Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Lúùkù 23:1-56

23  Nítorí náà, ògìdìgbó wọ́n dìde, gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ Pílátù.+  Nígbà náà ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹ̀sùn kàn án,+ pé: “A rí ọkùnrin yìí tí ń dojú orílẹ̀-èdè wa dé,+ tí ó sì ń ka sísan owó orí+ fún Késárì léèwọ̀, tí ó sì ń sọ pé òun fúnra òun ni Kristi ọba.”+  Wàyí o, Pílátù béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù bí?” Ní dídá a lóhùn, ó wí pé: “Ìwọ fúnra rẹ ń wí i.”+  Nígbà náà ni Pílátù wí fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ogunlọ́gọ̀ náà pé: “Èmi kò rí ìwà ọ̀daràn kankan nínú ọkùnrin yìí.”+  Ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹpẹlẹ mọ́ ọn, pé: “Ó ń ru àwọn ènìyàn sókè nípa kíkọ́ni jákèjádò Jùdíà, àní bẹ̀rẹ̀ láti Gálílì títí dé ìhín.”  Nígbà tí ó gbọ́ èyíinì, Pílátù béèrè bóyá ará Gálílì ni ọkùnrin náà,  lẹ́yìn tí ó sì ti rí i dájú pé abẹ́ àṣẹ Hẹ́rọ́dù+ ni ó ti wá, ó fi í ránṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù, ẹni tí òun fúnra rẹ̀ pẹ̀lú wà ní Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ wọ̀nyí.  Nígbà tí Hẹ́rọ́dù rí Jésù, ó yọ̀ gidigidi, nítorí ó ti ń fẹ́ láti rí+ i fún ìgbà pípẹ́ nítorí pé ó ti gbọ́+ nípa rẹ̀, ó sì ń retí láti rí i kí ó ṣe iṣẹ́ àmì díẹ̀.  Wàyí o, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ bi í ní ìbéèrè; ṣùgbọ́n kò fún un ní ìdáhùn kankan.+ 10  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin wà ní ìdúró, wọ́n sì ń fẹ̀sùn kàn án kíkankíkan.+ 11  Nígbà náà ni Hẹ́rọ́dù pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ ọmọ ogun rẹ̀ bẹ̀tẹ́ lù ú,+ ó sì fi í ṣe yẹ̀yẹ́+ nípa fífi ẹ̀wù títànyòyò wọ̀ ọ́, ó sì fi í ránṣẹ́ padà sí Pílátù. 12  Hẹ́rọ́dù àti Pílátù+ wá di ọ̀rẹ́ ara wọn ní ọjọ́ yẹn gan-an; nítorí pé ṣáájú èyíinì wọ́n ti ń bá ìṣọ̀tá bọ̀ láàárín ara wọn. 13  Nígbà náà ni Pílátù pe àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùṣàkóso àti àwọn ènìyàn jọ, 14  ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ mú ọkùnrin yìí wá sọ́dọ̀ mi gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń ru àwọn ènìyàn sókè láti dìtẹ̀, sì wò ó! èmi wádìí rẹ̀ wò níwájú yín, ṣùgbọ́n n kò rí ìdí+ kankan fún àwọn ẹ̀sùn tí ẹ ń fi kàn án. 15  Ní ti tòótọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni Hẹ́rọ́dù, nítorí ó fi í ránṣẹ́ padà sí wa; sì wò ó! kò sí nǹkan kan tí ó ṣe tí ó yẹ fún ikú.+ 16  Nítorí náà, ṣe ni èmi yóò nà án,+ tí n ó sì tú u sílẹ̀.” 17  —— 18  Ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo ògìdìgbó wọn, wọ́n ké jáde, pé: “Mú ẹni yìí kúrò,+ ṣùgbọ́n tú Bárábà sílẹ̀ fún wa!”+ 19  (Ọkùnrin tí a sọ sínú ẹ̀wọ̀n nítorí ìdìtẹ̀ kan sí ìjọba tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìlú ńlá náà àti nítorí ìṣìkàpànìyàn.) 20  Pílátù tún ké pè wọn, nítorí pé ó fẹ́ láti tú Jésù sílẹ̀.+ 21  Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ké rara, pé: “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!”+ 22  Ní ìgbà kẹta, ó wí fún wọn pé: “Họ́wù, ohun búburú wo ni ọkùnrin yìí ṣe? Èmi kò rí nǹkan kan nínú rẹ̀ tí ó yẹ fún ikú; nítorí náà, ṣe ni èmi yóò nà án, tí n ó sì tú u sílẹ̀.”+ 23  Látàrí èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹpẹlẹ mọ́ ọn, pẹ̀lú ohùn rara, wọ́n ń fi dandan béèrè pé kí a kàn án mọ́gi; ohùn wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí borí.+ 24  Nítorí náà, Pílátù ṣèdájọ́ pé kí a mú ohun tí wọ́n fi dandan béèrè fún ṣẹ:+ 25  ó tú ọkùnrin tí a ti sọ sẹ́wọ̀n fún ìdìtẹ̀ sí ìjọba àti ìṣìkàpànìyàn sílẹ̀,+ ẹni tí wọ́n ń fi dandan béèrè fún, ṣùgbọ́n ó fi Jésù lé wọn lọ́wọ́ fún ìfẹ́ wọn.+ 26  Wàyí o, bí wọ́n ti ń mú un lọ, wọ́n gbá Símónì mú, ẹnì kan tí ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Kírénè, tí ó ń bọ̀ láti ìgbèríko, wọ́n sì gbé òpó igi oró náà lé e lórí láti rù ú tẹ̀ lé Jésù lẹ́yìn.+ 27  Ṣùgbọ́n ògìdìgbó ńlá àwọn ènìyàn ń tẹ̀ lé e àti ti àwọn obìnrin tí wọ́n ń lu ara wọn ṣáá nínú ẹ̀dùn-ọkàn, tí wọ́n sì ń pohùn réré ẹkún fún un. 28  Jésù yíjú sí àwọn obìnrin náà, ó sì wí pé: “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, ẹ dẹ́kun sísunkún fún mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ sunkún fún ara yín àti nítorí àwọn ọmọ yín;+ 29  nítorí pé, wò ó! àwọn ọjọ́ ń bọ̀ nínú èyí tí àwọn ènìyàn yóò sọ pé, ‘Aláyọ̀ ni àwọn àgàn, àti àwọn ilé ọlẹ̀ tí kò bímọ àti àwọn ọmú tí a kò fi fún ọmọ mu!’+ 30  Nígbà náà ni wọ́n yóò bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn òkè ńlá pé, ‘Ẹ wó bò wá!’ àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, ‘Ẹ bò wá mọ́lẹ̀!’+ 31  Nítorí pé bí wọ́n bá ṣe nǹkan wọ̀nyí, nígbà tí igi wà ní tútù gbẹ̀dẹ́gbẹ̀dẹ́, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó bá rọ?”+ 32  Ṣùgbọ́n ọkùnrin méjì mìíràn, àwọn aṣebi, ni a ń mú lọ pẹ̀lú láti fi ikú pa wọ́n pẹ̀lú rẹ̀.+ 33  Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí,+ ibẹ̀ ni wọ́n ti kan òun àti àwọn aṣebi náà mọ́gi, ọ̀kan ní ọ̀tún rẹ̀ àti ọ̀kan ní òsì rẹ̀.+ 34  [[Ṣùgbọ́n Jésù ń wí pé: “Baba, dárí jì+ wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.”]] Síwájú sí i, láti pín ẹ̀wù rẹ̀, wọ́n ṣẹ́ kèké.+ 35  Àwọn ènìyàn sì dúró,+ tí wọ́n ń wòran. Ṣùgbọ́n àwọn olùṣàkóso ń yínmú, wọ́n ń wí pé: “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gba ara rẹ̀ là,+ bí ó bá jẹ́ ẹni yìí ni Kristi ti Ọlọ́run, Àyànfẹ́.”+ 36  Àwọn ọmọ ogun pàápàá fi í ṣe yẹ̀yẹ́,+ ní wíwá sí tòsí àti fífún un ní wáìnì kíkan,+ 37  tí wọ́n sì ń wí pé: “Bí ó bá jẹ́ ìwọ ni ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.” 38  Àkọlé kan wà lórí rẹ̀ pẹ̀lú pé: “Èyí ni ọba àwọn Júù.”+ 39  Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn aṣebi tí a gbé kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí wí fún un tèébútèébú+ pé: “Ìwọ ni Kristi, àbí ìwọ kọ́? Gba ara rẹ àti àwa là.” 40  Ní ìfèsìpadà, èkejì bá a wí lọ́nà mímúná, ó sì wí pé: “Ṣé ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run rárá ni, nísinsìnyí tí ìwọ wà nínú ìdájọ́ kan náà?+ 41  Ní tòótọ́, ó sì rí bẹ́ẹ̀ fún wa lọ́nà tí ó bá ìdájọ́ òdodo mu, nítorí ohun tí ó tọ́ sí wa ni àwa ń gbà ní kíkún nítorí àwọn ohun tí a ṣe; ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun kan tí kò tọ̀nà.”+ 42  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Jésù, rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.”+ 43  Ó sì wí fún un pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi+ ní Párádísè.”+ 44  Tóò, nísinsìnyí ó tí tó nǹkan bí wákàtí kẹfà, síbẹ̀ òkùnkùn kan ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsàn-án,+ 45  nítorí pé ìmọ́lẹ̀ oòrùn kùnà; nígbà náà ni aṣọ ìkélé+ ibùjọsìn ya délẹ̀ ní agbedeméjì.+ 46  Jésù sì fi ohùn rara kígbe, ó sì wí pé: “Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.”+ Nígbà tí ó ti sọ èyí, ó gbẹ́mìí mì.+ 47  Nítorí rírí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun bẹ̀rẹ̀ sí yin Ọlọ́run lógo, pé: “Ní ti tòótọ́, olódodo ni ọkùnrin yìí.”+ 48  Gbogbo àwọn ogunlọ́gọ̀ tí wọ́n sì kóra jọpọ̀ síbẹ̀ nítorí ìran àpéwò yìí, bẹ̀rẹ̀ sí padà, wọ́n ń lu igẹ̀ wọn, nígbà tí wọ́n rí àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀. 49  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ ojúlùmọ̀ rẹ̀ dúró ní òkèèrè.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn obìnrin tí wọ́n jùmọ̀ tẹ̀ lé e láti Gálílì, dúró tí wọ́n ń wo nǹkan wọ̀nyí.+ 50  Sì wò ó! ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jósẹ́fù, tí ó jẹ́ mẹ́ńbà Àjọ Ìgbìmọ̀, ọkùnrin rere àti olódodo+ 51  ọkùnrin yìí kò dìbò ní ìtìlẹyìn ète-ọkàn àti ìṣe wọn+—Arimatíà ni ó ti wá, ìlú ńlá kan ti àwọn ará Jùdíà, ó sì ń dúró de ìjọba Ọlọ́run;+ 52  ọkùnrin yìí lọ bá Pílátù, ó sì béèrè fún òkú Jésù.+ 53  Ó sì gbé e sọ̀ kalẹ̀,+ ó sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì+ kan tí a gbẹ́ sínú àpáta, èyí tí a kò tíì tẹ́ ẹnì kankan sí+ rí. 54  Wàyí o, ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́+ ni, ìmọ́lẹ̀ ìrọ̀lẹ́ sábáàtì+ sì ń sún mọ́lé. 55  Ṣùgbọ́n àwọn obìnrin, tí wọ́n ti bá a wá láti Gálílì, tẹ̀ lé e lọ, wọ́n sì bojú wo ibojì ìrántí+ náà àti bí a ti tẹ́ òkú rẹ̀;+ 56  wọ́n sì padà láti lọ pèsè èròjà atasánsán àti àwọn òróró onílọ́fínńdà+ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ṣá o, wọ́n sinmi ní sábáàtì+ ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé