Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Lúùkù 22:1-71

22  Wàyí o, àjọyọ̀ àkàrà aláìwú, tí àwọn ènìyàn ń pè ní Ìrékọjá,+ ti ń sún mọ́lé.  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin ń wá ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ fún wọn láti rẹ́yìn rẹ̀,+ nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn.+  Ṣùgbọ́n Sátánì wọ inú Júdásì, ẹni tí a ń pè ní Ísíkáríótù, tí a kà mọ́ àwọn méjìlá náà;+  ó sì lọ bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ láti fi í lé wọn lọ́wọ́.+  Tóò, wọ́n yọ̀, wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fún un ní owó fàdákà.+  Nítorí náà, ó gbà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wá àyè ṣíṣí sílẹ̀ tí ó dára láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ogunlọ́gọ̀ nítòsí.+  Ọjọ́ àkàrà aláìwú dé wàyí, nínú èyí tí a gbọ́dọ̀ fi ẹran-ẹbọ ìrékọjá rúbọ;+  ó sì rán Pétérù àti Jòhánù lọ, wí pé: “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá sílẹ̀+ fún wa láti jẹ.”  Wọ́n wí fún un pé: “Ibo ni o fẹ́ kí a pèsè rẹ̀ sílẹ̀ sí?” 10  Ó wí fún wọn pé:+ “Wò ó! Nígbà tí ẹ bá wọ ìlú ńlá náà, ọkùnrin kan tí ó ru ládugbó omi yóò pàdé yín. Ẹ tẹ̀ lé e lọ sínú ilé tí ó bá wọ̀.+ 11  Ẹ sì gbọ́dọ̀ sọ fún ẹni tí ó ni ilé náà pé, ‘Olùkọ́ sọ fún ọ pé: “Ibo ni yàrá àlejò wà, nínú èyí tí mo ti lè jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi?”’+ 12  Ọkùnrin yẹn yóò sì fi yàrá ńlá kan ní òkè hàn yín, tí a ti pèsè àwọn ohun èlò ilé sí. Ẹ pèsè rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀.”+ 13  Nítorí náà, wọ́n lọ, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún wọn gẹ́lẹ́, wọ́n sì pèsè ìrékọjá náà sílẹ̀.+ 14  Níkẹyìn, nígbà tí wákàtí náà dé, ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì, àti àwọn àpọ́sítélì pẹ̀lú rẹ̀.+ 15  Ó sì wí fún wọn pé: “Mo ti ní ìfẹ́-ọkàn gidigidi láti jẹ ìrékọjá yìí pẹ̀lú yín kí n tó jìyà; 16  nítorí mo sọ fún yín, Dájúdájú, èmi kì yóò tún jẹ ẹ́ mọ́ títí a ó fi mú un ṣẹ nínú ìjọba Ọlọ́run.”+ 17  Bí ó sì ti tẹ́wọ́ gba ife kan,+ ó dúpẹ́, ó sì wí pé: “Ẹ gba èyí, kí ẹ sì gbé e láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan sí èkejì láàárín ara yín; 18  nítorí mo sọ fún yín, Láti ìsinsìnyí lọ, dájúdájú, èmi kì yóò tún mu láti inú àmújáde àjàrà mọ́ títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé.”+ 19  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó mú ìṣù búrẹ́dì+ kan, ó dúpẹ́, ó bù ú, ó sì fi í fún wọn, ó wí pé: “Èyí túmọ̀ sí ara mi+ tí a ó fi fúnni nítorí yín.+ Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”+ 20  Àti ife+ pẹ̀lú, lọ́nà kan náà lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ oúnjẹ alẹ́, ó wí pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun+ nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi,+ tí a óò tú jáde nítorí yín.+ 21  “Ṣùgbọ́n, wò ó! ọwọ́ afinihàn+ mi wà pẹ̀lú mi nídìí tábìlì.+ 22  Nítorí pé Ọmọ ènìyàn ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a là sílẹ̀;+ síbẹ̀ náà, ègbé ni fún ọkùnrin yẹn tí a tipasẹ̀ rẹ̀ fi í léni lọ́wọ́!”+ 23  Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jíròrò láàárín ara wọn ìbéèrè nípa èwo nínú wọn ni yóò jẹ́ ẹni náà ní ti tòótọ́ tí ó fẹ́ ṣe èyí.+ 24  Bí ó ti wù kí ó rí, awuyewuye gbígbónájanjan kan tún dìde láàárín wọn lórí èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ.+ 25  Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn tí wọ́n sì ní ọlá àṣẹ lórí wọn ni a ń pè ní àwọn Olóore.+ 26  Àmọ́ ṣá o, ẹ̀yin kò ní jẹ́ bẹ́ẹ̀.+ Ṣùgbọ́n kí ẹni tí ó tóbi jù lọ láàárín yín dà bí ẹni tí ó kéré jù lọ,+ kí ẹni tí ó sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí olórí dà bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.+ 27  Nítorí ta ni ẹni tí ó tóbi jù, ṣé ẹni tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì ni tàbí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́? Kì í ha ṣe ẹni tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì ni? Ṣùgbọ́n èmi wà láàárín yín gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.+ 28  “Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá+ nínú àwọn àdánwò mi;+ 29  èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan,+ fún ìjọba kan,+ 30  kí ẹ lè máa jẹ,+ kí ẹ sì máa mu nídìí tábìlì mi nínú ìjọba mi,+ kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́+ láti ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá. 31  “Símónì, Símónì, wò ó! Sátánì+ ti fi dandan béèrè láti gbà yín, kí ó lè kù yín bí àlìkámà.+ 32  Ṣùgbọ́n èmi ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀+ nítorí rẹ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má bàa yẹ̀; àti ìwọ, ní gbàrà tí o bá ti padà, fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.”+ 33  Nígbà náà ni ó wí fún un pé: “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sẹ́wọ̀n àti sínú ikú.”+ 34  Ṣùgbọ́n ó wí pé: “Mo sọ fún ọ, Pétérù, Àkùkọ kì yóò kọ lónìí títí ìwọ yóò fi sẹ́ ní ìgbà mẹ́ta pé ìwọ kò mọ̀ mí.”+ 35  Ó tún wí fún wọn pé: “Nígbà tí mo rán+ yín jáde láìsí àpò àti àsùnwọ̀n oúnjẹ àti sálúbàtà, ẹ kò ṣe aláìní ohunkóhun, àbí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀?” Wọ́n wí pé: “Rárá!” 36  Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé: “Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, kí ẹni tí ó ní àpò gbé e, bákan náà pẹ̀lú ni àsùnwọ̀n oúnjẹ; kí ẹni tí kò sì ní idà ta ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀, kí ó sì ra ọ̀kan. 37  Nítorí mo sọ fún yín pé èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ ṣe parí nínú mi, èyíinì ni, ‘A sì kà á mọ́ àwọn aláìlófin.’+ Nítorí èyíinì tí ó kàn mí ń ní àṣeparí.”+ 38  Nígbà náà ni wọ́n wí pé: “Olúwa, wò ó! idà méjì nìyí.” Ó wí fún wọn pé: “Ó ti tó.” 39  Nígbà tí ó jáde, ó lọ sí Òkè Ńlá Olífì gẹ́gẹ́ bí àṣà rẹ̀; àwọn ọmọ ẹ̀yìn pẹ̀lú sì tẹ̀ lé e.+ 40  Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó wí fún wọn pé: “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò.”+ 41  Òun fúnra rẹ̀ sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn ní nǹkan bí ìwọ̀n ìsọ̀kò kan, ó sì tẹ eékún rẹ̀ ba, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà, 42  pé: “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mú ife yìí kúrò lórí mi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìfẹ́ mi+ ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.”+ 43  Nígbà náà ni áńgẹ́lì kan láti ọ̀run fara hàn án, ó sì fún un lókun.+ 44  Ṣùgbọ́n bí ó ti wà nínú ìroragógó, ó ń bá a lọ ní títúbọ̀ fi taratara gbàdúrà;+ òógùn rẹ̀ sì wá dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ tí ń já bọ́ sí ilẹ̀.+ 45  Ó sì dìde lórí àdúrà, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì bá wọn tí wọ́n ń tòògbé nítorí ẹ̀dùn-ọkàn;+ 46  ó sì wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ ń sùn? Ẹ dìde, kí ẹ sì máa gbàdúrà, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò.”+ 47  Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! ogunlọ́gọ̀ kan, àti ọkùnrin tí a ń pè ní Júdásì, ọ̀kan lára àwọn méjìlá, ń lọ níwájú wọn;+ ó sì sún mọ́ Jésù láti fi ẹnu kò ó lẹ́nu.+ 48  Ṣùgbọ́n Jésù wí fún un pé: “Júdásì, ìwọ ha fi ìfẹnukonu da Ọmọ ènìyàn?”+ 49  Nígbà tí àwọn tí wọ́n yí i ká rí ohun tí ó fẹ́ ṣẹlẹ̀, wọ́n wí pé: “Olúwa, ṣé kí a máa fi idà jà lọ?”+ 50  Ẹnì kan nínú wọ́n tilẹ̀ ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó sì gé etí rẹ̀ ọ̀tún dànù.+ 51  Ṣùgbọ́n ní ìfèsìpadà, Jésù wí pé: “Ẹ fi mọ sí ibí yìí.” Ó sì fọwọ́ kan etí náà, ó sì mú un lára dá.+ 52  Nígbà náà, Jésù wí fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì àti àwọn àgbà ọkùnrin tí wọ́n tìtorí rẹ̀ wá síbẹ̀ pé: “Ẹ ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀gọ bí ẹní wá bá ọlọ́ṣà?+ 53  Nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín nínú tẹ́ńpìlì+ láti ọjọ́ dé ọjọ́, ẹ kò na ọwọ́ yín lòdì sí mi.+ Ṣùgbọ́n wákàtí yín+ àti ọlá àṣẹ+ òkùnkùn+ nìyí.” 54  Nígbà náà ni wọ́n fi àṣẹ ọba mú un, wọ́n sì mú un lọ,+ wọ́n sì mú un wá sínú ilé àlùfáà àgbà;+ ṣùgbọ́n Pétérù ń tẹ̀ lé wọn ní òkèèrè.+ 55  Nígbà tí wọ́n dá iná kan ní àárín àgbàlá, tí wọ́n sì jókòó pa pọ̀, Pétérù jókòó ní àárín wọn.+ 56  Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́bìnrin kan rí i tí ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ iná mímọ́lẹ̀ yòò náà, ó sì wò ó délẹ̀, ó sì wí pé: “[Ọkùnrin] yìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”+ 57  Ṣùgbọ́n ó sẹ́,+ pé: “Èmi kò mọ̀ ọ́n, obìnrin yìí.”+ 58  Lẹ́yìn àkókò kúkúrú kan, ẹlòmíràn tí ó rí i sọ pé: “Ìwọ pẹ̀lú jẹ́ ọ̀kan lára wọn.” Ṣùgbọ́n Pétérù sọ pé: “Èmi kọ́, ọkùnrin yìí.”+ 59  Lẹ́yìn ìgbà tí nǹkan bí wákàtí kan ti là á láàárín, ọkùnrin mìíràn kan bẹ̀rẹ̀ sí tẹpẹlẹ mọ́ ọn kíkankíkan pé: “Dájúdájú, ọkùnrin yìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀; nítorí, ní ti tòótọ́, ará Gálílì ni!”+ 60  Ṣùgbọ́n Pétérù sọ pé: “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń sọ.” Ní ìṣẹ́jú akàn, nígbà tí ó ṣì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àkùkọ sì kọ.+ 61  Olúwa sì yí padà, ó sì bojú wo Pétérù, Pétérù sì rántí àsọjáde Olúwa nígbà tí ó sọ fún un pé: “Kí àkùkọ tó kọ lónìí, ìwọ yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi ní ìgbà mẹ́ta.”+ 62  Ó sì bọ́ sóde, ó sì sunkún kíkorò.+ 63  Wàyí o, àwọn ọkùnrin tí wọ́n fi í sínú ìhámọ́ bẹ̀rẹ̀ sí fi í ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n ń gbá+ a;+ 64  lẹ́yìn tí wọ́n bá sì ti fi nǹkan bò ó, wọn yóò sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Sọ tẹ́lẹ̀. Ta ni ó gbá ọ?”+ 65  Wọ́n sì tẹ̀ síwájú ní sísọ ọ̀pọ̀ ohun mìíràn ní ìsọ̀rọ̀ òdì+ sí i. 66  Níkẹyìn, nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àjọ àwọn àgbààgbà ọkùnrin àwọn ènìyàn náà, àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kóra jọpọ̀,+ wọ́n sì fà á lọ sínú gbọ̀ngàn Sànhẹ́dírìn wọn, wọ́n wí pé:+ 67  “Bí ó bá jẹ́ ìwọ ni Kristi+ náà, sọ fún wa.” Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: “Bí mo bá tilẹ̀ sọ fún yín, ẹ kò ní gbà á gbọ́ rárá.+ 68  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí mo bá bi yín ní ìbéèrè, ẹ kì yóò dáhùn rárá.+ 69  Bí ó ti wù kí ó rí, láti ìsinsìnyí lọ, Ọmọ ènìyàn+ yóò jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún lílágbára+ Ọlọ́run.”+ 70  Látàrí èyí, gbogbo wọ́n wí pé: “Ṣé ìwọ wá ni Ọmọ Ọlọ́run?” Ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ń sọ+ pé èmi ni.” 71  Wọ́n wí pé: “Èé ṣe tí a fi nílò ẹ̀rí síwájú sí i?+ Nítorí àwa fúnra wa tí gbọ́ ọ láti ẹnu òun fúnra rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé