Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 6:1-30

6  Jèhófà sì ń bá a lọ́ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkàn kan ṣẹ̀, ní ti pé ó hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà,+ tí ó sì tan+ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ nípa ohun kan tí ó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀ tàbí ohun ìfipamọ́ sọ́wọ́+ tàbí ìjanilólè tàbí tí ó lu ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní jì bìtì,+  tàbí tí ó rí ohun tí ó sọnù,+ tí ó sì ṣẹ̀tàn nípa rẹ̀ ní ti tòótọ́, tí ó sì búra èké+ lórí èyíkéyìí nínú gbogbo ohun tí ẹni náà bá ṣe, tí ó sì ṣẹ̀ nípasẹ̀ wọn;  nígbà náà, yóò sì ṣẹ̀lẹ̀ pé, bí ó bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì jẹ̀bi+ ní tòótọ́, kí ó dá ohun tí ó kó lọ nípasẹ̀ ìjanilólè padà tàbí ohun tí ó fi agbára gbà, èyí tí ó fi jì bìtì gbà, tàbí ohun tí ó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀, èyí tí a fi sábẹ́ àbójútó rẹ̀, tàbí ohun tí ó sọnù tí ó rí,  tàbí ohunkóhun mìíràn tí ó bá búra èké lé lórí, kí ó sì san àsanfidípò+ fún un ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye rẹ̀, kí ó sì fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un. Òun yóò sì fi í fún ẹni tí ó ni ín ní ọjọ́ tí a fi ẹ̀rí ìdánilójú ẹ̀bi rẹ̀ hàn.  Àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀, òun yóò mú àgbò tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá+ láti inú agbo ẹran wá fún Jèhófà, fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi,+ fún àlùfáà, ní ìbámu pẹ̀lú iye tí a dá lé e.  Kí àlùfáà sì ṣe ètùtù+ fún un níwájú Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì dárí rẹ̀ jì  í ní ti èyíkéyìí nínú gbogbo ohun tí ó bá ṣe tí ó yọrí sí ẹ̀bi.”  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Pàṣẹ fún Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, pé, ‘Èyí ni òfin ọrẹ ẹbọ sísun:+ Ọrẹ ẹbọ sísun yóò wà lórí ààrò tí ó wà lórí pẹpẹ láti òru mọ́jú títí di òwúrọ̀, kí iná pẹpẹ sì máa jó nínú rẹ̀. 10  Kí àlùfáà sì wọ aṣọ oyè rẹ̀ tí ó jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀,+ òun yóò sì wọ ṣòkòtò rẹ̀ àwọ̀tẹ́lẹ̀+ tí ó jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀. Lẹ́yìn náà, kí ó kó eérú ọlọ́ràá+ ti ọrẹ ẹbọ sísun tí iná ń jó déédéé lórí pẹpẹ, kí ó sì kó wọn sẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ. 11  Kí ó sì bọ́+ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wọ ẹ̀wù mìíràn, kí ó sì kó eérú ọlọ́ràá náà jáde sí ibi tí ó mọ́ ní òde ibùdó.+ 12  Kí iná tí ó wà lórí pẹpẹ máa jó lórí rẹ̀. Kò gbọ́dọ̀ kú. Kí àlùfáà sì máa jó igi+ lórí rẹ̀ ní òròòwúrọ̀, kí ó sì to ọrẹ ẹbọ sísun sórí rẹ̀, kí ó sì mú ọ̀rá ẹbọ ìdàpọ̀ rú èéfín lórí rẹ̀.+ 13  Kí iná+ máa jó lórí pẹpẹ nígbà gbogbo. Kò gbọ́dọ̀ kú. 14  “‘Wàyí o, èyí ni òfin ọrẹ ẹbọ ọkà:+ Ẹ̀yin ọmọkùnrin Áárónì, ẹ mú un wá síwájú Jèhófà, ní iwájú pẹpẹ. 15  Kí ọ̀kan lára wọn sì bu ẹ̀kúnwọ́ rẹ̀ kan lára ìyẹ̀fun kíkúnná ti ọrẹ ẹbọ ọkà àti lára òróró rẹ̀ àti gbogbo oje igi tùràrí tí ó wà lórí ọrẹ ẹbọ ọkà, kí ó sì mú un rú èéfín lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn amáratuni fún ohun ìránnilétí+ rẹ̀ sí Jèhófà. 16  Ohun tí ó bá sì ṣẹ́ kù lára rẹ̀ ni kí Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ.+ Kí a jẹ ẹ́ gẹ́gẹ́ bí àkàrà aláìwú+ ní ibi mímọ́. Kí wọ́n jẹ ẹ́ ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé. 17  A kò gbọ́dọ̀ fi ohunkóhun tí ó ní ìwúkàrà+ yan án. Mo ti fi í fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti inú àwọn ọrẹ ẹbọ mi tí a fi iná sun.+ Ohun mímọ́ jù lọ ni,+ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi. 18  Olúkúlùkù ọkùnrin+ láàárín àwọn ọmọ Áárónì ni kí ó jẹ ẹ́. Ó jẹ́ ohun tí a yọ̀ǹda fún àkókò tí ó lọ kánrin+ jálẹ̀ ìran-ìran yín, láti inú àwọn ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun sí Jèhófà. Ohun gbogbo tí ó bá fara kàn wọ́n yóò di mímọ́.’” 19  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 20  “Èyí ni ọrẹ ẹbọ+ Áárónì àti ti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, tí wọn yóò mú wá fún Jèhófà ní ọjọ́ tí a ó fòróró yàn án:+ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà+ ti ìyẹ̀fun kíkúnná gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà+ nígbà gbogbo, ààbọ̀ rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti ààbọ̀ rẹ̀ ní alẹ́. 21  Kí a fi òróró ṣe é lórí agbada.+ Ìwọ yóò mú un wá ní pípò pọ̀ dáadáa. Ìwọ yóò mú ọrẹ ọkà tí a fi ìyẹ̀fun àpòlẹ̀ ṣe, ti ọrẹ ẹbọ ọkà, wá ní wẹ́wẹ́, gẹ́gẹ́ bí òórùn amáratuni sí Jèhófà. 22  Àlùfáà, tí a fòróró yàn dípò rẹ̀ láti inú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀,+ ni yóò ṣe é. Ó jẹ́ ìlànà fún àkókò tí ó lọ kánrin: Gẹ́gẹ́ bí odindi ọrẹ ẹbọ ni a óò mú+ un rú èéfín sí Jèhófà. 23  Gbogbo ọrẹ ẹbọ ọkà àlùfáà+ ni kí ó jẹ́ odindi ọrẹ ẹbọ. A kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́.” 24  Jèhófà sì bá Mósè sọ̀rọ̀ síwájú sí i, pé: 25  “Bá Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀, pé, ‘Èyí ni òfin ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀:+ Ibi+ tí a ti ń pa ọrẹ ẹbọ sísun déédéé ni a ó ti pa ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú Jèhófà. Ohun mímọ́ jù lọ ni.+ 26  Àlùfáà tí ó fi í rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni yóò jẹ ẹ́.+ Ní ibi mímọ́+ ni a ó ti jẹ ẹ́ nínú àgbàlá+ àgọ́ ìpàdé. 27  “‘Ohun gbogbo tí ó bá fara kan ẹran rẹ̀ yóò di mímọ́,+ bí ẹnikẹ́ni bá sì wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ sára ẹ̀wù,+ ìwọ yóò fọ ohun tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ sí ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ ní ibi mímọ́.+ 28  Ìkòkò amọ̀+ tí a sè é nínú rẹ̀ ni kí a fọ́ túútúú. Ṣùgbọ́n bí a bá sè é nínú ìkòkò bàbà, nígbà náà, kí a fọ̀ ọ́ mọ́, kí a si fi omi ṣàn án. 29  “‘Olúkúlùkù ọkùnrin láàárín àwọn àlùfáà ni kí ó jẹ ẹ́.+ Ohun mímọ́ jù lọ ni.+ 30  Bí ó ti wù kí ó rí, a kò gbọ́dọ̀ jẹ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí a óò mú lára ẹ̀jẹ̀+ rẹ̀ wá sínú àgọ́ ìpàdé láti ṣe ètùtù ní ibi mímọ́. Sísun ni kí a fi iná sun ún.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé