Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 7:1-38

7  “‘Èyí sì ni òfin ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi:+ Ohun mímọ́ jù lọ ni.+  Ibi+ tí wọ́n ti ń pa ọrẹ ẹbọ sísun déédéé ni kí wọ́n ti pa ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi, kí a sì wọ́n+ ẹ̀jẹ̀+ rẹ̀ sórí pẹpẹ yíká-yíká.  Ní ti gbogbo ọ̀rá rẹ̀,+ òun yóò mú ìrù ọlọ́ràá àti ọ̀rá tí ó bo ìfun wá láti ara rẹ̀,  àti kíndìnrín méjì  àti ọ̀rá tí ó wà lára wọn, bí èyí tí ó wà níbi abẹ́nú. Àti ní ti àmọ́ tí ó wà lára ẹ̀dọ̀, kí ó mú un kúrò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín náà.+  Kí àlùfáà sì mú wọn rú èéfín lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà.+ Ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi ni.  Olúkúlùkù ọkùnrin láàárín àwọn àlùfáà ni kí ó jẹ ẹ́.+ Ibi mímọ́ ni kí a ti jẹ ẹ́. Ohun mímọ́ jù lọ ni.+  Bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi. Òfin kan ṣoṣo ni ó wà fún wọn.+ Àlùfáà tí ó fi ṣe ètùtù, tirẹ̀ ni yóò dà.  “‘Ní ti àlùfáà tí ó mú ọrẹ ẹbọ sísun ti ènìyàn èyíkéyìí wá, awọ+ ọrẹ ẹbọ sísun tí ó mú wá fún àlùfáà yóò di tirẹ̀.  “‘Gbogbo ọrẹ ẹbọ ọkà tí a bá sì yan nínú ààrò+ àti gbogbo èyí tí a ṣe nínú kẹ́tùrù jíjinnú+ àti nínú agbada+ jẹ́ ti àlùfáà tí ó mú un wá. Yóò di tirẹ̀.+ 10  Ṣùgbọ́n gbogbo ọrẹ ẹbọ ọkà tí a fi òróró+ rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ tàbí gbígbẹ+ yóò wà fún gbogbo àwọn ọmọkùnrin Áárónì, fún ẹnì kìíní bí ti ẹnì kejì . 11  “‘Wàyí ó, èyí ni òfin ẹbọ ìdàpọ̀+ tí ẹnikẹ́ni yóò mú wá fún Jèhófà: 12  Bí òun bá mú un wá láti fi ọpẹ́ hàn,+ nígbà náà, kí ó mú ẹbọ ìdúpẹ́ wá pa pọ̀ pẹ̀lú àkàrà aláìwú onírìísí òrùka, tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ àti àdíngbẹ àkàrà aláìwú tí ó rí pẹlẹbẹ, tí a fi òróró pa+ àti ìyẹ̀fun kíkúnná tí a pò pọ̀ dáadáa, tí a fi ṣe àkàrà onírìísí òrùka, tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. 13  Pa pọ̀ pẹ̀lú búrẹ́dì onírìísí òrùka, tí a fi ìwúkàrà sí,+ ni kí ó mú ọrẹ ẹbọ rẹ̀ wá, pa pọ̀ pẹ̀lú ẹbọ ìdúpẹ́ ti ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ̀. 14  Láti inú rẹ̀ sì ni kí ó ti mú ọ̀kọ̀ọ̀kan wá lára ọrẹ ẹbọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ìpín ọlọ́wọ̀ fún Jèhófà;+ ní ti àlùfáà tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹbọ ìdàpọ̀, yóò di tirẹ̀.+ 15  Àti ẹran ẹbọ ìdúpẹ́ ti ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ̀ ni kí a jẹ ní ọjọ́ tí ó rú ọrẹ ẹbọ rẹ̀. Kí ó má ṣe ṣẹ́ èyíkéyìí nínú rẹ̀ kù títí di òwúrọ̀.+ 16  “‘Bí ó bá sì jẹ́ pé ẹ̀jẹ́+ tàbí ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe+ ni ẹbọ ọrẹ ẹbọ rẹ̀, kí a jẹ ẹ́ ní ọjọ́ tí ó mú ẹbọ rẹ̀ wá, àti ní ọjọ́ kejì , ohun tí ó bá ṣẹ́ kù lára rẹ̀ ni a lè jẹ pẹ̀lú. 17  Ṣùgbọ́n ohun tí ó bá ṣẹ́ kù lára ẹran ẹbọ náà ní ọjọ́ kẹta ni kí a fi iná sun.+ 18  Àmọ́ ṣá o, bí a bá jẹ èyíkéyìí nínú ẹran ẹbọ ìdàpọ̀ ní ọjọ́ kẹta, ẹni tí ó mú un wá ni a kì yóò fi ojú rere tẹ́wọ́ gbà.+ A kì yóò kà á sí i lọ́rùn.+ Yóò di ohun tí a sọ di àìmọ́, ọkàn tí ó bá sì jẹ lára rẹ̀ yóò dáhùn fún ìṣìnà rẹ̀.+ 19  Ẹran tí ó bá sì kan ohunkóhun tí ó jẹ́ àìmọ́+ ni a kò gbọ́dọ̀ jẹ. Sísun ni kí a fi iná sun ún. Ní ti ẹran náà, gbogbo ẹni tí ó bá mọ́ ni ó lè jẹ ẹran náà. 20  “‘Ọkàn tí ó bà sì jẹ ẹran ẹbọ ìdàpọ̀ tí ó jẹ́ ti Jèhófà, nígbà tí àìmọ́ rẹ̀ wà lára rẹ̀, ọkàn yẹn ni kí a ké kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 21  Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ọkàn kan fara kan ohunkóhun tí ó jẹ́ aláìmọ́, ohun àìmọ́ ènìyàn+ tàbí ẹranko àìmọ́+ tàbí ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin èyíkéyìí tí ó jẹ́ àìmọ́,+ tí ó sì jẹ lára ẹran ẹbọ ìdàpọ̀ náà ní tòótọ́, èyí tí ó wà fún Jèhófà, ọkàn yẹn ni kí a ké kúrò nínú awọn ènìyàn rẹ̀.’” 22  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 23  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, pé, ‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá+ èyíkéyìí tí ó jẹ́ ti akọ màlúù tàbí ti ẹgbọrọ àgbò tàbí ti ewúrẹ́. 24  Wàyí o, ọ̀rá òkú ẹran àti ọ̀rá ẹran tí a fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ+ ni a lè lò fún ohun yòówù tí a lè ronú kàn, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́ rárá. 25  Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ọ̀rá ẹranko tí ó mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà, ọkàn tí ó bá jẹ ẹ́ ni kí a ké kúrò+ nínú awọn ènìyàn rẹ̀. 26  “‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀+ èyíkéyìí ní ibikíbi tí ẹ bá ń gbé, yálà ti ẹ̀dá abìyẹ́ tàbí ti ẹranko. 27  Ọkàn èyíkéyìí tí ó bá jẹ ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí, ọkàn yẹn ni kí a ké kúrò+ nínú awọn ènìyàn rẹ̀.’” 28  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 29  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, pé, ‘Ẹni tí ó bá mú ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ̀ wá fún Jèhófà yóò mú ọrẹ ẹbọ rẹ̀ wá fún Jèhófà láti inú ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ̀.+ 30  Ọwọ́ rẹ̀ ni kí ó fi mú ọ̀rá+ orí igẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí àwọn ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun sí Jèhófà. Kí ó mú un wá tòun ti igẹ̀ láti fì í síwá-sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì+ níwájú Jèhófà. 31  Kí àlùfáà sì mú ọ̀rá náà rú èéfín+ lórí pẹpẹ, ṣùgbọ́n kí igẹ̀ náà di ti Áárónì àti ti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.+ 32  “‘Kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ ọ̀tún fún àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìpín ọlọ́wọ̀+ láti inú àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ yín. 33  Ẹni náà lára àwọn ọmọkùnrin Áárónì tí ó mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ àti ọ̀rá náà wá, ni kí ẹsẹ̀ ọ̀tún náà di tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpín.+ 34  Nítorí igẹ̀ ọrẹ ẹbọ fífì+ àti ẹsẹ̀ ìpín ọlọ́wọ̀ náà ni mo gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti inú àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ wọn, èmi yóò sì fi wọ́n fún Áárónì àlùfáà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún àkókò tí ó lọ kánrin, láti ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 35  “‘Èyí ni ìpín àlùfáà fún Áárónì àti ìpín àlùfáà fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti inú àwọn ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun sí Jèhófà, ní ọjọ́ tí ó mú wọn wá+ láti ṣe àlùfáà fún Jèhófà, 36  gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ láti fi í fún wọn ní ọjọ́ tí ó fòróró yàn+ wọ́n láti àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ìlànà àgbékalẹ̀ ni fún àkókò tí ó lọ kánrin fún ìran-ìran wọn.’”+ 37  Èyí ni òfin nípa ọrẹ ẹbọ sísun,+ ọrẹ ẹbọ ọkà+ àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi+ àti ẹbọ ìfinijoyè+ àti ẹbọ ìdàpọ̀,+ 38  gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè ní Òkè Ńlá Sínáì+ ní ọjọ́ tí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti mú àwọn ọrẹ ẹbọ wọn wá fún Jèhófà ní aginjù Sínáì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé