùgbọ́n Hẹ́rọ́dù olùṣàkóso àgbègbè náà, nítorí tí ó ti bá a wí nípa Hẹrodíà aya arákùnrin rẹ̀ àti nípa gbogbo ìṣe burúkú tí Hẹ́rọ́dù ṣe,+ 20  tún fi èyí kún gbogbo ìṣe wọnnì: ó ti Jòhánù mọ́ ẹ̀wọ̀n.+ 21  Wàyí o, nígbà tí a batisí gbogbo ènìyàn, a batisí Jésù+ pẹ̀lú, bí ó sì ti ń gbàdúrà, ọ̀run+ ṣí sílẹ̀, 22  ẹ̀mí mímọ́ ní ìrí ti ara bí àdàbà bà lé e, ohùn kan sì jáde wá láti inú ọ̀run pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.”+ 23  Síwájú sí i, Jésù, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀,+ jẹ́ ẹni nǹkan bí ọgbọ̀n+ ọdún, gẹ́gẹ́ bí èrò náà ti jẹ́, ó jẹ́ ọmọkùnrin+Jósẹ́fù,+ọmọkùnrin Hélì, 24  ọmọkùnrin Mátátì,ọmọkùnrin Léfì,ọmọkùnrin Mélíkì,ọmọkùnrin Jánááì,ọmọkùnrin Jósẹ́fù, 25  ọmọkùnrin Mátátíà,ọmọkùnrin Ámósì,ọmọkùnrin Náhúmù,ọmọkùnrin Ésílì,ọmọkùnrin Nágáì, 26  ọmọkùnrin Máátì,ọmọkùnrin Mátátíà,ọmọkùnrin Séméínì,ọmọkùnrin Jósẹ́kì,ọmọkùnrin Jódà, 27  ọmọkùnrin Jóánánì,ọmọkùnrin Résà,ọmọkùnrin Serubábélì,+ọmọkùnrin Ṣéálítíẹ́lì,+ọmọkùnrin Nẹ́rì, 28  ọmọkùnrin Mélíkì,ọmọkùnrin Ádì,ọmọkùnrin Kósámù,ọmọkùnrin Élímádámù,ọmọkùnrin Éérì, 29  ọmọkùnrin Jésù,ọmọkùnrin Élíésérì,ọmọkùnrin Jórímù,ọmọkùnrin Mátátì,ọmọkùnrin Léfì, 30  ọmọkùnrin Símíónì,ọmọkùnrin Júdásì,ọmọkùnrin Jósẹ́fù,ọmọkùnrin Jónámù,ọmọkùnrin Élíákímù, 31  ọmọkùnrin Méléà,ọmọkùnrin Ménà,ọmọkùnrin Mátátà,ọmọkùnrin Nátánì,+ọmọkùnrin Dáfídì,+ 32  ọmọkùnrin Jésè,+ọmọkùnrin Óbédì,+ọmọkùnrin Bóásì,+ọmọkùnrin Sálímọ́nì,+ọmọkùnrin Náṣónì,+ 33  ọmọkùnrin Ámínádábù,+ọmọkùnrin Áánì,+ọmọkùnrin Hésírónì,+ọmọkùnrin Pérésì,+ọmọkùnrin Júdà,+ 34  ọmọkùnrin Jékọ́bù,+ọmọkùnrin Ísákì,+ọmọkùnrin Ábúráhámù,+ọmọkùnrin Térà,+ọmọkùnrin Náhórì,+ 35  ọmọkùnrin Sérúgù,+ọmọkùnrin Réù,+ọmọkùnrin Pélégì,+ọmọkùnrin Ébérì,+ọmọkùnrin Ṣélà,+ 36  ọmọkùnrin Káínánì,ọmọkùnrin Ápákíṣádì,+ọmọkùnrin Ṣémù,+ọmọkùnrin Nóà,+ọmọkùnrin Lámékì,+ 37  ọmọkùnrin Mètúsélà,+ọmọkùnrin Énọ́kù,+ọmọkùnrin Járédì,+ọmọkùnrin Máháláléélì,+ọmọkùnrin Káínánì,+ 38  ọmọkùnrin Énọ́ṣì,+ọmọkùnrin Sẹ́ẹ́tì,+ọmọkùnrin Ádámù,+ọmọkùnrin Ọlọ́run.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé