Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Lúùkù 11:1-54

11  Wàyí o, ní àkókò tí ó wà ní ibì kan tí ó ń gbàdúrà, nígbà tí ó ṣíwọ́, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé: “Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà,+ gẹ́gẹ́ bí Jòhánù pẹ̀lú ti kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.”+  Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé: “Nígbàkigbà tí ẹ bá ń gbàdúrà,+ ẹ wí pé, ‘Baba, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.+ Kí ìjọba rẹ dé.+  Fún wa ní oúnjẹ+ wa fún òòjọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí òòjọ́ ń béèrè.  Sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá,+ nítorí àwa fúnra wa pẹ̀lú a máa dárí ji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè;+ má sì mú wa wá sínú ìdẹwò.’”+  Síwájú sí i, ó wí fún wọn pé: “Ta ni nínú yín tí yóò ní ọ̀rẹ́ kan, tí yóò sì lọ bá a ní ọ̀gànjọ́ òru, tí yóò sì wí fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́, yá mi ní ìṣù búrẹ́dì mẹ́ta,  nítorí pé ọ̀rẹ́ mi kan ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sọ́dọ̀ mi láti ìrìn àjò, èmi kò sì ní nǹkan kan láti gbé ka iwájú rẹ̀’?  Tí ẹni yẹn láti inú ilé sì sọ ní ìfèsìpadà pé, ‘Yé dà mí láàmú.+ Ilẹ̀kùn ti wà ní títì pa, àwọn ọmọ mi kéékèèké sì wà pẹ̀lú mi lórí ibùsùn; èmi kò lè dìde kí n sì fún ọ ní ohunkóhun.’  Mo sọ fún yín, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì yóò dìde, kí ó sì fún un ní ohunkóhun nítorí pé ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, dájúdájú, nítorí ìtẹpẹlẹ rẹ̀ aláìṣojo,+ yóò dìde, yóò sì fún un ní àwọn ohun tí ó nílò.  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, mo wí fún yín, Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè,+ a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri,+ ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín. 10  Nítorí pé olúkúlùkù ẹni tí ń béèrè ń rí gbà,+ àti olúkúlùkù ẹni tí ń wá kiri ń rí, olúkúlùkù ẹni tí ó sì ń kànkùn ni a óò ṣí i fún. 11  Ní tòótọ́, baba wo ní ń bẹ láàárín yín tí ó jẹ́ pé, bí ọmọ+ rẹ̀ bá béèrè ẹja, bóyá tí yóò fi ejò lé e lọ́wọ́ dípò ẹja? 12  Tàbí bí ó bá tún béèrè ẹyin, tí yóò fi àkekèé lé e lọ́wọ́? 13  Nígbà náà, bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín,+ mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́+ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” 14  Lẹ́yìn èyí, ó ń lé ẹ̀mí èṣù kan tí ó yadi+ jáde. Lẹ́yìn tí ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin odi náà sọ̀rọ̀. Ẹnu sì ya ogunlọ́gọ̀ náà. 15  Ṣùgbọ́n àwọn kan nínú wọ́n wí pé: “Béélísébúbù olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù+ ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” 16  Bí ó ti wù kí ó rí, láti dẹ ẹ́ wò, àwọn mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí wá àmì+ kan láti ọ̀run ní ọwọ́ rẹ̀. 17  Ní mímọ èrò-ọkàn+ wọn, ó wí fún wọn pé: “Gbogbo ìjọba tí ó bá pínyà sí ara rẹ̀ a máa wá sí ìsọdahoro, ilé tí ó bá sì pínyà sí ara rẹ̀ a wó.+ 18  Nítorí náà, bí Sátánì pẹ̀lú bá pínyà sí ara rẹ̀, báwo ni ìjọba rẹ̀ yóò ṣe dúró?+ Nítorí tí ẹ sọ pé Béélísébúbù ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. 19  Bí ó bá jẹ́ Béélísébúbù ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ta ni àwọn ọmọ yín+ fi ń lé wọn jáde? Nítorí èyí ni wọn yóò fi jẹ́ onídàájọ́ yín. 20  Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ìka Ọlọ́run+ ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín lójijì+ ní ti tòótọ́. 21  Nígbà tí ọkùnrin alágbára kan,+ tí ó dìhámọ́ra dáadáa, bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, àwọn ohun ìní rẹ̀ a máa bá a lọ ní àlàáfíà. 22  Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹnì kan tí ó lágbára jù+ ú bá wá kọlù ú, tí ó sì ṣẹ́gun rẹ̀,+ a kó ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun ìjà ogun rẹ̀ lọ èyí tí ó gbẹ́kẹ̀ lé, a sì pín àwọn ohun tí ó fi ṣe ìjẹ lọ́dọ̀ rẹ̀. 23  Ẹni tí kò bá sí ní ìhà ọ̀dọ̀ mi lòdì sí mi, ẹni tí kò bá sì kó jọ pẹ̀lú mi ń tú ká.+ 24  “Nígbà tí ẹ̀mí àìmọ́ kan bá jáde kúrò lára ẹnì kan, a kọjá gba àwọn ibi gbígbẹ hán-ún hán-ún ní wíwá ibi ìsinmi káàkiri, lẹ́yìn tí kò bá sì rí ìkankan, a sọ pé, ‘Èmi yóò padà sí ilé mi láti inú èyí tí mo ti ṣí kúrò.’+ 25  Nígbà tí ó sì dé, ó rí i tí a ti gbá a mọ́, tí a sì ti ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́. 26  Nígbà náà ni ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì mú ẹ̀mí méje+ mìíràn dání tí wọ́n burú ju òun fúnra rẹ̀, lẹ́yìn wíwọlé, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀; ipò ẹni yẹn ní ìgbẹ̀yìn sì wá burú jù ti ìṣáájú.”+ 27  Wàyí o, bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, obìnrin kan láti inú ogunlọ́gọ̀ náà gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì wí fún un pé: “Aláyọ̀ ni ilé ọlẹ̀+ tí ó gbé ọ àti ọmú tí ìwọ mu!” 28  Ṣùgbọ́n ó wí pé: “Ó tì o, kàkà bẹ́ẹ̀, Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”+ 29  Nígbà tí àwọn ogunlọ́gọ̀ ń wọ́ jọpọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Ìran burúkú ni ìran yìí; ó ń wá àmì kan.+ Ṣùgbọ́n a kì yóò fún un ní àmì kankan àyàfi àmì Jónà.+ 30  Nítorí pé gan-an gẹ́gẹ́ bí Jónà+ ṣe di àmì kan fún àwọn ará Nínéfè, lọ́nà kan náà ni Ọmọ ènìyàn pẹ̀lú yóò jẹ́ bẹ́ẹ̀ fún ìran yìí. 31  A óò gbé ọbabìnrin+ gúúsù dìde ní ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìran yìí, yóò sì dá wọn lẹ́bi; nítorí pé ó wá láti òpin ilẹ̀ ayé láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómọ́nì, ṣùgbọ́n, wò ó! ohun kan tí ó ju+ Sólómọ́nì lọ wà níhìn-ín. 32  Àwọn ènìyàn Nínéfè yóò dìde ní ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, wọn yóò sì dá a lẹ́bi; nítorí pé wọ́n ronú pìwà dà lórí ohun tí Jónà wàásù;+ ṣùgbọ́n, wò ó! ohun tí ó ju+ Jónà lọ wà níhìn-ín. 33  Lẹ́yìn títan fìtílà, ẹnì kan kì í gbé e sí ihò abẹ́lẹ̀ tàbí abẹ́ apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà,+ kí àwọn tí ń wọlé wá lè rí ìmọ́lẹ̀. 34  Fìtílà ara ni ojú rẹ. Nígbà tí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan, gbogbo ara rẹ pẹ̀lú a mọ́lẹ̀ yòò;+ ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá burú, ara rẹ pẹ̀lú a ṣókùnkùn. 35  Wà lójúfò, nígbà náà. Bóyá ìmọ́lẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ jẹ́ òkùnkùn.+ 36  Nítorí náà, bí gbogbo ara rẹ bá mọ́lẹ̀ yòò, tí kò sí apá kan rárá tí ó ṣókùnkùn, gbogbo rẹ̀ yóò mọ́lẹ̀ yòò+ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí fìtílà kan bá fún ọ ní ìmọ́lẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìtànṣán rẹ̀.” 37  Nígbà tí ó ti sọ èyí, Farisí kan béèrè pé kí ó bá òun jẹun.+ Nítorí náà, ó wọlé lọ, ó sì rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì. 38  Bí ó ti wù kí ó rí, ó ya Farisí náà lẹ́nu ní rírí i pé kò kọ́kọ́ wẹwọ́+ ṣáájú oúnjẹ. 39  Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún un pé: “Wàyí o, ẹ̀yin Farisí, ẹ ń fọ òde ife àti àwopọ̀kọ́ mọ́, ṣùgbọ́n inú+ yín kún fún ìpiyẹ́ àti ìwà burúkú.+ 40  Ẹ̀yin aláìlọ́gbọ́n-nínú! Ẹni tí ó ṣe òde+ ni ó ṣe inú pẹ̀lú, àbí òun kọ́? 41  Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ fi àwọn ohun tí ń bẹ ní inú fúnni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn àánú,+ sì wò ó! gbogbo ohun mìíràn nípa yín mọ́. 42  Ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹ̀yin Farisí, nítorí pé ẹ ń fúnni ní ìdá mẹ́wàá+ efinrin àti ewéko rúè àti gbogbo ọ̀gbìn oko mìíràn, ṣùgbọ́n ẹ ń gbójú fo ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́ fún Ọlọ́run! Ẹ wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti ṣe nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ohun yòókù wọnnì ni kí ẹ má ṣe fò dá.+ 43  Ègbé ni fún ẹ̀yin Farisí, nítorí pé ẹ nífẹ̀ẹ́ ìjókòó iwájú nínú sínágọ́gù àti ìkíni ní àwọn ibi ọjà!+ 44  Ègbé ni fún yín, nítorí pé ẹ dà bí ibojì ìrántí wọnnì tí kò hàn gbangba, tí ó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń rìn lórí wọn láìmọ̀!”+ 45  Ní ìdáhùn, ẹnì kan nínú àwọn ògbóǹkangí+ nínú Òfin wí fún un pé: “Olùkọ́, ní sísọ nǹkan wọ̀nyí, ìwọ fi ìwọ̀sí lọ̀ wá pẹ̀lú.” 46  Nígbà náà ni ó wí pé: “Ègbé ni fún ẹ̀yin pẹ̀lú tí ẹ jẹ́ ògbóǹkangí nínú Òfin, nítorí pé ẹ di àwọn ẹrù tí ó ṣòro láti rù lé àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ẹ̀yin fúnra yín kò fi ọ̀kan nínú àwọn ìka yín kan àwọn ẹrù+ náà! 47  “Ègbé ni fún yín, nítorí pé ẹ kọ́ àwọn ibojì ìrántí àwọn wòlíì, ṣùgbọ́n àwọn baba ńlá yín ni ó pa wọ́n!+ 48  Dájúdájú, ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí àwọn ìṣe àwọn baba ńlá yín, síbẹ̀, ẹ fohùn ṣọ̀kan+ pẹ̀lú wọn, nítorí pé àwọn wọ̀nyí pa+ àwọn wòlíì ṣùgbọ́n ẹ ń kọ́ àwọn ibojì wọn. 49  Ní tìtorí èyí, ọgbọ́n+ Ọlọ́run sọ pẹ̀lú pé, ‘Èmi yóò rán àwọn wòlíì àti àwọn àpọ́sítélì jáde sí wọn, àwọn kan nínú wọn ni wọn yóò sì pa, tí wọn yóò sì ṣe inúnibíni sí, 50  kí a lè béèrè ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn wòlíì+ tí a ta sílẹ̀ láti ìgbà pípilẹ̀ ayé lọ́wọ́ ìran yìí,+ 51  láti ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì+ títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekaráyà,+ ẹni tí wọ́n pa láàárín pẹpẹ àti ilé.’+ Bẹ́ẹ̀ ni, mo sọ fún yín, a óò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ ìran yìí. 52  “Ègbé ni fún ẹ̀yin ògbóǹkangí nínú Òfin, nítorí tí ẹ mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀+ lọ; ẹ̀yin fúnra yín kò wọlé, àwọn tí wọ́n sì ń wọlé ni ẹ dí lọ́wọ́!”+ 53  Nítorí náà, nígbà tí ó jáde lọ láti ibẹ̀, àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí ṣù mọ́ ọn lọ́nà lílékenkà, wọ́n sì ń da ìbéèrè bò ó nípa àwọn nǹkan mìíràn, 54  ní lílúgọ dè é,+ láti rí ohun kan gbá mú+ láti ẹnu rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé