Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Lúùkù 1:1-80

1  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ti dáwọ́ lé ṣíṣe àkójọ àlàyé àwọn ìṣẹlẹ̀+ tí a gbà gbọ́ ní kíkún láàárín wa,  gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ọ̀ràn ṣojú wọn+ àti ẹmẹ̀wà ìhìn iṣẹ́+ náà láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀+ ti fi ìwọ̀nyí lé wa lọ́wọ́,  èmi pẹ̀lú pinnu, nítorí tí mo ti tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye, láti kọ̀wé wọn sí ọ ní ìṣètò tí ó bọ́gbọ́n mu,+ Tìófílọ́sì+ ẹni títayọlọ́lá jù lọ,+  kí ìwọ lè mọ̀ ní kíkún, ìdánilójú àwọn ohun tí a ti fi ọ̀rọ̀ ẹnu kọ́ ọ.+  Ní àwọn ọjọ́ Hẹ́rọ́dù,+ ọba Jùdíà, àlùfáà kan báyìí wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sekaráyà nínú ìpín Ábíjà,+ ó sì ní aya kan láti inú àwọn ọmọbìnrin Áárónì,+ orúkọ rẹ̀ sì ni Èlísábẹ́tì.  Àwọn méjèèjì jẹ́ olódodo+ níwájú Ọlọ́run nítorí rírìn láìlẹ́bi+ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo àṣẹ+ àti àwọn ohun tí òfin+ Jèhófà béèrè.+  Ṣùgbọ́n wọn kò ní ọmọ, nítorí pé Èlísábẹ́tì yàgàn,+ àwọn méjèèjì sì ti lọ́jọ́ lórí gan-an.  Wàyí o, bí ó ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà nínú iṣẹ́ àyànfúnni ìpín rẹ̀+ níwájú Ọlọ́run,  ní ìbámu pẹ̀lú àṣà aláàtò ìsìn ti ipò iṣẹ́ àlùfáà, ó yí kàn án láti sun tùràrí+ nígbà tí ó wọ inú ibùjọsìn Jèhófà;+ 10  gbogbo ògìdìgbó àwọn ènìyàn sì ń gbàdúrà ní òde ní wákàtí sísun tùràrí.+ 11  Áńgẹ́lì Jèhófà fara hàn án, ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún pẹpẹ tùràrí.+ 12  Ṣùgbọ́n Sekaráyà dààmú nítorí ìran náà, ẹ̀rù sì bà á.+ 13  Bí ó ti wù kí ó rí, áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, Sekaráyà, nítorí pé a ti gbọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ pẹ̀lú ojú rere,+ Èlísábẹ́tì aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan fún ọ, Jòhánù ni ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀.+ 14  Ìwọ yóò sì ní ìdùnnú àti ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ńláǹlà, ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò sì yọ̀+ nítorí ìbí rẹ̀; 15  nítorí tí yóò jẹ́ ẹni ńlá níwájú Jèhófà.+ Ṣùgbọ́n kò gbọ́dọ̀ mu wáìnì àti ohun mímu líle rárá,+ yóò sì kún fún ẹ̀mí mímọ́ àní láti inú ilé ọlẹ̀ ìyá rẹ̀ wá;+ 16  ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni òun yóò sì yí padà sọ́dọ̀ Jèhófà+ Ọlọ́run wọn. 17  Pẹ̀lúpẹ̀lù, òun yóò lọ ṣáájú rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí àti agbára Èlíjà,+ láti yí ọkàn-àyà+ àwọn baba padà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ àti àwọn aláìgbọràn sí ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ ti àwọn olódodo, láti pèsè sílẹ̀ fún Jèhófà+ àwọn ènìyàn kan tí a ti múra sílẹ̀.”+ 18  Sekaráyà sì sọ fún áńgẹ́lì náà pé: “Báwo ni èyí yóò ṣe dá mi lójú? Nítorí pé àgbàlagbà ni mí,+ aya mi sì lọ́jọ́ lórí gan-an.” 19  Ní ìfèsìpadà, áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Èmi ni Gébúrẹ́lì,+ ẹni tí ń dúró nítòsí níwájú Ọlọ́run, a sì rán mi jáde láti bá ọ sọ̀rọ̀,+ kí n sì polongo ìhìn rere nípa ohun wọ̀nyí fún ọ. 20  Ṣùgbọ́n, wò ó! ìwọ yóò dákẹ́+ láìlèsọ̀rọ̀ títí di ọjọ́ tí ohun wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, nítorí pé ìwọ kò gba àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́, èyí tí a óò mú ṣẹ ní àkókò wọn tí a ti yàn.” 21  Láàárín àkókò náà, àwọn ènìyàn náà ń bá a lọ ní dídúró de Sekaráyà,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì nítorí pípẹ́ tí ó ń pẹ́ nínú ibùjọsìn. 22  Ṣùgbọ́n nígbà tí ó jáde wá, kò lè bá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n sì róye pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ìran kan tí ó ju ti ẹ̀dá lọ+ nínú ibùjọsìn; ó sì ń ṣe àmì sí wọn, ṣùgbọ́n ó yadi síbẹ̀. 23  Wàyí o, nígbà tí àwọn ọjọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn pé,+ ó lọ sí ilé rẹ̀. 24  Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ wọ̀nyí, Èlísábẹ́tì aya rẹ̀ lóyún;+ ó sì fi ara rẹ̀ pa mọ́ fún oṣù márùn-ún, ó wí pé: 25  “Èyí ni ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà bá mi lò ní ọjọ́ wọ̀nyí nígbà tí ó ti fún mi ní àfiyèsí rẹ̀ láti mú ẹ̀gàn mi kúrò láàárín àwọn ènìyàn.”+ 26  Ní oṣù kẹfà rẹ̀, a rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì+ jáde láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sí ìlú ńlá kan ní Gálílì tí a ń pè ní Násárétì, 27  sí wúńdíá kan tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jósẹ́fù ní ilé Dáfídì; orúkọ wúńdíá+ náà sì ni Màríà.+ 28  Nígbà tí ó sì wọlé síwájú rẹ̀, ó wí pé: “Kú déédéé ìwòyí o,+ ẹni tí a ṣe ojú rere sí lọ́nà gíga, Jèhófà+ wà pẹ̀lú rẹ.”+ 29  Ṣùgbọ́n àsọjáde náà yọ ọ́ lẹ́nu gidigidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí irú ìkíni tí èyí lè jẹ́. 30  Nítorí náà, áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, Màríà, nítorí ìwọ ti rí ojú rere+ lọ́dọ̀ Ọlọ́run; 31  sì wò ó! ìwọ yóò lóyún nínú ilé ọlẹ̀ rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan,+ ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.+ 32  Ẹni yìí yóò jẹ́ ẹni ńlá,+ a ó sì máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ;+ Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́+ Dáfídì baba rẹ̀+ fún un, 33  yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.”+ 34  Ṣùgbọ́n Màríà sọ fún áńgẹ́lì náà pé: “Báwo ni èyí yóò ṣe rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí èmi kò ti ń ní ìbádàpọ̀+ kankan pẹ̀lú ọkùnrin?” 35  Ní ìdáhùn, áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Ẹ̀mí mímọ́+ yóò bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́. Nítorí ìdí èyí pẹ̀lú, ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́,+ Ọmọ Ọlọ́run.+ 36  Àti pé, wò ó! Èlísábẹ́tì ìbátan rẹ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú ti lóyún ọmọkùnrin kan, ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, èyí sì ni oṣù kẹfà fún un, ẹni tí àwọn ènìyàn ń pè ní àgàn;+ 37  nítorí pé lọ́dọ̀ Ọlọ́run kò sí ìpolongo kankan tí yóò jẹ́ aláìṣeéṣe.”+ 38  Nígbà náà ni Màríà wí pé: “Wò ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!+ Kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo rẹ.” Nígbà yẹn ni áńgẹ́lì náà lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 39  Nítorí náà, Màríà dìde ní ọjọ́ wọ̀nyí, ó sì lọ kánkán sí ilẹ̀ olókè ńláńlá, sí ìlú ńlá kan ní Júdà, 40  ó sì wọ ilé Sekaráyà, ó sì kí Èlísábẹ́tì. 41  Tóò, bí Èlísábẹ́tì ti gbọ́ ìkíni Màríà, ọmọ inú ilé ọlẹ̀ rẹ̀ sọ; Èlísábẹ́tì sì kún fún ẹ̀mí mímọ́, 42  ó sì fi igbe rara ké pé: “Alábùkún ni ìwọ láàárín àwọn obìnrin, alábùkún+ sì ni èso ilé ọlẹ̀ rẹ! 43  Nítorí náà, báwo ni ó ṣe jẹ́ tí àǹfààní yìí fi jẹ́ tèmi, láti rí i kí ìyá Olúwa mi+ wá sọ́dọ̀ mi? 44  Nítorí pé, wò ó! bí ìró ìkíni rẹ ti bọ́ sí etí mi, ọmọ inú ilé ọlẹ̀ mi sọ pẹ̀lú ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ńláǹlà.+ 45  Aláyọ̀ pẹ̀lú ni obìnrin náà tí ó gbà gbọ́, nítorí pé àṣepé+ ohun wọnnì tí a sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Jèhófà+ yóò wáyé.” 46  Màríà sì wí pé: “Ọkàn mi gbé Jèhófà ga lọ́lá,+ 47  ẹ̀mí mi kò sì lè dẹ́kun yíyọ ayọ̀ púpọ̀+ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi;+ 48  nítorí tí ó ti bojú wo ipò rírẹlẹ̀ ẹrúbìnrin rẹ̀.+ Nítorí, wò ó! láti ìsinsìnyí lọ, gbogbo ìran ni yóò máa pè mí ní aláyọ̀;+ 49  nítorí pé Ẹni alágbára ti ṣe àwọn ìṣe ńláǹlà fún mi, mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀;+ 50  àti pé láti ìran dé ìran àánú rẹ̀ ń bẹ lórí àwọn tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀.+ 51  Ó ti fi apá rẹ̀ ṣe iṣẹ́ alágbára ńlá,+ ó ti tú àwọn tí wọ́n jẹ́ onírera nínú ìpètepèrò ọkàn-àyà wọn+ ká kiri. 52  Ó ti rẹ àwọn ọkùnrin alágbára sílẹ̀+ láti orí ìtẹ́, ó sì gbé àwọn ẹni rírẹlẹ̀ ga;+ 53  ó ti fi àwọn ohun rere tẹ́ àwọn ẹni tí ebi ń pa lọ́rùn+ lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́, ó sì ti rán àwọn tí wọ́n ní ọlà lọ ní òfo.+ 54  Ó ti wá ṣe àrànṣe fún Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ̀,+ láti rántí àánú,+ 55  gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún àwọn baba ńlá wa, fún Ábúráhámù àti fún irú-ọmọ rẹ̀, títí láé.”+ 56  Lẹ́yìn náà, Màríà wà pẹ̀lú rẹ̀ fún nǹkan bí oṣù mẹ́ta, ó sì padà sí ilé tirẹ̀. 57  Àkókò wá tó nísinsìnyí fún Èlísábẹ́tì láti bímọ, ó sì bí ọmọkùnrin kan. 58  Àwọn aládùúgbò àti àwọn ìbátan rẹ̀ sì gbọ́ pé Jèhófà ti gbé àánú+ rẹ̀ ga lọ́lá sí i, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a yọ̀.+ 59  Ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n sì wá láti dádọ̀dọ́ ọmọ kékeré+ náà, wọ́n sì ti ń fẹ́ pè é ní orúkọ baba rẹ̀, Sekaráyà. 60  Ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ dáhùn, ó sì wí pé: “Rárá o! ṣùgbọ́n Jòhánù ni a ó máa pè é.” 61  Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé: “Kò sí ẹnì kan nínú àwọn ìbátan rẹ tí a fi orúkọ yìí pè.” 62  Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi àmì béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ ohun tí ó fẹ́ kí a pè é. 63  Ó sì béèrè fún wàláà kan, ó sì kọ ọ́ pé: “Jòhánù+ ni orúkọ rẹ̀.” Nígbà náà ni ẹnu ya gbogbo wọn. 64  Ní ìṣẹ́jú akàn, ẹnu rẹ̀ là,+ ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó ń fi ìbùkún fún Ọlọ́run. 65  Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń gbé ní àdúgbò wọn; àti ní gbogbo ilẹ̀ olókè ńláńlá ní Jùdíà, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a bẹ̀rẹ̀ sí sọ káàkiri, 66  gbogbo àwọn tí wọ́n sì gbọ́ fi í sínú ọkàn-àyà wọn,+ wọ́n ń sọ pé: “Ní ti gidi, kí ni ọmọ kékeré yìí yóò jẹ́?” Nítorí tí ọwọ́+ Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀ ní tòótọ́. 67  Sekaráyà baba rẹ̀ sì kún fún ẹ̀mí mímọ́,+ ó sì sọ tẹ́lẹ̀,+ pé: 68  “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ nítorí ó ti yí àfiyèsí rẹ̀, ó sì ti ṣe iṣẹ́ ìdáǹdè+ fún àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 69  Ó sì ti gbé ìwo+ ìgbàlà kan dìde fún wa ní ilé Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀, 70  gan-an gẹ́gẹ́ bí òun, láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ láti ìgbà láéláé,+ ti sọ̀rọ̀ 71  nípa ìgbàlà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa àti kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ó kórìíra wa;+ 72  láti ṣe iṣẹ́ àánú tí ó wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá wa àti láti rántí májẹ̀mú+ mímọ́ rẹ̀, 73  ìbúra tí òun búra fún Ábúráhámù baba ńlá wa,+ 74  láti yọ̀ǹda fún wa, lẹ́yìn tí a ti gbà wá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá,+ àǹfààní ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un+ láìbẹ̀rù 75  pẹ̀lú ìdúróṣinṣin àti òdodo níwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ wa.+ 76  Ṣùgbọ́n ní ti ìwọ, ọmọ kékeré, wòlíì Ẹni Gíga Jù Lọ ni a ó máa pè ọ́, nítorí tí ìwọ yóò lọ ṣáájú níwájú Jèhófà láti mú kí àwọn ọ̀nà rẹ̀ wà ní sẹpẹ́,+ 77  láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ nípasẹ̀ ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn,+ 78  nítorí ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Ọlọ́run wa. Pẹ̀lú ìyọ́nú yìí, ojúmọ́+ kan yóò bẹ̀ wá wò láti ibi gíga lókè,+ 79  láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí wọ́n jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú,+ láti fi àṣeyọrí sí rere darí ẹsẹ̀ wa lọ́nà àlàáfíà.” 80  Ọmọ kékeré náà sì ń bá a lọ ní dídàgbà+ àti ní dídi alágbára nínú ẹ̀mí, ó sì ń bá a lọ ní wíwà nínú àwọn aṣálẹ̀ títí di ọjọ́ fífi ara rẹ̀ hàn ní gbangba fún Ísírẹ́lì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé