Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Lúùkù 24:1-53

24  Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, wọ́n lọ sí ibojì náà ní kùtù hàì, wọ́n gbé èròjà atasánsán tí wọ́n ti pèsè sílẹ̀ dání.+  Ṣùgbọ́n wọ́n bá òkúta náà tí a ti yí i kúrò ní ibojì ìrántí náà,+  nígbà tí wọ́n sì wọlé, wọn kò rí òkú Jésù Olúwa.+  Nígbà tí ọkàn wọn ṣì dàrú lórí èyí, wò ó! ọkùnrin méjì nínú aṣọ tí ń kọ mànà dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.+  Bí jìnnìjìnnì ti bo àwọn obìnrin náà, tí wọ́n sì dojú kọ ilẹ̀, àwọn ọkùnrin náà wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń wá Alààyè láàárín àwọn òkú?  [[Kò sí níhìn-ín, ṣùgbọ́n a ti gbé e dìde.]]+ Ẹ rántí bí ó ti bá yín sọ̀rọ̀ nígbà tí ó ṣì wà ní Gálílì,+  pé a gbọ́dọ̀ fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́, kí a sì kàn án mọ́gi, síbẹ̀ kí ó sì dìde ní ọjọ́ kẹta.”+  Nítorí náà, wọ́n rántí àwọn àsọjáde rẹ̀,+  wọ́n sì padà láti ibi ibojì ìrántí, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún àwọn mọ́kànlá náà àti gbogbo àwọn yòókù.+ 10  Àwọn ni Màríà Magidalénì, àti Jòánà,+ àti Màríà ìyá Jákọ́bù. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìyókù àwọn obìnrin+ tí ń bẹ pẹ̀lú wọ́n ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn àpọ́sítélì. 11  Àmọ́ ṣá o, àsọjáde wọ̀nyí jọ ìsọkúsọ lójú wọn, wọn kò sì gba àwọn obìnrin náà gbọ́.+ 12  [[Ṣùgbọ́n Pétérù dìde, ó sì sáré lọ sí ibi ibojì ìrántí náà, àti pé, ní bíbẹ̀rẹ̀ síwájú, ó rí àwọn ọ̀já ìdìkú nìkan. Nítorí náà, ó lọ, ní ṣíṣe kàyéfì nínú ara rẹ̀ nítorí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀.]] 13  Ṣùgbọ́n, wò ó! ní ọjọ́ yẹn gan-an, méjì nínú wọ́n ń rin ìrìn àjò lọ sí abúlé kan tí a ń pè ní Ẹ́máọ́sì, tí ó jìnnà tó nǹkan bí ibùsọ̀ méje sí Jerúsálẹ́mù, 14  wọ́n sì ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ pọ̀ lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí+ tí ó ti ṣẹlẹ̀. 15  Wàyí o, bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ pọ̀, tí wọ́n sì ń jíròrò, Jésù fúnra rẹ̀ sún mọ́ tòsí,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn rìn; 16  ṣùgbọ́n a pa ojú wọn mọ́ kúrò nínú dídá a mọ̀.+ 17  Ó wí fún wọn pé: “Kí ni ọ̀ràn wọ̀nyí tí ẹ ń bá ara yín fà bí ẹ ti ń rìn lọ?” Wọ́n sì dúró jẹ́ẹ́ pẹ̀lú ojú fífàro. 18  Ní ìdáhùn, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kíléópà wí fún un pé: “Ìwọ ha ń ṣe àtìpó ní Jerúsálẹ́mù nítorí náà tí o kò sì mọ àwọn nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?” 19  Ó sì wí fún wọn pé: “Àwọn nǹkan wo?” Wọ́n wí fún un pé: “Àwọn nǹkan nípa Jésù ará Násárétì,+ ẹni tí ó di wòlíì+ kan tí ó jẹ́ alágbára nínú iṣẹ́ àti nínú ọ̀rọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn; 20  àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùṣàkóso wa ṣe fi í lé ìdájọ́ ikú lọ́wọ́, tí wọ́n sì kàn án mọ́gi.+ 21  Ṣùgbọ́n àwa ń retí pé ọkùnrin yìí ni ẹni tí a yàn tẹ́lẹ̀ láti dá Ísírẹ́lì+ nídè; bẹ́ẹ̀ ni, àti pé yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, èyí ni ó ṣe ọjọ́ kẹta tí nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀. 22  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn obìnrin kan+ láti àárín wa tún mú ẹnu yà wá, nítorí pé ní kùtùkùtù ni wọ́n ti dé ibojì ìrántí náà, 23  ṣùgbọ́n wọn kò rí òkú rẹ̀, wọ́n sì wá ń sọ pé àwọn tún rí ìran kan tí ó ju ti ẹ̀dá lọ, tí ó jẹ́ ti àwọn áńgẹ́lì, tí wọ́n sọ pé ó wà láàyè. 24  Síwájú sí i, àwọn kan lára àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú wa lọ sí ibi ibojì ìrántí+ náà; wọ́n sì bá a bẹ́ẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí, ṣùgbọ́n wọn kò rí i.” 25  Nítorí náà, ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin òpònú, tí ẹ sì lọ́ra ní ọkàn-àyà láti gbà gbọ́ nínú gbogbo ohun tí àwọn wòlíì sọ!+ 26  Kò ha pọn dandan fún Kristi láti jìyà+ nǹkan wọ̀nyí, kí ó sì bọ́ sínú ògo rẹ̀?”+ 27  Àti pé bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Mósè+ àti gbogbo àwọn Wòlíì,+ ó túmọ̀ àwọn nǹkan tí ó jẹ mọ́ ara rẹ̀ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ fún wọn. 28  Nígbẹ̀yìn, wọ́n sún mọ́ abúlé náà tí wọ́n ń rin ìrìn àjò lọ, ó sì ṣe bí ẹni pé ó ń rin ìrìn àjò lọ síwájú sí i. 29  Ṣùgbọ́n wọ́n rọ̀ ọ́ gidigidi, pé: “Dúró pẹ̀lú wa, nítorí pé ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ọjọ́ sì ti rọ̀.” Pẹ̀lú èyíinì, ó wọlé láti dúró pẹ̀lú wọn. 30  Bí ó sì ti rọ̀gbọ̀kú pẹ̀lú wọn nídìí oúnjẹ, ó mú ìṣù búrẹ́dì, ó súre sí i, ó bù ú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi í lé wọn lọ́wọ́.+ 31  Látàrí èyíinì, ojú wọn là lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́, wọ́n sì dá a mọ̀; ó sì nù mọ́ wọn lójú.+ 32  Wọ́n sì wí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Ọkàn-àyà wa kò ha ń jó fòfò bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀ ní ojú ọ̀nà, bí ó ti ń ṣí Ìwé Mímọ́ payá fún wa lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́?” 33  Ní wákàtí yẹn gan-an, wọ́n dìde, wọ́n sì padà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá àti àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú wọn tí wọ́n péjọ pọ̀, 34  wọ́n wí pé: “Ní ti tòótọ́ ni a gbé Olúwa dìde, ó sì fara han Símónì!”+ 35  Wàyí o, àwọn fúnra wọn ṣèròyìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti ojú ọ̀nà àti bí ó ṣe di mímọ̀ fún wọn nípa bíbu ìṣù búrẹ́dì.+ 36  Bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí, òun fúnra rẹ̀ dúró ní àárín wọn, [[ó sì wí fún wọn pé: “Àlàáfíà fún yín o.”]] 37  Ṣùgbọ́n nítorí pé àyà wọ́n já, tí jìnnìjìnnì sì ti bò wọ́n,+ wọ́n lérò pé àwọn rí ẹ̀mí kan. 38  Nítorí náà, ó wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi dààmú, èé sì ti ṣe tí iyèméjì fi dìde nínú ọkàn-àyà yín? 39  Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi fúnra mi ni; ẹ fọwọ́ bà mí,+ kí ẹ sì rí i, nítorí ẹ̀mí kò ní ẹran ara àti egungun+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí i pé mo ní.” 40  [[Bí ó sì ti sọ èyí, ó fi ọwọ́ rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n.]] 41  Ṣùgbọ́n bí wọn kò ti gbà gbọ́+ síbẹ̀ nítorí ìdùnnú bíbùáyà, tí wọ́n sì ń ṣe kàyéfì, ó wí fún wọn pé: “Ǹjẹ́ ẹ ní ohun kan níbẹ̀ láti jẹ?”+ 42  Wọ́n sì fi ẹyọ ẹja sísun kan lé e lọ́wọ́;+ 43  ó sì gbà á, ó sì jẹ ẹ́+ ní ìṣojú wọn. 44  Wàyí o, ó wí fún wọn pé: “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ mi tí mo sọ fún yín nígbà tí mo ṣì wà pẹ̀lú yín,+ pé gbogbo ohun tí a kọ̀wé rẹ̀ nípa mi nínú òfin Mósè àti nínú àwọn Wòlíì+ àti àwọn Sáàmù+ ni a gbọ́dọ̀ mú ṣẹ.” 45  Ó wá ṣí èrò inú wọn payá lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ láti mòye ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́,+ 46  ó sì wí fún wọn pé: “Lọ́nà yìí ni a kọ̀wé rẹ̀ pé Kristi yóò jìyà, yóò sì dìde kúrò láàárín àwọn òkú ní ọjọ́ kẹta,+ 47  àti pé ní orúkọ rẹ̀, a ó máa wàásù ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀+ ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè+—bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù+ lọ, 48  ẹ óò jẹ́ ẹlẹ́rìí+ nǹkan wọ̀nyí. 49  Sì wò ó! èmi yóò rán èyíinì tí Baba mi ti ṣèlérí jáde sórí yín. Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin ẹ máa gbé ní ìlú ńlá náà títí ẹ ó fi di ẹni tí a gbé agbára wọ̀ láti ibi gíga lókè.”+ 50  Ṣùgbọ́n, ó ṣamọ̀nà wọn jáde títí dé Bẹ́tánì, ó sì gbé àwọn ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì súre fún wọn.+ 51  Bí ó ti ń súre fún wọn, a yà á kúrò lọ́dọ̀ wọn, a sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé e sókè lọ sí ọ̀run.+ 52  Wọ́n sì wárí fún un, wọ́n sì padà sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú ìdùnnú ńláǹlà.+ 53  Wọ́n sì wà ní tẹ́ńpìlì nígbà gbogbo, wọ́n ń fi ìbùkún fún Ọlọ́run.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé