Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 3:1-17

3  “‘Bí ọrẹ ẹbọ rẹ̀ bá sì jẹ́ ẹbọ ìdàpọ̀,+ bí ó bá mú un wá láti inú ọ̀wọ́ ẹran, yálà ó jẹ́ akọ tàbí abo, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá+ ni kí ó mú wá síwájú Jèhófà.  Kí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí+ ọrẹ ẹbọ rẹ̀, kí a sì pa á ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé; kí àwọn ọmọkùnrin Áárónì, àwọn àlùfáà, sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí pẹpẹ yíká-yíká.  Kí ó sì mú lára ẹbọ ìdàpọ̀ náà wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà, èyíinì ni, ọ̀rá+ tí ó bo ìfun, àní gbogbo ọ̀rá tí ó wà lára ìfun,+  àti kíndìnrín méjèèjì + àti ọ̀rá tí ó wà lára wọn, gan-an bí èyí tí ó wà níbi abẹ́nú. Àti ní ti àmọ́ tí ó wà lára ẹ̀dọ̀, òun yóò mú un kúrò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín náà.  Kí àwọn ọmọkùnrin Áárónì+ sì mú un rú èéfín+ lórí pẹpẹ, lórí ẹbọ sísun tí ó wà lórí igi+ tí ó wà lórí iná, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni+ sí Jèhófà.  “‘Bí ọrẹ ẹbọ rẹ̀ bá sì wá láti inú agbo ẹran fún ẹbọ ìdàpọ̀ sí Jèhófà, akọ tàbí abo, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá+ ni kí ó mú wá.  Bí ó bá mú ẹgbọrọ àgbò wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ rẹ̀, nígbà náà, kí ó mú un wá síwájú Jèhófà.+  Kí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí+ ọrẹ ẹbọ rẹ̀, kí a sì pa+ á níwájú àgọ́ ìpàdé; kí àwọn ọmọkùnrin Áárónì sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí pẹpẹ yíká-yíká.  Láti inú ẹbọ ìdàpọ̀ sì ni kí ó ti mú ọ̀rá rẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà.+ Odindi ìrù ọlọ́ràá+ ni yóò gé kúrò nítòsí egungun ẹ̀yìn, àti ọ̀rá tí ó bo ìfun, àní gbogbo ọ̀rá tí ó wà lára ìfun,+ 10  àti kíndìnrín méjèèjì  àti ọ̀rá tí ó wà lára wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà níbi abẹ́nú. Àti ní ti àmọ́+ tí ó wà lára ẹ̀dọ̀, òun yóò kó o kúrò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín náà. 11  Kí àlùfáà sì mú un rú èéfín+ lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ,+ ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà. 12  “‘Bí ọrẹ ẹbọ rẹ̀ bá sì jẹ́ ewúrẹ́,+ nígbà náà, kí ó mú un wá síwájú Jèhófà. 13  Kí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí,+ kí a sì pa+ á níwájú àgọ́ ìpàdé; kí àwọn ọmọkùnrin Áárónì sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí pẹpẹ yíká-yíká. 14  Láti inú rẹ̀ sì ni kí ó ti mú wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ ẹbọ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà, ọ̀rá tí ó bo ìfun, àní gbogbo ọ̀rá tí ó wà lára ìfun,+ 15  àti kíndìnrín méjèèjì  àti ọ̀rá tí ó wà lára wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà níbi abẹ́nú. Àti ní ti àmọ́ tí ó wà lára ẹ̀dọ̀, òun yóò kó o kúrò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín náà. 16  Kí àlùfáà sì mú wọn rú èéfín lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ, ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun fún òórùn amáratuni. Gbogbo ọ̀rá jẹ́ ti Jèhófà.+ 17  “‘Ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin ni fún ìran-ìran yín, ní gbogbo ibi gbígbé yín: Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá èyíkéyìí tàbí ẹ̀jẹ̀+ èyíkéyìí rárá.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé