Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 4:1-35

4  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, pé, ‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkàn+ kan ṣèèṣì+ ṣẹ̀ nínú èyíkéyìí lára ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí a má ṣe, tí ó sì ṣe ọ̀kan nínú wọn ní ti tòótọ́:  “‘Bí àlùfáà, ẹni àmì òróró,+ bá dẹ́ṣẹ̀,+ tí ó fi mú ẹ̀bi wá sórí àwọn ènìyàn, nígbà náà, kí ó mú ẹgbọrọ akọ màlúù kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀+ rẹ̀ tí ó ti dá.  Kí ó sì mú akọ màlúù náà wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé+ níwájú Jèhófà, kí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí+ akọ màlúù náà, kí ó sì pa akọ màlúù náà níwájú Jèhófà.  Kí àlùfáà náà, ẹni àmì òróró,+ sì bù lára ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà, kí ó sì gbé e wá sínú àgọ́ ìpàdé;  kí àlùfáà náà sì tẹ ìka+ rẹ̀ bọ ẹ̀jẹ̀ náà, kí ó sì wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ náà ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ ní ìgbà méje+ níwájú Jèhófà, ní iwájú aṣọ ìkélé ibi mímọ́.  Kí àlùfáà náà sì fi lára ẹ̀jẹ̀ náà sára àwọn ìwo+ pẹpẹ ti tùràrí onílọ́fínńdà níwájú Jèhófà, èyí tí ó wà nínú àgọ́ ìpàdé, kí ó sì da gbogbo ìyókù ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà sí ìhà ìsàlẹ̀+ pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun, tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.  “‘Ní ti gbogbo ọ̀rá akọ màlúù ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, òun yóò ṣí ọ̀rá tí ó bo ìfun kúrò lára rẹ̀, àní gbogbo ọ̀rá tí ó wà lára ìfun,+  àti kíndìnrín méjèèjì  àti ọ̀rá tí ó wà lára wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà níbi abẹ́nú. Àti ní ti àmọ́ tí ó wà lára ẹ̀dọ̀, òun yóò mú un kúrò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín náà.+ 10  Yóò jẹ́ ohun kan náà bí ohun tí a ṣí kúrò lára akọ màlúù ẹbọ ìdàpọ̀.+ Kí àlùfáà sì mú wọn rú èéfín lórí pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun.+ 11  “‘Ṣùgbọ́n ní ti awọ akọ màlúù náà àti gbogbo ẹran rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú orí rẹ̀ àti tete rẹ̀ àti ìfun rẹ̀ àti imí rẹ̀,+ 12  kí ó mú kí a gbé odindi akọ màlúù náà jáde sí òde ibùdó+ ní ibi tí ó mọ́, níbi tí a ń da eérú+ ọlọ́ràá sí, kí ó sì fi iná sun ún lórí igi nínú iná.+ Ní ibi tí a ń da eérú ọlọ́ràá sí ni kí a ti sun ún. 13  “‘Wàyí o, bí gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì pátá bá ṣe àṣìṣe,+ tí ọ̀ràn náà sì fara sin kúrò lójú ìjọ, ní ti pé wọ́n ti ṣe ọ̀kan nínú gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí a má ṣe, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ̀bi,+ 14  tí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ sí ọ̀kan lára àwọn nǹkan wọ̀nyí sì di mímọ̀,+ nígbà náà, kí ìjọ mú ẹgbọrọ akọ màlúù kan wá fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí wọ́n sì mú un wá síwájú àgọ́ ìpàdé. 15  Kí àwọn àgbà ọkùnrin àpéjọ náà sì gbé ọwọ́ wọn lé orí+ akọ màlúù náà níwájú Jèhófà, kí a sì pa akọ màlúù náà níwájú Jèhófà. 16  “‘Lẹ́yìn náà, kí àlùfáà, ẹni àmì òróró,+ mú lára ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà wá sínú àgọ́ ìpàdé.+ 17  Kí àlùfáà náà sì tẹ ìka rẹ̀ bọ ẹ̀jẹ̀ náà, kí ó sì wọ́n ọn ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ ní ìgbà méje níwájú Jèhófà, ní iwájú aṣọ ìkélé.+ 18  Kí ó sì fi lára ẹ̀jẹ̀ náà sára àwọn ìwo pẹpẹ+ tí ó wà níwájú Jèhófà, èyí tí ó wà nínú àgọ́ ìpàdé; kí ó sì da gbogbo ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìhà ìsàlẹ̀ pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun,+ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 19  Kí ó sì ṣí gbogbo ọ̀rá rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, kí ó sì mú un rú èéfín lórí pẹpẹ.+ 20  Kí ó sì ṣe sí akọ màlúù náà gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí akọ màlúù tọ̀hún tí ó jẹ́ ti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí ó ṣe sí i; kí àlùfáà sì ṣe ètùtù+ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì dárí rẹ̀ jì  wọ́n. 21  Kí ó sì mú kí a gbé akọ màlúù náà jáde sí òde ibùdó, kí a sì fi iná sun ún, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti fi iná jó akọ màlúù àkọ́kọ́.+ Ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni fún ìjọ.+ 22  “‘Nígbà tí ìjòyè+ kan bá ṣẹ̀, tí ó sì fi àìmọ̀ọ́mọ̀ ṣe ọ̀kan nínú gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ pa láṣẹ pé kí a má ṣe,+ tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ̀bi, 23  tàbí tí a bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí o ti ṣẹ̀ sí àṣẹ di mímọ̀ fún un,+ nígbà náà, kí ó mú akọ+ ọmọ ewúrẹ́ wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ rẹ̀, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá. 24  Kí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí+ ọmọ ewúrẹ́ náà, kí ó sì pa á ní ibi tí a tí ń pa ọrẹ ẹbọ sísun déédéé níwájú Jèhófà.+ Ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.+ 25  Kí àlùfáà sì fi ìka rẹ̀ mú lára ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó sì fi í sára àwọn ìwo+ pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun, kí ó sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ìhà ìsàlẹ̀ pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun. 26  Kí ó sì mú gbogbo ọ̀rá rẹ̀ rú èéfín lórí pẹpẹ, bí ti ọ̀rá ẹbọ ìdàpọ̀;+ kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀+ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì dárí rẹ̀ jì  í. 27  “‘Bí ọkàn èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá sì fi àìmọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ̀ nípa ṣíṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí a má ṣe, tí ó sì jẹ̀bi,+ 28  tàbí tí a sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti dá di mímọ̀ fún un, nígbà náà, kí ó mú abo+ ọmọ ewúrẹ́ wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ rẹ̀, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti dá. 29  Kí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí+ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí ó sì pa ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ní ibì kan náà bí ti ọrẹ ẹbọ sísun.+ 30  Kí àlùfáà sì fi ìka rẹ̀ mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kí ó sì fi í sára àwọn ìwo pẹpẹ+ ọrẹ ẹbọ sísun, kí ó sì da gbogbo ìyókù ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ìhà ìsàlẹ̀ pẹpẹ.+ 31  Kí ó sì mú gbogbo ọ̀rá+ rẹ̀ kúrò, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti mú ọ̀rá kúrò lára ẹbọ ìdàpọ̀;+ kí àlùfáà sì mú un rú èéfín lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn amáratuni sí Jèhófà;+ kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì dárí rẹ̀ jì  í.+ 32  “‘Ṣùgbọ́n bí òun yóò bá mú ọ̀dọ́ àgùntàn+ wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ rẹ̀ fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, abo ọ̀dọ́ àgùntàn tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá+ ni kí ó mú wá. 33  Kí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó sì pa á gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ní ibi tí a ti ń pa ọrẹ ẹbọ sísun déédéé.+ 34  Kí àlùfáà sì fi ìka rẹ̀ mú lára ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó sì fi í sára àwọn ìwo pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun,+ kí ó sì da gbogbo ìyókù ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ìhà ìsàlẹ̀ pẹpẹ. 35  Kí ó sì mú gbogbo ọ̀rá rẹ̀ kúrò gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe ń mú ọ̀rá ẹgbọrọ àgbò ẹbọ ìdàpọ̀ kúrò déédéé, kí àlùfáà sì mú wọn rú èéfín lórí pẹpẹ lórí àwọn ọrẹ ẹbọ Jèhófà tí a fi iná sun;+ kí àlùfáà sì ṣe ètùtù+ fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti dá, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì dárí rẹ̀ jì  í.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé