Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Lúùkù 15:1-32

15  Wàyí o, gbogbo àwọn agbowó orí+ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀+ ń sún mọ́ ọn ṣáá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.  Nítorí náà, àti àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin ń kùn lábẹ́lẹ̀ ṣáá, pé: “[Ọkùnrin] yìí fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.”+  Nígbà náà ni ó sọ àpèjúwe yìí fún wọn, pé:  “Ọkùnrin wo nínú yín tí ó ní ọgọ́rùn-ún àgùntàn, nígbà tí ọ̀kan nínú wọn bá sọnù, tí kì yóò fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún sílẹ̀ sẹ́yìn ní aginjù, kí ó sì wá ọ̀kan tí ó sọnù lọ títí yóò fi rí i?+  Nígbà tí ó bá sì ti rí i, á gbé e lé èjìká rẹ̀, á sì yọ̀.+  Nígbà tí ó bá sì dé ilé, á pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, á sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, nítorí mo ti rí àgùntàn mi tí ó sọnù.’+  Mo sọ fún yín pé báyìí ni ìdùnnú púpọ̀ yóò ṣe wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà+ ju lórí mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún àwọn olódodo tí wọn kò nílò ìrònúpìwàdà.+  “Tàbí obìnrin wo tí ó ní ẹyọ owó dírákímà mẹ́wàá, bí ó bá sọ ẹyọ owó dírákímà kan nù, tí kì yóò tan fìtílà, kí ó sì gbá ilé rẹ̀, kí ó sì fara balẹ̀ wá a kiri títí yóò fi rí i?  Nígbà tí ó bá sì ti rí i, á pe àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò rẹ̀ jọ, á sọ pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, nítorí mo ti rí ẹyọ owó dírákímà tí mo sọnù.’ 10  Mo sọ fún yín, báyìí ni ìdùnnú ṣe máa ń sọ láàárín àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà.”+ 11  Lẹ́yìn náà, ó wí pé: “Ọkùnrin kan ní ọmọkùnrin méjì.+ 12  Èyí àbúrò nínú wọ́n sì wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Baba, fún mi ní ipa dúkìá tí ó jẹ́ ìpín tèmi.’+ Nígbà náà ni ó pín àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé+ rẹ̀ fún wọn. 13  Nígbà tí ó ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, ọmọkùnrin tí ó jẹ́ àbúrò kó gbogbo nǹkan jọpọ̀, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀ sí ilẹ̀ jíjìnnàréré, ibẹ̀ ni ó sì ti lo dúkìá rẹ̀ ní ìlò àpà nípa gbígbé ìgbésí ayé oníwà wọ̀bìà.+ 14  Nígbà tí ó ti ná ohun gbogbo tán, ìyàn wá mú gan-an jákèjádò ilẹ̀ yẹn, ó sì wá wà nínú àìní. 15  Ó tilẹ̀ lọ so ara rẹ̀ mọ́ ọ̀kan nínú àwọn aráàlú ilẹ̀ yẹn, ó sì rán an sínú àwọn pápá rẹ̀ láti máa ṣe olùṣọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀.+ 16  Òun a sì máa ní ìfẹ́-ọkàn láti jẹ àwọn pódi èso kárọ́ọ̀bù ní àjẹyó, èyí tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ, kò sì sí ẹni tí yóò fún un ní ohunkóhun.+ 17  “Nígbà tí orí rẹ̀ wálé, ó wí pé, ‘Mélòómélòó ni àwọn ọkùnrin tí baba mi háyà, tí wọ́n ní oúnjẹ púpọ̀ gidigidi, nígbà tí èmi ń ṣègbé lọ níhìn-ín lọ́wọ́ ìyàn! 18  Ṣe ni èmi yóò dìde, n ó sì rin ìrìn àjò+ lọ sọ́dọ̀ baba mi, n ó sì wí fún un pé: “Baba, èmi ti ṣẹ̀ sí ọ̀run àti sí ọ.+ 19  Èmi kò yẹ mọ́ ní ẹni tí a ń pè ní ọmọkùnrin rẹ. Fi mí ṣe bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin tí o háyà.”’ 20  Nítorí náà, ó dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ baba rẹ̀. Nígbà tí ó ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn, baba rẹ̀ tajú kán rí i, àánú sì ṣe é, ó sì sáré, ó sì rọ̀ mọ́ ọrùn rẹ̀, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. 21  Nígbà náà ni ọmọkùnrin náà wí fún un pé, ‘Baba, èmi ti ṣẹ̀ sí ọ̀run àti sí ọ.+ Èmi kò yẹ mọ́ ní ẹni tí a ń pè ní ọmọkùnrin rẹ. Fi mí ṣe bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin tí o háyà.’+ 22  Ṣùgbọ́n baba náà wí fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘Kíá! ẹ mú aṣọ jáde wá, èyí tí ó dára jù lọ, kí ẹ sì fi wọ̀ ọ́,+ kí ẹ sì fi òrùka+ sí ọwọ́ rẹ̀ àti sálúbàtà sí ẹsẹ̀ rẹ̀. 23  Kí ẹ sì mú àbọ́sanra+ ẹgbọrọ akọ màlúù wá, kí ẹ dúńbú rẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí a jẹun, kí a sì gbádùn ara wa, 24  nítorí pé ọmọkùnrin mi yìí kú, ó sì wá sí ìyè;+ ó sọnù, a sì rí i.’ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn ara wọn. 25  “Wàyí o, ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà+ wà nínú pápá; bí ó sì ti dé, tí ó sì sún mọ́ ilé, ó gbọ́ ohùn orin àwọn òṣèré àti ijó. 26  Nítorí náà, ó pe ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí ohun tí nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí. 27  Ó wí fún un pé, ‘Arákùnrin rẹ+ ti dé, baba rẹ+ sì dúńbú àbọ́sanra ẹgbọrọ akọ màlúù, nítorí tí ó rí i gbà padà ní ara líle.’ 28  Ṣùgbọ́n ó kún fún ìrunú, kò sì fẹ́ láti wọlé. Nígbà náà ni baba rẹ̀ jáde wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pàrọwà fún un.+ 29  Ní ìfèsìpadà, ó wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Ọ̀pọ̀ ọdún nìyí tí mo ti ń sìnrú fún ọ, n kò sì tíì ré àṣẹ rẹ kọjá lẹ́ẹ̀kan rí, síbẹ̀síbẹ̀, ìwọ kò tíì fi ọmọ ewúrẹ́ kan fún mi lẹ́ẹ̀kan rí kí èmi lè gbádùn ara mi pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi.+ 30  Ṣùgbọ́n gbàrà tí ọmọkùnrin rẹ yìí,+ tí ó jẹ àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé rẹ tán pẹ̀lú àwọn aṣẹ́wó+ dé, ìwọ dúńbú àbọ́sanra ẹgbọrọ akọ màlúù fún un.’+ 31  Nígbà náà ni ó wí fún un pé, ‘Ọmọ, nígbà gbogbo ni ìwọ wà pẹ̀lú mi, gbogbo ohun tí ó jẹ́ tèmi jẹ́ tìrẹ;+ 32  ṣùgbọ́n àwa sáà ní láti gbádùn ara wa, kí a sì yọ̀, nítorí pé arákùnrin rẹ yìí kú, ó sì wá sí ìyè, ó sọnù a sì rí i.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé