Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Léfítíkù 5:1-19

5  “‘Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkàn+ kan ṣẹ̀ ní ti pé ó gbọ́ ìgégùn-ún tí a ṣe ní gbangba,+ tí ó sì ṣe ẹlẹ́rìí tàbí tí ó rí i, tàbí tí ó wá mọ̀ nípa rẹ̀, bí òun kò bá sọ ọ́ di mímọ̀,+ nígbà náà, kí ó dáhùn fún ìṣìnà rẹ̀.  “‘Tàbí nígbà tí ọkàn kan bá fara kan ohun àìmọ́ kan, yálà òkú ẹranko ìgbẹ́ tí ó jẹ́ aláìmọ́ tàbí òkú ẹran agbéléjẹ̀ tí ó jẹ́ aláìmọ́ tàbí òkú ẹ̀dá agbáyìn-ìn tí ó jẹ́ aláìmọ́,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fara sin fún un,+ síbẹ̀, òun jẹ́ aláìmọ́, ó sì jẹ̀bi.+  Tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó fara kan ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ní ti ohun àìmọ́+ èyíkéyìí tí ó jẹ́ tirẹ̀ tí ó fi lè di aláìmọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fara sin fún un, síbẹ̀ tí òun fùnra rẹ̀ sì ti wá mọ èyí, nígbà náà, ó ti jẹ̀bi.  “‘Tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkàn kan búra débi pé ó fi ètè rẹ̀ sọ̀rọ̀ láìronú+ láti ṣe ibi+ tàbí láti ṣe rere ní ti ohunkóhun tí ènìyàn lè sọ láìronú nínú gbólóhùn ìbúra,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fara sin fún un, síbẹ̀ tí òun fúnra rẹ̀ sì ti wá mọ èyí, nígbà náà, ó ti jẹ̀bi ní ti ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí.  “‘Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ó bá jẹ̀bi ní ti ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí, nígbà náà, kí ó jẹ́wọ́+ ọ̀nà tí òun gbà ṣẹ̀.  Kí ó sì mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi+ rẹ̀ wá fún Jèhófà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti dá, èyíinì ni, abo láti inú agbo ẹran, abo ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí abo+ ọmọ ewúrẹ́, fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.+  “‘Síbẹ̀síbẹ̀, bí agbára rẹ̀ kò bá ká àgùntàn,+ nígbà náà, kí ó mú oriri méjì + tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì wá fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá, ọ̀kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti ọ̀kan fún ọrẹ ẹbọ sísun.  Kí ó sì mú wọn wá fún àlùfáà, ẹni tí yóò kọ́kọ́ mú èyí tí ó wà fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá, tí yóò sì já+ a ní orí ní iwájú ọrùn rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó má ṣe já a sọ́tọ̀ọ̀tọ̀.  Kí ó sì wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, ṣùgbọ́n ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà ni a ó ro sí ìhà ìsàlẹ̀ pẹpẹ.+ Ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 10  Èyí èkejì ni òun yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun ní ìbámú pẹ̀lú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é;+ kí àlùfáà sì ṣe ètùtù+ fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti dá, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì dárí rẹ̀ jì  í.+ 11  “‘Wàyí o, bí ọwọ́ rẹ̀ kò bá ká+ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì , nígbà náà, kí ó mú ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà+ ìyẹ̀fun kíkúnná fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá. Kò gbọ́dọ̀ fi òróró+ sórí rẹ̀, kò sì gbọ́dọ̀ fi oje igi tùràrí sórí rẹ̀, nítorí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.+ 12  Kí ó sì mú un wá fún àlùfáà, kí àlùfáà sì bu ẹ̀kúnwọ́ rẹ̀ láti inú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìránnilétí+ rẹ̀, kí ó sì mú un rú èéfín lórí pẹpẹ lórí àwọn ọrẹ ẹbọ Jèhófà tí a fi iná sun.+ Ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.+ 13  Kí àlùfáà sì ṣe ètùtù+ fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti dá, èyíkéyìí nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì dárí rẹ̀ jì  í; yóò sì di ti àlùfáà+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ti ọrẹ ẹbọ ọkà.’” 14  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 15  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkàn kan hùwà àìṣòótọ́, ní ti pé ó ṣèèṣì ṣẹ̀ ní ti tòótọ́ sí àwọn ohun mímọ́ Jèhófà,+ nígbà náà, kí ó mú àgbò tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá láti inú agbo ẹran wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi+ fún Jèhófà, ní ìbámu pẹ̀lú iye tí a dá ní ṣékélì fàdákà,+ gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi. 16  Kí ó sì san àsanfidípò fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá sí ibi mímọ́, kí ó sì fi ìdá márùn-ún+ rẹ̀ kún un, kí ó sì fi í fún àlùfáà, kí àlùfáà lè fi àgbò ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi ṣe ètùtù+ fún un, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì dárí rẹ̀ jì  í.+ 17  “Bí ọkàn kan bá sì ṣẹ̀, ní ti pé ó ṣe ọ̀kan nínú gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí a má ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò mọ èyí,+ síbẹ̀, ó ti jẹ̀bi, kí ó sì dáhùn fún ìṣìnà rẹ̀.+ 18  Kí ó sì mú àgbò tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún àlùfáà láti inú agbo ẹran, fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi,+ ní ìbámu pẹ̀lú iye tí a dá lé e; kí àlùfáà sì ṣe ètùtù+ fún un nítorí àṣìṣe tí ó ṣe láìmọ̀ọ́mọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò mọ èyí, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì dárí rẹ̀ jì  í.+ 19  Ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi ni. Dájúdájú, ó ti jẹ̀bi+ lọ́dọ̀ Jèhófà.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé