Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Lúùkù 12:1-59

12  Láàárín àkókò yìí, nígbà tí ogunlọ́gọ̀ ti kórajọpọ̀ ní ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ nípa sísọ lákọ̀ọ́kọ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà+ àwọn Farisí, èyí tí í ṣe àgàbàgebè.+  Ṣùgbọ́n kò sí ohun kan tí a rọra fi pa mọ́ tí a kì yóò ṣí payá, àti àṣírí tí kì yóò di mímọ̀.+  Nítorí náà, àwọn ohun tí ẹ bá sọ nínú òkùnkùn ni a óò gbọ́ nínú ìmọ́lẹ̀, àti ohun tí ẹ bá sọ wúyẹ́wúyẹ́ nínú yàrá àdáni ni a ó wàásù rẹ̀ láti orí ilé.+  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, mo wí fún yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi,+ Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ń pa ara àti lẹ́yìn èyí tí wọn kò lè ṣe nǹkan kan jù bẹ́ẹ̀ lọ.+  Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ́ka ẹni tí ẹ ní láti bẹ̀rù fún yín: Ẹ bẹ̀rù ẹni+ tí ó jẹ́ pé lẹ́yìn pípani, ó ní ọlá àṣẹ láti sọni sínú Gẹ̀hẹ́nà.+ Bẹ́ẹ̀ ni, mo sọ fún yín, Ẹni yìí ni kí ẹ bẹ̀rù.+  Ológoṣẹ́ márùn-ún ni a ń tà ní ẹyọ owó méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí a gbàgbé níwájú Ọlọ́run.+  Ṣùgbọ́n irun+ orí yín pàápàá ni a ti ka iye gbogbo wọn. Ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́.+  “Mo wí fún yín, nígbà náà, pé, Gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́+ níní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi níwájú àwọn ènìyàn, Ọmọ ènìyàn pẹ̀lú yóò jẹ́wọ́ níní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run.+  Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ níní ìsopọ̀+ pẹ̀lú mi níwájú àwọn ènìyàn ni a óò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run.+ 10  Olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì sọ ọ̀rọ̀ kan lòdì sí Ọmọ ènìyàn, a óò dárí rẹ̀ jì í; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dárí rẹ̀ jì í.+ 11  Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá mú yín wá síwájú àwọn àpéjọ gbogbo ènìyàn àti àwọn ìjòyè ìjọba àti àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣàníyàn nípa báwo tàbí kí ni ẹ ó sọ ní ìgbèjà tàbí ohun tí ẹ óò wí;+ 12  nítorí ẹ̀mí mímọ́+ yóò kọ́ yín ní wákàtí yẹn gan-an àwọn ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ.”+ 13  Nígbà náà ni ẹnì kan nínú ogunlọ́gọ̀ náà wí fún un pé: “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín ogún pẹ̀lú mi.” 14  Ó wí fún un pé: “Ọkùnrin yìí, ta ní yàn mí ṣe onídàájọ́+ tàbí olùpín nǹkan fún yín?” 15  Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò,+ nítorí pé nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.”+ 16  Pẹ̀lú èyíinì, ó sọ àpèjúwe kan fún wọn, pé: “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan mú èso jáde dáadáa. 17  Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí rò nínú ara rẹ̀, pé, ‘Kí ni èmi yóò ṣe, nísinsìnyí tí èmi kò ní ibì kankan láti kó àwọn irè oko mi jọ sí?’ 18  Nítorí náà, ó wí pé, ‘Èyí ni èmi yóò ṣe:+ Ṣe ni èmi yóò ya àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ mi lulẹ̀, èmi yóò sì kọ́ àwọn tí ó tóbi, ibẹ̀ ni èmi yóò sì kó gbogbo ọkà mi jọ sí àti gbogbo àwọn ohun rere mi;+ 19  ṣe ni èmi yóò sọ+ fún ọkàn mi pé: “Ọkàn, ìwọ ní ọ̀pọ̀ ohun rere tí a tò jọ pa mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún; fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn.”’+ 20  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Aláìlọ́gbọ́n-nínú, òru òní ni wọn yóò fi dandan béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ.+ Ta ni yóò wá ni àwọn ohun tí ìwọ tò jọ pa mọ́?’+ 21  Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń rí fún ẹni tí ó bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”+ 22  Ó wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ní tìtorí èyí, mo wí fún yín, Ẹ jáwọ́ nínú ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín, ní ti ohun tí ẹ ó jẹ tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ ó wọ̀.+ 23  Nítorí tí ọkàn níye lórí ju oúnjẹ lọ àti ara ju aṣọ lọ. 24  Ẹ ṣàkíyèsí dáadáa pé àwọn ẹyẹ ìwò+ kì í fún irúgbìn tàbí kárúgbìn, wọn kò sì ní yálà abà tàbí ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́, síbẹ̀ Ọlọ́run ń bọ́ wọn. Mélòómélòó ni ẹ fi níye lórí ju àwọn ẹyẹ?+ 25  Ta ni nínú yín nípa ṣíṣàníyàn tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?+ 26  Nítorí náà, bí ẹ kò bá lè ṣe ohun tí ó kéré jù lọ, èé ṣe tí ẹ fi ń ṣàníyàn+ nípa àwọn ohun tí ó ṣẹ́ kù? 27  Ẹ ṣàkíyèsí dáadáa bí àwọn òdòdó lílì ṣe ń dàgbà;+ wọn kì í ṣe làálàá tàbí rànwú; ṣùgbọ́n mo sọ fún yín, A kò ṣe Sólómọ́nì pàápàá ní ọ̀ṣọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí.+ 28  Wàyí o, bí Ọlọ́run bá ṣe báyìí wọ ewéko tí ń bẹ nínú pápá ní aṣọ, èyí tí ó wà lónìí, tí a sì jù sínú ààrò lọ́la, mélòómélòó ni òun yóò kúkú wọ̀ yín ní aṣọ, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré!+ 29  Nítorí náà, ẹ jáwọ́ nínú wíwá ohun tí ẹ lè jẹ àti ohun tí ẹ lè mu kiri, ẹ sì jáwọ́ nínú àníyàn àìdánilójú;+ 30  nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni ohun tí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ń fi ìháragàgà lépa, ṣùgbọ́n Baba yín mọ̀ pé ẹ nílò nǹkan wọ̀nyí.+ 31  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ máa wá ìjọba rẹ̀ nígbà gbogbo, a ó sì fi nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín.+ 32  “Má bẹ̀rù,+ agbo kékeré,+ nítorí pé Baba yín ti tẹ́wọ́ gba fífi ìjọba náà fún yín.+ 33  Ẹ ta+ àwọn ohun tí ó jẹ́ tiyín, kí ẹ sì fúnni ní àwọn ẹ̀bùn àánú.+ Ẹ ṣe àwọn àpò tí kì í gbó fún ara yín, ìṣúra tí kì í kùnà láé ní ọ̀run,+ níbi tí olè kì í sún mọ́ tàbí kí òólá jẹ run. 34  Nítorí ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà yín yóò wà pẹ̀lú.+ 35  “Ẹ jẹ́ kí abẹ́nú+ yín wà ní dídì ní àmùrè, kí àwọn fìtílà+ yín sì máa jó, 36  kí ẹ̀yin fúnra yín sì dà bí àwọn ọkùnrin tí ń dúró de ọ̀gá+ wọn nígbà tí ó padà dé láti ibi ìgbéyàwó,+ kí ó bàa lè jẹ́ pé ní dídé rẹ̀ àti kíkànkùn,+ wọn yóò lè ṣílẹ̀kùn ní kíá. 37  Aláyọ̀ ni ẹrú wọnnì tí ọ̀gá náà bá tí ń ṣọ́nà+ nígbà tí ó dé! Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Yóò di ara rẹ̀ lámùrè,+ yóò sì mú kí wọ́n rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì, yóò sì bọ́ sí tòsí, yóò sì ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.+ 38  Bí ó bá sì dé ní ìṣọ́ kejì, kódà bí ó jẹ́ ní ẹ̀kẹta, tí ó sì bá wọn bẹ́ẹ̀, aláyọ̀ ni wọ́n!+ 39  Ṣùgbọ́n mọ èyí, pé bí baálé ilé bá mọ wákàtí tí olè yóò wá ni, ì bá ti máa ṣọ́nà, kì bá sì ti jẹ́ kí a fọ́ ilé òun.+ 40  Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé ó lè jẹ́ ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.”+ 41  Nígbà náà ni Pétérù wí pé: “Olúwa, ṣé àwa ni ìwọ ń sọ àpèjúwe yìí fún àbí fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú?” 42  Olúwa sì wí pé: “Ní ti tòótọ́, ta ni olùṣòtítọ́ ìríjú náà,+ ẹni tí í ṣe olóye,+ tí ọ̀gá rẹ̀ yóò yàn sípò lórí ẹgbẹ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ láti máa fún wọn ní ìwọ̀n ìpèsè oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu?+ 43  Aláyọ̀ ni ẹrú yẹn, bí ọ̀gá rẹ̀ nígbà tí ó dé bá rí i tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀!+ 44  Mo sọ fún yín lótìítọ́, Òun yóò yàn án sípò lórí gbogbo nǹkan ìní rẹ̀.+ 45  Ṣùgbọ́n bí ẹrú yẹn bá lọ sọ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pẹ́nrẹ́n pé, ‘Ọ̀gá mi ń pẹ́ ní dídé,’+ tí ó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, tí ó ń jẹ, tí ó ń mu, tí ó sì ń mutí para,+ 46  ọ̀gá ẹrú náà yóò dé ní ọjọ́ tí kò fojú sọ́nà fún un àti ní wákàtí tí kò mọ̀,+ yóò sì fi ìyà mímúná jù lọ jẹ ẹ́, yóò sì yan ipa kan lé e lọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn aláìṣòótọ́.+ 47  Nígbà náà, ẹrú yẹn tí ó lóye ohun tí ọ̀gá rẹ̀ fẹ́ ṣùgbọ́n tí kò wà ní ìmúratán tàbí hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó fẹ́ ni a ó nà ní ẹgba púpọ̀.+ 48  Ṣùgbọ́n èyí tí kò lóye,+ tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe àwọn ohun tí ó yẹ fún ẹgba ni a ó nà ní ìwọ̀nba díẹ̀.+ Ní tòótọ́, olúkúlùkù ẹni tí a bá fi púpọ̀ fún, púpọ̀ ni a ó fi dandan béèrè+ lọ́wọ́ rẹ̀; àti ẹni tí àwọn ènìyàn fi sí àbójútó púpọ̀, wọn yóò fi dandan béèrè fún púpọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ́wọ́ rẹ̀.+ 49  “Èmi wá láti dá iná+ kan sórí ilẹ̀ ayé, kí ni èmi ì bá sí dàníyàn fún ju pé kí a ti tàn án nísinsìnyí? 50  Ní tòótọ́, mo ní ìbatisí kan tí a ó fi batisí mi, ẹ sì wo bí wàhálà-ọkàn ti bá mi tó títí yóò fi parí!+ 51  Ṣé ẹ lérò pé mo wá láti fúnni ní àlàáfíà lórí ilẹ̀ ayé ni? Rárá o, ni mo sọ fún yín, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ ìpínyà.+ 52  Nítorí láti ìsinsìnyí lọ, ẹni márùn-ún yóò wà nínú ilé kan tí ó pínyà, mẹ́ta sí méjì àti méjì sí mẹ́ta.+ 53  Wọn yóò pínyà, baba sí ọmọkùnrin àti ọmọkùnrin sí baba, ìyá sí ọmọbìnrin àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, ìyá ọkọ sí aya ọmọ àti aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀.”+ 54  Nígbà náà ni ó ń bá a lọ láti sọ fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà pẹ̀lú pé: “Nígbà tí ẹ bá rí àwọsánmà tí ń ṣú ní apá ìwọ̀-oòrùn, ní kíá ẹ̀yin a sọ pé, ‘Ìjì ń bọ̀,’ yóò sì rí bẹ́ẹ̀.+ 55  Nígbà tí ẹ bá sì rí pé ẹ̀fúùfù gúúsù ń fẹ́, ẹ̀yin a sọ pé, ‘Ìgbì ooru yóò wà,’ yóò sì ṣẹlẹ̀. 56  Ẹ̀yin alágàbàgebè, ẹ mọ bí a ti í ṣàyẹ̀wò ìrísí òde ilẹ̀ ayé àti sánmà, ṣùgbọ́n báwo ni ó ti jẹ́, tí ẹ kò mọ bí a ṣe lè ṣàyẹ̀wò àkókò yìí gan-an?+ 57  Èé ṣe tí ẹ̀yin pẹ̀lú kò fi fúnra yín ṣèdájọ́ ohun tí í ṣe òdodo?+ 58  Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ìwọ pẹ̀lú elénìní rẹ lábẹ́ òfin bá ń lọ sọ́dọ̀ olùṣàkóso kan, mú iṣẹ́ ṣe, nígbà tí ẹ wà ní ọ̀nà, láti yọ ara rẹ kúrò nínú awuyewuye pẹ̀lú rẹ̀, kí ó má bàa fà ọ́ lọ síwájú onídàájọ́, onídàájọ́ a sì fà ọ́ lé onípò àṣẹ nínú kóòtù lọ́wọ́, onípò àṣẹ nínú kóòtù a sì sọ ọ́ sẹ́wọ̀n.+ 59  Mo sọ fún ọ, Dájúdájú, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀ títí ìwọ yóò fi san ẹyọ owó kékeré tí ó bá kù tí ìníyelórí rẹ̀ kéré jọjọ.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé