Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Lúùkù 18:1-43

18  Nígbà náà ni ó ń bá a lọ láti sọ àpèjúwe kan fún wọn nípa àìní náà fún wọn láti máa gbàdúrà nígbà gbogbo àti láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀,+  ó wí pé: “Ní ìlú ńlá kan, onídàájọ́ kan wà tí kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ní ọ̀wọ̀ fún ènìyàn.  Ṣùgbọ́n opó kan wà ní ìlú ńlá yẹn, ó sì ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣáá,+ ó ń wí pé, ‘Rí i pé mo rí ìdájọ́ òdodo gbà lára elénìní mi lábẹ́ òfin.’  Tóò, fún ìgbà díẹ̀, kò fẹ́, ṣùgbọ́n nígbẹ̀yìn, ó wí fún ara rẹ̀ pé, ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò bẹ̀rù Ọlọ́run tàbí bọ̀wọ̀ fún ènìyàn kan,  bí ó ti wù kí ó rí, nítorí tí opó yìí ń dà mí láàmú nígbà gbogbo,+ dájúdájú, èmi yóò rí i pé ó rí ìdájọ́ òdodo gbà, kí ó má bàa máa wá ṣáá, kí ó sì máa lù mí kíkankíkan+ dé òpin.’”  Nígbà náà ni Olúwa wí pé: “Ẹ gbọ́ ohun tí onídàájọ́ náà wí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ aláìṣòdodo!  Dájúdájú, nígbà náà, Ọlọ́run kì yóò ha mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo+ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí ń ké jáde sí i tọ̀sán-tòru, kódà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní ìpamọ́ra+ sí wọn?  Mo sọ fún yín, Yóò mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún wọn pẹ̀lú ìyára kánkán.+ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé, yóò ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?”  Ṣùgbọ́n ó sọ àpèjúwe yìí pẹ̀lú fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ara wọn pé àwọn jẹ́ olódodo,+ tí wọ́n sì ka àwọn yòókù sí aláìjámọ́ nǹkan kan:+ 10  “Ọkùnrin méjì gòkè lọ sínú tẹ́ńpìlì láti gbàdúrà, ọ̀kan Farisí àti èkejì agbowó orí. 11  Farisí náà dúró,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gba nǹkan wọ̀nyí ní àdúrà+ sí ara rẹ̀, ‘Ọlọ́run, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé èmi kò rí bí àwọn ènìyàn yòókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòdodo, panṣágà, tàbí bí agbowó orí+ yìí pàápàá. 12  Mo ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì lọ́sẹ̀, mo ń fúnni ní ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí mo ní.’+ 13  Ṣùgbọ́n agbowó orí tí ó dúró ní òkèèrè kò fẹ́ láti gbé ojú rẹ̀ sókè sí ọ̀run pàápàá, ṣùgbọ́n ó sáà ń lu igẹ̀ rẹ̀ ṣáá,+ ó ń wí pé, ‘Ọlọ́run, fi oore ọ̀fẹ́ hàn sí èmi ẹlẹ́ṣẹ̀.’+ 14  Mo sọ fún yín, Ọkùnrin yìí sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ẹni tí a fi hàn ní olódodo ju+ ọkùnrin yẹn; nítorí pé olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óò tẹ́ lógo, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.”+ 15  Wàyí o, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ọmọ wọn kéékèèké pẹ̀lú wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ó lè fọwọ́ kàn wọ́n; ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí èyí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn wí kíkankíkan.+ 16  Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù pe àwọn ọmọ kéékèèké náà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó wí pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun. Nítorí ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.+ 17  Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnì yòówù tí kò bá gba ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré kì yóò dé inú rẹ̀ lọ́nàkọnà.”+ 18  Olùṣàkóso kan sì bi í léèrè, pé: “Olukọ Rere, nípa ṣíṣe kí ni èmi yóò fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 19  Jésù wí fún un pé: “Èé ṣe tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere, àyàfi ẹnì kan, Ọlọ́run.+ 20  Ìwọ mọ àwọn àṣẹ+ náà, ‘Má ṣe panṣágà,+ Má ṣìkà pànìyàn,+ Má jalè,+ Má ṣe jẹ́rìí èké,+ Bọlá fún baba àti ìyá rẹ.’”+ 21  Nígbà náà ni ó wí pé: “Gbogbo ìwọ̀nyí ni mo ti pa mọ́ láti ìgbà èwe wá.”+ 22  Lẹ́yìn gbígbọ́ ìyẹn, Jésù wí fún un pé: “Ohun kan ṣì wà tí o ṣaláìní: Ta gbogbo ohun tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run; sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.”+ 23  Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó wá ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi, nítorí ó ní ọrọ̀ gan-an.+ 24  Jésù wò ó, ó sì wí pé: “Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun tí ó ṣòro fún àwọn tí wọ́n ní owó láti rí ọ̀nà wọ ìjọba Ọlọ́run!+ 25  Ní ti tòótọ́, ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ ìránṣọ kọjá jù fún ọlọ́rọ̀ láti dé inú ìjọba Ọlọ́run.”+ 26  Àwọn tí wọ́n gbọ́ èyí wí pé: “Ta ni ó lè ṣeé ṣe kí a gbà là?” 27  Ó wí pé: “Àwọn ohun tí kò ṣeé ṣe fún ènìyàn ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”+ 28  Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé: “Wò ó! Àwa ti fi àwọn ohun tiwa sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”+ 29  Ó wí fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Kò sí ẹni tí ó fi ilé sílẹ̀ tàbí aya tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn òbí tàbí àwọn ọmọ nítorí ìjọba Ọlọ́run,+ 30  tí kì yóò gba ìlọ́po-ìlọ́po sí i lọ́nà èyíkéyìí ní sáà àkókò yìí, àti nínú ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀, ìyè àìnípẹ̀kun.”+ 31  Nígbà náà ni ó mú àwọn méjìlá náà wá sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì wí fún wọn pé: “Wò ó! A ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, gbogbo nǹkan tí a sì kọ nípasẹ̀ àwọn wòlíì+ lórí Ọmọ ènìyàn ni a ó ṣe ní àṣepé.+ 32  Fún àpẹẹrẹ, wọn yóò fà á lé àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, a ó sì fi í ṣe yẹ̀yẹ́,+ a ó sì hùwà sí i lọ́nà àfojúdi,+ a ó sì tutọ́ sí i lára;+ 33  àti pé lẹ́yìn nínà án lọ́rẹ́,+ wọn yóò pa á,+ ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kẹta, yóò dìde.”+ 34  Bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò lóye ìtumọ̀ èyíkéyìí nínú nǹkan wọ̀nyí; ṣùgbọ́n àsọjáde yìí ni a fi pa mọ́ fún wọn, wọn kò sì mọ àwọn ohun tí a sọ.+ 35  Wàyí o, bí ó ti ń sún mọ́ Jẹ́ríkò, ọkùnrin afọ́jú kan jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú ọ̀nà, ó ń ṣagbe.+ 36  Nítorí tí ó gbọ́ tí ogunlọ́gọ̀ ń kọjá lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí ohun tí èyí lè túmọ̀ sí. 37  Wọ́n ròyìn fún un pé: “Jésù ará Násárétì ni ó ń kọjá lọ!”+ 38  Látàrí èyíinì, ó ké jáde, pé: “Jésù, Ọmọkùnrin Dáfídì, ṣàánú fún mi!”+ 39  Àwọn tí wọ́n sì ń lọ níwájú sọ fún un kíkankíkan pé kí ó dákẹ́, ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ ni ó túbọ̀ ń kígbe sí i pé: “Ọmọkùnrin Dáfídì, ṣàánú fún mi.”+ 40  Nígbà náà ni Jésù dúró jẹ́ẹ́, ó sì pàṣẹ pé kí a mú ọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ òun.+ Lẹ́yìn tí ó sún mọ́ tòsí, Jésù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: 41  “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?”+ Ó wí pé: “Olúwa, jẹ́ kí n tún ríran.”+ 42  Nítorí náà, Jésù wí fún un pé: “Tún ríran; ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+ 43  Ó sì tún ríran ní ìṣẹ́jú akàn,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé e, ó ń yin Ọlọ́run lógo.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, gbogbo ènìyàn fi ìyìn fún Ọlọ́run nígbà tí wọ́n rí èyí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé