Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 21:1-24

21  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Mósè pé: “Bá àwọn àlùfáà sọ̀rọ̀, àwọn ọmọkùnrin Áárónì, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ tìtorí ọkàn tí ó ti di olóògbé sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.+  Ṣùgbọ́n nítorí ẹbí rẹ̀ tí ó sún mọ́ ọn, nítorí ìyá rẹ̀ àti baba rẹ̀ àti ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀  àti arábìnrin rẹ̀, wúńdíá tí ó sún mọ́ ọn, tí kò tíì di ti ọkùnrin kan, nítorí rẹ̀ ni ó fi lè sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin.  Òun kò gbọ́dọ̀ sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin [nítorí obìnrin tí ó ti ní] olúwa ní àárín àwọn ènìyàn rẹ̀, kí ó sì sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́.  Wọn kò gbọ́dọ̀ mú orí ara wọn pá,+ ìpẹ̀kun irùngbọ̀n wọn ni wọn kò sì gbọ́dọ̀ gé,+ wọn kò sì gbọ́dọ̀ sín gbẹ́rẹ́ sí ara wọn.+  Kí wọ́n jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run wọn,+ kí wọ́n má sì sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di aláìmọ́,+ nítorí pé àwọn ni wọ́n ń mú àwọn ọrẹ ẹbọ Jèhófà tí a fi iná sun wá, oúnjẹ Ọlọ́run wọn;+ kí wọ́n sì jẹ́ mímọ́.+  Wọn kò gbọ́dọ̀ fẹ́ kárùwà+ tàbí obìnrin tí a tẹ́ lógo; wọn kò sì gbọ́dọ̀ fẹ́+ obìnrin tí a ti kọ̀ sílẹ̀+ kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀, nítorí pé àlùfáà jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run rẹ̀.  Nítorí náà, kí o sọ ọ́ di mímọ́,+ nítorí pé òun ni ó ń gbé oúnjẹ Ọlọ́run rẹ wá síwájú. Kí ó jẹ́ mímọ́ lójú rẹ,+ nítorí pé èmi Jèhófà, tí ń sọ yín di mímọ́, jẹ́ mímọ́.+  “‘Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọmọbìnrin àlùfáà sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa ṣíṣe iṣẹ́ kárùwà, baba rẹ̀ ni ó sọ di aláìmọ́. Kí a fi iná sun ọmọbìnrin náà.+ 10  “‘Ní ti àlùfáà àgbà nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, orí ẹni tí a ó da òróró àfiyanni sí,+ tí a sì fi agbára kún ọwọ́ rẹ̀ láti wọ ẹ̀wù náà,+ kí ó má ṣe jẹ́ kí orí òun wà láìtọ́jú,+ kí ó má sì ya ẹ̀wù rẹ̀.+ 11  Kí ó má sì dé ọ̀dọ̀ òkú ọkàn èyíkéyìí.+ Kí ó má sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin nítorí baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀. 12  Bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì jáde kúrò nínú ibùjọsìn, kí ó má sì sọ ibùjọsìn Ọlọ́run rẹ̀ di aláìmọ́,+ nítorí pé àmì ìyàsímímọ́, òróró àfiyanni Ọlọ́run rẹ̀,+ wà lórí rẹ̀. Èmi ni Jèhófà. 13  “‘Ní tirẹ̀, kí ó fẹ́ obìnrin tí ó wà ní ipò wúńdíá rẹ̀.+ 14  Ní ti opó tàbí obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ àti ẹni tí a tẹ́ lógo, kárùwà, kí ó má ṣe fẹ́ ìkankan nínú àwọn wọ̀nyí, ṣùgbọ́n kí ó fẹ́ wúńdíá ṣe aya láti inú àwọn ènìyàn rẹ̀. 15  Kí ó má sì sọ irú-ọmọ rẹ̀ di aláìmọ́ láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀,+ nítorí pé èmi ni Jèhófà tí ń sọ ọ́ di mímọ́.’”+ 16  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 17  “Bá Áárónì sọ̀rọ̀, pé, ‘Ọkùnrin èyíkéyìí nínú irú-ọmọ rẹ jálẹ̀ ìran-ìran wọn, tí àbùkù bá wà lára rẹ̀,+ kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀ wá síwájú.+ 18  Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin èyíkéyìí tí àbùkù wà lára rẹ̀ bá wà, kí ó má ṣe sún mọ́ tòsí: afọ́jú tàbí arọ tàbí tí imú rẹ̀ là tàbí tí ó ní ẹ̀yà ara tí ó gùn jù,+ 19  tàbí ọkùnrin tí egungun ẹsẹ̀ rẹ̀ ṣẹ́ tàbí tí egungun ọwọ́ rẹ̀ ṣẹ́, 20  tàbí abuké tàbí ẹni tí ó gbẹ tàbí tí ó ní òkùnrùn ojú tàbí tí ó ní ẹ̀yi tàbí làpálàpá tàbí tí kórópọ̀n rẹ̀ fọ́.+ 21  Ọkùnrin èyíkéyìí nínú irú-ọmọ Áárónì àlùfáà tí ó ní àbùkù lára kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé àwọn ọrẹ ẹbọ Jèhófà tí a fi iná sun wá síwájú.+ Àbùkù wà lára rẹ̀. Kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀ wá síwájú.+ 22  Ó lè máa jẹ oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀ láti inú àwọn ohun mímọ́ jù lọ+ àti láti inú àwọn ohun mímọ́.+ 23  Bí ó ti wù kí ó rí, kí ó má wọlé wá sí tòsí aṣọ ìkélé,+ kí ó má sì ṣe sún mọ́ pẹpẹ,+ nítorí pé àbùkù wà lára rẹ̀;+ kí ó má sọ ibùjọsìn mi di aláìmọ́,+ nítorí èmi ni Jèhófà tí ń sọ wọ́n di mímọ́.’”+ 24  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Mósè bá Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé