Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Lúùkù 16:1-31

16  Nígbà náà ni ó ń bá a lọ láti sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pẹ̀lú pé: “Ọkùnrin kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, ó sì ní ìríjú kan,+ a sì fi ẹ̀sùn kan ẹni yìí lọ́dọ̀ rẹ̀ pé ó ń fi àwọn ẹrù rẹ̀ ṣòfò.+  Nítorí náà, ó pè é, ó sì wí fún un pé, ‘Kí ni ohun tí mo gbọ́ nípa rẹ yìí? Gbé àkọsílẹ̀+ iṣẹ́ ìríjú rẹ wá, nítorí ìwọ kò lè mójútó ilé yìí mọ́.’  Nígbà náà ni ìríjú náà sọ fún ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni kí n ṣe, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọ̀gá mi+ yóò gba iṣẹ́ ìríjú kúrò lọ́wọ́ mi? Èmi kò lágbára tó láti gbẹ́lẹ̀, ojú ń tì mí láti ṣagbe.  Áà! Mo mọ ohun tí n ó ṣe, kí ó bàa lè jẹ́ pé, nígbà tí a bá yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ ìríjú náà, àwọn ènìyàn yóò gbà mí sínú ilé wọn.’+  Ní pípe olúkúlùkù àwọn ajigbèsè ọ̀gá rẹ̀ sọ́dọ̀, ó tẹ̀ síwájú láti sọ fún ẹni àkọ́kọ́ pé, ‘Èló ni gbèsè tí o jẹ ọ̀gá mi?’  Ó wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n báàfù òróró ólífì.’ Ó wí fún un pé, ‘Gba àdéhùn alákọsílẹ̀ rẹ padà, sì jókòó, kí o sì kọ àádọ́ta kíákíá.’  Lẹ́yìn náà, ó wí fún òmíràn pé, ‘Wàyí o, ìwọ, èló ni gbèsè tí o jẹ?’ Ó wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n kọ́ọ̀ àlìkámà.’ Ó wí fún un pé, ‘Gba àdéhùn alákọsílẹ̀ rẹ padà, kí o sì kọ ọgọ́rin.’  Ọ̀gá rẹ̀ sì gbóríyìn fún ìríjú náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ aláìṣòdodo, nítorí pé ó gbé ìgbésẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́;+ nítorí àwọn ọmọ ètò àwọn nǹkan yìí gbọ́n lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ sí ìran tiwọn ju bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ ti jẹ́.+  “Pẹ̀lúpẹ̀lù, mo wí fún yín, Ẹ yan àwọn ọ̀rẹ́+ fún ara yín nípasẹ̀ ọrọ̀ àìṣòdodo,+ kí ó bàa lè jẹ́ pé, nígbà tí irúfẹ́ bẹ́ẹ̀ bá kùnà, wọn yóò lè gbà yín sínú àwọn ibi gbígbé àìnípẹ̀kun.+ 10  Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú, ẹni tí ó bá sì jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.+ 11  Nítorí náà, bí ẹ kò bá tíì fi ara yín hàn ní olùṣòtítọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ àìṣòdodo, ta ni yóò fi ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ sí ìkáwọ́ yín?+ 12  Bí ẹ kò bá sì tíì fi ara yín hàn ní olùṣòtítọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun tí ó jẹ́ ti ẹlòmíràn,+ ta ni yóò fi ohun tí ó jẹ́ tiyín fún yín? 13  Kò sí ìránṣẹ́ ilé tí ó lè jẹ́ ẹrú fún ọ̀gá méjì; nítorí pé, yálà yóò kórìíra ọ̀kan, tí yóò sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí yóò fà mọ́ ọ̀kan, tí yóò sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè jẹ́ ẹrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.”+ 14  Wàyí o, àwọn Farisí, tí wọ́n jẹ́ olùfẹ́ owó, ń fetí sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yínmú sí i.+ 15  Nítorí náà, ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ni ẹ ń polongo ara yín ní olódodo níwájú àwọn ènìyàn,+ ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ ọkàn-àyà yín;+ nítorí pé ohun tí ó ga fíofío láàárín àwọn ènìyàn jẹ́ ohun ìríra lójú Ọlọ́run.+ 16  “Òfin àti àwọn Wòlíì wà títí di ìgbà Jòhánù.+ Láti ìgbà náà lọ ni a ti ń polongo ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere, onírúurú ènìyàn gbogbo sì ń fi ìsapá tẹ̀ síwájú síhà rẹ̀.+ 17  Ní tòótọ́, ó rọrùn kí ọ̀run àti ilẹ̀ ayé kọjá lọ+ jù kí gínńgín+ kan lára lẹ́tà kan nínú Òfin lọ láìní ìmúṣẹ.+ 18  “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó ṣe panṣágà, ẹni tí ó bá sì gbé obìnrin tí ọkọ kan kọ̀ sílẹ̀ níyàwó ṣe panṣágà.+ 19  “Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan+ jẹ́ ọlọ́rọ̀, a sì máa fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ wọ ara rẹ̀, ó ń gbádùn ara rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́ pẹ̀lú ọlá ńlá.+ 20  Ṣùgbọ́n alágbe kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lásárù ni a máa ń gbé sí ẹnubodè rẹ̀, ó kún fún egbò, 21  ó sì máa ń ní ìfẹ́-ọkàn láti jẹ àwọn nǹkan tí ń bọ́ sílẹ̀ láti orí tábìlì ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà ní àjẹyó. Bẹ́ẹ̀ ni, pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ajá a máa wá pọ́n àwọn egbò rẹ̀ lá. 22  Wàyí o, nígbà tí ó ṣe, alágbe náà kú,+ àwọn áńgẹ́lì sì gbé e lọ sí ipò oókan àyà+ Ábúráhámù.+ “Pẹ̀lúpẹ̀lù, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà kú,+ a sì sin ín. 23  Ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè nínú Hédíìsì, bí ó ti ń joró,+ ó sì rí Ábúráhámù lókèèrè réré àti Lásárù ní ipò oókan àyà pẹ̀lú rẹ̀. 24  Nítorí náà, ó pè, ó sì wí pé, ‘Ábúráhámù baba,+ ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lásárù láti tẹ orí ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó sì mú ahọ́n mi tutù,+ nítorí tí mo wà nínú làásìgbò nínú iná tí ń jó wòwò yìí.’+ 25  Ṣùgbọ́n Ábúráhámù wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé ìwọ gba àwọn ohun rere tìrẹ ní kíkún ní ìgbà ayé rẹ, ṣùgbọ́n Lásárù lọ́nà tí ó bamu rẹ́gí gba àwọn ohun aṣeniléṣe. Nísinsìnyí, bí ó ti wù kí ó rí, ó ń ní ìdẹ̀ra níhìn-ín ṣùgbọ́n ìwọ wà nínú làásìgbò.+ 26  Àti pé yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ọ̀gbun ńlá+ kan ni a ti gbé kalẹ̀ sí àárín àwa àti ẹ̀yin,+ tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí ń fẹ́ kọjá lọ láti ìhín sọ́dọ̀ yín kò lè ṣe bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò lè sọdá láti ibẹ̀ sọ́dọ̀ wa.’+ 27  Nígbà náà ni ó wí pé, ‘Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, mo bẹ̀ ọ́, baba, pé kí o rán an sí ilé baba mi, 28  nítorí mo ní arákùnrin márùn-ún, kí ó bàa lè fún wọn ní ìjẹ́rìí kúnnákúnná, kí àwọn pẹ̀lú má bàa bọ́ sínú ibi ìjoró yìí.’ 29  Ṣùgbọ́n Ábúráhámù wí pé, ‘Wọ́n ní Mósè+ àti àwọn Wòlíì;+ kí wọ́n fetí sí àwọn wọ̀nyí.’+ 30  Nígbà náà ni ó wí pé, ‘Rárá o, Ábúráhámù baba, ṣùgbọ́n bí ẹnì kan láti inú òkú bá lọ sọ́dọ̀ wọn, wọn yóò ronú pìwà dà.’ 31  Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, ‘Bí wọn kò bá fetí sí Mósè+ àti àwọn Wòlíì, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò yí wọn lérò padà bí ẹnì kan bá dìde láti inú òkú.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé