Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Lúùkù 14:1-35

14  Àti ní àkókò kan, nígbà tí ó lọ sínú ilé ọ̀kan nínú àwọn olùṣàkóso àwọn Farisí ní sábáàtì láti jẹ oúnjẹ,+ wọ́n ń ṣọ́ ọ lójú méjèèjì.+  Sì wò ó! ọkùnrin kan wà níwájú rẹ̀ tí ó ní àrùn ògùdùgbẹ̀.  Nítorí náà ní ìdáhùnpadà, Jésù bá àwọn ògbóǹkangí nínú Òfin àti àwọn Farisí sọ̀rọ̀, pé: “Ó ha bófin mu ní sábáàtì láti ṣe ìwòsàn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́?”+  Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́. Pẹ̀lú èyíinì, ó di ọkùnrin náà mú, ó mú un lára dá, ó sì rán an lọ.  Ó sì wí fún wọn pé: “Ta ni nínú yín, bí ọmọ tàbí akọ màlúù rẹ̀ bá já sínú kànga,+ tí kì yóò fà á jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní ọjọ́ sábáàtì?”+  Wọn kò sì lè dáhùn padà lórí nǹkan wọ̀nyí.+  Nígbà náà ni ó ń bá a lọ láti sọ àpèjúwe kan fún àwọn ènìyàn tí a ké sí, bí ó ti kíyè sí bí wọ́n ti ń yan àwọn ibi yíyọrí ọlá jù lọ fún ara wọn, ó wí fún wọn pé:+  “Nígbà tí ẹnì kan bá ké sí ọ síbi àsè ìgbéyàwó, má ṣe fi ara lélẹ̀ ní ibi yíyọrí ọlá jù lọ.+ Bóyá ó lè ti ké sí ẹnì kan tí ó ṣe sàràkí jù ọ́ lọ ní àkókò náà,  ẹni tí ó sì ké sí ìwọ àti òun yóò wá, yóò sì wí fún ọ pé, ‘Fún ọkùnrin yìí ní àyè.’ Nígbà náà ni ìwọ yóò sì fi ìtìjú gbéra lọ jókòó sí ibi rírẹlẹ̀ jù lọ.+ 10  Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá ké sí ọ, lọ kí o sì rọ̀gbọ̀kú ní ibi rírẹlẹ̀ jù lọ,+ pé nígbà tí ẹni tí ó ké sí ọ bá dé, yóò wí fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, gòkè lọ sí ibi tí ó ga sí i.’ Nígbà náà ni ìwọ yóò ní ọlá níwájú gbogbo àlejò ẹlẹ́gbẹ́ rẹ.+ 11  Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ àti ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.”+ 12  Lẹ́yìn náà, ó tẹ̀ síwájú láti sọ fún ọkùnrin tí ó ké sí i pẹ̀lú pé: “Nígbà tí ìwọ bá se àsè oúnjẹ ọ̀sán tàbí oúnjẹ alẹ́, má ṣe pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ tàbí àwọn aládùúgbò tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀. Bóyá ní àkókò kan, àwọn pẹ̀lú lè ké sí ìwọ náà, yóò sì di ìsanpadà fún ọ. 13  Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá se àsè, ké sí àwọn òtòṣì, amúkùn-ún, arọ, afọ́jú;+ 14  ìwọ yóò sì láyọ̀, nítorí tí wọn kò ní nǹkan kan láti fi san án padà fún ọ. Nítorí a ó san án padà fún ọ ní àjíǹde+ àwọn olódodo.” 15  Bí ó ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnì kan nínú àwọn àlejò ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ wí fún un pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ó bá ń jẹ oúnjẹ ní ìjọba Ọlọ́run.”+ 16  Jésù wí fún un pé: “Ọkùnrin kan ń se àsè oúnjẹ alẹ́ tí ó tóbi lọ́lá, ó sì ké sí ọ̀pọ̀ ènìyàn.+ 17  Ó sì rán ẹrú rẹ̀ jáde ní wákàtí oúnjẹ alẹ́ láti sọ fún àwọn ẹni tí a ké sí pé, ‘Ẹ máa bọ̀,+ nítorí pé àwọn nǹkan ti wà ní sẹpẹ́ báyìí.’ 18  Ṣùgbọ́n gbogbo wọn káríkárí bẹ̀rẹ̀ sí tọrọ gáfárà.+ Èkíní wí fún un pé, ‘Mo ra pápá kan, mo sì ní láti jáde lọ wò ó; mo bẹ̀ ọ́, Yọ̀ǹda mi.’+ 19  Òmíràn sì wí pé, ‘Mo ra àjàgà márùn-ún màlúù, mo sì ń lọ láti yẹ̀ wọ́n wò; mo bẹ̀ ọ́, Yọ̀ǹda mi.’+ 20  Síbẹ̀, òmíràn wí pé, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́+ aya ni àti pé fún ìdí yìí, n kò lè wá.’ 21  Nítorí náà, ẹrú náà wá, ó sì ròyìn nǹkan wọ̀nyí fún ọ̀gá rẹ̀. Nígbà náà ni baálé ilé náà kún fún ìrunú, ó sì wí fún ẹrú rẹ̀ pé, ‘Jáde lọ kíákíá sí àwọn ọ̀nà fífẹ̀ àti àwọn ọ̀nà tóóró ìlú ńlá náà, kí ó sì mú àwọn òtòṣì àti amúkùn-ún àti afọ́jú àti arọ+ wọlé wá síhìn-ín.’ 22  Nígbà tí ó ṣe, ẹrú náà wí pé, ‘Ọ̀gá, ohun tí o pa láṣẹ ti di ṣíṣe, síbẹ̀síbẹ̀, àyè ṣì wà.’ 23  Ọ̀gá náà sì wí fún ẹrú náà pé, ‘Jáde lọ sí àwọn ojú ọ̀nà+ àti àwọn ibi tí a sọgbà yí ká, kí o sì ṣe é ní ọ̀ranyàn fún wọn láti wọlé wá, kí ilé mi lè kún.+ 24  Nítorí mo wí fún yín pé, Dájúdájú, kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tí a ké sí tẹ́lẹ̀ tí yóò tọ́ oúnjẹ alẹ́ mi wò.’”+ 25  Wàyí o, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ń bá a rin ìrìn àjò, ó sì yí padà, ó sì wí fún wọn pé: 26  “Bí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ mi, tí kò sì kórìíra baba àti ìyá àti aya àti àwọn ọmọ àti àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, àti ọkàn tirẹ̀ pàápàá,+ kò lè jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn mi.+ 27  Ẹnì yòówù tí kò bá sì máa gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn kò lè jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn mi.+ 28  Fún àpẹẹrẹ, ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà,+ láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀? 29  Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó má lè parí rẹ̀, gbogbo òǹwòran sì lè bẹ̀rẹ̀ sí yọ ṣùtì sí i, 30  pé, ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́lé ṣùgbọ́n kò lè parí rẹ̀.’ 31  Tàbí ọba wo, tí ń lọ láti ko ọba mìíràn lójú ogun, tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gba ìmọ̀ràn bóyá òun pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọ̀wọ́ ọmọ ogun lè kojú ẹni tí ń bọ̀ wá gbéjà kò ó pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún?+ 32  Ní ti tòótọ́, bí kò bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà náà, nígbà tí ẹni yẹn ṣì wà ní ọ̀nà jíjìnréré, yóò rán ẹgbẹ́ àwọn ikọ̀ jáde, kí ó sì tẹ́wọ́ ẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà.+ 33  Nípa báyìí, ìwọ lè mọ̀ dájú pé, kò sí ẹnì kankan nínú yín tí kò sọ pé ó dìgbòóṣe fún gbogbo àwọn nǹkan ìní+ rẹ̀ tí ó lè jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn mi. 34  “Láìsí àní-àní, iyọ̀ dára púpọ̀. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ pàápàá bá pàdánù okun rẹ̀, kí ni a ó fi mú un dùn?+ 35  Kò yẹ yálà fún erùpẹ̀ tàbí fún ajílẹ̀. Àwọn ènìyàn a dà á nù sí òde. Kí ẹni tí ó ní etí láti fetí sílẹ̀, fetí sílẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé