Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 22:1-33

22  Jèhófà sì wí fún Mósè síwájú sí i, pé:  “Bá Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀, kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ohun mímọ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n má sì sọ orúkọ+ mímọ́ mi di aláìmọ́ nínú àwọn ohun tí wọ́n sọ di mímọ́ fún mi.+ Èmi ni Jèhófà.  Sọ fún wọn pé, ‘Jálẹ̀ ìran-ìran yín, ẹnikẹ́ni nínú gbogbo ọmọ yín tí ó bá sún mọ́ àwọn ohun mímọ́, tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò sọ di mímọ́ fún Jèhófà, nígbà tí àìmọ́ rẹ̀ ṣì wà lára rẹ̀,+ ọkàn yẹn ni kí a ké kúrò níwájú mi. Èmi ni Jèhófà.  Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Áárónì tí ó bá jẹ́ adẹ́tẹ̀+ tàbí tí ó ní àsunjáde+ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú àwọn ohun mímọ́ títí di ìgbà tí ó bá mọ́,+ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá fara kan ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìmọ́ nípasẹ̀ ọkàn tí ó ti di olóògbé+ tàbí ọkùnrin tí àtọ̀ dà lára rẹ̀,+  tàbí ènìyàn tí ó bá fara kan ohun agbáyìn-ìn èyíkéyìí tí ó jẹ́ aláìmọ́ fún un+ tàbí tí ó fara kan ènìyàn tí ó jẹ́ aláìmọ́ fún un nítorí àìmọ́ rẹ̀ èyíkéyìí.+  Ọkàn tí ó bá fara kan irú ohun bẹẹ yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́, kò sì gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun nínú àwọn ohun mímọ́, ṣùgbọ́n kí ó wẹ ara rẹ̀ nínú omi.+  Nígbà tí oòrùn bá wọ̀, kí ó mọ́, lẹ́yìn ìgbà náà, ó lè jẹ nínú àwọn ohun mímọ́, nítorí pé oúnjẹ rẹ̀ ni.+  Bẹ́ẹ̀ ni òun kò gbọ́dọ̀ jẹ òkú ẹran èyíkéyìí tàbí ohunkóhun tí ẹranko ẹhànnà fà ya, láti di aláìmọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.+ Èmi ni Jèhófà.  “‘Kí wọ́n sì pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe wọn sí mi mọ́, kí wọ́n má bàa ru ẹ̀ṣẹ̀ nítorí rẹ̀, kí wọ́n sì kú+ nítorí rẹ̀, nítorí pé wọ́n sọ ọ́ di aláìmọ́. Èmi ni Jèhófà tí ń sọ wọ́n di mímọ́. 10  “‘Àjèjì  kankan kò sì gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó jẹ́ mímọ́.+ Olùtẹ̀dó sọ́dọ̀ àlùfáà tàbí lébìrà tí a háyà kò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó jẹ́ mímọ́. 11  Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àlùfáà kan ra ọkàn kan, ohun tí ó fi owó rẹ̀ rà, òun, nípa bẹ́ẹ̀, lè jẹ nínú rẹ̀. Ní ti àwọn ẹrú tí a bí ní ilé rẹ̀, àwọn, nípa bẹ́ẹ̀, lè jẹ nínú oúnjẹ rẹ̀.+ 12  Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọmọbìnrin àlùfáà di ti ọkùnrin tí ó jẹ́ àjèjì , òun, nípa bẹ́ẹ̀, kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú ọrẹ àwọn ohun mímọ́. 13  Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọmọbìnrin àlùfáà di opó tàbí ẹni tí a kọ̀ sílẹ̀, nígbà tí kò ní ọmọ, tí ó sì padà sí ilé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà èwe rẹ̀,+ ó lè jẹ nínú oúnjẹ baba rẹ̀;+ ṣùgbọ́n àjèjì  kankan kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́. 14  “‘Wàyí ó, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ènìyàn kan ṣèèṣì jẹ ohun mímọ́,+ nígbà náà, kí ó fi ìdá márùn-ún+ rẹ̀ kún un, kí ó sì fi ohun mímọ́ náà fún àlùfáà. 15  Nítorí kí àwọn àlùfáà má bàa sọ àwọn ohun mímọ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di aláìmọ́, èyí tí wọn yóò fi ṣe ìtọrẹ fún Jèhófà,+ 16  kí a sì mú wọn ru ìyà ẹ̀bi ní ti gidi, nítorí jíjẹ tí wọ́n jẹ àwọn ohun mímọ́ wọn; nítorí èmi ni Jèhófà tí ń sọ wọ́n di mímọ́.’” 17  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 18  “Bá Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ní ti ẹnikẹ́ni nínú ilé Ísírẹ́lì tàbí àtìpó kan ní Ísírẹ́lì tí ó bá mú ọrẹ ẹbọ rẹ̀ wá,+ fún èyíkéyìí nínú ẹ̀jẹ́+ wọn tàbí fún èyíkéyìí nínú ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe wọn,+ èyí tí wọ́n lè mú wá fún Jèhófà fún ọrẹ ẹbọ sísun, 19  láti rí ìtẹ́wọ́gbà+ fún yín, kí ó jẹ́ èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá,+ akọ láàárín ọ̀wọ́ ẹran, láàárín àwọn ẹgbọrọ àgbò àti láàárín àwọn ewúrẹ́. 20  Ohunkóhun tí àbùkù bá ti wà lára rẹ̀ ni ẹ kò gbọ́dọ̀ mú wá,+ nítorí pé kì yóò ṣiṣẹ́ láti rí ìtẹ́wọ́gbà fún yín. 21  “‘Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ènìyàn kan mú ẹbọ ìdàpọ̀+ wá fún Jèhófà láti san ẹ̀jẹ́+ tàbí ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe, kí ó jẹ́ èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá nínú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran, láti lè rí ìtẹ́wọ́gbà. Àbùkù kankan kò gbọ́dọ̀ sí lára rẹ̀. 22  Kò sí ti ọ̀ràn ìfọ́jú tàbí ìṣẹ́léegun tàbí ojú-ọgbẹ́ tàbí èkúrú tàbí ẹ̀yi tàbí làpálàpá,+ èyíkéyìí nínú ìwọnyí ni ẹ kò gbọ́dọ̀ mú wá fún Jèhófà, ọrẹ ẹbọ àfinásun+ èyíkéyìí nínú wọn ni ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fi sórí pẹpẹ sí Jèhófà. 23  Ní ti akọ màlúù tàbí àgùntàn tí ó ní ẹ̀yà ara tí ó gùn jù tàbí tí ó kúrú jù,+ ìwọ lè fi í ṣe ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe; ṣùgbọ́n fún ẹ̀jẹ́, a kì yóò fi ojú rere tẹ́wọ́ gbà á. 24  Ṣugbọn èyí tí a ti tẹ kórópọ̀n+ rẹ̀ tàbí tí a fọ́ tàbí tí a yọ kúrò tàbí tí a gé kúrò ni ẹ kò gbọ́dọ̀ mú wá fún Jèhófà, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fi wọ́n rúbọ ní ilẹ̀ yín. 25  Èyíkéyìí nínú gbogbo ìwọ̀nyí tí ó wá láti ọwọ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ni ẹ kò sì gbọ́dọ̀ mú wá gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ Ọlọ́run yín, nítorí pé ìdíbàjẹ́ wọn wà nínú wọn. Àbùkù+ wà lára wọn. A kì yóò fi ojú rere+ tẹ́wọ́ gbà wọ́n fún yín.’” 26  Jèhófà sì sọ fún Mósè síwájú sí i, pé: 27  “Bí a bá bí akọ màlúù kan tàbí ẹgbọrọ àgbò tàbí ewúrẹ́, nígbà náà, kí ó wà lábẹ́ ìyá rẹ̀ fún ọjọ́ méje,+ ṣùgbọ́n láti ọjọ́ kẹjọ lọ síwájú, a ó fi ojú rere tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ, ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà. 28  Ní ti akọ màlúù àti àgùntàn, ẹ kò gbọ́dọ̀ pa òun àti ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.+ 29  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ rú ẹbọ ìdúpẹ́ sí Jèhófà,+ kí ẹ rú u láti rí ìtẹ́wọ́gbà fún ara yín. 30  Ní ọjọ́ yẹ́n ni kí a jẹ ẹ́.+ Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi èyíkéyìí lára rẹ̀ sílẹ̀ títí di òwúrọ̀.+ Èmi ni Jèhófà. 31  “Kí ẹ máa pa àṣẹ mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn.+ Èmi ni Jèhófà. 32  Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́,+ kí a sì sọ mi di mímọ́ ní àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Èmi ni Jèhófà tí ń sọ yín di mímọ́,+ 33  Ẹni tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì láti fi ara mi hàn ní Ọlọ́run fún yín.+ Èmi ni Jèhófà.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé