Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Lúùkù 2:1-52

2  Wàyí o, ní ọjọ́ wọnnì àṣẹ àgbékalẹ̀+ kan jáde lọ láti ọ̀dọ̀ Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì pé kí gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé forúkọ sílẹ̀;  (ìforúkọsílẹ̀ àkọ́kọ́ yìí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Kúírínọ́sì jẹ́ gómìnà Síríà;)  gbogbo ènìyàn sì ń rin ìrìn àjò lọ láti forúkọ sílẹ̀,+ olúkúlùkù sí ìlú ńlá tirẹ̀.  Bí a ti lè retí, Jósẹ́fù pẹ̀lú gòkè lọ láti Gálílì, kúrò ní ìlú ńlá Násárétì, lọ sí Jùdíà, sí ìlú ńlá Dáfídì, èyí tí a ń pè ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ nítorí jíjẹ́ tí ó jẹ́ mẹ́ńbà ilé àti ìdílé Dáfídì,+  láti forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú Màríà,+ ẹni tí a ti fi fún un nínú ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí a ti ṣèlérí,+ tí ó ti súnmọ́ àkókò àtibímọ+ nísinsìnyí.  Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ pé fún un láti bímọ.  Ó sì bí ọmọkùnrin rẹ̀, àkọ́bí,+ ó sì fi àwọn ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran+ kan, nítorí pé kò sí àyè fún wọn nínú yàrá ibùwọ̀.  Àwọn olùṣọ́ àgùntàn pẹ̀lú wà ní ìgbèríko kan náà, tí wọ́n ń gbé ní ìta, tí wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru.  Lójijì, áńgẹ́lì Jèhófà+ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, ògo Jèhófà+ sì ràn yòò yí wọn ká, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. 10  Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì náà wí fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù, nítorí, wò ó! èmi ń polongo fún yín ìhìn rere ti ìdùnnú ńlá kan tí gbogbo ènìyàn yóò ní,+ 11  nítorí pé a bí Olùgbàlà+ kan fún yín lónìí, ẹni tí í ṣe Kristi Olúwa,+ ní ìlú ńlá Dáfídì.+ 12  Èyí sì ni àmì fún yín: ẹ óò rí ọmọdé jòjòló kan tí a fi àwọn ọ̀já wé, ó sì wà ní ìdùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran.” 13  Lójijì, ògìdìgbó ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run+ sì wà pẹ̀lú áńgẹ́lì náà, wọ́n ń yin Ọlọ́run,+ wọ́n sì ń sọ pé: 14  “Ògo fún Ọlọ́run ní àwọn ibi gíga+ lókè, àti lórí ilẹ̀ ayé àlàáfíà+ láàárín àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà.”+ 15  Nítorí náà, nígbà tí àwọn áńgẹ́lì náà ti kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Ẹ jẹ́ kí a rí i dájú pé a lọ ní tààràtà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, kí a sì rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ yìí, èyí tí Jèhófà+ ti sọ di mímọ̀ fún wa.” 16  Wọ́n sì lọ pẹ̀lú ìṣekánkán, wọ́n sì rí Màríà àti Jósẹ́fù, àti ọmọdé jòjòló tí ó wà ní ìdùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran. 17  Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n sọ àsọjáde tí a ti sọ fún wọn nípa ọmọ kékeré yìí di mímọ̀. 18  Gbogbo àwọn tí wọ́n sì gbọ́ ni ẹnu yà sí àwọn ohun tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà sọ fún wọn, 19  ṣùgbọ́n Màríà bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo àsọjáde wọ̀nyí mọ́, ní dídé ìparí èrò nínú ọkàn-àyà rẹ̀.+ 20  Nígbà náà ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì ń yìn ín fún gbogbo ohun tí wọ́n gbọ́, tí wọ́n sì rí, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ìwọ̀nyí fún wọn. 21  Wàyí o, nígbà tí ọjọ́ mẹ́jọ+ pé láti dádọ̀dọ́+ rẹ̀, a pe orúkọ rẹ̀ pẹ̀lú ní Jésù,+ orúkọ tí áńgẹ́lì náà pè kí a tó lóyún rẹ̀ nínú ilé ọlẹ̀.+ 22  Pẹ̀lúpẹ̀lù, nígbà tí ọjọ́ wíwẹ̀ wọ́n mọ́ gaara+ ní ìbámu pẹ̀lú òfin Mósè pé, wọ́n gbé e gòkè wá sí Jerúsálẹ́mù láti fi í fún Jèhófà, 23  gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú òfin Jèhófà pé: “Gbogbo akọ tí ó ṣí ilé ọlẹ̀ ni kí a pè ní mímọ́ fún Jèhófà,”+ 24  àti láti rú ẹbọ ní ìbámu pẹ̀lú nǹkan tí a sọ nínú òfin Jèhófà: “Oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.”+ 25  Sì wò ó! ọkùnrin kan wà ní Jerúsálẹ́mù tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Síméónì, ọkùnrin yìí sì jẹ́ olódodo àti onífọkànsìn, tí ń dúró de ìtùnú Ísírẹ́lì,+ ẹ̀mí mímọ́ sì wà lára rẹ̀. 26  Síwájú sí i, a ti ṣí i payá fún un látọ̀runwá nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ pé kì yóò rí ikú kí ó tó rí Kristi+ ti Jèhófà. 27  Lábẹ́ agbára ẹ̀mí,+ ó wá sínú tẹ́ńpìlì nísinsìnyí; bí àwọn òbí náà sì ti gbé ọmọ kékeré náà Jésù wọlé láti ṣe fún un ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a ń ṣe ní àṣà bí òfin ti wí,+ 28  òun fúnra rẹ̀ gbà á sí apá rẹ̀, ó sì fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó sì wí pé: 29  “Nísinsìnyí, Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìwọ ń jẹ́ kí ẹrú rẹ lọ lómìnira ní àlàáfíà+ ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo rẹ; 30  nítorí ojú mi ti rí ohun àmúlò rẹ fún gbígbanilà+ 31  tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ lójú gbogbo ènìyàn,+ 32  ìmọ́lẹ̀+ fún mímú ìbòjú kúrò+ lójú àwọn orílẹ̀-èdè+ àti ògo àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì.” 33  Baba àti ìyá rẹ̀ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe kàyéfì lórí àwọn ohun tí a ń sọ nípa rẹ̀. 34  Pẹ̀lúpẹ̀lù, Síméónì súre fún wọn, ṣùgbọ́n ó wí fún Màríà ìyá rẹ̀ pé: “Wò ó! Ẹni yìí ni a gbé kalẹ̀ fún ìṣubú+ àti ìtúndìde ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní Ísírẹ́lì+ àti fún àmì kan tí a ó sọ̀rọ̀ lòdì sí+ 35  (bẹ́ẹ̀ ni, idà gígùn kan ni a ó fi gún ọkàn tìrẹ),+ kí èrò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn-àyà lè di èyí tí a tú síta.”+ 36  Wàyí o, Ánà wòlíì obìnrin kan wà, ọmọbìnrin Fánúẹ́lì, ti ẹ̀yà Áṣérì (obìnrin yìí ti lọ́jọ́ lórí gan-an, ó sì ti gbé pẹ̀lú ọkọ kan fún ọdún méje láti ìgbà wúńdíá rẹ̀, 37  ó sì jẹ́ opó+ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin nísinsìnyí), ẹni tí kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ, tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ lóru àti lọ́sàn-án+ pẹ̀lú ààwẹ̀ àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀. 38  Ní wákàtí yẹn gan-an, ó wá sí tòsí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ọpẹ́ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ó sì ń sọ̀rọ̀ nípa ọmọ náà fún gbogbo àwọn tí ń dúró de ìdáǹdè Jerúsálẹ́mù.+ 39  Nítorí náà, nígbà tí wọ́n ti ṣe ohun gbogbo tán ní ìbámu pẹ̀lú òfin+ Jèhófà, wọ́n padà lọ sí Gálílì sí Násárétì+ ìlú ńlá tiwọn. 40  Ọmọ kékeré náà sì ń bá a lọ ní dídàgbà àti dídi alágbára,+ ó kún fún ọgbọ́n, ojú rere Ọlọ́run+ sì ń bá a lọ ní wíwà lórí rẹ̀. 41  Wàyí o, ó jẹ́ àṣà àwọn òbí rẹ̀ láti máa lọ sí Jerúsálẹ́mù+ láti ọdún dé ọdún fún àjọyọ̀ ìrékọjá. 42  Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ ní ìbámu pẹ̀lú àṣà+ àjọyọ̀ náà, 43  wọ́n sì lo àwọn ọjọ́ náà pé. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n ń padà bọ̀, ọmọdékùnrin náà Jésù dúró sẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù, àwọn òbí rẹ̀ kò sì kíyè sí i. 44  Ní rírò pé ó wà nínú àwùjọ ẹgbẹ́ tí ń rin ìrìn àjò pa pọ̀, wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan,+ lẹ́yìn náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá a kiri láàárín àwọn ìbátan àti àwọn ojúlùmọ̀. 45  Ṣùgbọ́n, nígbà tí wọn kò rí i, wọ́n padà sí Jerúsálẹ́mù, ní wíwá a kiri taápọn-taápọn. 46  Tóò, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, wọ́n rí i nínú tẹ́ńpìlì,+ ó jókòó sáàárín àwọn olùkọ́, ó sì ń fetí sí wọn, ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè. 47  Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ń fetí sí i ni wọ́n ń ṣe kàyéfì léraléra nítorí òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀.+ 48  Wàyí o, nígbà tí wọ́n rí i, háà ṣe wọ́n, ìyá rẹ̀ sì wí fún un pé: “Ọmọ, èé ṣe tí o fi hùwà sí wa lọ́nà yìí? Kíyè sí i, baba rẹ àti èmi ti ń wá ọ nínú ìdààmú-ọkàn.” 49  Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ní láti máa wá mi? Ṣé ẹ kò mọ̀ pé èmi gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi+ ni?” 50  Bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò mòye àsọjáde tí ó sọ fún wọn.+ 51  Ó sì bá wọn sọ̀ kalẹ̀ lọ, wọ́n sì wá sí Násárétì, ó sì ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́+ wọn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìyá rẹ̀ rọra pa gbogbo àsọjáde wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.+ 52  Jésù sì ń bá a lọ ní títẹ̀síwájú ní ọgbọ́n+ àti ní ìdàgbàsókè ti ara-ìyára àti ní níní ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé