Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 8:1-36

8  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Mú Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀+ àti àwọn ẹ̀wù+ àti òróró àfiyanni+ àti akọ màlúù ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti àgbò méjì  àti apẹ̀rẹ̀ àkàrà aláìwú,+  kí o sì mú kí gbogbo àpéjọ náà péjọ pọ̀+ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.”+  Nígbà náà ni Mósè ṣe gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún un, àpéjọ náà sì péjọ pọ̀ sí ẹnu ọ̀nà+ àgọ́ ìpàdé.  Wàyí o, Mósè wí fún àpéjọ náà pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà pa láṣẹ láti ṣe.”+  Bẹ́ẹ̀ ni Mósè mú Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sún mọ́ tòsí, ó sì fi omi+ wẹ̀ wọ́n.+  Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi aṣọ+ wọ̀ ọ́, ó sì dì í ní ìgbàjá,+ ó sì fi aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá+ wọ̀ ọ́, ó sì fi éfódì+ wọ̀ ọ́, ó sì fi àmùrè+ éfódì dì í ní ìgbàjá, ó sì dì í pinpin mọ́ ọn.  Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi aṣọ ìgbàyà+ wọ̀ ọ́, ó sì fi Úrímù àti Túmímù sí aṣọ ìgbàyà náà.+  Lẹ́yìn náà, ó fi láwàní+ wé orí rẹ̀, ó sì fi àwo wúrà dídán, àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́,+ sára láwàní náà ní iwájú, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 10  Wàyí o, Mósè mú òróró àfiyanni, ó sì fòróró yan àgọ́ ìjọsìn+ àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, ó sì sọ wọ́n di mímọ́. 11  Lẹ́yìn ìyẹn, ó wọ́n lára rẹ̀ ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ ní ìgbà méje sórí pẹpẹ, ó sì fòróró yan pẹpẹ+ àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀ àti bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀ láti sọ wọ́n di mímọ́. 12  Níkẹyìn, ó dà lára òróró àfiyanni náà sí orí Áárónì, ó sì fòróró yàn án láti sọ ọ́ di mímọ́.+ 13  Lẹ́yìn náà ni Mósè mú àwọn ọmọkùnrin Áárónì sún mọ́ tòsí,+ ó sì fi aṣọ wọ̀ wọ́n, ó sì dì wọ́n ní ìgbàjá,+ ó sì fi gèlè+ wé wọn lórí, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 14  Lẹ́yìn náà, ó fa akọ màlúù+ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá sókè, Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gbé ọwọ́ wọn lé orí+ akọ màlúù ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà. 15  Mósè sì tẹ̀ síwájú láti pa+ á, ó sì mú ẹ̀jẹ̀+ rẹ̀, ó sì fi ìka rẹ̀ fi í sára àwọn ìwo pẹpẹ yíká-yíká, ó sì wẹ pẹpẹ náà mọ́ gaara kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà ni ó dà sí ìhà ìsàlẹ̀ pẹpẹ, kí ó lè sọ ọ́ di mímọ́ láti ṣe ètùtù+ lórí rẹ̀. 16  Lẹ́yìn ìyẹn, ó mú gbogbo ọ̀rá tí ó wà lára ìfun àti àmọ́ ara ẹ̀dọ̀ àti kíndìnrín méjèèjì  àti ọ̀rá wọn, Mósè sì mú wọn rú èéfín lórí pẹpẹ.+ 17  Akọ màlúù náà àti awọ rẹ̀ àti ẹran rẹ̀ àti imí rẹ̀ ni ó sì mú kí a fi iná sun ní òde ibùdó,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 18  Wàyí ó, ó mú àgbò ọrẹ ẹbọ sísun náà sún mọ́ tòsí, Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gbé ọwọ́ wọn lé orí àgbò náà.+ 19  Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè pa á, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí pẹpẹ yíká-yíká.+ 20  Ó sì gé àgbò náà sí àwọn ègé rẹ̀,+ Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí mú orí àti àwọn ègé náà àti ọ̀rá líle rú èéfín. 21  Ó sì fi omi fọ ìfun àti tete, lẹ́yìn náà, Mósè sì mú odindi àgbò náà rú èéfín lórí pẹpẹ.+ Ọrẹ ẹbọ sísun fún òórùn amáratuni ni.+ Ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà ni, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 22  Lẹ́yìn náà, ó mú àgbò kejì, àgbò ìfinijoyè,+ sún mọ́ tòsí, Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gbé ọwọ́ wọn lé orí àgbò náà. 23  Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè pa á, ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó sì fi í sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún Áárónì àti sí àtàǹpàkò ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún.+ 24  Lẹ́yìn èyí, Mósè mú àwọn ọmọkùnrin Áárónì sún mọ́ tòsí, ó sì fi lára ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ etí wọn ọ̀tún àti sí àtàǹpàkò ọwọ́ wọn ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ wọn ọ̀tún: ṣùgbọ́n Mósè wọ́n ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sórí pẹpẹ yíká-yíká.+ 25  Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀rá àti ìrù ọlọ́ràá àti gbogbo ọ̀rá tí ó wà lára ìfun,+ àti àmọ́ ara ẹ̀dọ̀ àti kíndìnrín méjèèjì  àti ọ̀rá wọn àti ẹsẹ̀ ọ̀tún.+ 26  Àti láti inú apẹ̀rẹ̀ àkàrà aláìwú tí ó wà níwájú Jèhófà, ó mú àkàrà aláìwú kan onírìísí òrùka+ àti búrẹ́dì kan onírìísí òrùka, tí a fi òróró sí+ àti àdíngbẹ àkàrà pẹlẹbẹ kan.+ Lẹ́yìn náà, ó kó wọn sórí ọ̀rá àti ẹsẹ̀ ọ̀tún náà. 27  Lẹ́yìn ìyẹn, ó kó gbogbo wọn sórí àtẹ́lẹwọ́ Áárónì àti àtẹ́lẹwọ́ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fì wọ́n síwá-sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì níwájú Jèhófà.+ 28  Lẹ́yìn náà, Mósè kó wọn kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ wọn, ó sì mú wọn rú èéfín lórí pẹpẹ ní orí ọrẹ ẹbọ sísun.+ Wọ́n jẹ́ ẹbọ ìfinijoyè+ fún òórùn amáratuni.+ Ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà ni.+ 29  Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí mú igẹ̀,+ ó sì fì í síwá-sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì níwájú Jèhófà.+ Láti inú àgbò ìfinijoyè, ó di ìpín+ fún Mósè, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 30  Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè mú lára òróró àfiyanni+ àti lára ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ, ó sì wọ́n ọn ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ sára Áárónì àti ẹ̀wù rẹ̀ àti sára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ẹ̀wù àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Nípa báyìí, ó sọ Áárónì àti ẹ̀wù rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ẹ̀wù àwọn ọmọkùnrin rẹ̀+ pẹ̀lú rẹ̀ di mímọ́.+ 31  Lẹ́yìn náà, Mósè sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ se+ ẹran náà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ibẹ̀ sì ní kí ẹ ti jẹ ẹ́+ àti búrẹ́dì tí ó wà nínú apẹ̀rẹ̀ ìfinijoyè náà, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti pàṣẹ fún mi, pé, ‘Kí Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ ẹ́.’ 32  Ohun tí ó bá sì ṣẹ́ kù nínú ẹran náà àti búrẹ́dì náà ni kí ẹ fi iná sun.+ 33  Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ jáde kúrò ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje,+ títí di ọjọ́ tí àwọn ọjọ́ ìfinijoyè yín yóò fi pé, nítorí yóò gba ọjọ́ méje láti fi agbára kún ọwọ́ yín.+ 34  Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe é ní òní yìí ni Jèhófà pàṣẹ pé kí a ṣe é láti ṣe ètùtù fún yín.+ 35  Ẹ ó sì wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé ní ọ̀sán àti ní òru fún ọjọ́ méje,+ kí ẹ sì pa ìṣọ́ àìgbọ́dọ̀máṣe fún Jèhófà mọ́,+ kí ẹ má bàa kú; nítorí bẹ́ẹ̀ ni a pàṣẹ fún mi.” 36  Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé