Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Lúùkù 13:1-35

13  Ní àsìkò yẹn gan-an, àwọn kan wà níbẹ̀ tí wọ́n ròyìn fún un nípa àwọn ará Gálílì+ tí Pílátù po ẹ̀jẹ̀ wọn mọ́ àwọn ẹbọ wọn.  Nítorí náà, ní ìfèsìpadà, ó wí fún wọn pé: “Ẹ ha lérò pé àwọn ará Gálílì wọ̀nyí ni a fi hàn ní ẹlẹ́ṣẹ̀+ tí ó burú ju gbogbo àwọn ara Gálílì mìíràn nítorí tí wọ́n jìyà nǹkan wọ̀nyí?  Rárá o, ni mo sọ fún yín; ṣùgbọ́n, láìjẹ́ pé ẹ ronú pìwà dà, gbogbo yín ni a ó pa run bákan náà.+  Tàbí àwọn méjìdínlógún wọnnì tí ilé gogoro tí ń bẹ ní Sílóámù wó lé lórí, tí ó tipa bẹ́ẹ̀ pa wọ́n, ṣé ẹ lérò pé a fi wọ́n hàn ní ajigbèsè ju gbogbo ènìyàn mìíràn tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù lọ ni?  Rárá o, ni mo sọ fún yín; ṣùgbọ́n, láìjẹ́ pé ẹ ronú pìwà dà, gbogbo yín ni a ó pa run lọ́nà kan náà.”+  Ó wá ń bá a lọ láti sọ àpèjúwe yìí pé: “Ọkùnrin kan ní igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí a gbìn sínú ọgbà àjàrà rẹ̀,+ ó sì wá ń wá èso lórí rẹ̀,+ ṣùgbọ́n kò rí ìkankan.+  Nígbà náà ni ó wí fún olùrẹ́wọ́ àjàrà pé, ‘Ọdún mẹ́ta+ nìyí tí mo ti wá ń wá èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, ṣùgbọ́n n kò rí ìkankan. Ké e lulẹ̀!+ Èé ṣe ní ti gidi tí yóò fi sọ ilẹ̀ náà di aláìwúlò?’  Ní ìfèsìpadà, ó wí fún un pé, ‘Ọ̀gá, jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́+ ní ọdún yìí pẹ̀lú, títí èmi yóò fi walẹ̀ yí i ká, kí n sì fi ajílẹ̀ sí i;  nígbà náà bí ó bá sì mú èso jáde ní ẹ̀yìn ọ̀la, dáadáa náà ni; ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣe ni ìwọ yóò ké e lulẹ̀.’”+ 10  Wàyí o, ó ń kọ́ni nínú ọ̀kan lára àwọn sínágọ́gù ní sábáàtì. 11  Sì wò ó! obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mí+ àìlera fún ọdún méjìdínlógún, ó sì ti tẹ̀ kòlòbà, kò sì lè gbé ara rẹ̀ nà ró rárá. 12  Nígbà tí ó rí i, Jésù bá a sọ̀rọ̀, ó sì wí fún un pé: “Obìnrin, a tú ọ sílẹ̀+ kúrò nínú àìlera rẹ.” 13  Ó sì gbé àwọn ọwọ́ rẹ̀ lé e; ó sì nà ró ṣánṣán+ ní ìṣẹ́jú akàn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí yin Ọlọ́run lógo. 14  Ṣùgbọ́n ní ìdáhùnpadà, alága sínágọ́gù, tí ìkannú rẹ̀ ru nítorí pé Jésù ṣe ìwòsàn náà ní sábáàtì, bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ogunlọ́gọ̀ náà pé: “Ọjọ́ mẹ́fà ni ó wà nínú èyí tí iṣẹ́ yẹ ní ṣíṣe;+ nítorí náà, nínú wọn ni kí ẹ wá, kí ẹ sì gba ìwòsàn, kì í sì í ṣe ní ọjọ́ sábáàtì.”+ 15  Bí ó ti wù kí ó rí, Olúwa dá a lóhùn, ó sì wí pé: “Ẹ̀yin alágàbàgebè,+ ní sábáàtì olúkúlùkù yín kò ha ń tú akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kúrò ní ibùso, kí ó sì mú un lọ láti fún un ní ohun mímu?+ 16  Ṣé kò wá yẹ fún obìnrin yìí tí í ṣe ọmọbìnrin Ábúráhámù,+ ẹni ti Sátánì sì dè, wò ó! fún ọdún méjìdínlógún, pé kí a tú u kúrò nínú ìdè yìí ní ọjọ́ sábáàtì?” 17  Tóò, nígbà tí ó sọ nǹkan wọ̀nyí, ojú bẹ̀rẹ̀ sí ti+ gbogbo àwọn alátakò rẹ̀; ṣùgbọ́n gbogbo ogunlọ́gọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ látàrí gbogbo ohun ológo tí ó ṣe.+ 18  Nítorí náà, ó ń bá a lọ ní sísọ pé: “Kí ni ohun tí ìjọba Ọlọ́run dà bí, kí ni èmi yóò sì fi í wé?+ 19  Ó dà bí hóró músítádì tí ọkùnrin kan mú, tí ó sì fi sínú ọgbà rẹ̀, ó sì dàgbà, ó sì di igi, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run+ sì fi àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣe ibùwọ̀.”+ 20  Ó sì tún sọ pé: “Kí ni èmi yóò fi ìjọba Ọlọ́run wé? 21  Ó dà bí ìwúkàrà, tí obìnrin kan mú, tí ó sì fi pa mọ́ sínú àwọn òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ńlá mẹ́ta títí gbogbo ìṣùpọ̀ náà fi di wíwú.”+ 22  Ó sì rin ìrìn àjò lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń kọ́ni, ó sì ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù.+ 23  Wàyí o, ọkùnrin kan sọ fún un pé: “Olúwa, díẹ̀ ha ni àwọn tí a ó gbà là?”+ Ó wí fún wọn pé: 24  “Ẹ tiraka+ tokuntokun láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró+ wọlé, nítorí, mo sọ fún yín, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò wá ọ̀nà láti wọlé ṣùgbọ́n wọn kì yóò lè ṣe bẹ́ẹ̀,+ 25  níwọ̀n ìgbà tí baálé ilé bá ti dìde, tí ó sì ti ti ilẹ̀kùn pa, tí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí dúró ní òde, tí ẹ sì ń kan ilẹ̀kùn, tí ẹ sì ń wí pé, ‘Ọ̀gá, ṣílẹ̀kùn fún wa.’+ Ṣùgbọ́n ní ìdáhùn, yóò wí fún yín pé, ‘Èmi kò mọ ibi tí ẹ ti wá.’+ 26  Ẹ óò wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, ‘Àwa jẹ, a sì mu níwájú rẹ, ìwọ sì kọ́ni ní àwọn ọ̀nà fífẹ̀ wa.’+ 27  Ṣùgbọ́n yóò sọ̀rọ̀, yóò sì wí fún yín pé, ‘Èmi kò mọ ibi tí ẹ ti wá. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ àìṣòdodo!’+ 28  Ibẹ̀ ni ẹkún yín àti ìpayínkeke+ yín yóò wà, nígbà tí ẹ bá rí Ábúráhámù àti Ísákì àti Jékọ́bù àti gbogbo wòlíì nínú ìjọba Ọlọ́run,+ ṣùgbọ́n tí a sọ ẹ̀yin fúnra yín sí òde. 29  Síwájú sí i, àwọn ènìyàn yóò wá láti àwọn apá ìlà-oòrùn àti ti ìwọ̀-oòrùn, àti láti àríwá àti gúúsù,+ wọn yóò sì rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì ní ìjọba Ọlọ́run.+ 30  Sì wò ó! àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹni ìkẹyìn ń bẹ tí yóò di ẹni àkọ́kọ́, àwọn tí wọ́n sì jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ ń bẹ tí yóò di ẹni ìkẹyìn.”+ 31  Ní wákàtí yẹn gan-an, àwọn Farisí kan wá, wọn wí fún un pé: “Jáde, kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n kúrò ní ìhín, nítorí tí Hẹ́rọ́dù fẹ́ pa ọ́.” 32  Ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ lọ sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀+ yẹn pé, ‘Wò ó! Èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, mo sì ń ṣàṣeparí ìmúláradá lónìí àti lọ́la, ní ọjọ́ kẹta èmi yóò sì ṣe tán.’+ 33  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi gbọ́dọ̀ mú ọ̀nà mi pọ̀n lónìí àti lọ́la àti ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, nítorí pé kò ṣeé gbà wọlé pé kí a pa wòlíì kan run lẹ́yìn òde Jerúsálẹ́mù.+ 34  Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, olùpa+ àwọn wòlíì àti olùsọ àwọn tí a rán jáde sí i lókùúta+—iye ìgbà tí mo fẹ́ láti kó àwọn ọmọ rẹ jọpọ̀ ti pọ̀ tó ní irú ọ̀nà tí àgbébọ̀ adìyẹ gbà ń kó ọ̀wọ́ àwọn òròmọdìyẹ rẹ̀ sábẹ́ ìyẹ́ apá+ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò fẹ́!+ 35  Wò ó! A pa ilé yín+ tì fún yín. Mo sọ fún yín, Ẹ kì yóò rí mi lọ́nàkọnà títí ẹ ó fi wí pé, ‘Alábùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Jèhófà!’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé