Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 25:1-55

25  Jèhófà sì wí fún Mósè síwájú sí i ní Òkè Ńlá Sínáì, pé:  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún yín,+ nígbà náà, kí ilẹ̀ náà pa sábáàtì mọ́ sí Jèhófà.+  Ọdún mẹ́fà ni kí o fi fún irúgbìn sí pápá rẹ, ọdún mẹ́fà sì ni kí o fi rẹ́wọ́ ọgbà àjàrà rẹ, kí o sì kó èso ilẹ̀ náà jọ.+  Ṣùgbọ́n ní ọdún keje kí sábáàtì ìsinmi pátápátá wà fún ilẹ̀ náà,+ sábáàtì sí Jèhófà. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn sí pápá rẹ, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ rẹ́wọ́ ọgbà àjàrà rẹ.  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ kárúgbìn èéhù láti inú àwọn kóró dídàálẹ̀ lára ìkórè rẹ, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe àkójọ èso àjàrà rẹ ti inú àjàrà tí a kò rẹ́wọ́ rẹ̀. Kí ọdún kan tí ó jẹ́ ti ìsinmi pátápátá wà fún ilẹ̀ náà.  Kí sábáàtì ilẹ̀ náà sì jẹ́ oúnjẹ fún yín, fún ìwọ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti lébìrà rẹ tí o háyà àti olùtẹ̀dó tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ, àwọn tí ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ rẹ,  àti fún ẹran agbéléjẹ̀ rẹ àti fún ẹranko ìgbẹ́ tí ó wà lórí ilẹ̀ rẹ. Kí gbogbo èso rẹ̀ wà fún jíjẹ.  “‘Kí o sì ka ọdún sábáàtì méje fún ara rẹ, ọdún méje ní ìlọ́po méje, iye ọjọ́ ọdún sábáàtì méje náà yóò sì jẹ́ ọdún mọ́kàn-dín-láàádọ́ta fún ọ.  Kí o sì mú kí ìwo tí ó ní ìró-ohùn kíkan dún+ ní oṣù keje, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù;+ ọjọ́ ètùtù+ ni kí ẹ mú kí ìwo dún ní gbogbo ilẹ̀ yín. 10  Kí ẹ sì sọ ọdún àádọ́ta di mímọ́, kí ẹ sì pòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira ní gbogbo ilẹ̀ náà fún àwọn olùgbé rẹ̀.+ Yóò di Júbílì+ fún yín, kí ẹ sì padà, olúkúlùkù sí ohun ìní rẹ̀, kí ẹ sì padà, olúkúlùkù sínú ìdílé rẹ̀.+ 11  Júbílì ni ohun tí ọdún àádọ́ta yóò dà fún yín.+ Ẹ kò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn tàbí kí ẹ kárúgbìn èéhù láti inú àwọn kóró dídàálẹ̀ tàbí kí ẹ ṣe àkójọ èso àjàrà tí ó jẹ́ ti àjàrà rẹ̀ tí a kò rẹ́wọ́ rẹ̀.+ 12  Nítorí pé Júbílì ni. Kí ó di ohun mímọ́ lójú yín. Ẹ lè máa jẹ ohun tí ilẹ̀ náà mú jáde+ láti inú pápá. 13  “‘Ní ọdún Júbílì yìí, kí ẹ padà, olúkúlùkù sí ohun ìní rẹ̀.+ 14  Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ ta ọjà fún ẹlẹgbẹ́ rẹ tàbí tí ẹ rà lọ́wọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, ẹ má ṣe àìtọ́ sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì .+ 15  Ní ìbámu pẹ̀lú iye ọdún tí ó tẹ̀ lé Júbílì ni kí o fi rà lọ́wọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ; ní ìbámu pẹ̀lú iye ọdún irè oko ni kí ó fi tà fún ọ.+ 16  Ní ìwọ̀n ọ̀pọ̀ iye ọdún ni kí ó mú iye tí a ó fi rà+ á pọ̀ sí i, ní ìwọ̀n ìkéréníye ọdún sì ni kí ó dín iye tí a ó fi rà á kù, nítorí pé iye irè oko ni òun yóò tà fún ọ. 17  Ẹnikẹ́ni nínú yín kò sì gbọ́dọ̀ ṣe àìtọ́ sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀,+ kí o sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ,+ nítorí pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.+ 18  Nítorí náà, kí ẹ mú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi ṣẹ, kí ẹ sì máa pa àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi mọ́, kí ẹ mú wọn ṣẹ. Nígbà náà, ó dájú pé ẹ óò máa gbé lórí ilẹ̀ náà ní ààbò.+ 19  Ní tòótọ́, ilẹ̀ náà yóò mú ìdìpọ̀ èso rẹ̀ wá,+ dájúdájú, ẹ ó sì jẹ àjẹyó, ẹ ó sì máa gbé ní ààbò lórí rẹ̀.+ 20  “‘Ṣùgbọ́n bí ẹ bá wí pé: “Kí ni àwa yóò jẹ ní ọdún keje níwọ̀n bí a kò ti lè fún irúgbìn tàbí kí a kó irè oko jọ?”+ 21  bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èmi yóò pàṣẹ ìbùkún fún yín dájúdájú ní ọdún kẹfà, òun yóò sì so irè oko rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta.+ 22  Kí ẹ sì fún irúgbìn ní ọdún kẹjọ, kí ẹ sì jẹ láti inú irè oko ẹ̀gbẹ títí di ọdún kẹsàn-án. Títí irè oko rẹ̀ yóò fi dé ni ẹ óò máa jẹ ẹ̀gbẹ. 23  “‘Bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́dọ̀ ta ilẹ̀ náà fún àkókò títí lọ fáàbàdà,+ nítorí pé tèmi ni ilẹ̀ náà.+ Nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ àtìpó àti olùtẹ̀dó ní ojú ìwòye mi.+ 24  Àti ní gbogbo ilẹ̀ ìní yín, kí ẹ yọ̀ǹda ẹ̀tọ́ rírà padà+ fún ilẹ̀ náà. 25  “‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin rẹ di òtòṣì, tí ó sì ní láti tà lára ohun ìní rẹ̀, kí olùtúnnirà tí ó bá a tan tímọ́tímọ́ sì wá, kí ó sì ra ohun tí arákùnrin rẹ̀ tà+ padà. 26  Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan kò ní olùtúnnirà, tí ọwọ́ rẹ̀ sì mú èrè wá, tí ó sì rí èyí tí ó tó fún ìtúnrà rẹ̀, 27  kí ó sì gbéṣirò lé àwọn ọdún náà láti ìgbà tí ó ti tà á, kí ó sì dá owó tí ó ṣẹ́ kù lórí rẹ̀ padà fún ẹni tí ó tà á fún, kí ó sì padà sí ohun ìní rẹ̀.+ 28  “‘Ṣùgbọ́n bí ọwọ́ rẹ̀ kò bá tẹ ohun tí ó tó láti fi fún un padà, ohun tí ó tà yóò sì máa wà lọ ní ọwọ́ ẹni tí ó rà á títí di ọdún Júbílì;+ kí ohun náà sì bọ́ nígbà Júbílì, kí ẹni náà sì padà sí ohun ìní rẹ̀.+ 29  “‘Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan ta ilé gbígbé nínú ìlú ńlá tí a mọ ògiri yí ká, kí ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti tún un rà máa bá a lọ títí ọdún kan yóò fi parí, láti ìgbà tí ó ti tà á; kí ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti tún un rà+ máa bá a lọ fún ọdún kan gbáko. 30  Ṣùgbọ́n bí a kò bá rà  á padà kí ọdún náà tó pé tán fún ẹni náà, kí ilé náà tí ó wà nínú ìlú ńlá tí ó ní ògiri wà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí dúkìá ẹni tí ó rà á fún àkókò títí lọ fáàbàdà ní ìran-ìran rẹ̀. Kí ó má ṣe bọ́ nígbà Júbílì. 31  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ilé ibi ìtẹ̀dó tí kò ní ògiri yí ká wọn ni kí a kà sí apá kan pápá ìgbèríko. Kí ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà+ máa wà lọ fún un, kí ó sì bọ́ nígbà Júbílì.+ 32  “‘Ní ti ìlú ńlá àwọn ọmọ Léfì pẹ̀lú àwọn ilé ìlú ńlá tí ó jẹ́ ohun ìní+ wọn, kí ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà máa wà lọ fún àwọn ọmọ Léfì fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 33  Nígbà tí a kò bá ra dúkìá àwọn ọmọ Léfì padà, kí ilé tí a tà nínú ìlú ńlá tí ohun ìní rẹ̀ wà sì bọ́ nígbà Júbílì;+ nítorí pé àwọn ilé ìlú ńlá àwọn ọmọ Léfì jẹ́ ohun ìní wọn ní àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 34  Síwájú sí i, pápá ilẹ̀ ìjẹko+ ìlú ńlá wọn ni a kò gbọ́dọ̀ tà, nítorí pé ohun ìní ni ó jẹ́ fún wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin. 35  “‘Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin rẹ di òtòṣì, tí ó sì wá jẹ́ pé nǹkan kò rọgbọ fún un ní ti ọ̀ràn ìnáwó nítòsí rẹ,+ kí o gbé e ró.+ Gẹgẹ́ bí àtìpó àti olùtẹ̀dó+ ni, kí ó máa wà láàyè nìṣó pẹ̀lú rẹ. 36  Má gba èlé àti ẹ̀dá owó lọ́wọ́ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n kí o máa bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ;+ kí arákùnrin rẹ sì máa wà láàyè nìṣó pẹ̀lú rẹ. 37  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi owó rẹ fún un ní èlé,+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ fi oúnjẹ rẹ fún un ní ẹ̀dá owó. 38  Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì láti fún yín ní ilẹ̀ Kénáánì,+ láti fi hàn pé èmi ni Ọlọ́run yín.+ 39  “‘Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin rẹ di òtòṣì nítòsí rẹ, tí ó sì ní láti ta ara rẹ̀ fún ọ,+ ìwọ kò gbọ́dọ̀ lò ó gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìnrú.+ 40  Kí ó wà pẹ̀lú rẹ bí lébìrà tí a háyà,+ bí olùtẹ̀dó. Kí ó máa sìn lọ́dọ̀ rẹ títí di ọdún Júbílì. 41  Kí ó sì jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì padà sínú ìdílé rẹ̀, kí ó sì padà sí ohun ìní àwọn baba ńlá rẹ̀.+ 42  Nítorí àwọn ni ẹrú mi tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Wọn kò gbọ́dọ̀ ta ara wọn ní ọ̀nà tí a gbà ń ta ẹrú. 43  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lọ́nà ìfìkà-gboni-mọ́lẹ̀,+ kí o sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ.+ 44  Ní ti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ tí ó di tìrẹ láti inú àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí yín ká, ìwọ lè ra ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin láti inú wọn. 45  Pẹ̀lúpẹ̀lù, láti inú àwọn ọmọ olùtẹ̀dó tí ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ yín,+ ẹ lè rà láti inú wọn, àti láti inú ìdílé wọn tí ó wà pẹ̀lú yín, àwọn tí a bí fún wọn ní ilẹ̀ yín; kí wọ́n sì di ohun ìní yín. 46  Kí ẹ sì ta àtaré wọn gẹ́gẹ́ bí ogún sí àwọn ọmọ yín lẹ́yìn yín láti jogún gẹ́gẹ́ bí ohun ìní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Ẹ lè lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́, ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀, ẹnì kìíní lórí ẹnì kejì  rẹ̀, lọ́nà ìfìkà-gboni-mọ́lẹ̀.+ 47  “‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọwọ́ àtìpó tàbí olùtẹ̀dó ní ọ̀dọ̀ rẹ di ọlọ́là, tí arákùnrin rẹ sì di òtòṣì nítòsí rẹ̀ tí ó sì ní láti ta ara rẹ̀ fún àtìpó tàbí olùtẹ̀dó ní ọ̀dọ̀ rẹ, tàbí fún mẹ́ńbà ìdílé àtìpó náà, 48  lẹ́yìn tí ó ti ta ara rẹ̀,+ ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà yóò máa wà lọ nínú ọ̀ràn tirẹ̀.+ Ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ lè rà á padà.+ 49  Tàbí arákùnrin òbí rẹ̀ tàbí ọmọkùnrin tí ó jẹ́ ti arákùnrin òbí rẹ̀ lè rà á padà, tàbí ẹbí tí ó jẹ́ ẹran ara rẹ̀,+ ẹnì kan láti inú ìdílé rẹ̀, lè rà á padà. “‘Tàbí tí ọwọ́ òun fúnra rẹ̀ bá di ọlọ́là, kí ó ra ara rẹ̀ padà.+ 50  Kí ó sì bá ẹni tí ó rà á ṣírò láti ọdún tí ó ti ta ara rẹ̀ fún un títí di ọdún Júbílì,+ kí owó títà á sì ṣe rẹ́gí pẹ̀lú iye ọdún+ náà. Ọ̀nà tí a gbà ń ṣírò àwọn ọjọ́ iṣẹ́ lébìrà tí a háyà ni kí ó fi máa wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 51  Bí ọdún púpọ̀ bá ṣì kù, ní ìwọ̀n iye wọn ni kí ó san owó ìtúnrà rẹ̀ láti inú owó tí a fi rà á. 52  Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé kìkì díẹ̀ ni ó kù nínú àwọn ọdún náà títí di ọdún Júbílì,+ nígbà náà, kí ó gbéṣirò lé e fún ara rẹ̀. Ní ìwọ̀n àwọn ọdún rẹ̀ ni kí ó san iye owó ìtúnrà rẹ̀. 53  Kí ó máa bá a lọ láti wà lọ́dọ̀ rẹ bí lébìrà tí a háyà+ láti ọdún dé ọdún. Òun kò gbọ́dọ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lọ́nà ìfìkà-gboni-mọ́lẹ̀+ lójú rẹ. 54  Àmọ́ ṣá o, bí òun kò bá lè ra ara rẹ̀ padà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí, nígbà náà, kí ó bọ́ nígbà ọdún Júbílì,+ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. 55  “‘Nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ẹrú mi. Àwọn ni ẹrú+ mi tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé