Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 27:1-34

27  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ènìyàn kan jẹ́ ẹ̀jẹ́+ àkànṣe nígbà tí ó ń fi àwọn ọkàn rúbọ sí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí iye tí a dá lé e,  tí iye tí a dá lé e sì jẹ́ ti ọkùnrin láti ẹni ogún ọdún títí dé ẹni ọgọ́ta ọdún, nígbà náà, kí iye tí a dá lé e jẹ́ àádọ́ta ṣékélì fàdákà gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́.  Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ obìnrin, nígbà náà, kí iye tí a dá lé e jẹ́ ọgbọ̀n ṣékélì.  Bí ọjọ́ orí náà bá sì jẹ́ láti ọdún márùn-ún títí dé ogún ọdún, nígbà náà, kí iye tí a dá lé ọkùnrin jẹ́ ogún ṣékélì àti fún obìnrin, ṣékélì mẹ́wàá.  Bí ọjọ́ orí náà bá sì jẹ́ láti oṣù kan títí dé ọdún márùn-ún, nígbà náà, kí iye tí a dá lé ọkùnrin jẹ́ ṣékélì márùn-ún+ fàdákà àti fún obìnrin, kí iye tí a dá lé e náà jẹ́ ṣékélì mẹ́ta fàdákà.  “‘Wàyí o, bí ọjọ́ orí náà bá jẹ́ láti ọgọ́ta ọdún sókè, bí ó bá jẹ́ ọkùnrin, nígbà náà, kí iye tí a dá lé e jẹ́ ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti fún obìnrin, ṣékélì mẹ́wàá.  Ṣùgbọ́n bí ó ba jẹ́ òtòṣì ju iye tí a dá lé e,+ nígbà náà, kí ó mú ẹni náà dúró níwájú àlùfáà, kí àlùfáà díye lé e.+ Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí agbára ẹni tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ lè gbé,+ àlùfáà yóò díye lé e.  “‘Bí ó bà sì jẹ́ ẹranko bí èyí tí a mú wá ní ọrẹ ẹbọ fún Jèhófà, gbogbo ohun tí ó lè fí fún Jèhófà yóò di ohun mímọ́.+ 10  Òun kò lè pààrọ̀ rẹ̀, òun kò lè ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ̀ ní fífi èyí tí ó dára dípò èyí tí ó burú tàbí fifi èyí tí ó burú dípò èyí tí ó dára. Ṣùgbọ́n bí ó bá ní láti ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ̀ rárá ní fífi ẹranko dípò ẹranko, nígbà náà, kí ohun náà àti ohun tí a fi ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ̀ di ohun mímọ́. 11  Bí ó bá sì jẹ́ ẹranko àìmọ́+ èyíkéyìí bí èyí tí a kò gbọ́dọ̀ mú wá ní ọrẹ ẹbọ fún Jèhófà,+ nígbà náà, kí ó mú ẹranko náà dúró níwájú àlùfáà.+ 12  Kí àlùfáà sì díye lé e, yálà ó dára tàbí ó burú. Gẹ́gẹ́ bí iye tí àlùfáà dá lé e,+ bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́. 13  Ṣùgbọ́n bí ó bá fẹ́ rà á padà rárá, nígbà náà, kí ó mú ìdá márùn-ún+ rẹ̀ wá ní àfikún sí iye tí a dá lé e. 14  “‘Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ènìyàn kan sọ ilé rẹ̀ di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ lójú Jèhófà, nígbà náà, kí àlùfáà ṣe ìdíyelé rẹ̀ yálà ó dára tàbí o búrú.+ Gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé tí àlùfáà ṣe nípa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí iye owó rẹ̀ jẹ́. 15  Ṣùgbọ́n bí olùsọdimímọ́ náà bá fẹ́ ra ilé rẹ̀ padà, nígbà náà, kí ó mú ìdá márùn-ún owó iye tí a dá lé e wá ní àfikún sí i;+ kí ó sì di tirẹ̀. 16  “‘Bí ó bá sì jẹ́ pé lára pápá rẹ̀ tí ó ní,+ ni ènìyàn kan yóò sọ di mímọ́ fún Jèhófà, nígbà náà, kí a fojú díwọ̀n iye rẹ̀ ní ìwọ̀n irúgbìn rẹ̀: bí ó bá jẹ́ òṣùwọ̀n hómérì+ irúgbìn ọkà bálì ni, nígbà náà, àádọ́ta ṣékélì fàdákà ni. 17  Bí ó ba sọ pápá ara rẹ̀ di mímọ́ láti ọdún Júbílì+ lọ, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ gẹ́gẹ́ bí iye tí a dá lé e. 18  Bí ó bá sì jẹ́ lẹ́yìn Júbílì ni ó sọ pápá ara rẹ̀ di mímọ́, nígbà náà, kí àlùfáà gbéṣirò lé iye owó náà fún un ní ìwọ̀n àwọn ọdún tí ó ṣẹ́ kù títí di ọdún Júbílì tí ń bọ̀, kí a sì ṣe ìyọkúrò nínú iye tí a dá lé e.+ 19  Ṣùgbọ́n bí olùsọdimímọ́ rẹ̀ bá ra pápá náà padà rárá, nígbà náà, kí ó mú ìdá márùn-ún owó iye tí a dá lé e wá ní àfikún sí i, kí ó sì dúró pa gẹ́gẹ́ bí tirẹ̀.+ 20  Wàyí o, bí òun kò bá ní ra pápá náà padà ṣùgbọ́n tí a bá ta pápá náà fún ènìyàn mìíràn, a kò gbọ́dọ̀ rà á padà mọ́. 21  Nígbà tí pápá náà bá bọ́ nígbà Júbílì, kí ó di ohun mímọ́ lójú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí pápá tí a yà sọ́tọ̀.+ Yóò di ti àlùfáà.+ 22  “‘Bí ó bá sì sọ pápá tí ó rà, tí kì í ṣe apá kan pápá ohun ìní rẹ̀,+ di mímọ́ fún Jèhófà, 23  nígbà náà, kí àlùfáà gbéṣirò lé iye ìdíyelé náà fún un títí di ọdún Júbílì, kí ó sì mú iye tí a dá lé e wá ní ọjọ́ náà.+ Ohun mímọ́ ni lójú Jèhófà.+ 24  Ní ọdún Júbílì, pápá náà yóò padà sí ọwọ́ ẹni tí ó ti rà á, sọ́dọ̀ ẹni tí ó ni ilẹ̀ náà.+ 25  “‘Wàyí o, gbogbo iye rẹ̀ ni kí a fojú díwọ̀n gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́. Kí ṣékélì náà jẹ́ ogún òṣùwọ̀n gérà.+ 26  “‘Kì kì àkọ́bí nínú ẹranko, tí a bí gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí fún Jèhófà,+ ènìyàn kankan kò gbọ́dọ̀ sọ ọ́ di mímọ́. Yálà akọ màlúù tàbí àgùntàn, ti Jèhófà ni.+ 27  Bí ó bá sì jẹ́ nínú àwọn ẹranko àìmọ́+ ni, kí ó sì tún un rà padà gẹ́gẹ́ bí iye tí a dá lé e, nígbà náà, kí ó mú ìdá márùn-ún rẹ̀ wá ní àfikún sí i.+ Ṣùgbọ́n bí a kò bá rà á padà, nígbà náà, kí a tà á gẹ́gẹ́ bí iye tí a dá lé e. 28  “‘Kì kì pé, ohun èyíkéyìí tí a yà sọ́tọ̀, tí ènìyàn kan lè yà sọ́tọ̀ fún ìparun+ fún Jèhófà láti inú ohun gbogbo tí ó ní, yálà nínú aráyé tàbí ẹranko tàbí nínú pápá tí ó jẹ́ ohun ìní rẹ̀, ni a kò gbọ́dọ̀ tà, a kò sì gbọ́dọ̀ ra ohun èyíkéyìí tí a yà sọ́tọ̀ padà.+ Ohun mímọ́ jù lọ ni lójú Jèhófà. 29  Ẹnikẹ́ni tí a bá yà sọ́tọ̀, tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun láti inú aráyé, ni a kò gbọ́dọ̀ tún rà padà.+ Kí a fi ikú pa á láìkùnà.+ 30  “‘Gbogbo ìdá mẹ́wàá+ ilẹ̀ náà, láti inú irúgbìn ilẹ̀ náà àti èso igi, jẹ́ ti Jèhófà. Ohun mímọ́ ni lójú Jèhófà. 31  Bí ènìyàn kan bá fẹ́ ra èyíkéyìí nínú ìdá mẹ́wàá rẹ̀ padà rárá, kí ó mú ìdá márùn-ún rẹ̀ wá ní àfikún sí i.+ 32  Ní ti gbogbo ìdá mẹ́wàá ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran, ohun gbogbo tí ó kọjá lábẹ́ ọ̀pá ìdaran,+ kí orí kẹwàá di ohun mímọ́ lójú Jèhófà. 33  Kí ó má ṣe ṣàyẹ̀wò yálà ó dára tàbí ó burú, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe pààrọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí yóò bá pààrọ̀ rẹ̀ rárá, nígbà náà, kí ohun náà àti ohun tí a fi pààrọ̀ rẹ̀ di ohun mímọ́.+ A kò gbọ́dọ̀ rà á padà.’” 34  Ìwọ̀nyí ni àṣẹ+ tí Jèhófà pa fún Mósè gẹ́gẹ́ bí àṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òkè Ńlá Sínáì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé