Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Lúùkù 21:1-38

21  Wàyí o, bí ó ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ tí wọ́n ń sọ ẹ̀bùn wọn sínú àwọn àpótí ìṣúra.+  Nígbà náà ni ó rí opó aláìní kan tí ó sọ ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an síbẹ̀,+  ó sì wí pé: “Lótìítọ́ ni mo sọ fún yín, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé opó yìí jẹ́ òtòṣì, ó sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ.+  Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí sọ ẹ̀bùn sílẹ̀ láti inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n obìnrin yìí láti inú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé tí ó ní sínú rẹ̀.”+  Lẹ́yìn náà, bí àwọn kan ti ń sọ̀rọ̀ nípa tẹ́ńpìlì, bí a ti ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn òkúta àtàtà àti àwọn ohun tí a yà sí mímọ́,+  ó wí pé: “Ní ti nǹkan wọ̀nyí tí ẹ ń wò, àwọn ọjọ́ yóò dé nínú èyí tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan níhìn-ín, tí a kì yóò sì wó palẹ̀.”+  Nígbà náà ni wọ́n bi í léèrè, pé: “Olùkọ́, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ ní ti gidi, kí ni yóò sì jẹ́ àmì ìgbà tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ pé kí nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀?”+  Ó wí pé: “Ẹ ṣọ́ra kí a má bàa ṣì yín lọ́nà;+ nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá ní orúkọ mi, wí pé, ‘Èmi ni ẹni náà,’ àti pé, ‘Àkókò yíyẹ ti sún mọ́lé.’+ Ẹ má ṣe tẹ̀ lé wọn.  Síwájú sí i, nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn ogun àti rúgúdù, kí ẹ má ṣe jáyà.+ Nítorí nǹkan wọ̀nyí gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì yóò wáyé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.” 10  Ó wá tẹ̀ síwájú láti sọ fún wọn pé: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè,+ àti ìjọba sí ìjọba;+ 11  ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn àti àìtó oúnjẹ+ láti ibì kan dé ibòmíràn; àwọn ìran bíbanilẹ́rù yóò sì wà àti àwọn àmì ńláǹlà láti ọ̀run.+ 12  “Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwọn ènìyàn yóò gbé ọwọ́ wọn lé yín, wọn yóò sì ṣe inúnibíni+ sí yín, ní fífà yín lé àwọn sínágọ́gù àti ẹ̀wọ̀n lọ́wọ́, tí a ó fà yín lọ síwájú àwọn ọba àti àwọn gómìnà nítorí orúkọ mi.+ 13  Yóò já sí ẹ̀rí fún yín.+ 14  Nítorí náà, ẹ pinnu rẹ̀ nínú ọkàn-àyà yín láti má ṣe fi bí ẹ ó ṣe gbèjà ara yín dánrawò ṣáájú,+ 15  nítorí dájúdájú èmi yóò fún yín ni ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn alátakò yín lápapọ̀ kì yóò lè dúró tiiri lòdì sí tàbí bá ṣe awuyewuye.+ 16  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àní àwọn òbí+ àti àwọn arákùnrin àti àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ pàápàá yóò fà yín léni lọ́wọ́, wọn yóò sì fi ikú pa àwọn kan nínú yín;+ 17  ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi.+ 18  Síbẹ̀, irun+ orí yín kan kì yóò ṣègbé lọ́nàkọnà. 19  Nípasẹ̀ ìfaradà níhà ọ̀dọ̀ yín ni ẹ ó fi jèrè ọkàn yín.+ 20  “Síwájú sí i, nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká,+ nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé.+ 21  Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀;+ 22  nítorí pé ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ọjọ́ fún pípín ìdájọ́ òdodo jáde, kí gbogbo ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀ lè ní ìmúṣẹ.+ 23  Ègbé ni fún àwọn obìnrin tí ó lóyún àti àwọn tí ń fi ọmú fún ọmọ ọwọ́ ní ọjọ́ wọnnì!+ Nítorí ipò àìní ńláǹlà yóò wà lórí ilẹ̀ náà àti ìrunú lórí àwọn ènìyàn yìí; 24  wọn yóò sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì kó wọn lọ ní òǹdè sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;+ àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì tẹ Jerúsálẹ́mù mọ́lẹ̀, títí àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀+ fún àwọn orílẹ̀-èdè yóò fi pé. 25  “Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn àmì yóò wà nínú oòrùn+ àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀, àti lórí ilẹ̀ ayé làásìgbò àwọn orílẹ̀-èdè, láìmọ ọ̀nà àbájáde nítorí ìpariwo omi òkun+ àti ìrugùdù rẹ̀,+ 26  nígbà tí àwọn ènìyàn yóò máa kú sára nítorí ìbẹ̀rù+ àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé tí a ń gbé;+ nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì.+ 27  Nígbà náà ni wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn+ tí ń bọ̀ nínú àwọsánmà pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.+ 28  Ṣùgbọ́n bí nǹkan wọ̀nyí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, ẹ gbé ara yín nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.” 29  Pẹ̀lú èyíinì, ó sọ àpèjúwe kan fún wọn pé: “Ẹ fiyè sí igi ọ̀pọ̀tọ́ àti gbogbo igi yòókù:+ 30  Nígbà tí wọ́n bá ti rudi, nípa ṣíṣàkíyèsí rẹ̀, ẹ̀yin mọ̀ fúnra yín pé nísinsìnyí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́lé.+ 31  Lọ́nà yìí, ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá rí nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé.+ 32  Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, Ìran yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan yóò fi ṣẹlẹ̀.+ 33  Ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò kọjá lọ,+ ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà.+ 34  “Ṣùgbọ́n ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó+ kẹ́ri àti àwọn àníyàn+ ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn+ 35  gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn.+ Nítorí yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé.+ 36  Ẹ máa wà lójúfò,+ nígbà náà, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀+ ní gbogbo ìgbà, kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró níwájú Ọmọ ènìyàn.”+ 37  Nítorí náà, ní ọ̀sán, òun a máa kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì,+ ṣùgbọ́n ní òru, a jáde lọ wọ̀ sí òkè ńlá tí a ń pè ní Òkè Ńlá Olífì.+ 38  Gbogbo ènìyàn+ yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù nínú tẹ́ńpìlì láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé