Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Léfítíkù 23:1-44

23  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Àwọn àjọyọ̀ abágbàyí+ ti Jèhófà tí ẹ ó pòkìkí+ jẹ́ àpéjọpọ̀ mímọ́. Ìwọ̀nyí ni àjọyọ̀ abágbàyí mi:  “‘Ọjọ́ mẹ́fà ni kí a fi ṣe iṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni sábáàtì ìsinmi pátápátá,+ àpéjọpọ̀ mímọ́. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí. Sábáàtì ni sí Jèhófà ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé.+  “‘Ìwọ̀nyí ni àjọyọ̀ abágbàyí+ ti Jèhófà, àwọn àpéjọpọ̀ mímọ́,+ tí ẹ ó pòkìkí ní àwọn àkókò wọn tí a yàn kalẹ̀:+  Ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù,+ láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì ni ìrékọjá+ fún Jèhófà.  “‘Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù yìí sì ni àjọyọ̀ àkàrà aláìwú fún Jèhófà.+ Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ àkàrà aláìwú.+  Ní ọjọ́ kìíní, kí ẹ ní àpéjọpọ̀ mímọ́.+ Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe òpò èyíkéyìí.  Ṣùgbọ́n kí ẹ mú ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà wá fún ọjọ́ méje. Ní ọjọ́ keje, àpéjọpọ̀ mímọ́ yóò wà. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe òpò èyíkéyìí.’”  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 10  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún yín, tí ẹ sì ti kórè rẹ̀, kí ẹ mú ìtí àkọ́so+ ìkórè yín wá sọ́dọ̀ àlùfáà. 11  Kí ó sì fi ìtí náà síwá-sẹ́yìn+ níwájú Jèhófà láti rí ìtẹ́wọ́gbà fún yín. Ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé sábáàtì gan-an ni kí àlùfáà fì í síwá-sẹ́yìn. 12  Ní ọjọ́ tí ẹ mú kí a fi ìtí náà síwá-sẹ́yìn ni kí ẹ fi ẹgbọrọ àgbò tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá rúbọ, ní ọdún rẹ̀ àkọ́kọ́, fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Jèhófà; 13  àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ̀, ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà, òórùn amáratuni; àti wáìnì ìlàrin òṣùwọ̀n hínì gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ohun mímu rẹ̀. 14  Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ jẹ búrẹ́dì kankan tàbí àyangbẹ ọkà tàbí ọkà tuntun títí di ọjọ́ náà gan-an,+ títí di ìgbà tí ẹ óò mú ọrẹ ẹbọ Ọlọ́run yín wá. Ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin ni fún ìran-ìran yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé. 15  “‘Kí ẹ sì ka sábáàtì méje+ fún ara yín láti ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé sábáàtì, láti ọjọ́ tí ẹ mú ìtí ọrẹ ẹbọ fífì wá. Kí wọ́n sì pé pérépéré. 16  Títí dé ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé sábáàtì keje ni kí ẹ kà á, àádọ́ta ọjọ́,+ kí ẹ sì mú ọrẹ ẹbọ ọkà+ tuntun wá fún Jèhófà. 17  Láti ibi gbígbé yín ni kí ẹ ti mú ìṣù búrẹ́dì méjì + wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì. Ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà ìyẹ̀fun kíkúnná ni kí wọ́n jẹ́. Kí a fi ìwúkàrà yan+ wọ́n, gẹ́gẹ́ bí àkọ́pọ́n èso fún Jèhófà.+ 18  Kí ẹ mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje,+ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dun kan, tí ara wọn dá ṣáṣá àti ẹgbọrọ akọ màlúù kan àti àgbò méjì wá pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣù búrẹ́dì . Kí wọ́n jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun sí Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ ọkà wọn àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu wọn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà. 19  Kí ẹ sì fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ewúrẹ́+ rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí ẹ sì fi akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì rúbọ, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìdàpọ̀.+ 20  Kí àlùfáà sì fì wọ́n síwá-sẹ́yìn+ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣù búrẹ́dì ti àkọ́pọ́n èso, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì níwájú Jèhófà, pa pọ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì náà. Kí wọ́n sì jẹ́ ohun mímọ́ lójú Jèhófà fún àlùfáà náà.+ 21  Kí ẹ sì pòkìkí+ ní ọjọ náà gan-an; àpéjọpọ̀ mímọ́ yóò wà fún yín. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe òpò èyíkéyìí. Ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin ni, ní gbogbo ibi gbígbé yín, fún ìran-ìran yín. 22  “‘Nígbà tí ẹ bá sì kórè ilẹ̀ yín, ìwọ kò gbọ́dọ̀ kórè eteetí pápá rẹ pátápátá nígbà tí o bá ń kárúgbìn, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ pèéṣẹ́ ìkórè rẹ.+ Kí o fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́+ àti àtìpó.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’” 23  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 24  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, pé, ‘Ní oṣù keje,+ ní ọjọ́ kìíní oṣù, kí ìsinmi pátápátá wà fún yín, ìrántí kan nípasẹ̀ fífun kàkàkí,+ àpéjọpọ̀ mímọ́.+ 25  Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe òpò èyíkéyìí, kí ẹ sì mú ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà wá.’” 26  Jèhófà sì sọ fún Mósè síwájú sí i, pé: 27  “Bí ó ti wù kí ó rí, ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni ọjọ́ ètùtù.+ Kí àpéjọpọ̀ mímọ́ wà fún yín, kí ẹ sì ṣẹ́ ọkàn yín níṣẹ̀ẹ́,+ kí ẹ sì mú ọrẹ ẹbọ+ àfinásun sí Jèhófà wá. 28  Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí ni ọjọ́ náà gan-an, nítorí pé ó jẹ́ ọjọ́ ètùtù+ láti ṣe ètùtù fún yín níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín; 29  nítorí pé gbogbo ọkàn tí a kò bá ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ ni ọjọ́ náà gan-an ni kí a ké kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 30  Ní ti ọkàn èyíkéyìí tí yóò ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí ní ọjọ́ náà gan-an, èmi yóò pa ọkàn yẹn run kúrò láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 31  Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí.+ Ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin ni fún ìran-ìran yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé. 32  Sábáàtì ìsinmi pátápátá ni fún yín,+ kí ẹ sì ṣẹ́ ọkàn yín níṣẹ̀ẹ́+ ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù ní ìrọ̀lẹ́. Láti ìrọ̀lẹ́ sí ìrọ̀lẹ́ ní kí ẹ pa sábáàtì yín mọ́.” 33  Jèhófà sì ń bá a lọ́ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 34  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, pé, ‘Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje yìí ni àjọyọ̀ àtíbàbà fún ọjọ́ méje sí Jèhófà.+ 35  Ọjọ́ kìíní ni àpéjọpọ̀ mímọ́. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe òpò èyíkéyìí. 36  Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà wá. Ní ọjọ́ kẹjọ kí àpéjọpọ̀ mímọ́ wà fún yín,+ kí ẹ sì mú ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà wá. Àpéjọ ọ̀wọ̀ ni. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe òpò èyíkéyìí. 37  “‘Ìwọ̀nyí ni àjọyọ̀ abágbàyí+ ti Jèhófà tí ẹ ó pòkìkí pé wọ́n jẹ́ àpéjọpọ̀ mímọ́,+ fún mímú ọrẹ ẹbọ àfinásun+ sí Jèhófà wá: ọrẹ ẹbọ sísun+ àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ fún ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ ní ìbámu pẹ̀lú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ojoojúmọ́, 38  ní àfikún sí àwọn sábáàtì Jèhófà+ àti ní àfikún sí àwọn ẹ̀bùn+ yín àti ní àfikún sí gbogbo ọrẹ ẹbọ ẹ̀jẹ́+ yín àti ní àfikún sí gbogbo ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe+ yín, tí ẹ ó fi fún Jèhófà. 39  Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje, nígbà tí ẹ bá kó èso ilẹ̀ náà jọ, kí ẹ ṣe àjọyọ̀+ Jèhófà fún ọjọ́ méje.+ Ní ọjọ́ kìíní, kí ìsinmi pátápátá wà, àti ní ọjọ́ kẹjọ, kí ìsinmi pátápátá wà.+ 40  Ní ọjọ́ kìíní kí ẹ̀yin fúnra yín sì mú èso igi dáradára, àwọn imọ̀ ọ̀pẹ+ àti àwọn ẹ̀tun ẹlẹ́ka púpọ̀ àti igi pọ́pílà àfonífojì olójú ọ̀gbàrá, kí ẹ sì yọ̀+ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje. 41  Kí ẹ sì ṣe ayẹyẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àjọyọ̀ fún Jèhófà fún ọjọ́ méje lọ́dún.+ Gẹ́gẹ́ bí ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin ní ìran-ìran yín, ni kí ẹ máa ṣe ayẹyẹ rẹ̀ ní oṣù keje. 42  Inú àtíbàbà ni kí ẹ gbé fún ọjọ́ méje.+ Gbogbo àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Ísírẹ́lì ni kí ó gbé inú àtíbàbà,+ 43  kí ìran-ìran yín lè mọ̀+ pé inú àwọn àtíbàbà ni mo mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé, nígbà tí mo mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’” 44  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa àwọn àjọyọ̀ abágbàyí+ ti Jèhófà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé