Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Lúùkù 20:1-47

20  Ní ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ náà, nígbà tí ó ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú tẹ́ńpìlì, tí ó sì ń polongo ìhìn rere, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin pẹ̀lú àwọn àgbà ọkùnrin wá sí tòsí,+  wọ́n sì sọ̀rọ̀ jáde, wọ́n wí fún un pé: “Sọ ọlá àṣẹ tí ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún wa, tàbí ẹni tí ó fún ọ ní ọlá àṣẹ yìí.”+  Ní ìfèsìpadà, ó wí fún wọn pé: “Dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ yín, kí ẹ sì sọ fún mi:+  Ìbatisí Jòhánù, ṣé láti ọ̀run ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?”+  Nígbà náà ni wọ́n dé ìparí èrò láàárín ara wọn, pé: “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ yóò sọ pé, ‘Èé ṣe tí ẹ kò gbà á gbọ́?’+  Ṣùgbọ́n bí àwa bá sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ gbogbo ènìyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan yóò sọ wá lókùúta,+ nítorí wọ́n gbà pé wòlíì+ ni Jòhánù.”+  Nítorí náà, wọ́n fèsì pé àwọn kò mọ orísun rẹ̀.  Jésù sì wí fún wọn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò sọ ọlá àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín.”+  Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ àpèjúwe yìí fún àwọn ènìyàn pé: “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà+ kan, ó sì gbé e fún àwọn aroko, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀ fún àkókò gígùn.+ 10  Ṣùgbọ́n ní àsìkò yíyẹ, ó rán ẹrú kan+ jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn aroko+ náà, kí wọ́n lè fún un lára èso ọgbà àjàrà+ náà. Àmọ́ ṣá o, àwọn aroko náà rán an lọ lọ́wọ́ òfo,+ lẹ́yìn lílù ú ní ìlùkulù. 11  Ṣùgbọ́n ó tún ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì rán ẹrú mìíràn sí wọn. Èyíinì pẹ̀lú ni wọ́n lù ní ìlùkulù, wọ́n sì tàbùkù sí i, wọ́n sì rán an lọ lọ́wọ́ òfo.+ 12  Síbẹ̀, ó tún rán ẹ̀kẹta;+ eléyìí pẹ̀lú ni wọ́n ṣá lọ́gbẹ́, tí wọ́n sì jù síta. 13  Látàrí èyí, ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà wí pé, ‘Kí ni èmi yóò ṣe? Ṣe ni èmi yóò rán ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n.+ Ó jọ pé wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ẹni yìí.’ 14  Nígbà tí àwọn aroko náà tajú kán rí i, wọ́n wá ń fèrò wérò láàárín ara wọn, pé, ‘Ajogún nìyí; ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún náà lè di tiwa.’+ 15  Pẹ̀lú èyíinì, wọ́n sọ ọ́ sóde+ ọgbà àjàrà náà, wọ́n sì pa á.+ Nítorí náà, kí ni ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà yóò ṣe sí wọn?+ 16  Yóò wá, yóò sì pa aroko wọ̀nyí run, yóò sì fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn ẹlòmíràn.”+ Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wọ́n wí pé: “Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé!” 17  Ṣùgbọ́n ó bojú wò wọ́n, ó sì wí pé: “Kí wá ni èyí túmọ̀ sí tí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Òkúta tí àwọn akọ́lé kọ̀ tì,+ èyí ti di olórí òkúta igun ilé’?+ 18  Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ṣubú lu òkúta náà ni a óò fọ́ túútúú.+ Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá bọ́ lù,+ yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”+ 19  Wàyí o, àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn olórí àlùfáà ń wá bí ọwọ́ wọn yóò ṣe tẹ̀ ẹ́ ní wákàtí yẹn gan-an, ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn; nítorí wọ́n róye pé àwọn ni ó ní lọ́kàn tí ó fi sọ àpèjúwe yìí.+ 20  Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti ṣàkíyèsí rẹ̀ fínnífínní, wọ́n rán àwọn ọkùnrin jáde tí wọ́n háyà ní bòókẹ́lẹ́ láti díbọ́n pé àwọn jẹ́ olódodo, kí wọ́n lè mú un+ nínú ọ̀rọ̀, kí wọ́n bàa lè fi í lé ọwọ́ ìjọba àti ọlá àṣẹ gómìnà.+ 21  Wọ́n sì bi í léèrè, pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ a máa sọ̀rọ̀, ìwọ a sì máa kọ́ni lọ́nà títọ̀nà, o kì í sì í fi ojúsàájú kankan hàn, ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́:+ 22  Ó ha bófin mu fún wa láti san owó orí fún Késárì tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́?”+ 23  Ṣùgbọ́n ó jádìí àlùmọ̀kọ́rọ́yí wọn, ó sì wí fún wọn pé:+ 24  “Ẹ fi owó dínárì kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ta ni ó ní?” Wọ́n wí pé: “Ti Késárì.”+ 25  Ó wí fún wọn pé: “Ẹ rí i dájú, nígbà náà, pé ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì,+ ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”+ 26  Tóò, kò ṣeé ṣe fún wọn láti mú un nínú àsọjáde yìí níwájú àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n, ní ṣíṣe kàyéfì látàrí ìdáhùn rẹ̀, wọn kò sọ ohunkóhun.+ 27  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn kan nínú àwọn Sadusí, àwọn tí wọ́n sọ pé kò sí àjíǹde, wá+ bi í léèrè, 28  pé: “Olùkọ́, Mósè+ kọ̀wé fún wa pé, ‘Bí arákùnrin ọkùnrin kan bá kú tí ó ní aya, ṣùgbọ́n tí ẹni yìí wà láìbímọ, arákùnrin rẹ̀+ ní láti fẹ́ aya náà, kí ó sì gbé ọmọ dìde láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ fún arákùnrin rẹ̀.’+ 29  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, arákùnrin méje wà; èkíní sì fẹ́ aya kan, ó sì kú láìbímọ.+ 30  Bákan náà ni èkejì, 31  àti ẹ̀kẹta fẹ́ ẹ. Àní bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn méjèèje: wọn kò fi ọmọ sílẹ̀ sẹ́yìn, ṣùgbọ́n wọ́n kú lọ́kọ̀ọ̀kan.+ 32  Níkẹyìn, obìnrin náà pẹ̀lú kú.+ 33  Nítorí náà, ní àjíǹde, èwo nínú wọn ni yóò di aya fún? Nítorí àwọn méjèèje ni wọ́n fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí aya.”+ 34  Jésù wí fún wọn pé: “Àwọn ọmọ ètò àwọn nǹkan yìí a máa gbéyàwó,+ a sì máa ń fi wọ́n fúnni nínú ìgbéyàwó, 35  ṣùgbọ́n àwọn tí a ti kà yẹ+ fún jíjèrè ètò àwọn nǹkan yẹn+ àti àjíǹde láti inú òkú+ kì í gbéyàwó, bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi wọ́n fúnni nínú ìgbéyàwó. 36  Ní ti tòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè kú mọ́,+ nítorí wọ́n dà bí àwọn áńgẹ́lì, ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n nípa jíjẹ́ àwọn ọmọ àjíǹde.+ 37  Ṣùgbọ́n pé a gbé àwọn òkú dìde ni Mósè pàápàá sọ di mímọ̀, nínú ìròyìn nípa igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún,+ nígbà tí ó pe Jèhófà ní ‘Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù.’+ 38  Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè, nítorí gbogbo wọ́n wà láàyè lójú rẹ̀.”+ 39  Ní ìdáhùnpadà, àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé òfin wí pé: “Olùkọ́, ìwọ sọ̀rọ̀ dáadáa.” 40  Nítorí wọn kò ní ìgboyà láti béèrè ẹyọ ìbéèrè kan lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́. 41  Ẹ̀wẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Báwo ni ó ṣe jẹ́ tí wọ́n ń sọ pé Kristi jẹ́ ọmọkùnrin Dáfídì?+ 42  Nítorí Dáfídì fúnra rẹ̀ sọ nínú ìwé àwọn Sáàmù pé, ‘Jèhófà wí fún Olúwa mi pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi 43  títí èmi yóò fi gbé àwọn ọ̀tá rẹ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.”’+ 44  Nítorí náà, Dáfídì pè é ní ‘Olúwa’; nítorí náà, báwo ni òun ṣe jẹ́ ọmọkùnrin rẹ̀?” 45  Lẹ́yìn náà, bí gbogbo ènìyàn ti ń fetí sílẹ̀, ó wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé:+ 46  “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n ní ìfẹ́-ọkàn láti máa rìn káàkiri nínú aṣọ ńlá, tí wọ́n sì ń fẹ́ ìkíni ní àwọn ibi ọjà àti àwọn ìjókòó iwájú nínú àwọn sínágọ́gù àti àwọn ibi yíyọrí ọlá jù lọ níbi oúnjẹ alẹ́,+ 47  tí wọ́n sì ń jẹ ilé àwọn opó run,+ wọ́n ń gba àdúrà gígùn fún bojúbojú. Àwọn wọ̀nyí yóò gba ìdájọ́ tí ó wúwo jù.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé